Jésù Ń gbani Là—Lọ́nà Wo?
“Jésù ń gbani là!” “Jésù ni Olùgbàlà wa!” A lè rí irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lára àwọn ògiri ilé àtàwọn ibòmíràn nígboro ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kárí ayé. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló fi tọkàntọkàn gbà pé Jésù ni Olùgbàlà wọn. Tó o bá bi wọ́n pé, “Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ Olùgbàlà wa?” ó ṣeé ṣe kí wọ́n dáhùn pé, “Jésù kú fún wa,” tàbí “Jésù kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Dájúdájú, ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìgbàlà. Àmọ́ báwo ni ikú ọkùnrin kan ṣoṣo ṣe lè ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ògìdìgbó ènìyàn? Tá a bá bi ọ́ pé, “Báwo ni ikú Jésù ṣe lè gbà wá là?” Kí lo máa sọ?
BÍ BÍBÉLÌ ṣe dáhùn ìbéèrè yìí ò le rárá, àmọ́, ó ṣe kedere, ó sì ṣe pàtàkì púpọ̀. Ṣùgbọ́n ká tó lè mọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wo ìgbésí ayé Jésù àti ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ojútùú sí ìṣòro líle koko kan. Ìgbà yẹn nìkan ṣoṣo la lè lóye bí ikú Jésù ṣe níye lórí tó.
Nípa jíjẹ́ kí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, Ọlọ́run ń tipa bẹ́ẹ̀ bójú tó ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ádámù ṣẹ̀. Àjálù ńlá mà ni ẹ̀ṣẹ̀ yẹn o! Ọkùnrin àkọ́kọ́ pàá àti Éfà aya rẹ̀ jẹ́ ẹni pípé. Ọgbà Édẹ́nì rírẹwà ni ilé wọn. Ọlọ́run fún wọn ní iṣẹ́ àtàtà náà pé kí wọ́n máa bójú tó ọgbà ẹlẹ́wà tó jẹ́ ilé wọn. Wọ́n tún ní láti máa fìfẹ́ bójú tó àwọn nǹkan abẹ̀mí mìíràn tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Báwọn èèyàn ṣì ṣe ń pọ̀ sí i, tí wọ́n ń fi àràádọ́ta ọ̀kẹ́ irú tiwọn kún orí ilẹ̀ ayé, wọn yóò nasẹ̀ Párádísè náà dé igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ tó mìrìngìndìn, tó sì ń mórí ẹni yá la fún wọn yìí! Láfikún sí i, àwọn méjèèjì ń gbádùn ìfararora. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Kò sí nǹkan tí wọn ò ní. Ìyè ayérayé aláyọ̀ sì wà fún wọn.
Ó yani lẹ́nu gan-an pé Ádámù tàbí Éfà lè dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́, tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí ẹni náà gan-an tó ṣẹ̀dá wọn—ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Nípa lílo ejò, ẹ̀dá ẹ̀mí náà Sátánì Èṣù tan Éfà láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà, Ádámù sì tẹ̀ lé e.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6.
Kò sí iyèméjì kankan nípa ohun tí Ẹlẹ́dàá máa ṣe sí ọ̀ràn Ádámù àti Éfà. Ó kúkú ti sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde àìgbọràn fún wọn, nígbà tó sọ pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì gan-an wá dìde báyìí.
Ìran Ènìyàn Dojú Kọ Ìṣòro Líle Koko
Ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ yẹn fa ìṣòro líle koko fún ìran ènìyàn. Ẹni pípé ni Ádámù nígbà tí a dá a. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ ì bá ti gbádùn ìwàláàyè pípé láìnípẹ̀kun. Àmọ́, Ádámù ṣẹ̀ kó tó bí ọmọ kankan. Gbogbo ìran ènìyàn ṣì wà ní abẹ́nú rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá a lẹ́jọ́ pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Nítorí náà, nígbà tí Ádámù ṣẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ sí kú díẹ̀díẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe sọ, gbogbo ìran ènìyàn la dájọ́ ikú fún pẹ̀lú rẹ̀.
Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [ìyẹn, Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ yẹn, àwọn ọmọ tó yẹ kí wọ́n bí ní pípé, kí wọ́n sì wà láàyè títí láé wá di ẹni tó jogún àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú.
Ẹnì kan lè sọ pé: “Kò sì dára bẹ́ẹ̀ o. Ṣebí àwa kọ́ la ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run—Ádámù ni. Kí wá nìdí tá a ó fi pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun àti ayọ̀ wa?” A mọ̀ pé bí ilé ẹjọ́ kan bá fi ọmọ kan sẹ́wọ̀n nítorí pé baba rẹ̀ jí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé, ó tọ́ kí ọmọ náà ṣàròyé pé: “Èyí ò bójú mu rárá! Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀.”—Diutarónómì 24:16.
Nípa sísún àwọn ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀, Sátánì ti lè parí rẹ̀ sí pé òun máa bá Ọlọ́run débi tí kò ti ní rí ohunkóhun ṣe sí ọ̀ràn náà. Àtìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn ni Èṣù ti dá wàhálà sílẹ̀, àní kó tó di pé wọ́n bí ọmọ èyíkéyìí. Gbàrà tí Ádámù ṣẹ̀, ìbéèrè pàtàkì tó dìde ni pé, Kí ni Jèhófà máa ṣe nípa àwọn ọmọ tí Ádámù àti Éfà yóò bí?
