Básíláì Ọkùnrin Tó Mọ̀wọ̀n Ara Ẹ̀
‘ÈÉ ṢE tí màá fi di ìnira fún olúwa mi ọba?’ Básíláì ẹni ọgọ́rin [80] ọdún ló sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Dáfídì ọba Ísírẹ́lì. Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ torí ọrọ̀ tó ní ni Bíbélì fi sọ pé ó jẹ́ “ọkùnrin tí ó pọ̀ gidigidi.” (2 Sámúẹ́lì 19:32, 35) Ilẹ̀ Gílíádì, níbi àgbègbè olókè tó wà ní ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì, ni Básíláì ń gbé.—2 Sámúẹ́lì 17:27; 19:31.
Ipò wo ni Dáfídì wà nígbà tí Básíláì sọ̀rọ̀ yẹn fún un? Kí ló sì fà á tí bàbá àgbàlagbà yìí fi sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀?
Ábúsálómù Dìtẹ̀ Mọ́ Ọba
Dáfídì wà nínú ewu. Ìdí ni pé Ábúsálómù ọmọ rẹ̀ ti fèrú gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tó ti “jí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ.” Ó dájú pé Ábúsálómù ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí bàbá rẹ̀ lọ lófo. Nítorí náà Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 15:6, 13, 14) Nígbà tí Dáfídì dé Máhánáímù tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, Básíláì ràn án lọ́wọ́.
Básíláì àtàwọn ọkùnrin méjì míì, ìyẹn Ṣóbì àti Mákírù, kó jíjẹ àti mímu àti ọ̀pọ̀ ohun èlò wá fún Dáfídì. Ọ̀rọ̀ táwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n dúró ti Dáfídì yìí sọ nípa Dáfídì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ fi hàn pé wọ́n mọ irú iná tó ń jó Dáfídì. Wọ́n ní: “Ebi ń pa àwọn ènìyàn náà, ó sì rẹ̀ wọ́n, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní aginjù.” Básíláì, Ṣóbì àti Mákírù wá ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti pèsè àwọn nǹkan tí Dáfídì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nílò, àwọn nǹkan bí ibùsùn, àlìkámà, ọkà bálì, ìyẹ̀fun, àyangbẹ ọkà, ẹ̀wà pàkálà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, oyin, bọ́tà, àgùntàn àtàwọn nǹkan míì.—2 Sámúẹ́lì 17:27-29.
Ó léwu kí ẹnikẹ́ni ran Dáfídì lọ́wọ́ nírú àkókò yẹn. Ìdí ni pé Ábúsálómù máa fẹ́ fìyà jẹ ẹni yòówù tó bá ń ti Dáfídì, ọba tí Ọlọ́run yàn, lẹ́yìn. Nítorí náà, ó gba ìgbóyà fún Básíláì láti ran Dáfídì lọ́wọ́ nírú àkókò bẹ́ẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Ò Rí Bí Ábúsálómù Ṣe Rò
Láìpẹ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ tí Ábúsálómù kó sòdí dojú ìjà kọ àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà pẹ̀lú Dáfídì. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àgbègbè Máhánáímù tó wà nínú aginjù Éfúráímù ni ìjà náà ti wáyé. Ọwọ́ ìyà ba àwọn ọmọ ogun Ábúsálómù, “ìfikúpa tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ sì já sí èyí tí ó pọ̀ ní ọjọ́ yẹn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúsálómù fẹ́ sá lọ, ọwọ́ bà á, wọ́n sì pa á.—2 Sámúẹ́lì 18:7-15.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, Dáfídì tún padà sórí ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì láìsí alátakò kankan mọ́. Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò máa sá káàkiri mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, dídúró tí wọ́n dúró ti Dáfídì mú kí wọ́n níyì lójú ẹ̀, ó sì fi ìmoore hàn.
Nígbà tí Dáfídì ń múra láti padà sí Jerúsálẹ́mù, “Básíláì ọmọ Gílíádì alára sì sọ̀ kalẹ̀ wá láti Rógélímù, kí ó lè bá ọba kọjá lọ sí Jọ́dánì, kí ó bàa lè sìn ín lọ sí Jọ́dánì.” Lọ́jọ́ yẹn, Dáfídì sọ fún Básíláì bàbá àgbàlagbà yẹn pé: “Ìwọ alára bá mi sọdá, dájúdájú, èmi yóò sì pèsè oúnjẹ fún ọ lọ́dọ̀ mi ní Jerúsálẹ́mù.”—2 Sámúẹ́lì 19:15, 31, 33.
Láìsí àní-àní, Dáfídì mọrírì oore tí Básíláì ṣe fún un gan-an ni. Kò jọ pé ọba kàn fẹ́ fún Básíláì ní àwọn ohun ìní láti fi san oore tó ṣe é padà. Ẹni tó rí já jẹ́ ní Básíláì, nítorí náà kò nílò irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ní Dáfídì fẹ́ kó wà ní àgbàlá ọba nítorí pé ó ní àwọn ànímọ́ tó dára gan-an. Ohun iyì ló máa jẹ́ fún Básíláì láti máa gbé nínú àgbàlá ọba, nítorí pé á lè máa jàǹfààní jíjẹ́ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba.
Básíláì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ̀, Kò sì Tan Ara Rẹ̀ Jẹ
Nígbà tí Básíláì ń fún Dáfídì Ọba lésì nípa àǹfààní tó nawọ́ rẹ̀ sí i yìí, ó ní: “Kí ni àwọn ọjọ́ ọdún ìgbésí ayé mi ti rí, tí èmi yóò fi bá ọba gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù? Ẹni ọgọ́rin ọdún ni mí lónìí. Mo ha lè fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú, tàbí ìránṣẹ́ rẹ ha lè máa tọ́ ohun tí mo ń jẹ àti ohun tí mo ń mu wò, tàbí mo ha tún lè fetí sílẹ̀ mọ́ rárá sí ohùn àwọn akọrin tí ó jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin?” (2 Sámúẹ́lì 19:34, 35) Bí Básíláì ṣe fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kọ àǹfààní bàǹtàbanta tí ọba gbé síwájú rẹ̀ nìyẹn. Àmọ́, kí ló fà á tó fi kọ̀?
Ó lè jẹ́ nítorí ara rẹ̀ tó ti dara àgbà àti àwọn ìṣòro tó máa ń bá ọjọ́ ogbó rìn. Básíláì lè ti máa wò ó pé òun ò ní pẹ́ láyé mọ́. (Sáàmù 90:10) Ó ti ṣe ohun tó lè ṣe láti ran Dáfídì lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ó tún mọ kùdìẹ̀-kudiẹ tí ọjọ́ ogbó ti fà bá òun. Kò jẹ́ kí èrò pé òun máa dẹni iyì ẹni ẹ̀yẹ gba òun lọ́kàn débi tí ò fi ní rántí ibi tágbára rẹ̀ mọ. Básíláì ò dà bí Ábúsálómù tó ń wá bó ṣe máa dépò ọba, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló hùwà ọgbọ́n, tó yáa mọ̀wọ̀n ara rẹ̀.—Òwe 11:2.
Ohun míì tó tún lè fà á tí Básíláì ò fi bá ọba lọ ni pé kò fẹ́ kí àìlera ọjọ́ ogbó òun ṣèdíwọ́ lọ́nàkọnà fún ọba tí Ọlọ́run yàn. Básíláì bi ọba pé: “Èé ṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò tún fi di ẹrù ìnira fún olúwa mi ọba?” (2 Sámúẹ́lì 19:35) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Básíláì ṣì ti Dáfídì lẹ́yìn gbágbáágbá, síbẹ̀ ó gbà pé ọ̀dọ́kùnrin á lè ṣe iṣẹ́ lọ́nà tó jà fáfá ju òun lọ. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ọmọ rẹ̀ ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ìránṣẹ́ rẹ Kímúhámù rèé. Jẹ́ kí ó bá olúwa mi ọba sọdá; kí o sì ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ fún un.” Dípò kí Dáfídì gba ọ̀rọ̀ náà sí ìbínú ńṣe ló fara mọ́ àbá tí bàbá náà mú wá. Kódà kó tó sọdá odò Jọ́dánì, ó “fi ẹnu ko Básíláì lẹ́nu, ó sì súre fún un.”—2 Sámúẹ́lì 19:37-39.
Ó Yẹ Ká Jẹ́ Ẹni Tó Ń Lo Òye
Ìtàn Básíláì fi hàn pé ó yẹ ká jẹ́ ẹni tó ń lo òye tọ́rọ̀ bá kan àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kò yẹ ká jẹ́ ẹni tó ń kọ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn sílẹ̀ tàbí ẹni tí kò fẹ́ sapá láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn torí pé a fẹ́ gbé ìgbésí ayé jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tàbí nítorí à ń rò pé a ò kúnjú ìwọ̀n láti bojú tó iṣẹ́ èyíkéyìí. Ọlọ́run máa fún wa ní okun àti ọgbọ́n tá a máa fi borí kùdìẹ̀-kudiẹ wa, bá a bá gbára lé e.—Fílípì 4:13; Jákọ́bù 4:17; 1 Pétérù 4:11.
Bákan náà, ó tún yẹ ká mọ ibi tágbára wá mọ. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ọwọ́ Kristẹni kan ń dí gan-an nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń bójú tó nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ó wá kíyè sí i pé tóun bá tún gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì kún èyí tóun ń bojú tó, ó lè má ṣeé ṣe fóun mọ́ láti máa pèsè àtijẹ àtimu àti ìtọ́ni látinú Ìwé Mímọ́ fún ìdílé òun bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Bí ọ̀rọ̀ bá ti dà bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kò ní dáa kó jẹ́ ẹni tó lo òye, kó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ kó má tíì gbà kún àwọn iṣẹ́ tó ń bójú tó báyìí?—Fílípì 4:5; 1 Tímótì 5:8.
Àpẹẹrẹ àtàtà ni Básíláì fi lélẹ̀ fún wa, ó sì yẹ ká ronú lé e lórí. Olóòótọ́ èèyàn ni, ó jẹ́ onígboyà, ó lawọ́, ó sì tún mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Lékè gbogbo rẹ̀, Básíláì ṣe tán láti fi ti Ọlọ́run ṣáájú tirẹ̀.—Mátíù 6:33.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Básíláì ẹni ọgọ́rin ọdún rin ìrìn àjò tó gbomi mu kó báa lè ran Dáfídì lọ́wọ́
GÍLÍÁDÌ
Rógélímù
Súkótù
Máhánáímù
Odò Jọ́dánì
Gílígálì
Jẹ́ríkò
Jerúsálẹ́mù
ÉFÚRÁÍMÙ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Kí nìdí tí Básíláì fí kọ̀ láti bá Dáfídì lọ?