ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 9/1 ojú ìwé 17-21
  • Nígbà Tí Èèyàn Wa Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Èèyàn Wa Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tó Fi Máa Ń Nira Gan-an Láti Fara Dà Á
  • Ohun Tó O Lè Ṣe
  • O Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Tí Èèyàn Ẹ Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Báwo Lo Ṣe Lè Ran Ọmọ “Onínàákúnàá” Lọ́wọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 9/1 ojú ìwé 17-21

Nígbà Tí Èèyàn Wa Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀

ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ni Mark àti Louise.a Wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn lohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe gba àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ṣe. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́ àti lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. (Òwe 22:6; 2 Tímótì 3:15) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé nígbà táwọn ọmọ náà dàgbà tán, kì í ṣe gbogbo wọn ló sin Jèhófà. Louise sọ pé, “Lọ́kàn mi, ó máa ń wù mí gan-an pé káwọn ọmọ mi tó ṣáko lọ yẹn padà wá. Báwo ni mo ṣe fẹ́ sọ pé kì í dùn mí gan-an lójoojúmọ́? Nígbà táwọn mìíràn bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ tiwọn, ńṣe lọkàn mi máa ń bà jẹ́, tí mo sì máa ń kó ara mi níjàánu kí n má bàa sunkún.”

Ká sòótọ́, nígbà tẹ́nì kan bá sọ pé òun ò sin Jèhófà mọ́, pé òun ò sì fẹ́ tẹ̀ lé ọ̀nà tí Jèhófà là sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ pé ká máa gbà gbé ìgbésí ayé wa, ìbànújẹ́ ńláǹlà ló máa ń jẹ́ fáwọn ará ilé onítọ̀hún tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Irene sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin gan-an. Màá sì ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe kó lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà!” Maria, tí àbúrò rẹ̀ ọkùnrin fi Jèhófà sílẹ̀ tó sì lọ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèṣekúṣe, sọ pé: “Kò rọrùn fún mi rárá láti fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, nítorí pé tá a bá yọwọ́ ti ohun tó ṣe yẹn, àbúrò àtàtà ló jẹ́ fún mi. Ìgbà tí ìdílé wa bá kóra jọ láti gbádùn ara wa tóun ò sì lè wà níbẹ̀ ló máa ń dùn mí jù.”

Ìdí Tó Fi Máa Ń Nira Gan-an Láti Fara Dà Á

Kí nìdí tó fi máa ń ba àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lọ́kàn jẹ́ gan-an nígbà tí ọmọ wọn tàbí èèyàn wọn kan bá fi Jèhófà sílẹ̀? Nítorí wọ́n mọ̀ pé Ìwé Mímọ́ ṣèlérí ìwàláàyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé fáwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀. (Sáàmù 37:29; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3-5) Wọ́n nírètí láti gbádùn àwọn ìbùkún yìí pẹ̀lú ọkọ tàbí aya wọn, àwọn ọmọ wọn, àwọn òbí wọn, àwọn ọmọ ìyá wọn, àtàwọn ọmọ ọmọ wọn. Ó máa ń dùn wọ́n gan-an nígbà tí wọ́n bá rántí pé èèyàn wọn tí kò sin Jèhófà mọ́ lè pàdànú àǹfààní yìí! Kódà tá a bá ń sọ nípa ìgbésí ayé ìsinsìnyí pàápàá, àwọn Kristẹni mọ̀ pé fún àǹfààní àwọn ni Jèhófà ṣe ṣe òfin àtàwọn ìlànà rẹ̀. Ìdí nìyí tọ́kàn àwọn Kristẹni fi máa ń bà jẹ́ gan-an nígbà táwọn èèyàn wọn bá gbin ohun tó máa mú kí wọ́n kórè ìbànújẹ́.—Aísáyà 48:17, 18; Gálátíà 6:7, 8.

Àwọn tírú nǹkan báyìí ò bá ṣẹlẹ̀ sí rí lè má mọ bó ṣe máa ń bani nínú jẹ́ tó. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbà gbogbo ló máa ń nípa lórí ohun téèyàn ń rò àtohun téèyàn ń ṣe. Louise sọ pé: “Ó ti wá ṣòro fún mi gan-an báyìí láti jókòó nípàdé Kristẹni kí n sì máa wo àwọn òbí tó ń bá àwọn ọmọ wọn rẹ́rìn-ín tí wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀. Tí nǹkan kan bá tiẹ̀ ń múnú mi dùn, kíá ni ìbànújẹ́ máa ń dorí mi kodò nítorí àwọn ọmọ mi tó ṣáko lọ.” Alàgbà kan sọ̀rọ̀ nípa ọdún mẹ́rin tí ọmọ ìyàwó rẹ̀ fi fi wọ́n sílẹ̀. Ó ní: “Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ohun tó tiẹ̀ yẹ kó múnú ẹni dùn pàápàá máa ń kó ìbànújẹ́ bá wa. Bí mo bá fún ìyàwó mi lẹ́bùn kan tàbí tí mo bá mú un lọ síbì kan tó dára gan-an láti lọ gbádùn òpin ọ̀sẹ̀, ńṣe ló máa bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, tá a máa rántí pé ọmọ òun kò nípìn-ín nínú ayọ̀ wa.”

Ṣé kì í ṣe pé àwọn Kristẹni wọ̀nyí mú ọ̀ràn náà le ju bó ṣe yẹ lọ? Rárá o. Ká sòótọ́, a lè sọ pé ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn ànímọ́ Jèhófà hàn dé àyè kan, ẹni tó dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Kí lèyí túmọ̀ sí? Ó dáa, báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí i? Àkọsílẹ̀ inú Sáàmù 78:38-41 fi yé wa pé ohun tí wọ́n ṣe dun Jèhófà gan-an, ó sì bà á nínú jẹ́. Síbẹ̀, Jèhófà fi sùúrù kìlọ̀ fún wọn, ó ń bá wọn wí, bẹ́ẹ̀ ló sì ń dárí jì wọ́n nígbàkigbà tí wọ́n bá fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn. Èyí fi hàn dájúdájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ìyẹn àwọn “iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,” àti pé kì í tètè pa wọ́n tì. (Jóòbù 14:15; Jónà 4:10, 11) Ó dá ìfẹ́ ọmọnìkejì mọ́ àwa èèyàn, ìfẹ́ tó sì máa ń wà láàárín àwọn tó wá látinú ìdílé kan náà máa ń lágbára gan-an. Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé inú èèyàn máa ń bà jẹ́ nígbà tí mọ̀lẹ́bí kan ò bá sin Jèhófà mọ́.

Ká sòótọ́, kí èèyàn ẹni má sin Jèhófà mọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àdánwò tó nira jù lọ fáwọn olùjọ́sìn tòótọ́ láti fara dà. (Ìṣe 14:22) Jésù sọ pé gbígbà táwọn èèyàn bá tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ òun yóò fa ìyapa nínú àwọn ìdílé kan. (Mátíù 10:34-38) Èyí kò túmọ̀ sí pé ohun tó wà nínú Bíbélì ń tú ìdílé ká o. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí àwọn tó di aláìṣòótọ́ nínú ìdílé ló ń fa ìyapa nígbà tí wọ́n ò bá fara mọ́ ìlànà ìsìn Kristẹni mọ́, tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tàbí tí wọ́n tiẹ̀ ń ta kò ó pàápàá. Àmọ́ a dúpẹ́ pé Jèhófà kì í fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀, ó máa ń ṣe ọ̀nà tí wọ́n á fi lè fara da àwọn àdánwò tó bá dé bá wọn. Tó o bá wà nínú ìbànújẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ nítorí pé èèyàn rẹ kan fi Jèhófà sílẹ̀, àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tí ìbànújẹ́ náà ò fi ní gbé ọ mì, tí wàá sì rí ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ díẹ̀?

Ohun Tó O Lè Ṣe

“Nípa gbígbé ara yín ró . . . , ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Júúdà 20, 21) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, kò sóhun tó o lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún aráalé rẹ kan tí kò sin Jèhófà mọ́, èyí sì sinmi lórí bí ọ̀ràn náà ṣe rí. Síbẹ̀, o lè gbé ara rẹ àtàwọn yòókù tó jẹ́ olóòótọ́ nínú ìdílé rẹ ró, ó sì yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Veronica, tí méjì lára àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tó bí fi òtítọ́ sílẹ̀, sọ pé: “Àwọn ará máa ń sọ fún èmi àti ọkọ mi pé tá a bá dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, a óò wà nípò tó dára gan-an láti kí àwọn ọmọ wa káàbọ̀ nígbà tí orí wọn bá padà wálé. Ibo lọmọ onínàákúnàá yẹn ì bá wà ká ní bàbá rẹ̀ ò sí nípò tó fi lè gbà á padà?”

Gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́, èyí á jẹ́ kó o lágbára nipa tẹ̀mí. Lára rẹ̀ ni pé kó o ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀jinlẹ̀ àti lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, kó o sì rí i pé ò ń tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Máa ran àwọn ará lọ́wọ́ nínú ìjọ débi tí ipò rẹ bá yọ̀ǹda fún ọ dé. Lóòótọ́, irú àwọn nǹkan báwọ̀nyí lè kọ́kọ́ nira fún ọ láti ṣe. Veronica sọ pé: “Ńṣe ló kọ́kọ́ ṣe mí bíi pé kí n máa ya ara mi sọ́tọ̀ bí ẹranko tó fara gbọgbẹ́. Àmọ́ ọkọ mi sọ pé dandan, a gbọ́dọ̀ máa bá àwọn ìgbòkègbodò tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa nìṣó. Ó rí i dájú pé à ń lọ sáwọn ìpàdé. Nígbà tí àkókò àpéjọ àgbègbè sì tó, ó gba ìgboyà gan-an fún mi láti lọ kí n sì bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, gbogbo ohun tá a gbọ́ níbẹ̀ mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà gan-an. Àpéjọ àgbègbè yẹn gbé ọmọkùnrin wa kan ṣoṣo tó kù tó jẹ́ olóòótọ́ ró gan-an ni.”

Maria, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè rí i pé kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù lójú méjèèjì ran òun lọ́wọ́ gan-an, èèyàn mẹ́rin ló sì ń ràn lọ́wọ́ báyìí láti ní ìmọ̀ Bíbélì. Bákan náà, Arábìnrin Laura sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì máa ń sunkún lójoojúmọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé bí mi ò tiẹ̀ ṣe àṣeyọrí táwọn òbí mìíràn ṣe nínú ọmọ títọ́, mo mọ àwọn nǹkan dáradára tí Bíbélì sọ tó lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí.” Ken àti Eleanor, táwọn ọmọ wọn tó ti dàgbà fi ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀, ṣètò ara wọn, wọ́n kó lọ sí àgbègbè táwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run kò fi bẹ́ẹ̀ sí, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún níbẹ̀. Èyí ràn wọ́n lọ́wọ́ láti má ṣe ní èrò tí kò tọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, kò sí jẹ́ kí ìbànújẹ́ wọn pọ̀ kọjá bó ṣe yẹ.

Má ṣe sọ̀rètí nù. Ìfẹ́ “máa [ń] retí ohun gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Arákùnrin Ken tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè sọ pé: “Nígbà táwọn ọmọ wa fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀, bí ẹni pé wọ́n ti kú ló rí lọ́kàn mi. Àmọ́ èrò mi yí padà nígbà tí èkejì mi obìnrin tá a jọ jẹ́ ìbejì kú. Inú mi dùn pé àwọn ọmọ mi kò tíì kú ikú tara, àti pé Jèhófà ṣì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti padà wá, ó ń retí pé wọ́n á padà sọ́dọ̀ òun.” Àní, àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ti fi òtítọ́ sílẹ̀ ló máa ń padà wá níkẹyìn.—Lúùkù 15:11-24.

Má ṣe máa dá ara rẹ lẹ́bi. Àwọn tó jẹ́ òbí lè máa ronú padà sẹ́yìn kí wọ́n sì máa kábàámọ̀ pé àwọn ò bójú tó àwọn ipò kan bó ṣe yẹ káwọn bójú tó o. Àmọ́ o, olórí ohun tí Ìsíkíẹ́lì 18:20 fẹ́ ká mọ̀ ni pé, ẹni tó ṣẹ̀ ni Jèhófà sọ pé yóò dáhùn fún ìwà àìtọ́ tó hù kì í ṣe àwọn òbí rẹ̀. Ó sì tún yẹ ká kíyè sí i pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwé Òwe sọ tó fi hàn pé ojúṣe àwọn òbí ni láti tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tó tọ́, ìmọ̀ràn tó fún àwọn èwe pé kí wọ́n tẹ́tí sáwọn òbí wọn kí wọ́n sì ṣègbọràn sí wọn fi ìlọ́po mẹ́rin ju ti àwọn òbí lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, ojúṣe àwọn ọmọ ni láti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn òbí wọn tó jẹ́ aláìpé ń kọ́ wọn. Kò sí àní-àní pé ọ̀nà tó dára jù lọ lójú rẹ lo gbà bójú tó ìdílé rẹ. Síbẹ̀, bó o bá tiẹ̀ ń rò pé o ti ṣe àwọn àṣìṣe kan àti pé dájúdájú, ẹ̀bi rẹ làwọn àṣìṣe náà, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ìyẹn ló mú kí èèyàn rẹ fi òtítọ́ sílẹ̀. Èyí tó wù kó jẹ́, kíkábàámọ̀ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá kò lè ṣàǹfààní kankan. Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe náà, pinnu pé o ò ní ṣe wọ́n mọ́, kó o sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dárí jì ọ́. (Sáàmù 103:8-14; Aísáyà 55:7) Lẹ́yìn náà, máa wo ọjọ́ iwájú, má ṣe máa ronú nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.

Máa ní sùúrù fáwọn èèyàn. Ó lè ṣòro fáwọn kan láti mọ báwo gan-an làwọn ì bá ṣe fún ọ níṣìírí tàbí tù ọ́ nínú, àgàgà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò bá ṣẹlẹ̀ sí wọn rí. Yàtọ̀ síyẹn, tó bá di ọ̀rọ̀ fífúnni ní ìṣírí tàbí ìtùnú, àwọn èèyàn yàtọ̀ síra. Nítorí náà, táwọn kan bá sọ ohun tí kò dùn mọ́ ọ nínú, ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Kólósè 3:13 ni kó o ṣe, ó ní: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”

Mọyì ètò tí Jèhófà ṣe fún bíbániwí. Bí ìjọ Ọlọ́run bá bá mọ̀lẹ́bí rẹ kan wí, máa rántí pé ara ètò tí Jèhófà ṣe lèyí jẹ́, àti pé fún àǹfààní gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni, títí kan ẹni tó hùwà àìtọ́ náà. (Hébérù 12:11) Nítorí náà, má ṣe fàyè gba èròkérò kankan táá mú kó o máa ṣàríwísí àwọn alàgbà tó ṣe ìdájọ́ náà tàbí kó o máa ta ko ìdájọ́ tí wọ́n ṣe. Rántí pé, ṣíṣe nǹkan ní ọ̀nà Jèhófà ló ń mú àṣeyọrí tó dára jù wá, ńṣe ni títako àwọn ètò tí Jèhófà ṣe sì máa ń dá kún ìbànújẹ́ ẹni.

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, Mósè ló ń ṣe onídàájọ́ fún wọn. (Ẹ́kísódù 18:13-16) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé tó bá dá ẹnì kan láre, ẹ̀bi ló ṣeé ṣe kó jẹ́ fún ẹlòmíràn, èyí lè jẹ́ ká rí ìdí tí inú àwọn kan ò fi ní dùn sí ìdájọ́ tí Mósè bá ṣe. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àríwísí táwọn èèyàn ṣe nípa Mósè ló fa àwọn ọ̀tẹ̀ kan tó wáyé, tí wọ́n sì ta ko ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú. Àmọ́ o, Mósè ni Jèhófà ń lò láti darí àwọn èèyàn Rẹ̀. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyẹn àtàwọn ìdílé wọn tó dara pọ̀ mọ́ wọn ni Jèhófà sì fìyà jẹ kì í ṣe Mósè. (Númérì 16:31-35) A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú èyí, ká rí i pé à ń fara mọ́ àwọn ìdájọ́ táwọn tó wà nípò àṣẹ nínú ètò Ọlọ́run bá ṣe, ká sì máa jẹ́ káwọn ìdájọ́ náà tẹ́ wa lọ́rùn.

Lórí kókó yìí, Arábìnrin Delores sọ bó ṣe ṣòro gan-an fún òun láti ní èrò tó tọ́ nígbà tí ìjọ Ọlọ́run bá ọmọ rẹ̀ obìnrin wí. Ó ní: “Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni kíka àwọn àpilẹ̀kọ tó ní í ṣe pẹ̀lú bí àwọn ètò Jèhófà ṣe bọ́gbọ́n mu, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì ka àwọn àpilẹ̀kọ náà. Mo dìídì ní ìwé kan tí mò ń kọ àwọn ohun tí mo bá gbọ́ nínú àwọn àsọyé àtèyí tí mo bá rí nínú àwọn àpilẹ̀kọ sí, ìyẹn àwọn ohun tó lè ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìfaradà táá sì jẹ́ kí n máa sin Jèhófà nìṣó.” Èyí ló mú wa dórí kókó mìíràn tó ṣe pàtàkì gan-an tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfaradà.

