ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 1/15 ojú ìwé 26-30
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Ṣe Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Ṣe Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • Àwọn Ọ̀nà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tó Múná Dóko Jù Lọ
  • Ran Akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Di Olùkọ́
  • “Gba Ara Rẹ àti Àwọn Tí Ń Fetí sí Ọ Là”
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 1/15 ojú ìwé 26-30

Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Ṣe Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni

“Ní ti èyíinì tí ó wà lórí erùpẹ̀ àtàtà, ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹ́yìn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ọkàn-àyà àtàtà àti rere, wọ́n dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso pẹ̀lú ìfaradà.”—LÚÙKÙ 8:15.

1, 2. (a) Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? (b) Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, báwo ni Jèhófà ṣe bù kún iṣẹ́ sísọni-dọmọ-ẹ̀yìn táwọn èèyàn rẹ̀ ṣe?

“ÌWÉ yìí ti lọ wà jù. Ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń gbádùn rẹ̀ gan-an ni, èmi pàápàá sì ń gbádùn rẹ̀. Ìwé yìí mú kó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì orí ìdúró.” Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù ló sọ bẹ́ẹ̀ nípa ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tó jẹ́ àgbàlagbà sọ nípa ìwé yìí kan náà pé: “Láti àádọ́ta [50] ọdún sẹ́yìn tí mo ti ń wàásù, mo ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti dẹni tó mọ Jèhófà. Àmọ́, mo gbà pé ìwé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀. Àwọn àpèjúwe téèyàn lè finú yàwòrán àtàwọn àwòrán tó wà nínú rẹ̀ máa ń gbádùn mọ́ni gan-an ni.” Ṣé èrò tí ìwọ náà ní nípa ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni nìyẹn? Ṣó o rí i, ńṣe la ṣe ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ, pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.

2 Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà ń dùn bó ṣe ń rí i tí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ààbọ̀ ń fi tọkàntọkàn ṣe ohun tí Jésù sọ, pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. (Òwe 27:11) Ẹ̀rí sì fi hàn pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2005, wọ́n wàásù ìhìn rere náà ní igba ó lé márùndínlógójì [235] orílẹ̀-èdè. Iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń darí lóṣooṣù lọ́dún yẹn tá a bá pín in dọ́gba jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́fà, ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [6,061,500]. Ohun tí èyí sì yọrí sí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ‘gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ́n sì gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ èèyàn, ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ (1 Tẹsalóníkà 2:13) Ní ọdún méjì tó kọjá, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ọmọ ẹ̀yìn tó mú ìgbé ayé wọn bá ìlànà Jèhófà mu tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí nípa bá a ṣe máa lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni?

3 Ǹjẹ́ o ti kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó o sì ní ayọ̀ tí èyí máa ń mú wá? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì wà jákèjádò ayé tí wọ́n ní “ọkàn-àyà àtàtà àti rere” tó jẹ́ pé tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n á “dì í mú ṣinṣin, wọ́n [á] sì so èso pẹ̀lú ìfaradà.” (Lúùkù 8:11-15) Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lẹ́nu iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Ìbéèrè mẹ́ta la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àwọn ìbéèrè náà rèé: (1) Báwo lo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (2) Irú àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo ló múná dóko jù lọ? (3) Báwo lo ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kóun náà sì lè máa fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́?

Bó O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

4. Kí ló lè mú káwọn kan lọ́ra láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, báwo lo sì ṣe lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbà láti kẹ́kọ̀ọ́?

4 Tí wọ́n bá ní kó o fo odò kan tó fẹ̀ dá lọ́wọ́ kan, bóyá lo máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ká ní ńṣe ni wọ́n to òkúta tó o lè gbà kọjá síbẹ̀, o lè má lọ́ra láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bọ́rọ̀ ṣe rí fún ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí nìyẹn. Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí lè má fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó lè máa rò pé tóun ò bá lè sapá gan-an, òun ò ní lè kẹ́kọ̀ọ́, àti pé á gba àkókò tó pọ̀ jù. Báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́ tó fi máa gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Tó o bá lo ìwé Bíbélì Fi Kọni láti fi bá a jíròrò ṣókí nínú Bíbélì fún ìgbà mélòó kan tẹ̀ léra wọn, tó o sì ṣe é lọ́nà tó fi máa rí nǹkan kọ́, ìyẹn lè mú kó gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Tó o bá ń múra sílẹ̀ dáadáa, ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpadàbẹ̀wò tó o bá ń ṣe sọ́dọ̀ rẹ̀ yóò máa ràn án lọ́wọ́ díẹ̀díẹ̀ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ńṣe ló máa dà bí ìgbà tó ń gbẹ́sẹ̀ lé orí àwọn òkúta tí wọ́n tò sínú odò níkọ̀ọ̀kan láti sọdá.

5. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ka ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni?

5 Àmọ́ ṣá o, kó o tó lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ìwọ alára ní láti mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ dáadáa. Ǹjẹ́ o ti ka ìwé náà látòkèdélẹ̀? Nígbà tí tọkọtaya kan rin ìrìn àjò lákòókò tí wọ́n gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n mú ìwé náà dání wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á bí wọ́n ṣe ń gbafẹ́ ní etíkun kan. Bí obìnrin kan tó ń gbé lágbègbè náà ṣe ń tajà fáwọn tó ń gbafẹ́ ní etíkun náà, ó dé ọ̀dọ̀ tọkọtaya yìí. Ó kíyè sí i pé àkọlé ìwé tí wọ́n mú dání ni, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ó wá sọ fún tọkọtaya náà pé ìbéèrè tó wà lára ìwé yẹn gan-an lòun gbàdúrà nípa rẹ̀ ní nǹkan bíi wákàtí mélòó kan sẹ́yìn, pé kí Ọlọ́run jẹ́ kóun rí ìdáhùn rẹ̀. Tayọ̀tayọ̀ ni tọkọtaya yìí fi fún un ní ẹ̀dà kan ìwé náà. Ǹjẹ́ o lè ‘ra àkókò padà’ láti ka ìwé náà tán, bóyá lẹ́ẹ̀kejì, kó o máa kà á nígbà tó o bá ń dúró de ẹnì kan tàbí lákòókò ìsinmi ọ̀sán ní iléèwé tàbí nígbà tó o bá ń sinmi lẹ́nu iṣẹ́? (Éfésù 5:15, 16) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ ohun tó wà nínú ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí dáadáa, ìyẹn á sì mú kó o fẹ́ láti wáyè sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nínú rẹ̀ fáwọn èèyàn.

6, 7. Báwo lo ṣe lè fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

6 Nígbà tó o bá ń fi ìwé náà lọ àwọn èèyàn lóde ẹ̀rí, máa lo àwòrán, ẹsẹ ìwé Mímọ́ àtàwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé 4, 5 àti 6 lọ́nà tó múná dóko. Bí àpẹẹrẹ, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ nípa sísọ pé: “Pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀ ìṣòro ṣe ń pọ́n aráyé lójú lóde òní, ibo lo rò pé a ti lè rí amọ̀nà tó ṣeé gbára lé?” Lẹ́yìn tó o bá ti fetí sílẹ̀ dáadáa sí èsì onítọ̀hún, ka 2 Tímótì 3:16, 17 kó o sì ṣàlàyé pé Bíbélì sọ ohun tó jẹ́ ojútùú gidi sí ìṣòro aráyé. Fi ojú ìwé 4 àti 5 hàn án kó o sì béèrè pé: “Nínú àwọn nǹkan tí wọ́n yàwòrán rẹ̀ sójú ìwé méjèèjì yìí, èwo ló ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́ jù lọ?” Lẹ́yìn tí onílé náà bá ti tọ́ka sí ọ̀kan, ka ẹsẹ Bíbélì tó wà níbi tó tọ́ka sí náà fún un látinú Bíbélì rẹ, kó o sì ní kó mú ìwé náà dání nígbà tó o bá ń ka ẹsẹ Bíbélì náà. Lẹ́yìn náà, ka ohun tó wà ní ojú ìwé 6 kó o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Nínú ìbéèrè mẹ́fà tó wà ní ọwọ́ ìsàlẹ̀ lójú ìwé yìí, èwo ni wàá fẹ́ mọ ìdáhùn rẹ̀?” Tó bá ti sọ èyí tó fẹ́, fi orí tí ìdáhùn rẹ̀ wà hàn án kó o sì fún un ní ìwé náà, kó o wá ṣe ètò tó mọ́yán lórí láti padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kẹ́ ẹ lè jíròrò ìbéèrè náà.

