Ṣé Ẹní Bá Ti Kú Lè Pa Dà Wà Láàyè?
NÍNÚ fíìmù kan tí wọ́n ṣe ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ọ̀dọ́mọkùnrin kan dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ sàréè èèyàn rẹ̀ kan. Ó sọ pé: “Màmá máa ń sọ fún mi pé gbogbo ẹ̀dá ló ti dá agbádá ikú.” Lẹ́yìn yẹn, bí wọ́n ṣe fi sàréè tí wọ́n sin màmá ẹ̀ sí hàn báyìí, ló bá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ì bá wù mí ká léèyàn lè rí oògùn ikú ṣe.”
Èrò tí ọmọkùnrin yìí ní jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ èèyàn tí ẹni wọn kan ti ṣaláìsí. Ọ̀tá èèyàn mà ni ikú jẹ́ lóòótọ́ o! Abájọ tí Ọlọ́run fi ṣèlérí pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Àmọ́, kí nìdí tá a fi ń kú, nígbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run dá wa pẹ̀lú ọpọlọ àgbàyanu tó fi hàn pé a lè máa wà láàyè títí láé? Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa sọ ikú di asán?
Ìdí Tá A Fi Ń Darúgbó Tá A sì Ń Kú
Bíbélì sọ nípa Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4; Sáàmù 83:18) Ọlọ́run dá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ ní pípé, ó sì lágbára láti wà láàyè títí láé nínú ọgbà Édẹ́nì, ìyẹn ọgbà Párádísè tí Ọlọ́run fi í sí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9) Kí nìdí tí Ádámù fi pàdánù ọgbà Párádísè yẹn, tó darúgbó tó sì kú?
Ohun tó fà á ni pé Ádámù ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé kó má ṣe jẹ lára èso igi kan báyìí nínú ọgbà náà. Ọlọ́run sì ti kìlọ̀ fún un nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bó bá jẹ nínú èso igi náà, pé: “Dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ádámù dara pọ̀ mọ́ aya rẹ̀, Éfà láti ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, torí náà, Ọlọ́run lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Ó ṣe pàtàkì ká kíyè sí i pé nígbà tí Bíbélì ń ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run ò fi fi ìdájọ́ wọn falẹ̀, ó sọ pé: “Kí [Ádámù] má bàa na ọwọ́ rẹ̀ jáde, kí ó sì tún mú èso ní ti tòótọ́, láti ara igi ìyè [tó wà nínú ọgbà náà], kí ó sì jẹ kí ó sì wà láàyè [títí láé].”—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 22.
Ádámù àti Éfà kú nítorí pé wọ́n ṣàìgbọràn, àmọ́ kí nìdí tí gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn fi ń ṣàìsàn tí wọ́n sì ń kú? Ìdí ni pé wọ́n ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù, ẹ̀ṣẹ̀ sọ gbogbo wọn di aláìpé, gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í kú. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.
Èèyàn Lè Pa Dà Wà Láàyè
Bá a ṣe kà á nínú Bíbélì lẹ́ẹ̀kan, “ikú ni a ó sọ di asán,” àní sẹ́, Ọlọ́run yóò mú un kúrò títí láé fáàbàdà! (1 Kọ́ríńtì 15:26) Lọ́nà wo nìyẹn? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè.” (Róòmù 5:18) Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún onírúurú èèyàn láti jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run kí wọ́n sì gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun?
Ètò tí Ọlọ́run ti ṣe láti mú ẹ̀ṣẹ̀ tí gbogbo aráyé ti jogún látọ̀dọ̀ Ádámù tó jẹ́ ọkùnrin àkọ́kọ́ kúrò ló máa mú kó ṣeé ṣe. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ètò tó wà nílẹ̀ fún pípolongo àwọn èèyàn ní olódodo fún ìyè, ó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [aráyé] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Ronú nípa bí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ṣe pọ̀ tó àti ìfẹ́ tí Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ ní sí wa tó fi jìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nítorí wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Ọmọ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.’ (Gálátíà 2:20) Kí wá nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù ni ẹ̀dá èèyàn kan ṣoṣo tó lè “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà” nítorí tiwa kó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà wá lọ́wọ́ àbájáde búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ ń mú wá?—Mátíù 20:28.
Jésù ni ẹnì kan ṣoṣo tó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà torí pé òun ni ẹ̀dá èèyàn kan ṣoṣo tí kò jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Ádámù. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ńṣe ni Ọlọ́run mú kí Màríà tó jẹ́ wúńdíá lóyún Jésù lọ́nà ìyanu. Torí náà, gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì kan ṣe sọ fún Màríà, ọmọ rẹ̀ jẹ́ “mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:34, 35) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jésù ní “Ádámù ìkẹyìn” ìyẹn náà ló sì fà á tí kò fi jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ “Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:45) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀, ó wá ṣeé ṣe fún Jésù láti fi ara rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí.” Ìyẹn ni pé ẹ̀mí rẹ̀ ṣe rẹ́gí tàbí pé ó dọ́gba pẹ̀lú ti ọkùnrin àkọ́kọ́, tó ti fìgbà kan jẹ́ ẹni pípé.—1 Tímótì 2:6.
Nípasẹ̀ ìràpadà yìí ni Ọlọ́run fi mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ohun tí Ádámù àkọ́kọ́ pàdánù gbà, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, ká bàa lè jàǹfààní ìràpadà yìí, àfi kí èyí tó pọ̀ jù lọ lára ẹ̀dá èèyàn tó ti kú tún pa dà wà láàyè. Ohun àgbàyanu tó yẹ kéèyàn máa fojú sọ́nà fún mà lèyí o! Àbí ọ̀rọ̀ àsọdùn lásán là ń sọ ni?
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Á Gbọ́
Ṣó yẹ kó ṣòro jù fún wa láti gbà gbọ́ pé ó máa ṣeé ṣe fún Jèhófà Ọlọ́run tó dá ohun gbogbo láti tún ẹni tó ti wà láàyè rí dá? Ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe mú kó ṣeé ṣe fún obìnrin àkọ́kọ́ láti lóyún. “Ádámù ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú Éfà,” lóṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, Éfà bí ọmọdé jòjòló kan tó rí gẹ́lẹ́ bíi tiwọn. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1) Ìyanu gbáà ni gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tọ́mọ náà ń dàgbà nínú ikùn Éfà, àwámárìídìí sì ni fáwa ẹ̀dá!—Sáàmù 139:13-16.
Torí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ làwọn èèyàn ń bí lójoojúmọ́, kò tún fi bẹ́ẹ̀ dà bí ohun àrà mọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì ń rò pé kò lè ṣeé ṣe fẹ́ni tó ti kú láti pa dà wà láàyè. Nígbà tí Jésù ń sọ fáwọn èèyàn tó ń ṣọ̀fọ̀ ikú ọmọdébìnrin kan pé kí wọ́n má sunkún mọ́, “wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi í rẹ́rìn-ín tẹ̀gàn-tẹ̀gàn” torí wọ́n mọ̀ pó ti kú. Àmọ́, Jésù sọ fún ọmọdébìnrin náà pé: “‘Dìde!’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, omidan náà sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn.” Bíbélì jẹ́ kó yé wa pé: “Ní kíá, [àwọn tó wà níbẹ̀] kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.”—Máàkù 5:39-43; Lúùkù 8:51-56.
Nígbà tí Jésù sọ pé kí wọ́n ṣí ibojì Lásárù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n, Màtá, ẹ̀gbọ́n Lásárù kọ̀ láti ṣí i, ó ní: “Ní báyìí yóò ti máa rùn, nítorí ó di ọjọ́ mẹ́rin.” Àmọ́, ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún wọn nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde! (Jòhánù 11:38-44) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Nígbà tí Jòhánù Oníbatisí wà lẹ́wọ̀n, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ròyìn àwọn nǹkan tí Jésù ń ṣe fún un, pé: “A ń gbé àwọn òkú dìde.”—Lúùkù 7:22.
Àjíǹde Á Mú Kó Ṣeé Ṣe Láti Pa Dà Wà Láàyè
Kí nìdí tí Jésù fi ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó wò sàn àtàwọn tó jí dìde tún pa dà ṣàìsàn tí wọ́n sì kú? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó bàa lè fẹ̀rí hàn pé Ọlọ́run máa mú ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, èyí tí Ádámù àkọ́kọ́ pàdánù wá, ó sì dájú pé ohun tó máa ṣe gan-an nìyẹn. Àwọn òkú tí Jésù jí dìde fi hàn pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ èèyàn máa jogún “ilẹ̀ ayé” tí wọ́n á sì “máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
Inú wa dùn pé a lè wà lára àwọn tó máa jàǹfààní ìbùkún àgbàyanu láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé bá a bá ń fi ‘ìfọkànsìn Ọlọ́run’ ṣèwà hù. Bíbélì sọ pé irú ìfọkànsìn Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” ‘Ìyè tí ń bọ̀’ yẹn ni Bíbélì tún pè ní “ìyè tòótọ́.”—1 Tímótì 4:8; 6:19.
Wàyí o, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí ìyè tòótọ́ yìí, ìyẹn ìwàláàyè tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun òdodo, ṣe máa rí gan-an.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
“Wọn kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ”