ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 6/1 ojú ìwé 21-25
  • Bí Àwọn Àgbàlagbà Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Nìṣó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Àwọn Àgbàlagbà Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Nìṣó
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Kì Í Pa Wíwà ní Tẹ́ńpìlì Jẹ”
  • Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nìṣó
  • Wọ́n Ń Sin Ọlọ́run Tọkàntọkàn Bó Tiẹ̀ Jẹ́ Pé Wọ́n Ti Di Àgbàlagbà
  • Ìfaradà Tí Àkọsílẹ̀ Rẹ̀ Kò Lè Pa Rẹ́
  • Básíláì Ọkùnrin Tó Mọ̀wọ̀n Ara Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ̀yin Àgbàlagbà—Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Kò Dàgbà Jù Láti Ṣiṣẹ́sin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Bá A Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Kí Àwọn Ọjọ́ Oníwàhálà Tó Dé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 6/1 ojú ìwé 21-25

Bí Àwọn Àgbàlagbà Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Nìṣó

“Àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà . . . yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú.”—SÁÀMÙ 92:13, 14.

1, 2. (a) Èrò wo ló sábà máa ń wá sáwọn èèyàn lọ́kàn nípa ọjọ́ ogbó? (b) Ìlérí wo ni Ìwé Mímọ́ ṣe nítorí àwọn ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà?

ỌJỌ́ OGBÓ. Èrò wo ni ọ̀rọ̀ yẹn gbé wá sí ọ lọ́kàn ná? Ṣé ara tó ń hun jọ ni? Ṣé etí tí kò gbọ́rọ̀ dáadáa mọ́ ni? Àbí ẹsẹ̀ tí kò lè rìn dáadáa mọ́? Àbí àwọn nǹkan mìíràn tí “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” máa ń fà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú Oníwàásù 12:1-7? Tó bá jẹ́ àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ni, a jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì láti fiyè sí bí Oníwàásù orí kejìlá ṣe ṣàpèjúwe ọjọ́ ogbó, pé kì í ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa, fẹ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nìyẹn, àmọ́ ó jẹ́ àbájáde tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ní lórí ara èèyàn.—Róòmù 5:12.

2 Dídi àgbà fúnra rẹ̀ kì í ṣe ègún, nítorí pé téèyàn bá ṣì wà láàyè, ọdún á máa gorí ọdún ni. Ká sòótọ́, dídi àgbà jẹ́ ohun tó dára tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ohun alààyè. Àwọn ohun búburú tá à ń rí, èyí tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti ń fà láti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún sẹ́yìn kò ní pẹ́ di ohun àtijọ́, gbogbo èèyàn tó jẹ́ onígbọràn yóò sì gbádùn ìgbésí ayé wọn bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí, láìsí ìrora ọjọ́ ogbó àti ikú mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Ìṣípayá 21:4, 5) Ní àkókò yẹn, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Àwọn arúgbó yóò tún padà ní “okun inú ti ìgbà èwe,” ara wọn yóò sì tún “jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe.” (Jóòbù 33:25) Àmọ́, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, gbogbo wa ni yóò máa bá ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù yí. Síbẹ̀, Jèhófà ń bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ bí wọ́n ti ń di àgbàlagbà.

3. Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni lè gbà “máa gbèrú nígbà orí ewú”?

3 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé “àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà . . . yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú.” (Sáàmù 92:13, 14) Onísáàmù lo àpèjúwe yìí láti jẹ́ ká rí òtítọ́ kan tó ṣe pàtàkì, ìyẹn ni pé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú, kí wọ́n máa gbèrú, kí wọ́n sì máa ṣàṣeyọrí nípa tẹ̀mí, bí ara wọn tilẹ̀ ń dara àgbà. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì àtàwọn tá à ń rí lóde òní ló fi hàn pé òótọ́ gidi lọ̀rọ̀ yìí.

“Kì Í Pa Wíwà ní Tẹ́ńpìlì Jẹ”

4. Báwo ni Ánà tó jẹ́ wòlíì obìnrin tó sì ti di arúgbó ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, báwo ni Ọlọ́run sì ṣe bù kún un?

4 Wo àpẹẹrẹ wòlíì obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ánà ni ọ̀rúndún kìíní. Nígbà tó wà lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ó jẹ́ ẹni tí “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ lóru àti lọ́sàn-án pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” Kò ṣeé ṣe fún Ánà láti máa gbé nínú tẹ́ńpìlì, nítorí pé bàbá rẹ̀ kì í ṣe ẹ̀yà Léfì, “ẹ̀yà Áṣérì” ni. Fojú inú wo ipa tí Ánà ti ní láti sà kó tó lè máa wà ní tẹ́ńpìlì lójoojúmọ́, láti àkókò ìsìn òwúrọ̀ títí di àkókò ìsìn ìrọ̀lẹ́! Àmọ́, Jèhófà bù kún Ánà gan-an nítorí ìfọkànsìn rẹ̀ yìí. Ó láǹfààní láti wà níbẹ̀ nígbà tí Jósẹ́fù àti Màríà gbé Jésù tó jẹ́ ọmọ ọwọ́ jòjòló wá sí tẹ́ńpìlì láti fi í fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Òfin ti wí. Nígbà tí Ánà rí Jésù, ó “bẹ̀rẹ̀ sí dá ọpẹ́ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà fún gbogbo àwọn tí ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.”—Lúùkù 2:22-24, 36-38; Númérì 18:6, 7.

5, 6. Ọ̀nà wo ni ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà lóde òní gbà ń fi hàn pé àwọn ní irú ẹ̀mí tí Ánà ní?

5 Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wa lónìí ló dà bíi Ánà nínú bí wọ́n ṣe ń lọ sípàdé déédéé, tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn gbàdúrà pé kí ìjọsìn tòótọ́ máa tẹ̀ síwájú, tó sì máa ń wù wọ́n gan-an láti wàásù ìhìn rere. Arákùnrin kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún tóun àti ìyàwó rẹ̀ sì máa ń wá sípàdé déédéé sọ pé: “A ti jẹ́ kí lílọ sípàdé mọ́ wa lára gan-an. Kò síbòmíràn tó máa ń wù wá láti wà. Ibi táwọn èèyàn Ọlọ́run bá wà la máa ń fẹ́ wà. Ibẹ̀ lọkàn wa ti máa ń balẹ̀.” Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere lèyí jẹ́ fún gbogbo wa!—Hébérù 10:24, 25.

6 Ohun tí arábìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jean, tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún, tó sì jẹ́ opó, máa ń sọ ní gbogbo ìgbà ni pé: “Bí mo bá rí ohunkóhun tó jẹ mọ́ ọ̀ràn Ìjọba Ọlọ́run, mo máa ń fẹ́ lọ́wọ́ sí i, kódà ó máa ń wù mí láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ìgbà míì wà tinú mi máa ń bà jẹ́, ṣùgbọ́n kí nìdí tí máa fi jẹ́ kínú àwọn tó yí mi ká bà jẹ́ nítorí pé inú mi kò dùn?” Tayọ̀tayọ̀ ló fi sọ pé lílọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì nítorí àwọn ohun tó ń gbéni ró nípa tẹ̀mí máa ń jẹ́ kóun láyọ̀ gan-an. Nígbà ìrìn àjò kan tó lọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó sọ fáwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò náà pé, “Mi o fẹ́ lọ máa wo àwọn nǹkan mèremère táwọn àlejò máa ń fẹ́ wò mọ́, òde ẹ̀rí ni mo fẹ́ lọ!” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jean ò mọ èdè tí wọ́n ń sọ ní ìlú náà sọ, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe fún un láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ọdún bíi mélòó kan ló fi bá ìjọ kan tó nílò ìrànlọ́wọ́ ṣiṣẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí gba pé kó kọ́ èdè tuntun, tó sì tún ní láti rìnrìn àjò wákàtí kan lọ sáwọn ìpàdé náà àti wákàtí kan padà wálé.

Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nìṣó

7. Nígbà tí Mósè di àgbàlagbà, ọ̀nà wo ló gbà fi hàn pé òun fẹ́ kí àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run dán mọ́rán sí i?

7 Béèyàn bá ṣe ń dàgbà sí i léèyàn ń gbọ́n sí i. (Jóòbù 12:12) Àmọ́ ọgbọ́n tẹ̀mí kì í ṣàdédé wá nítorí pé èèyàn lọ́jọ́ lórí. Nítorí náà, dípò káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ adúróṣinṣin gbára lé ìmọ̀ tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń làkàkà láti “pọ̀ sí i ní ẹ̀kọ́” bí ọdún ti ń gorí ọdún. (Òwe 9:9) Ẹni ọgọ́rin ọdún ni Mósè nígbà tí Jèhófà ni kó lọ ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta kan. (Ẹ́kísódù 7:7) Bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀ rárá kéèyàn lo iye ọdún tó pọ̀ tóyẹn nígbà ayé Mósè, nítorí ó kọ̀wé pé: “Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá.” (Sáàmù 90:10) Síbẹ̀, Mósè ò fìgbà kan ronú pé òun ti dàgbà kọjá ẹni tó lè kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn tó ti sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún, tó ní ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, tó sì tún bójú tó àwọn iṣẹ́ kàǹkà-kàǹkà, ó wá bẹ Jèhófà pé: “Jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, kí n lè mọ̀ ọ́.” (Ẹ́kísódù 33:13) Ńṣe ló máa ń wu Mósè kí àjọṣe àárín òun àti Jèhófà máa dán mọ́rán sí i nígbà gbogbo.

8. Kí ni Dáníẹ́lì ṣì ń ṣe kódà lẹ́yìn tó ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí wòlíì Dáníẹ́lì ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún, ó ṣì ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kínníkínní. Ohun tó fòye mọ̀ látinú ẹ̀kọ́ tó kọ́ nínú àwọn “ìwé,” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwé Léfítíkù, Aísáyà, Jeremáyà, Hóséà àti Ámósì, mú kó gba àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. (Dáníẹ́lì 9:1, 2) Jèhófà dáhùn àdúrà yẹn nípa jíjẹ́ kí Dáníẹ́lì mọ àwọn ohun tó jẹ mọ́ dídé Mèsáyà àti bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú.—Dáníẹ́lì 9:20-27.

9, 10. Kí làwọn àgbàlagbà kan ń ṣe kí ọpọlọ wọn lè máa jí pépé?

9 Bíi ti Mósè àti Dáníẹ́lì, àwa náà lè sapá láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó nípa fífọkàn sí àwọn nǹkan tẹ̀mí níwọ̀n ìgbà tá a bá ṣì lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Alàgbà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Worth, tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún, ń rí i dájú pé bí àwọn ìwé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń tẹ̀ bá ti ń jáde lòun ń kà wọ́n. (Mátíù 24:45) Ohun tó sọ ni pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ gan-an, inú mi sì máa ń dùn láti rí i bí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ṣe túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i.” (Òwe 4:18) Bákan náà ni Fred, tó ti lo ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Òun náà rí i pé jíjíròrò ẹsẹ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ máa ń gbé òun ró nípa tẹ̀mí gan-an. Ó ní: “Mo máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Bíbélì wà lọ́kàn mi nígbà gbogbo. Tó o bá lè mú kí Bíbélì nítumọ̀ sí ọ, tó o bá sì lè jẹ́ kí ohun tó ò ń kọ́ bá ‘àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera’ mu, wàá rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ náà kò ní rí gátagàta lọ́kàn rẹ. Wàá wá rí i bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe ń dán yinrin.”—2 Tímótì 1:13.