7 Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí ò lè gbà ju nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún lọ. Àmọ́ láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún yẹn, á ṣeé ṣe fún ọ láti mọ ohun tó ń jẹ ẹni náà lọ́kàn, á ṣeé ṣe fún ọ láti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjì kó o sì ṣàlàyé rẹ̀, á sì ṣeé ṣe fún ọ láti lànà sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò. Ó lè jẹ́ pé ó ti pẹ́ gan-an tẹ́ni náà ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ń mórí ẹni yá tó sì ń tuni nínú bí irú èyí tó o bá a sọ. Ìyẹn lè mú kí ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí pàápàá fẹ́ kó o fi kún àkókò tó ò ń lò lọ́dọ̀ òun bó o ṣe ń ràn án lọ́wọ́ kó lè bọ́ sójú ‘ọ̀nà tó lọ sí ìyè’ kó sì máa rìn nínú rẹ̀. (Mátíù 7:14) Bí ìfẹ́ tẹ́ni náà ní sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣe ń pọ̀ sí i, jẹ́ kí àkókò tẹ́ ẹ fi ń kẹ́kọ̀ọ́ gùn sí i. O lè dábàá pé kẹ́ ẹ jọ fẹnu kò sórí iye àkókò tẹ́ ẹ máa fi kún àkókò tẹ́ ẹ̀ ń lò.

Àwọn Ọ̀nà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tó Múná Dóko Jù Lọ

8, 9. (a) Báwo lo ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè borí àwọn ohun ìdíwọ́ àti ìdánwò tó ṣeé ṣe kó dojú kọ? (b) Ibo lo ti lè rí àwọn ohun èlò tí kò lè jóná tó o lè fi ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára?

8 Tẹ́nì kàn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, ó ṣeé ṣe kó dojú kọ àwọn ohun tó máa dí i lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Pọ́ọ̀lù fi àwọn ìdánwò bẹ́ẹ̀ wé iná tó lè jó àwọn ohun èlò ìkọ́lé tó lè jóná, àmọ́ tí kò lè jó àwọn ohun èlò ìkọ́lé bíi wúrà, fàdákà àti òkúta iyebíye. (1 Kọ́ríńtì 3:10-13; 1 Pétérù 1:6, 7) Kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lè ní àwọn ànímọ́ tó gbọ́dọ̀ ní kó tó lè borí ìdánwò tó ṣeé ṣe kó dojú kọ, o ní láti ràn án lọ́wọ́ nípa lílo àwọn ohun èlò tí kò lè jóná nígbà tó o bá ń kọ́ ọ.

9 Onísáàmù fi “àwọn àsọjáde Jèhófà” wé “fàdákà tí a yọ́ mọ́ nínú ìléru ìyọ́rin ti ilẹ̀, tí a mú mọ́ kedere ní ìgbà méje.” (Sáàmù 12:6) Gbogbo àwọn ohun èlò tí kò lè jóná téèyàn lè lò kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára wà nínú Bíbélì. (Sáàmù 19:7-11; Òwe 2:1-6) Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe máa lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó múná dóko.

10. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ̀ pé inú Bíbélì làwọn ohun tó ń kọ́ ti wá?

10 Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́, máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ̀ pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú orí tẹ́ ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì gan-an. Lo àwọn ìbéèrè láti fi jẹ́ kó lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì kó sì sọ bó ṣe kan òun alára. Rí i pé ìwọ kọ́ lò ń pinnu ohun tó yẹ kó ṣe fún un o. Ńṣe ni kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà tí ọkùnrin kan tó mọ Òfin Mósè dáadáa béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù, Jésù fèsì pé: “Kí ni a kọ sínú Òfin? Báwo ni ìwọ ṣe kà á?” Ọkùnrin náà dáhùn látinú Ìwé Mímọ́, Jésù sì jẹ́ kó mọ bó ṣe máa fi ìlànà náà sílò. Jésù tún lo àpèjúwe kan tó jẹ́ kí ọkùnrin náà rí ọ̀nà tí ẹ̀kọ́ náà gbà kan òun. (Lúùkù 10:25-37) Ọ̀pọ̀ àpèjúwe tó rọrùn ló wà nínú Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tó o lè fi ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè mọ bí òun ṣe máa lo àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó ń kọ́.