Máa sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn rẹ. Tó o bá sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún ọ̀rẹ́ kan tàbí méjì tó o fọkàn tán tí wọ́n sì jẹ́ olóye èèyàn, èyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Tó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ tó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ ni kó o tọ̀ lọ. Àmọ́ ohun tó dájú pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ jù lọ ni pé kó o ‘tú ọkàn rẹ jáde’ nínú àdúrà sí Jèhófà.b (Sáàmù 62:7, 8) Kí nìdí? Nítorí pé ó mọ bí ọ̀rọ̀ náà ti rí lára rẹ. Bí àpẹẹrẹ, o lè máa rò pé kò bójú mu bó o ṣe ń ní ìbànújẹ́ tó lékenkà. Ó ṣe tán, ìwọ ò fi Jèhófà sílẹ̀. Sọ ohun tó ń da ọkàn rẹ láàmú fún Jèhófà nínú àdúrà, kó o bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa ìṣòro náà, èyí tí kò ní jẹ́ kó o ní ìbànújẹ́ ọkàn.—Sáàmù 37:5.

Bí àkókò ti ń lọ, kò sí àní-àní pé á túbọ̀ rọrùn fún ọ láti kápá àwọn èrò ọkàn rẹ. Àmọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, má ṣe juwọ́ sílẹ̀ rárá, túbọ̀ máa sapá láti múnú Baba rẹ ọ̀run dùn, má sì ṣe rò pé asán ni gbogbo ìsapá rẹ yìí. (Gálátíà 6:9) Rántí pé, béèyàn bá tiẹ̀ fi Jèhófà sílẹ̀, ìyẹn ò sọ pé onítọ̀hún kò ní níṣòro. Àmọ́, tá a bá ń jẹ́ olóòótọ́ sí i nìṣó, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àdánwò tó ń bá wa. Nítorí náà, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ò ń fojú winá rẹ̀, yóò sì máa fún ọ lókun nìṣó lákòókò tó o nílò rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:13; Hébérù 4:16.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Bó o bá fẹ́ mọ̀ nípa gbígbàdúrà fún mọ̀lẹ́bí kan tá a yọ lẹ́gbẹ́, wo Ilé Ìṣọ́ December 1, 2001, ojú ìwé 30 àti 31.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

Ohun Tá A Lè Ṣe

◆ “Nípa gbígbé ara yín ró . . . , ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Júúdà 20, 21.

◆ Má ṣe sọ̀rètí nù. —1 1 Kọ́ríńtì 13:7.

◆ Má ṣe máa dá ara rẹ lẹ́bi. —Ìsíkíẹ́lì 18:20.

◆ Ní sùúrù fáwọn èèyàn. —Kólósè 3:13.

◆ Mọyì ètò tí Jèhófà ṣe fún bíbániwí.—Hébérù 12:11.

◆ Máa sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn rẹ. —Sáàmù 62:7, 8.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ṣé O Ti Fi Jèhófà Sílẹ̀?

Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ohunkóhun tí ì báà fà á, àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà àti ìrètí rẹ láti wàláàyè títí láé wà nínú ewu. Ó ṣeé ṣe kó o ní in lọ́kàn pé o fẹ́ padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ṣé ò ń sa gbogbo ipá rẹ báyìí láti rí i pé o ṣe bẹ́ẹ̀. Àbí ńṣe lò ń sún un síwájú títí di àkókò tó bá dára lójú rẹ? Rántí o, ìjì Amágẹ́dọ́nì kò ní pẹ́ jà. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbésí ayé wa nínú ètò àwọn nǹkan yìí kúrú, kò sì láyọ̀lé. O ò mọ̀ bóyá wàá tiẹ̀ wà láàyè lọ́la. (Sáàmù 102:3; Jákọ́bù 4:13, 14) Ọkùnrin kan tí wọ́n sọ fún pé àrùn tó ń gbẹ̀mí èèyàn ló ń ṣe é sọ pé: “Ẹnu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sí Jèhófà ni àìsàn yìí ti bá mi, mi ò sì yọ́ ohun tí kò dára ṣe ní kọ̀rọ̀. Irú èrò yìí ló sì dára fún mi láti ní lọ́wọ́ tí mo wà yìí.” Àmọ́, wo bí ì bá ti rí lára arákùnrin yìí ká ní ẹnu ibi tó ti ń sọ pé, “Lọ́jọ́ kan, màá padà sọ́dọ̀ Jèhófà” ni àìsàn náà ti dé bá a! Bó o bá ti fi Jèhófà sílẹ̀, àkókò tó dára jù lọ fún ọ nìyí láti padà sọ́dọ̀ rẹ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Gbígbájúmọ́ àwọn nǹkan tó dá lórí ìjọsìn tòótọ́ á jẹ́ kó o lè máa ní èrò tó tọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́