10 Pé èèyàn dàgbàlagbà kò sọ pé kéèyàn má lè kọ́ ohun tuntun àtàwọn ohun tó ṣòroó lóye. Àwọn èèyàn tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún, àwọn tó ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún, kódà àwọn tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún pàápàá ti kọ́ béèyàn ṣe ń mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kọ́ èdè tuntun pàápàá. Àwọn kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn ní onírúurú orílẹ̀-èdè. (Máàkù 13:10) Harry àti ìyàwó rẹ̀ ti lé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún nígbà tí wọ́n pinnu pé àwọn fẹ́ lọ máa wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Potogí. Harry sọ pé: “Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ohunkóhun téèyàn bá fàgbà ara ṣe kì í rọrùn.” Síbẹ̀, pẹ̀lú ìsapá àti ìfaradà, ó ṣeé ṣe fún wọn láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè Potogí. Fún ọ̀pọ̀ ọdún báyìí ni Harry ti ń sọ àsọyé láwọn ìpàdé àgbègbè tí wọ́n ń ṣe lédè Potogí.

11. Kí nìdí tá a fi ń mẹ́nu kan ohun táwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ti gbé ṣe?

11 Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo àgbàlagbà ni ara wọn le tí wọ́n sì wà nípò tí wọn ti lè ṣe irú nǹkan tó gba agbára bẹ́ẹ̀. Kí wá nìdí tá a fi ń sọ ohun táwọn àgbàlagbà kan ti gbé ṣe? Ó dájú pé a ò ní kí gbogbo àwọn àgbàlagbà sapá láti ṣe ohun kan náà o. Dípò ìyẹn, ohun tá a fẹ́ kí wọ́n ṣe ni ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé káwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù máa ṣe nípa àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Ó ní: “Bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.” (Hébérù 13:7) Nígbà tá a bá gbé àpẹẹrẹ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò, ìyẹn lè fún wa níṣìírí láti fara wé ìgbàgbọ́ tó lágbára tó ń mú káwọn àgbàlagbà wọ̀nyí ṣe bẹbẹ nínú iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run. Nígbà tí Harry tó ti dẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87] ń ṣàlàyé ohun tó sún un láti ṣe ohun tó ṣe yẹn, ó ní, “Mo fẹ́ lo ìyókù ìgbésí ayé mi lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, kí n sì rí i pé mo wúlò gan-an nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà níbi tágbára mi bá gbé e dé.” Inú Fred tá a mẹ́nu kàn tẹ́lẹ̀ máa ń dùn gan-an bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un ní Bẹ́tẹ́lì. Ohun tó sọ ni pé: “O ní láti wá ọ̀nà tó dára jù lọ láti sin Jèhófà kó o sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.”

Wọ́n Ń Sin Ọlọ́run Tọkàntọkàn Bó Tiẹ̀ Jẹ́ Pé Wọ́n Ti Di Àgbàlagbà

12, 13. Báwo ni Básíláì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run láìfi àgbàlagbà tó jẹ́ pè?

12 Kì í rọrùn rárá láti gbà pé ara ẹni ti ń dara àgbà. Síbẹ̀, èèyàn ṣì lè fi hàn pé òun jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run láìfi ọjọ́ ogbó pè. Básíláì ará Gílíádì jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa nípa èyí. Nígbà tó wà lẹ́nì ọgọ́rin ọdún, ó ṣe Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ lálejò gan-an, ó fún wọn ní oúnjẹ àti ilé tí wọn máa gbé lákòókò tí Ábúsálómù dìtẹ̀ mọ́ bàbá rẹ̀. Nígbà tí Dáfídì sì ń padà lọ sí Jerúsálẹ́mù, Básíláì sin òun àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ dé Odò Jọ́dánì. Dáfídì sọ pé òun fẹ́ kí Básíláì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí yóò máa gbé àgbàlá ọba. Kí ni Básíláì wá sọ? Ó ní: “Ẹni ọgọ́rin ọdún ni mí lónìí. . . . Ìránṣẹ́ rẹ ha lè máa tọ́ ohun tí mo ń jẹ àti ohun tí mo ń mu wò, tàbí mo ha tún lè fetí sílẹ̀ mọ́ rárá sí ohùn àwọn akọrin tí ó jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin? . . . Ìránṣẹ́ rẹ Kímúhámù rèé. Jẹ́ kí ó bá olúwa mi ọba sọdá; kí o sì ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ fún un.”—2 Sámúẹ́lì 17:27-29; 19:31-40.

