ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 7/1 ojú ìwé 32
  • Ìbẹ̀wò Kan Tó Yí Èrò Mi Padà Pátápátá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbẹ̀wò Kan Tó Yí Èrò Mi Padà Pátápátá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 7/1 ojú ìwé 32

Ìbẹ̀wò Kan Tó Yí Èrò Mi Padà Pátápátá

“ARA mi ti wà lọ́nà báyìí láti sọ fáwọn ará ilé mi nípa ‘àwọn áńgẹ́lì’ méjì tí Ọlọ́run rán sí mi.” Ohun tí ọkùnrin kan sọ rèé lẹ́yìn táwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú ìgbà tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ yẹn ni ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélógójì kú. Ìyẹn sì bà á nínú jẹ́ gan-an. Àwọn ọmọ rẹ̀ tó ti dàgbà ló ń tù ú nínú, àmọ́ ibi tí wọ́n ń gbé jìnnà gan-an sọ́dọ̀ rẹ̀. Kò sí ọ̀rẹ́ tàbí aládùúgbò kankan tó wá kì í.

Ọkùnrin náà sọ fáwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ yìí pé: “Mi ò bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ mọ́.” Àmọ́ àánú rẹ̀ ṣe wọ́n gan-an, wọ́n sì fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àkòrí àṣàrò kúkúrú náà sọ pé Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí wọn Ti Kú? Alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ló kà á tán, ohun tó kà níbẹ̀ sì tù ú nínú.

Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí náà tún padà wá. Wọ́n rántí bí ọkàn rẹ̀ ṣe gbọgbẹ́ tó nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wá wo bó ṣe ń ṣe sí nísinsìnyí. Ọkùnrin náà wá kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé àwọn àjèjì tí wọn ò mọ̀ mí rí rárá lè bìkítà nípa mi kí ọ̀rọ̀ mi sì ká wọn lára tó bẹ́ẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá a sọ látinú Bíbélì fún un níṣìírí gan-an. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin náà sọ pé àwọn á tún padà wá. Inú ọkùnrin náà dùn gan-an, ìyẹn sì mú kó kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí sínú lẹ́tà kan tó fi ránṣẹ́ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ̀.

Kó tó di pé ọkùnrin náà kó lọ sí tòsí ibi tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ wà, ó wá sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́ẹ̀kan ó sì jẹun lọ́dọ̀ ìdílé ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ yẹn. Ó wá kọ̀wé pé: “Mo ti ń fi àgbègbè yìí sílẹ̀ o, àmọ́ ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjì yẹn àti ìjọ yín kò ní kúrò lọ́kàn mi àti nínú àdúrà mi láé. Kódà, mo ti wá ń gbàdúrà gan-an báyìí. Mo sì ti yí èrò mi padà pátápátá. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin wọ̀nyẹn ló ṣe èyí tó pọ̀ jù níbẹ̀, màá sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn títí láé.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́