ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 10/1 ojú ìwé 4-7
  • O Lè Wà Láàyè Títí Láé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Aráyé Ṣe Pàdánù Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Bí Aráyé Yóò Tún Ṣe Rí Ìyè Àìnípẹ̀kun Gbà Padà
  • Ẹ̀bùn Àìkú
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Párádísè Orí Ilẹ̀ Ayé
  • Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tó Lọ Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ṣé Ẹní Bá Ti Kú Lè Pa Dà Wà Láàyè?
    Jí!—2008
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 10/1 ojú ìwé 4-7

O Lè Wà Láàyè Títí Láé

ÈYÍ tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹlẹ́sìn ló gbà gbọ́ pé ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, èèyàn lè wà láàyè títí láé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan fi kọ́ni nípa èyí lè yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ohun kan náà ni gbogbo wọn ń sọ. Ìyẹn ni pé wọ́n fẹ́ ní ayọ̀, wọ́n sì fẹ́ wà nípò tó dáa láìsí ìbẹ̀rù pé àwọn máa kú. Ǹjẹ́ ohun tíwọ náà fẹ́ kọ́ nìyẹn? Kí la lè sọ pé ó fà á tírú ìgbàgbọ́ yìí fi kárí ayé? Ǹjẹ́ ìyè ayérayé táwọn èèyàn ń fẹ́ yìí máa tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ láé?

Ìwé Mímọ́ fi ye wá pé Ẹlẹ́dàá ti fi ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé sọ́kàn ọmọ aráyé látìbẹ̀rẹ̀, ìyẹn látìgbà tó ti dá àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́. Bíbélì sọ pé: “Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.”—Oníwàásù 3:11.

Báwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹn bá máa wà láàyè títí láé, wọ́n ní láti gbà pé Ọlọ́run ló ni àṣẹ láti pinnu bóyá ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́, kí wọ́n sì fara mọ́ àṣẹ náà. Ká ní wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ì bá kà wọ́n yẹ láti wà láàyè “fún àkókò tí ó lọ kánrin” ní ibi tó ṣe fún wọn láti máa gbé, ìyẹn ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́nẹ́sísì 2:8; 3:22.

Bí Aráyé Ṣe Pàdánù Ìyè Àìnípẹ̀kun

Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run gbin “igi ìmọ̀ rere àti búburú” sínú ọgbà náà, ó sì sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso igi náà, kí wọ́n má bàa kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 17) Ṣíṣàì jẹ nínú èso igi náà ni Ọlọ́run á fi mọ̀ pé Ádámù àti Éfà fara mọ́ àṣẹ òun. Àmọ́ ńṣe ni jíjẹ́ nínú rẹ̀ á fi hàn pé wọn ò fara mọ́ àṣẹ Ọlọ́run rárá. Ádámù àti Éfà kò tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, Sátánì ni wọ́n tẹ̀ lé, ìyẹn ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run pinnu pé Ádámù àti Éfà ò yẹ lẹ́ni tó ń wà láàyè títí láé.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6.

Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n yan ìyè tàbí ikú, láti wà láàyè tàbí láti jẹ́ aláìsí. Ikú ni àìgbọ́ràn wọn yọrí sí, ìyẹn sì fòpin sí ìwàláàyè wọn. Kò ṣeé ṣe fún Ádámù àti Éfà tàbí èyíkéyìí lára àwọn àtọmọdọ́mọ wọn láti máa wà láàyè títí lọ nípasẹ̀ oògùn ajẹ́bíidán kan tàbí nípasẹ̀ ọkàn kan tí kò lè kú.a

Gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù ló ń jìyà nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀ yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tó wá jẹ́ àbájáde rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

Bí Aráyé Yóò Tún Ṣe Rí Ìyè Àìnípẹ̀kun Gbà Padà

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ipò tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù wà. Ó fi ipò wọn wé ti ẹrú kan ní ọ̀rúndún kìíní. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá yìí, àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà dẹni tá a bí ní “ẹrú ẹ̀ṣẹ̀,” tó sì di dandan kí wọ́n kú. (Róòmù 5:12; 6:16, 17) Kò sí bí wọn ṣe lè bọ́ nínú ipò ẹrú yìí tí kì í bá ṣe ohun tó bófin mu tí Jèhófà ṣe láti sọ wọ́n dòmìnira kúrò nínú ipò ẹrú yẹn. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àṣemáṣe kan [ìyẹn ti Ádámù] ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ ìdálẹ́bi, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè.” “Ìṣe ìdáláre” yẹn ló mú kí Jésù tó jẹ́ ẹni pípé fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.” Jèhófà mọ agbára tí ìràpadà yẹn ní láti gba èèyàn lọ́wọ́ ‘ìdájọ́ ìdálẹ́bi.’—Róòmù 5:16, 18, 19; 1 Tímótì 2:5, 6.

