Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni ìtumọ̀ ohun tí akónijọ sọ, pé òun rí kìkì “ọkùnrin kan nínú ẹgbẹ̀rún,” àmọ́ òun ò rí “obìnrin kan nínú gbogbo àwọn wọ̀nyí”?—Oníwàásù 7:28.
Ká tó lè mọ ohun tí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí túmọ̀ sí gan-an, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin. Bíbélì pe Rúùtù aya ọmọ Náómì tó jẹ́ opó ní “obìnrin títayọ lọ́lá.” (Rúùtù 3:11) Bákan náà, Òwe 31:10 sọ nípa aya rere pé, “ìníyelórí rẹ̀ pọ̀ púpọ̀púpọ̀ ju ti iyùn.” Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí ni Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Mo ti rí ọkùnrin kan nínú ẹgbẹ̀rún, ṣùgbọ́n èmi kò tíì rí obìnrin kan nínú gbogbo àwọn wọ̀nyí”?
Ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì ń bá bọ̀ kó tó kan ẹsẹ yìí fi hàn pé ìwàkiwà kún ọwọ́ ọ̀pọ̀ obìnrin nígbà ayé Sólómọ́nì. (Oníwàásù 7:26) Ohun tó sì ṣeé ṣe kó fa èyí jù ni àwọn obìnrin ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n ń jọ́sìn òrìṣà tí wọ́n ń pè ní Báálì. Kódà ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí Sólómọ́nì Ọba fi ṣaya sún un ṣe ohun tí kò yẹ. Bíbélì sọ pé Sólómọ́nì “ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin aya, àwọn ọmọbìnrin ọba, àti ọ̀ọ́dúnrún wáhàrì; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn aya rẹ̀ tẹ ọkàn-àyà rẹ̀” láti bá wọn bọ òrìṣà. (1 Àwọn Ọba 11:1-4) Bákan náà, ìwàkiwà kún ọwọ́ àwọn ọkùnrin. Tá a bá kó ẹgbẹ̀rún ọkùnrin kalẹ̀, agbára káká lèèyàn fi máa rí ẹnì kan lára wọn tó jẹ́ olódodo, àfi bíi pé kò tiẹ̀ sí rárá. Gbólóhùn tí Sólómọ́nì wá fi parí ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Èyí nìkan ṣoṣo ni mo ti rí, pé Ọlọ́run tòótọ́ ṣe aráyé ní adúróṣánṣán, ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwéwèé.” (Oníwàásù 7:29) Nígbà tó sọ bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé ó ń fi àwọn ọkùnrin wé àwọn obìnrin o, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń sọ̀rọ̀ nípa aráyé ní gbogbo gbòò, àtọkùnrin àtobìnrin. Nítorí náà, ó yẹ ká wo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Oníwàásù 7:28 gẹ́gẹ́ bí àlàyé nípa bí ìwà àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin ṣe rí nígbà ayé Sólómọ́nì.
Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ẹsẹ yìí ní ìtumọ̀ míì. Ó lè jẹ́ pé asọtẹ́lẹ̀ ni, nítorí pé kò tíì sí obìnrin kankan tó ṣègbọràn sí Jèhófà lọ́nà pípé. Àmọ́, a ti rí ẹnì kan láàárín àwọn ọkùnrin tó ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni náà ni Jésù Kristi.—Róòmù 5:15-17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“Ọkùnrin kan nínú ẹgbẹ̀rún”