ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Mọ̀wọ̀n Ara Ẹ Bíi Ti Básíláì
Ọba Dáfídì nawọ́ àǹfààní kan sí Básíláì (2Sa 19:32, 33; w07 7/15 14 ¶5)
Básíláì kọ àǹfààní yìí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ torí pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ (2Sa 19:34, 35; w07 7/15 14 ¶7)
Ó yẹ káwa náà mọ̀wọ̀n ara wa bíi ti Básíláì (w07 7/15 15 ¶1-2)
Ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń mọ ohun tágbára ẹ̀ gbé. A gbọ́dọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa ká tó lè múnú Jèhófà dùn. (Mik 6:8) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa?