ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 12/15 ojú ìwé 30
  • Ǹjẹ́ O Rántí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Rántí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ni Aṣòdì sí Kristi?
    Jí!—2001
  • Àwọn Wo ni Aṣòdì sí Kristi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ta Ni Aṣòdì sí Kristi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bá A Ṣe Lè Dá Aṣòdì-sí-Kristi Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 12/15 ojú ìwé 30

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ o gbádùn àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ bí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ bá fi Jèhófà sílẹ̀?

Gbìyànjú láti gbé ara rẹ àtàwọn yòókù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nínú ìdílé rẹ ró. Gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́. Máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Má ṣe rò pé aráalé rẹ tó fi Jèhófà sílẹ̀ ò lè padà láé. Má ṣe máa dá ara rẹ lẹ́bi. Mọyì ètò tí Jèhófà ṣe fún bíbániwí, kó o sì jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ mọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn rẹ gan-an.—9/1, ojú ìwé 18 sí 21.

• Ọ̀nà méjì wo ni Bíbélì gbà jẹ́ ká mọ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?

Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:11) Bíbélì tún sọ nípa bí ìwà àti ìṣesí àwọn èèyàn yóò ṣe yí padà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5) Àmọ́ ó tún sọ pé a óò máa wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí kan náà.—9/15, ojú ìwé 4 sí 6.

• Kí ló yẹ kí ìjọ ṣe bí Kristẹni kan tó ń wakọ̀ bá ní jàǹbá ọkọ̀, tí èyí sì yọrí sí ikú ẹlòmíràn?

Tí àwọn alàgbà tó ń wádìí ọ̀rọ̀ náà bá rí i pé kò sí bí awakọ̀ náà ṣe lè dènà jàǹbá ọkọ̀ tó la ẹ̀mí lọ, wọ́n lè wò ó pé awakọ̀ náà kò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹ̀bi awakọ̀ náà ni tó sì ronú pìwà dà, àwọn alàgbà náà yóò fi Ìwé Mímọ́ bá a wí, wọ́n á sì fi í sábẹ́ ìkálọ́wọ́kò tó fi jẹ́ pé kò ní láwọn àǹfààní tàbí ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ.—9/15, ojú ìwé 30.

• Kí nìdí tí ìtẹ̀síwájú nínú ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò fi lè mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe?

Òótọ́ ni pé onírúurú nǹkan làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbìyànjú rẹ̀ láti mú kí ìwàláàyè gùn sí i. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fẹ́ ṣe é kí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara lè máa sọ ara wọn dọ̀tun títí lọ gbére. Nǹkan míì ni pé wọ́n fẹ́ fi èròjà inú àbùdá èèyàn ṣe ẹ̀dà ẹ̀yà ara tí wọ́n lè fi pààrọ̀ ẹ̀yà ara aláìsàn. Àmọ́ Bíbélì fi yéni pé ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà ní ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ nípasẹ̀ ìràpadà Jésù.—10/1, ojú ìwé 3 sí 5.

• Ṣé àpẹẹrẹ ààtò ìwẹ̀nùmọ́ àwọn Júù ni ìrìbọmi táwọn Kristẹni ń ṣe jẹ́?

Rárá o. Ńṣe làwọn Júù tó bá ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ máa ń wẹ̀ fúnra wọn, àmọ́ ní ti ìrìbọmi tí Jòhánù fi lélẹ̀, kì í ṣe àwọn èèyàn ló ń fúnra wọn ri ara wọn bọmi. Àwọn èèyàn lè ṣe ààtò ìwẹ̀nùmọ́ tí Òfin Mósè là kalẹ̀ láṣetúnṣe, àmọ́ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ìrìbọmi tàwa Kristẹni máa ń ṣe.—10/15, ojú ìwé 12 àti 13.

• Ilé ẹ̀kọ́ wo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

Òun ni ilé ẹ̀kọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́jọ tí ètò Ọlọ́run ṣètò fáwọn alàgbà ìjọ àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ àpọ́n tí wọ́n sì wà nípò tí ètò Ọlọ́run ti lè rán wọn lọ sáwọn ibi táwọn èèyàn ti nílò ìrànlọ́wọ́ gidigidi. Ó lè jẹ́ ìjọ tí wọ́n ti kúrò ni wọ́n máa rán wọn padà sí, wọ́n sì lè rán wọn lọ sílùú ibòmíì tàbí orílẹ̀-èdè míì pàápàá.—11/15, ojú ìwé 10 àti 11.

• Àwọn wo ni aṣòdì sí Kristi tí 1 Jòhánù 2:18; 4:3 mẹ́nu kàn?

Tá a bá fẹ́ sọ ibi tí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí gbòòrò dé, gbogbo àwọn tó lòdì sí Kristi tàbí tí wọ́n ń purọ́ pé Kristi làwọn tàbí pé aṣojú rẹ̀ làwọn ni ọ̀rọ̀ náà “aṣòdì sí Kristi” ń tọ́ka sí. Ọ̀rọ̀ tí Jésù àti Jòhánù sọ jẹ́ ká rí i kedere pé, aṣòdì sí Kristi kì í ṣe ẹyọ ẹnì kan, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n jẹ́ àwùjọ àwọn èèyàn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ èké, tí wọn ò sì fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run.—12/1, ojú ìwé 4 sí 6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́