Jèhófà Ọlọ́run ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ. Élíhù ọkùnrin olódodo nì polongo pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú, àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!” (Jóòbù 34:10) Wòlíì Mósè sì kọ̀wé nípa Jèhófà pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Ojútùú tí Ọlọ́run òtítọ́ wá sí ìṣòro tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù dá sílẹ̀ kò gba àǹfààní tá a ní láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé kúrò lọ́wọ́ wa.
Ọlọ́run Wá Ojútùú sí Ọ̀ràn Náà
Ronú nípa ọ̀nà àbájáde tí Ọlọ́run là sílẹ̀ nígbà tó ń dá Sátánì Èṣù lẹ́jọ́. Jèhófà sọ fún Sátánì pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà [ètò Ọlọ́run ti òkè ọ̀run] àti sáàárín irú-ọmọ rẹ [ayé tó wà lábẹ́ àkóso Sátánì] àti irú-ọmọ rẹ̀ [Jésù Kristi]. Òun yóò pa ọ́ [Sátánì] ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀ [ikú Jésù].” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Inú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì yìí ni Jèhófà ti mẹ́nu kan ète rẹ̀ láti jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí, tó wà ní ọ̀run, wá sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin pípé náà, Jésù, kí ó sì kú,—ìyẹn ni kí a pa á ní gìgísẹ̀—gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìlẹ́ṣẹ̀.
Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fẹ́ kí ẹni pípé kan kú? Tóò, ìyà wo ni Jèhófà Ọlọ́run sọ pé òun máa fi jẹ Ádámù bí ó bá ṣẹ̀? Ṣebí ikú ni, àbí? (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Ikú tí Ádámù kú ló fi san ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. A fún un ní ìyè, ó yan ẹ̀ṣẹ̀, ó sì kú gẹ́gẹ́ bí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ìdálẹ́bi tí ìran ènìyàn lápapọ̀ wá ń bá yí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ńkọ́? Ó pọn dandan kí ẹnì kan kú láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àmọ́ ta ni ikú rẹ̀ tóótun láti mú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé kúrò?
Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì béèrè fún “ọkàn fún ọkàn [ìyẹn, ẹ̀mí fún ẹ̀mí].” (Ẹ́kísódù 21:23) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tó bófin mu yìí, ikú tó máa mú ẹ̀ṣẹ̀ ìran ènìyàn kúrò ní láti jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú ohun tí Ádámù sọ nù. Kìkì ikú ọkùnrin pípé mìíràn ló lè kájú ẹ̀ṣẹ̀ náà. Jésù sì ni ọkùnrin náà. Láìsí àní-àní, Jésù ni “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí” fún ìgbàlà gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù tó ṣeé rà padà.—1 Tímótì 2:6; Róòmù 5:16, 17.
Ikú Jésù Níye Lórí Gan-an
Ikú Ádámù kò ní ìtóye kankan; ó yẹ kó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ ikú Jésù níye lórí gan-an nítorí pé ó kú láìlẹ́ṣẹ̀ kankan. Jèhófà Ọlọ́run lè tẹ́wọ́ gba ìtóye ìwàláàyè pípé ti Jésù gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún àwọn onígbọràn tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀. Ìtóye ẹbọ Jésù ọ̀hún kò sì mọ sórí kíkájú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn nìkan. Ká ní ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn nìkan ló kájú ni, a jẹ́ pé kò sí ìrètí ọjọ́ ọ̀la kankan fún wa nìyẹn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ẹ̀ṣẹ̀ la ti lóyún wa, kò sí bí a ò ṣe tún ní dẹ́ṣẹ̀. (Sáàmù 51:5) A mà dúpẹ́ o, pé ikú Jésù fún wa láǹfààní láti jèrè ìjẹ́pípé tí Jèhófà ní lọ́kàn fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà níbẹ̀rẹ̀!
A lè fi Ádámù wé baba kan tó kú, tó sì fi gbèsè rẹpẹtẹ (ẹ̀ṣẹ̀) sílẹ̀ fún wa débi pé kò sọ́gbọ́n tá a fi lè bọ́ nínú gbèsè náà. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Jésù dà bí baba rere tó kú, tó fi ogún tó pọ̀ rẹpẹtẹ sílẹ̀ fún wa, tí kì í ṣe pé ó wulẹ̀ gbà wá nínú gbèsè wíwúwo tí Ádámù dá sí wa lọ́rùn nìkan àmọ́ tó tún fún wa ní ohun púpọ̀ láti gbádùn títí láé. Iṣẹ́ tí ikú Jésù ń ṣe kò mọ sórí wíwulẹ̀ mú ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn kúrò; ó tún jẹ́ ìpèsè àgbàyanu fún ọjọ́ ọ̀la wa.
Jésù ń gbani là nítorí pé ó kú fún wa. Ẹ sì wo ìṣètò tó níye lórí tí ikú rẹ̀ jẹ́! Tá a bá wò ó gẹ́gẹ́ bí ara ètò tí Ọlọ́run ṣe láti fi yanjú ìṣòro dídíjú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà, ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà àti nínú ọ̀nà tó gbà ń ṣe àwọn nǹkan yóò máa lágbára sí i. Dájúdájú, ikú Jésù jẹ́ ọ̀nà tí “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́” nínú Jésù yóò gbà bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àrùn, ọjọ́ ogbó, àti ikú pàápàá. (Jòhánù 3:16) Ǹjẹ́ o ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìṣètò onífẹ̀ẹ́ yìí fún ìgbàlà wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ádámù mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá sórí ìran ènìyàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Jèhófà wá ojútùú sí ọ̀ràn náà