Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ Fún Àwọn Ẹlòmíràn Níṣìírí
NÍGBÀ tí wọ́n bí Silvia ní oṣù December ọdún 1992, kò sí àmì pé ó ní àìsàn kankan lára, ńṣe ni ara rẹ̀ dá ṣáṣá. Àmọ́ nígbà tí Silvia pé ọmọ ọdún méjì, àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fi hàn pé ó ní àìsàn burúkú kan tí kò gbóògùn, èyí tí kì í jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa, tí kì í sì í jẹ́ kí oúnjẹ dà nínú èèyàn. Nítorí àìsàn yìí, Silvia máa ń lo hóró mẹ́rìndínlógójì oògùn òyìnbó lójoojúmọ́, ó sì tún láwọn oògùn kan tó máa ń fà símú. Wọ́n tún máa ń wọ́ra fún un. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ tí ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ lè ṣe kò ju ìdá mẹ́rin iṣẹ́ tí ẹ̀dọ̀fóró ẹni tára rẹ̀ le máa ń ṣe, ó ní láti máa lo àpò afẹ́fẹ́ ọ́síjìn kan kó sì máa gbé e kiri ibikíbi tó bá ń lọ.
Ìyá rẹ̀ tó ń jẹ́ Teresa sọ pé: “Ọwọ́ tí Silvia fi mú àìsàn rẹ̀ náà yani lẹ́nu gan-an. Ìmọ̀ Bíbélì tó ní mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára gan-an. Ìgbàgbọ́ yìí ló ń jẹ́ kó lè máa fara da ìbànújẹ́ àti ìrora tó máa ń ní. Gbogbo ìgbà ló máa ń rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ayé tuntun, níbi tí yóò ti mú gbogbo àwọn aláìsàn lára dá.” (Ìṣípayá 21:4) Nígbà mìíràn táwọn ará ilé Silvia bá rẹ̀wẹ̀sì, ẹ̀rín tó máa ń rín tọ̀yàyàtọ̀yàyà ló máa ń dá wọn nínú dùn. Ó máa ń sọ fáwọn òbí rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ pé: “Ìgbésí ayé tá a máa gbé nínú ayé tuntun á jẹ́ ká gbàgbé gbogbo ìrora tá à ń ní lóde òní.”
Gbogbo ìgbà ni Silvia máa ń sọ ìhìn rere Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, àwọn tó sì ń bá sọ̀rọ̀ máa ń rí i pé ìdùnnú àti ayọ̀ máa ń hàn lójú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Àwọn ará ìjọ ibi tó ti ń ṣèpàdé ní Erékùṣù Canary máa ń láyọ̀ gan-an tó bá ti ń dáhùn nípàdé tàbí tó bá ń kópa láwọn ìpàdé. Tí ìpàdé bá ti parí, Silvia máa ń fẹ́ láti dúró díẹ̀ kóun àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ lè jọ sọ̀rọ̀ díẹ̀ kó tó máa lọ sílé. Jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni tára rẹ̀ yọ̀ mọ́ èèyàn tó sì lọ́yàyà gan-an mú kí gbogbo ará ìjọ náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.
Bàbá rẹ̀ tó ń jẹ́ Antonio sọ pé: “Silvia ti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Bá a tiẹ̀ níṣòro, ó yẹ ká ṣì mọ̀ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìwàláàyè wa jẹ́, a sì gbọ́dọ̀ mọyì rẹ̀ gan-an.” Bíi ti Silvia, gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run, lọ́mọdé lágbà ló ń fojú sọ́nà de ìgbà tí ‘kò ní sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”’—Aísáyà 33:24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Silvia ń ka ẹsẹ Bíbélì kan, màmá rẹ̀ sì bá a gbé àpò afẹ́fẹ́ ọ́síjìn rẹ̀ dání