Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ló yẹ kí ìjọ ṣe bí Kristẹni kan tó ń wakọ̀ bá ní jàǹbá ọkọ̀, tí èyí sì yọrí sí ikú ẹlòmíràn?
Ó yẹ kí ìjọ wò ó bóyá awakọ̀ náà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí pé bí ìjọ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn náà á pín nínú ẹ̀bi yẹn. (Diutarónómì 21:1-9; 22:8) Awakọ̀ tó bá ní jàǹbá ọkọ̀ tí ìyẹn sì yọrí sí ikú ẹlòmíràn lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó bá jẹ́ pé òun ni kò bìkítà tàbí pé ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ rú ọ̀kan lára àwọn òfin ààbò tàbí òfin ìrìnnà tí ìjọba ṣe. (Máàkù 12:14) Àmọ́ àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó yẹ kí ìjọ gbé yẹ̀ wò.
Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, apààyàn tó bá sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ààbò tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì ní láti jẹ́jọ́. Tí wọ́n bá rí i pé kò mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn, wọ́n á gbà á láyè láti dúró sínú ìlú náà kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa pa á. (Númérì 35:6-25) Nítorí náà, bí Kristẹni awakọ̀ kan bá ní jàǹbá ọkọ̀ tó yọrí sí ikú ẹnì kan, àwọn alàgbà ní láti wádìí ọ̀rọ̀ náà kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Kì í ṣe ohun tí ìjọba tàbí kóòtù bá ṣáà ti sọ ló máa pinnu ohun tí ìjọ máa ṣe.
Bí àpẹẹrẹ, kóòtù lè sọ pé onítọ̀hún jẹ̀bi torí pé ó rú àwọn òfin ìrìnnà kan, síbẹ̀ káwọn alàgbà tó ń wádìí ọ̀rọ̀ náà wò ó pé awakọ̀ náà kò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nítorí kò sí bí awakọ̀ náà ṣe lè dènà jàǹbá tó la ẹ̀mí lọ náà. Àmọ́, bí kóòtù bá tiẹ̀ tú ẹjọ́ náà ká, àwọn alàgbà lè wò ó pé onítọ̀hún ṣì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.
Káwọn alàgbà tó sọ bóyá onítọ̀hún jàre àbí ó jẹ̀bi, wọ́n gbọ́dọ̀ gbé ìdájọ́ wọn ka Ìwé Mímọ́ àtàwọn ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ tó sì ṣe kedere. Irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ọ̀rọ̀ tí awakọ̀ náà fẹnu ara rẹ̀ sọ pé òun jẹ̀bi àti ọ̀rọ̀ ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta tó ṣeé gbà gbọ́. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tí awakọ̀ náà sọ nìkan tàbí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí náà nìkan ni wọ́n máa lò. (Diutarónómì 17:6; Mátíù 18:15, 16) Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló jẹ̀bi, àwọn alàgbà ní láti yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́. Bí ìgbìmọ̀ náà bá gbà pé ẹni tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ náà ronú pìwà dà, wọ́n á fi Ìwé Mímọ́ bá a wí, wọ́n á sì fi í sábẹ́ ìkálọ́wọ́kò tó fi jẹ́ pé kò ní láwọn àǹfààní tàbí ẹrù iṣẹ́ kan nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á mú un kúrò ní ipò alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, wọ́n á sì tún fi àwọn àǹfààní mìíràn dù ú nínú ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, yóò jíhìn fún Ọlọ́run nítorí àìbìkítà tàbí àìkíyèsára rẹ̀ tó fa jàǹbá tó ṣekú pààyàn náà.—Gálátíà 6:5, 7.
Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé ojú ọjọ́ ni ò dáa nígbà tí jàǹbá náà ṣẹlẹ̀, ńṣe ló yẹ kí awakọ̀ náà túbọ̀ kíyè sára. Bó bá sì jẹ́ pé oorun ló ń kùn ún, ó yẹ kó ti dúró sinmi títí dìgbà tí ojú rẹ̀ á fi dá, tàbí kó sọ pé kí ẹlòmíràn wakọ̀.
Ká ní ńṣe ni awakọ̀ náà sáré kọjá ohun tí òfin ìrìnnà sọ ńkọ́? Kristẹni tó bá sáré kọjá ohun tí òfin sọ ti tàpá sí ọ̀rọ̀ Jésù pé ká fi “àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì.” Ó tún fi hàn pé ẹ̀mí èèyàn ò jọ ọ́ lójú, torí pé eré àsájù lè yọrí sí jàǹbá tó la ẹ̀mí lọ. (Mátíù 22:21) Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, ẹ jẹ́ ká tún wo ọ̀rọ̀ náà síwájú sí i. Irú àpẹẹrẹ wo ni alàgbà kan ń fi lélẹ̀ fún àwọn ará ìjọ bí kò bá fọwọ́ pàtàkì mú àwọn òfin ìrìnnà tí ìjọba ṣe tàbí tó mọ̀ọ́mọ̀ tàpá sí wọn?—1 Pétérù 5:3.
Kò yẹ kí Kristẹni kan máa sọ fún Kristẹni bíi tiẹ̀ pé kó tètè dé ibì kan ní àkókò tí onítọ̀hún ò ní lè débẹ̀ láìjẹ́ pé ó sá kọjá ìwọ̀n eré tí òfin sọ pé èèyàn lè sá. Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn tètè gbéra nílé tàbí kéèyàn sọ àwọn ohun tó fẹ́ ṣe dìgbà mìíràn kó má bàa di pé èèyàn ń sáré àsápajúdé. Ó dájú pé tí Kristẹni kan bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní sí pé ó ń sáré ju bó ṣe yẹ lọ, ṣùgbọ́n yóò lè tẹ̀ lé òfin ìrìnnà tí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ṣe. (Róòmù 13:1, 5) Èyí ò ní jẹ́ kí jàǹbá ọkọ̀ tó lè mú kó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wáyé. Yóò tún jẹ́ kó lè fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀, kó sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.—1 Pétérù 3:16.