Ẹnì Kan Tó Ti Lé Lọ́gọ́rùn-ún Ọdún Lóhun Pàtàkì Tó Ń Fayé Rẹ̀ Ṣe
ÌYÁ àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Elin wà lára ọgọ́ta [60] èèyàn tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ orúkọ wọn lórílẹ̀-èdè Sweden lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé wọ́n ti tó ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé márùn-ún [105] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé márùn-ún ni Elin, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè jáde nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó tó wà, ara rẹ̀ ṣì le tó láti máa wàásù, èyí sì ni ohun tó yàn láti máa ṣe láti ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn.
Tó bá di pé ká wàásù, àpẹẹrẹ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ ni Elin ń tẹ̀ lé. Nígbà táwọn aláṣẹ sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé, tí wọn ò jẹ́ kó jáde, gbogbo àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ló máa ń wàásù fún. (Ìṣe 28:16, 30, 31) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, Elin máa ń lo gbogbo àǹfààní tó bá ní láti wàásù ìhìn rere inú Bíbélì fún àwọn tó ń tọ́jú ilé tó ń gbé, àwọn olùtọ́jú eyín, àwọn dókítà, àwọn tó ń ṣe irun lóge, àwọn nọ́ọ̀sì, àtàwọn míì tó bá rí nínú ilé náà. Kódà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ìjọ tí Elin ń dara pọ̀ mọ́ máa ń mú àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lóòrèkóòrè káwọn yẹn lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìmọ̀ àti ìrírí rẹ̀.
Àwọn tó wà nínú ìjọ tí Elin wà mọyì bó ṣe jẹ́ ọlọ́yàyà àtẹni tó máa ń fẹ́ láti mọ̀ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan. Ẹlẹ́rìí kan sọ pé: “Bó ṣe darúgbó tó yẹn, ó mọ gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ìjọ. Ó máa ń rántí orúkọ gbogbo àwọn ọmọdé àtorúkọ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìjọ náà.” Kò mọ síbẹ̀ o, wọ́n tún mọ Elin sí ẹni tó láájò àlejò, tó máa ń ṣàwàdà tó sì máa ń túra ká.
Kí ló ran Elin lọ́wọ́ tó fi ń láyọ̀ tó sì gbájú mọ́ ohun tó yàn láti fìgbésí ayé rẹ̀ ṣe? Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni kíkà tó máa ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ látinú ìwé pẹlẹbẹ kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tí orúkọ rẹ̀ jẹ́, Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Bákan náà, ó máa ń lo awò tó ń sọ ọ̀rọ̀ di ńlá láti fi ka Bíbélì lójoojúmọ́. Láfikún, ó máa ń gbé ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ ní àwọn ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yẹ̀ wò kí àkókò àwọn ìpàdé náà tó tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í lè lọ sáwọn ìpàdé náà, àwọn ará máa ń gba ohun tí wọ́n kọ́ níbẹ̀ sínú kásẹ́ẹ̀tì kó lè gbọ́ ọ. Ohun yòówù kí ọjọ́ orí wa jẹ́, tá a bá ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì déédéé tí a kì í sì í pa ìpàdé ìjọ jẹ, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti máa gbé ìgbésí ayé tó dára tó sì nítumọ̀.—Sáàmù 1:2; Hébérù 10:24, 25.