Ìdí nìyẹn tí kò fi lè ṣeé ṣe láé fáwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ láti fi ìwádìí àbùdá èèyàn mọ báa ṣe lè wà láàyè títí láé. Ibòmíràn ni ojútùú sí ìṣòro náà wà. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, kì í ṣe pé Ọlọ́run dá ikú mọ́ èèyàn, àìgbọràn èèyàn ló fà á, Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ikú ni èrè àìgbọràn. Bákan náà, ẹbọ ìràpadà Jésù ni ọ̀nà tó bá ìdájọ́ òdodo mu tí aráyé yóò gbà ní ìyè àìnípẹ̀kun padà. Ìràpadà yẹn tún fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ olódodo, ó sì ní inú rere. Àwọn wo ni yóò wá jàǹfààní látinú ìràpadà náà tí wọ́n á sì ní ìyè àìnípẹ̀kun?

Ẹ̀bùn Àìkú

Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run tó wà “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” Kò lè kú. (Sáàmù 90:2) Jésù Kristi ni ẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà fún lẹ́bùn àìkú yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Kristi, nísinsìnyí tí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú, kò tún kú mọ́; ikú kò tún jẹ́ ọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.” (Róòmù 6:9) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ohun kan tí Jésù tá a jí dìde fi yàtọ̀ sáwọn alákòóso ayé, ó ní Jésù nìkan ṣoṣo ni kò lè kú. Jésù máa ‘wà láàyè títí láé.’ Ẹ̀mí rẹ̀ kò “ṣeé pa run.”—Hébérù 7:15-17, 23-25; 1 Tímótì 6:15, 16.

Kì í ṣe Jésù nìkan ló gba irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nínú ògo ti ọ̀run náà ní irú àjíǹde kan náà tí Jésù ní. (Róòmù 6:5) Àpọ́sítélì Jòhánù fi hàn pé Ọlọ́run fún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ní àǹfààní yìí pẹ̀lú. (Ìṣípayá 14:1) Àwọn náà gba ẹ̀bùn àìkú. Ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ nípa àjíǹde wọn ni pé: “Ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run . . . Kàkàkí yóò dún, a ó sì gbé àwọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́, a ó sì yí wa padà. Nítorí èyí tí ó lè díbàjẹ́ yìí gbọ́dọ̀ gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, àti èyí tí ó jẹ́ kíkú yìí gbọ́dọ̀ gbé àìkú wọ̀.” Ikú kò ní agbára kankan lórí àwọn tó gba irú àjíǹde bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:50-53; Ìṣípayá 20:6.

Ohun tí Ọlọ́run ṣí payá fún wa yìí ga lọ́lá gan-an. Kódà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni ẹ̀mí làwọn áńgẹ́lì, Ọlọ́run ò dá wọn lẹ́ni tí kò lè kú. Ìdí tá a fi mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé gbogbo àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ yẹn ni Ọlọ́run máa pa run. (Mátíù 25:41) Àmọ́ àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi gba ẹ̀bùn àìkú ní tiwọn, èyí tó fi hàn pé Jèhófà fọkàn tán wọn gan-an pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kìkì àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí wọ́n jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ lára ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti gbé ayé yìí, ló máa wà láàyè títí láé? Rárá o. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.

Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Párádísè Orí Ilẹ̀ Ayé

Ìwé Ìṣípayá inú Bíbélì fi ìran kan tó lẹ́wà hanni, èyí tó sọ nípa àìlóǹkà èèyàn tó máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Lára àwọn wọ̀nyí làwọn òkú tó máa jíǹde tí ara wọn á tún padà dà bíi ti ọ̀dọ́ tí wọ́n á sì lókun. (Ìṣípayá 7:9; 20:12, 13; 21:3, 4) A darí wọn sí ‘odò omi ìyè kan tí ó mọ́ kedere bí kírísítálì, tí ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run.’ “Àwọn igi ìyè” sì wà ní ẹgbẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀. “Ewé àwọn igi náà sì wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” Jèhófà Ọlọ́run wá ń fìfẹ́ pe àwọn èèyàn pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ . . . máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìṣípayá 22:1, 2, 17.

Àwọn igi wọ̀nyí àti omi náà kì í ṣe oògùn ajẹ́bíidán tí kì í jẹ́ kéèyàn kú o, èyí táwọn kan tó máa ń lọ káàkiri láti rí oògùn tó ń jẹ́ kí ẹ̀mí èèyàn gùn ń wá ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Kì í sì í ṣe ìsun omi àjídèwe táwọn olùṣèwádìí kan ń wá kiri nígbà náà lọ́hùn-ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dúró fún ohun tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Jésù Kristi ṣe láti mú ọmọ aráyé padà di pípé bí wọ́n ṣe wà níbẹ̀rẹ̀.

Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn kò tíì yí padà o, ìyẹn ni láti fún àwọn èèyàn tó bá ṣègbọràn ní ìyè ayérayé. Ó máa nímùúṣẹ, nítorí pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin. Sáàmù 37:29 sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Ìlérí yìí ló mú kí àwa àtàwọn tó máa gba ẹ̀bùn àìkú ni ọ̀run máa polongo pé: “Títóbi àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ ní ti gidi, Jèhófà, tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo, nítorí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin?”—Ìṣípayá 15:3, 4.

Ǹjẹ́ ìyè ayérayé tó jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye wù ọ́? Tó bá wù ọ́, ó gbọ́dọ̀ fẹ̀rí hàn pé adúróṣinṣin ni ọ́, kó o sì máa ṣègbọràn sí “Ọba ayérayé.” O ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtẹni tó jẹ́ pé ipasẹ̀ rẹ̀ ni ìyè ayérayé náà yóò fi ṣeé ṣe, ìyẹn Jésù Kristi. Gbogbo ẹni tó múra tán láti fara mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ ló máa rí ẹ̀bùn “ìyè àìnípẹ̀kun” gbà.—Jòhánù 17:3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jọ̀wọ́ wo ìwé pẹlẹbẹ Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú? kó o lè rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìyè Àìnípẹ̀kun Ti Ń Wu Àwọn Èèyàn Tipẹ́

Ìtàn Akọni ti Gilgamesh táwọn ará Mesopotámíà máa ń sọ tí wọ́n sì gbà pé ó ṣẹlẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, sọ nípa bí akọni kan ṣe ń wá ohun tí kò ní jẹ́ kóun darúgbó. Àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì náà máa ń kun òkú lọ́ṣẹ, wọ́n lérò pé ọkàn kì í kú, pé yóò sì tún padà wá lo ara tó bọ́ sílẹ̀ náà tó bá yá. Nítorí èyí, oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n kó sínú ibojì àwọn ará Íjíbítì kan, èrò wọn ni pé òkú náà lè nílò àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tó bá débi tí wọ́n gbà pé ó ń lọ lẹ́yìn ikú.

Àwọn ará Ṣáínà tó ń wá oògùn tó máa jẹ́ kí ẹ̀mí èèyàn gùn kiri gbà gbọ́ pé ara èèyàn kì í kú, ìgbàgbọ́ yìí sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí di ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Kristẹni. Bákan náà, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní pé ara èèyàn lè wà láìkú nípasẹ̀ oògùn àwọn oníṣẹ́ idán kan tún fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí di ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Kristẹni. Àwọn ará ilẹ̀ Yúróòpù àti ilẹ̀ Lárúbáwá nígbà ojú dúdú, tí wọ́n ń wá oògùn tó máa jẹ́ kéèyàn wà láàyè títí láé kiri gbìyànjú láti fúnra wọn ṣe àwọn oògùn àjídèwe kan. Lára àwọn ohun tí wọ́n pò pọ̀ láti fi ṣe oògùn náà ni iyọ̀ tó ní àwọn èròjà kan tó ń jẹ́ arsenic, mẹ́kúrì àti imí ọjọ́ nínú. Ọlọ́run ló mọye àwọn tó para wọn níbi tí wọ́n ti ń mu ohun tí wọ́n pò pọ̀ yìí!

Ohun kan tó tún gbòde kan lákòókò kan ni ìtàn àròsọ nípa ibì kan tí wọ́n pè ní Ìsun Omi Àjídèwe, ìyẹn ìsun omi kan tí wọ́n sọ pé ó máa ń sọ agbára ẹnikẹ́ni tó bá mu nínú rẹ̀ dọ̀tun.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé Ayé Á Súni Tá A Bá Wà Láàyè Títí Láé?

Àwọn kan sọ pé bópẹ́ bóyá, ayé á súni téèyàn bá wà láàyè títí láé. Wọ́n ní ńṣe lèèyàn á kàn máa fàkókò ṣòfò lórí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ níláárí, téèyàn á sì máa ṣe èyí láṣetúnṣe títí ayé. Bóyá ohun tí wọ́n rò pé kéèyàn wà láàyè títí láé túmọ̀ sí ni pé, kéèyàn máa gbé irú ìgbésí ayé tá à ń gbé nísinsìnyí lọ, àti pé ipò tá a wà báyìí á máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbà pé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ yóò súni, kò sì ní nítumọ̀. Àmọ́, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fáwọn èèyàn tó máa gbé nínú Párádísè tó máa mú padà wá ni pé, “wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) Irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ yóò fún aráyé láǹfààní láti ní ìmọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá, wọ́n á sì lè lo àkókò wọn láti lóye iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́ tàbí gbogbo iṣẹ́ pàápàá, wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á sì ṣe àwọn iṣẹ́ tó ń wù wọ́n nísinsìnyí àmọ́ tí wọn ò láǹfààní láti ṣe.

Ọ̀mọ̀wé Aubrey de Grey, onímọ̀ nípa àbùdá èèyàn láti Yunifásítì Cambridge tó ṣèwádìí lórí ọ̀nà táwọn èèyàn fi lè túbọ̀ pẹ́ láyé sí i, sọ pé: “Lónìí, nǹkan kì í su àwọn tó ní ẹ̀kọ́ tó jíire tí wọ́n sì ní àkókò láti lo ẹ̀kọ́ náà, wọn ò sì jẹ́ ronú pé ìgbà kan máa wà táwọn ò ní rí nǹkan tuntun tó máa wu àwọn láti ṣe.” Kódà, Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí sọ pé, “aráyé [kò lè] rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”—Oníwàásù 3:11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́