13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Básíláì ti di arúgbó, síbẹ̀ ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún ọba tí Jèhófà yàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé oúnjẹ ò dùn lẹ́nu òun bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ àti pé òun ò gbọ́rọ̀ dáadáa mọ́, kò tìtorí bẹ́ẹ̀ máa banú jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, bó ṣe fi àìmọtara ẹni nìkan sọ pé kí Kímúhámù gbádùn àǹfààní tí ọba sọ yẹn, jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Básíláì jẹ́. Bíi ti Básíláì, ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó lóde òní ló ní ẹ̀mí àìmọtara ẹni nìkan àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́. Wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn, níwọ̀n bí wọ́n ti mọ̀ pé “irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ pé a ní irú àwọn olóòótọ́ èèyàn wọ̀nyí láàárín wa!—Hébérù 13:16.

14. Báwo ni jíjẹ́ tí Dáfídì jẹ́ arúgbó ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 37:23-25 túbọ̀ wọni lọ́kàn gan-an?

14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni ipò tí Dáfídì ń bá ara rẹ̀ ń yí padà bọ́dún ti ń gorí ọdún, síbẹ̀ ó dá a lójú gbangba pé Jèhófà kò dáwọ́ dúró láti máa bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Dáfídì ti ń sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀, ó kọ orin tá a wá mọ̀ sí Sáàmù kẹtàdínlógójì lónìí. Fojú inú wo bí Dáfídì ṣe ń ronú padà sẹ́yìn pẹ̀lú háàpù lọ́wọ́ rẹ̀ tó sì ń kọ orín pé: “Nípasẹ̀ Jèhófà ni a pèsè àwọn ìṣísẹ̀ abarapá ọkùnrin sílẹ̀, ọ̀nà rẹ̀ sì ni Òun ní inú dídùn sí. Bí ó tilẹ̀ ṣubú, a kì yóò fi í sọ̀kò sísàlẹ̀, nítorí pé Jèhófà ń ti ọwọ́ rẹ̀ lẹ́yìn. Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sáàmù 37:23-25) Jèhófà rí i pé ó dára láti fi bí Dáfídì ṣe dàgbà tó hàn nínú sáàmù tó mí sí yìí. Ẹ ò rí i pé ìyẹn jẹ́ kí ohun tí Dáfídì sọ yìí túbọ̀ wọni lọ́kàn gan-an!

15. Báwo ni àpọ́sítélì Jòhánù ṣe fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láìfi ipò rẹ̀ tó yí padà àti ọjọ́ ogbó pè?

15 Àpọ́sítélì Jòhánù tún jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nípa jíjẹ́ olóòótọ́ láìfi ipò rẹ̀ tó yí padà àti ọjọ́ ogbó pè. Lẹ́yìn tí Jòhánù ti sin Ọlọ́run fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rin ọdún, wọ́n mú un nígbèkùn lọ sí erékùṣù Pátímọ́sì “nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 1:9) Síbẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ kò tíì parí. Kódà, ìgbà tí Jòhánù ti di arúgbó tó sì kù díẹ̀ kó kú ló kọ gbogbo ìwé tó kọ nínú Bíbélì. Ìgbà tó wà ní Pátímọ́sì ni wọ́n fi ìran ẹlẹ́rù-jẹ̀jẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá hàn án, ó sì fara balẹ̀ kọ gbogbo wọn sílẹ̀. (Ìṣípayá 1:1, 2) Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ìgbà tí Olú Ọba Róòmù tó ń jẹ́ Nerva wà lórí oyè ní wọ́n dá Jòhánù nídè kúrò nígbèkùn tó wà. Lẹ́yìn náà, ní nǹkan bí ọdún 98 Sànmánì Kristẹni, nígbà tó ṣeé ṣe kí Jòhánù jẹ́ ẹni nǹkan bí àádọ́rùn-ún sí ọgọ́rùn-ún ọdún, ó kọ ìwé Ìhìn Rere àtàwọn ìwé mẹ́ta tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pè.

