ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọmọ Aráyé Ń Wá Ọ̀nà Tí Wọ́n Lè Gbà Wà Láàyè Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́—2006 | October 1
    • Ọmọ Aráyé Ń Wá Ọ̀nà Tí Wọ́n Lè Gbà Wà Láàyè Títí Láé

      LÁTÌGBÀ ìjímìjí ló ti ń wu ọmọ aráyé pé káwọn wà láàyè títí láé. Síbẹ̀, àlá yìí ò tíì ṣẹ, nítorí pé kò sẹ́ni tó tíì rí ọ̀nà téèyàn lè gbà ṣẹ́gun ikú. Àmọ́, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìwádìí lórí ọ̀ràn ìṣègùn ti jẹ́ káwọn èèyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí í retí pé tó bá yá, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn lè mú ẹ̀mí èèyàn gùn sí i ju ti ìsinsìnyí lọ. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìwádìí tó ti wáyé ní onírúurú ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lórí ọ̀ràn yìí.

      Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ń ṣàyẹ̀wò bí wọ́n ṣe máa ṣe nǹkan sí èròjà kan tó ń jẹ́ telomerase tó wà nínú àbùdá ara èèyàn kí àwọn sẹ́ẹ̀lì ara (àwọn ohun tín-tìn-tín tó para pọ̀ di èèyàn) lè máa sọ ara wọn dọ̀tun títí láé. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ̀ pé àwọn sẹ́ẹ̀lì tuntun máa ń rọ́pò àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ti di ògbólógbòó. Àní, ara máa ń sọra rẹ̀ dọ̀tun lọ́pọ̀ ìgbà láàárín àkókò téèyàn fi wà láàyè. Àwọn tó ń ṣèwádìí yìí ronú pé táwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń sọ ara wọn dọ̀tun yìí bá lè máa bá a lọ bẹ́ẹ̀, “a jẹ́ pé ara èèyàn á lè sọ ara rẹ̀ dọ̀tun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àní títí láé pàápàá.”

      Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tí wọ́n sọ pé àwọn lè fi èròjà inú àbùdá èèyàn ṣe àwọn ẹ̀yà ara èèyàn ṣèlérí pé àwọn lè ṣe ẹ̀dà ẹ̀dọ̀, kíndìnrín, tàbí ọkàn tó máa bá ti aláìsàn tí wọ́n fẹ́ pààrọ̀ ẹ̀ya ara rẹ̀ mu wẹ́kú. Wọ́n ní àwọn lè ṣe irú àwọn ẹ̀yà ara bẹ́ẹ̀ nípa lílo àwọn sẹ́ẹ̀lì ara aláìsàn náà. Ohun tí wọ́n sì sọ pé àwọn fẹ́ ṣe yìí ti dá ọ̀pọ̀ awuyewuye sílẹ̀.

      Àwọn tó ń ṣèwádìí nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ohun kan tí kò ju orí abẹ́rẹ́ lọ sọ pé, ìgbà kan ń bọ̀ táwọn dókítà máa ṣe àwọn ohun tín-tìn-tín tí kò ju sẹ́ẹ̀lì lọ. Àwọn ohun tín-tìn-tín yìí ni wọ́n máa fi sínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn láti máa wá àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ní àrùn jẹjẹrẹ àtàwọn tó ní kòkòrò àrùn tí wọ́n á sì pa wọ́n. Àwọn kan gbà gbọ́ pé bópẹ́bóyá, ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì yìí, àti ìlànà fífi èròjà inú àbùdá tọ́jú àìsàn, yóò mú kí ara èèyàn lè máa sọ ara rẹ̀ dọ̀tun títí láé.

      Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ń ronú nípa ìlànà gbígbé òkú sínú yìnyín. Ìdí tí wọ́n fi fẹ́ ṣe èyí ni pé kí wọ́n lè tọ́jú ara àwọn òkú náà pa mọ́ títí dìgbà tí àwárí tuntun nínú ìmọ̀ ìṣègùn yóò fi jẹ́ káwọn dókítà mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà wo gbogbo àìsàn. Wọ́n ní àwọ́n á mú ohun tó ń sọ èèyàn darúgbó kúrò, àwọ́n á wá mú káwọn òkú wọ̀nyẹn jí padà, àwọ́n á sì wá wò wọ́n sàn. Ìwé àtìgbàdégbà kan tó dá lórí ìṣègùn, èyí tí wọ́n ń pè ní American Journal of Geriatric Psychiatry pe ìlànà yìí ní “àṣà òde òní tó fara jọ àṣà kíkun òkú lọ́ṣẹ táwọn ará Íjíbítì ìgbàanì máa ń ṣe.”

      Bí ọmọ aráyé ṣe ń wá ọ̀nà téèyàn lè gbà wà láàyè títí láé lójú méjèèjì fi hàn pé kò sẹ́ni tó fẹ́ kú. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kéèyàn wà láàyè títí láé? Kí ni Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí ni yóò dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí.

  • O Lè Wà Láàyè Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́—2006 | October 1
    • O Lè Wà Láàyè Títí Láé

      ÈYÍ tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹlẹ́sìn ló gbà gbọ́ pé ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, èèyàn lè wà láàyè títí láé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan fi kọ́ni nípa èyí lè yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ohun kan náà ni gbogbo wọn ń sọ. Ìyẹn ni pé wọ́n fẹ́ ní ayọ̀, wọ́n sì fẹ́ wà nípò tó dáa láìsí ìbẹ̀rù pé àwọn máa kú. Ǹjẹ́ ohun tíwọ náà fẹ́ kọ́ nìyẹn? Kí la lè sọ pé ó fà á tírú ìgbàgbọ́ yìí fi kárí ayé? Ǹjẹ́ ìyè ayérayé táwọn èèyàn ń fẹ́ yìí máa tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ láé?

      Ìwé Mímọ́ fi ye wá pé Ẹlẹ́dàá ti fi ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé sọ́kàn ọmọ aráyé látìbẹ̀rẹ̀, ìyẹn látìgbà tó ti dá àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́. Bíbélì sọ pé: “Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.”—Oníwàásù 3:11.

      Báwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹn bá máa wà láàyè títí láé, wọ́n ní láti gbà pé Ọlọ́run ló ni àṣẹ láti pinnu bóyá ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́, kí wọ́n sì fara mọ́ àṣẹ náà. Ká ní wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ì bá kà wọ́n yẹ láti wà láàyè “fún àkókò tí ó lọ kánrin” ní ibi tó ṣe fún wọn láti máa gbé, ìyẹn ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́nẹ́sísì 2:8; 3:22.

      Bí Aráyé Ṣe Pàdánù Ìyè Àìnípẹ̀kun

      Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run gbin “igi ìmọ̀ rere àti búburú” sínú ọgbà náà, ó sì sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso igi náà, kí wọ́n má bàa kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 17) Ṣíṣàì jẹ nínú èso igi náà ni Ọlọ́run á fi mọ̀ pé Ádámù àti Éfà fara mọ́ àṣẹ òun. Àmọ́ ńṣe ni jíjẹ́ nínú rẹ̀ á fi hàn pé wọn ò fara mọ́ àṣẹ Ọlọ́run rárá. Ádámù àti Éfà kò tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, Sátánì ni wọ́n tẹ̀ lé, ìyẹn ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run pinnu pé Ádámù àti Éfà ò yẹ lẹ́ni tó ń wà láàyè títí láé.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6.

      Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n yan ìyè tàbí ikú, láti wà láàyè tàbí láti jẹ́ aláìsí. Ikú ni àìgbọ́ràn wọn yọrí sí, ìyẹn sì fòpin sí ìwàláàyè wọn. Kò ṣeé ṣe fún Ádámù àti Éfà tàbí èyíkéyìí lára àwọn àtọmọdọ́mọ wọn láti máa wà láàyè títí lọ nípasẹ̀ oògùn ajẹ́bíidán kan tàbí nípasẹ̀ ọkàn kan tí kò lè kú.a

      Gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù ló ń jìyà nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀ yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tó wá jẹ́ àbájáde rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

      Bí Aráyé Yóò Tún Ṣe Rí Ìyè Àìnípẹ̀kun Gbà Padà

      Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ipò tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù wà. Ó fi ipò wọn wé ti ẹrú kan ní ọ̀rúndún kìíní. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá yìí, àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà dẹni tá a bí ní “ẹrú ẹ̀ṣẹ̀,” tó sì di dandan kí wọ́n kú. (Róòmù 5:12; 6:16, 17) Kò sí bí wọn ṣe lè bọ́ nínú ipò ẹrú yìí tí kì í bá ṣe ohun tó bófin mu tí Jèhófà ṣe láti sọ wọ́n dòmìnira kúrò nínú ipò ẹrú yẹn. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àṣemáṣe kan [ìyẹn ti Ádámù] ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ ìdálẹ́bi, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè.” “Ìṣe ìdáláre” yẹn ló mú kí Jésù tó jẹ́ ẹni pípé fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.” Jèhófà mọ agbára tí ìràpadà yẹn ní láti gba èèyàn lọ́wọ́ ‘ìdájọ́ ìdálẹ́bi.’—Róòmù 5:16, 18, 19; 1 Tímótì 2:5, 6.

      Ìdí nìyẹn tí kò fi lè ṣeé ṣe láé fáwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ láti fi ìwádìí àbùdá èèyàn mọ báa ṣe lè wà láàyè títí láé. Ibòmíràn ni ojútùú sí ìṣòro náà wà. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, kì í ṣe pé Ọlọ́run dá ikú mọ́ èèyàn, àìgbọràn èèyàn ló fà á, Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ikú ni èrè àìgbọràn. Bákan náà, ẹbọ ìràpadà Jésù ni ọ̀nà tó bá ìdájọ́ òdodo mu tí aráyé yóò gbà ní ìyè àìnípẹ̀kun padà. Ìràpadà yẹn tún fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ olódodo, ó sì ní inú rere. Àwọn wo ni yóò wá jàǹfààní látinú ìràpadà náà tí wọ́n á sì ní ìyè àìnípẹ̀kun?

      Ẹ̀bùn Àìkú

      Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run tó wà “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” Kò lè kú. (Sáàmù 90:2) Jésù Kristi ni ẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà fún lẹ́bùn àìkú yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Kristi, nísinsìnyí tí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú, kò tún kú mọ́; ikú kò tún jẹ́ ọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.” (Róòmù 6:9) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ohun kan tí Jésù tá a jí dìde fi yàtọ̀ sáwọn alákòóso ayé, ó ní Jésù nìkan ṣoṣo ni kò lè kú. Jésù máa ‘wà láàyè títí láé.’ Ẹ̀mí rẹ̀ kò “ṣeé pa run.”—Hébérù 7:15-17, 23-25; 1 Tímótì 6:15, 16.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́