Ìfaradà Tí Àkọsílẹ̀ Rẹ̀ Kò Lè Pa Rẹ́

16. Báwo làwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa mọ́ ṣe lè fi hàn pé àwọn jẹ́ olùfọkànsin Jèhófà?

16 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìṣòro lè gbà yọjú, wọn sì máa ń le jura wọn lọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti dẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa mọ́. Àmọ́, inú wọn ṣì máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń rántí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wọn àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó ń fi hàn sí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ ni wọ́n lè fẹnu wọn sọ, síbẹ̀ wọn ń sọ fún Jèhófà nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 119:97) Jèhófà mọ àwọn tó “ń ronú lórí orúkọ rẹ̀,” ó sì mọrírì bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ẹgbàágbèje èèyàn tí kò bìkítà nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Málákì 3:16; Sáàmù 10:4) Ó mà ń tuni nínú gan-an o, pé àwọn àṣàrò tá à ń ṣe nínú ọkàn wa ń múnú Jèhófà dùn!—1 Kíróníkà 28:9; Sáàmù 19:14.

17. Kí làwọn tó ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà látọjọ́ pípẹ́ ní tó jẹ́ ohun àrà ọ̀tọ̀?

17 Ohun pàtàkì mìíràn tí kò yẹ ká gbójú fò dá ni pé, àwọn tó ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún ti ní ohun kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, kò sì sí ọ̀nà mìíràn téèyàn lè gbà ní irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Nǹkan ọ̀hún ni ìfaradà tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ kò lè pa rẹ́. Jésù sọ pé: “Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.” (Lúùkù 21:19) Ìfaradà ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn tó lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Kí ẹ̀yin tẹ́ ẹ “ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run,” tí ọ̀nà tẹ́ ẹ gbà gbé ìgbésí ayé yín sì ti fi hàn pé ẹ jẹ́ adúróṣinṣin, máa retí àtirí “ìmúṣẹ ìlérí náà” gbà.—Hébérù 10:36.

18. (a) Kí ni inú Jèhófà máa ń dùn láti rí látọ̀dọ̀ àwọn àgbàlagbà? (b) Kí la ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Jèhófà mọyì iṣẹ́ ìsìn rẹ tó ò ń ṣe tọkàntọkàn, ì báà jẹ́ púpọ̀ lo lè ṣe tàbí kékeré. Ohun yòówù tó lè máa ṣẹlẹ̀ sí ‘ẹni tá a jẹ́ ní òde’ bí ara ṣe ń dara àgbà, ‘ẹni tá a jẹ́ ní inú’ lè máa dọ̀tun lójoojúmọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:16) Kò sí àní-àní pé Jèhófà mọyì ohun tó o ti ṣe sẹ́yìn, ó sì tún hàn gbangba pé ó mọyì ohun tó ò ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí nítorí orúkọ rẹ̀. (Hébérù 6:10) A ó ṣàyẹ̀wò bí irú ìṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ ti ṣàǹfààní tó nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Ánà fi lélẹ̀ fún àwọn àgbàlagbà tó jẹ Kristẹni lóde òní?

• Kí nìdí tí kò fi pọn dandan pé ọjọ́ ogbó lè díni lọ́wọ́ ohun téèyàn lè ṣe?

• Báwo làwọn àgbàlagbà ṣe lè máa bá a lọ láti fi hàn pé olùfọkànsin Ọlọ́run làwọn?

• Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ ìsìn táwọn àgbàlagbà ń ṣe?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn “ìwé” tí Dáníẹ́lì tó ti darúgbó kà ló jẹ́ kó fòye mọ̀ bí iye ọdún tí àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà fi máa wà nígbèkùn yóò ṣe gùn tó

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ló jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú bí wọ́n ṣe ń lọ sípàdé déédéé, tí wọn ń fìtara wàásù, tó sì máa ń wù wọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́