11. Báwo ni ibi tẹ́ ẹ ó máa kà lẹ́ẹ̀kan ṣe yẹ kó pọ̀ tó?

11 Bí Jésù ṣe máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ tó lè tètè yéni ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tó ta kókó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ṣe fi ọ̀rọ̀ tó rọrùn-ún lóye ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 7:28, 29) Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kó o máa ṣe àlàyé tó péye, àmọ́ kó o lo ọ̀rọ̀ tó rọrùn-ún lóye kí àlàyé náà sì ṣe kedere. Má ṣe kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ibi tó pọ̀ jù lẹ́ẹ̀kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fi ipò ẹni náà àti ibi tí òye rẹ̀ mọ pinnu iye ìpínrọ̀ tẹ́ ẹ ó kà lẹ́ẹ̀kan. Nítorí pé Jésù mọ ibi tí òye àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ, kò ṣe àlàyé tó pọ̀ ju ohun tí wọ́n máa lè lóye lákòókò tó ṣe àlàyé náà fún wọn.—Jòhánù 16:12.

12. Báwo ló ṣe yẹ kó o lo àfikún tó wà nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni?

12 Àfikún kan tó ní àkòrí mẹ́rìnlá wà ní apá ìparí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Níwọ̀n bó o ti mọ ibi tí òye akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ àti ohun tó nílò, pinnu bó o ṣe máa lo àwọn àkòrí tó wà nínú àfikún yìí lọ́nà tó dára jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, bó bá ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láti lóye ẹ̀kọ́ kan tàbí tó ní ìbéèrè lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan pàtó nítorí àwọn ẹ̀kọ́ tó ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀, o kàn lè sọ fún un pé kó fúnra rẹ̀ ka àkòrí tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àfikún náà. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tó máa ràn án lọ́wọ́ ni pé kẹ́ ẹ jọ jíròrò àkòrí náà. Àwọn àkòrí pàtàkì tá a mú látinú ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ ló wà nínú àfikún náà, irú bíi “Kí Ni ‘Ọkàn’ àti ‘Ẹ̀mí’ Jẹ́ Gan-an?” àti “Bá A Ṣe Dá ‘Bábílónì Ńlá’ Mọ̀.” O lè fẹ́ kí ìwọ àti akẹ́kọ̀ọ́ rẹ jọ jíròrò àwọn àkòrí wọ̀nyí. Níwọ̀n bí àfikún náà kò ti ní ìbéèrè nínú, ó yẹ kó o mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ dáadáa kó o lè béèrè àwọn ìbéèrè tó bá a mu.

13. Ipa wo ni àdúrà ń kó nínú mímú kí ìgbàgbọ́ ẹni lágbára?

13 Sáàmù 127:1 sọ pé: “Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.” Nítorí náà, máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kí àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí tó o bá ń gbà ní gbogbo ìgbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa fi àjọṣe tó dára tó o ní pẹ̀lú Jèhófà hàn. Gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún òun ní ọgbọ́n kóun lè lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó sì ràn òun lọ́wọ́ kóun lè máa fi ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀ sílò. (Jákọ́bù 1:5) Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó lè máa fara da àdánwò, ìgbàgbọ́ rẹ̀ yóò sì máa lágbára sí i.

Ran Akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Di Olùkọ́

14. Ìtẹ̀síwájú wo ló yẹ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní?

14 Káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tó lè ṣe “gbogbo ohun” tí Jésù pa láṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, wọ́n ní láti tẹ̀ síwájú débi táwọn náà á fi dẹni tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:6-8) Kí lo lè ṣe láti ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè ní irú ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀?

15. Kí nìdí tó fi yẹ kó o gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó máa wá sí ìpéjọpọ̀ àwa Kristẹni?

15 Látìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ ni kó o ti máa sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ pé kó bá ọ lọ sí ìpàdé ìjọ. Ṣàlàyé fún un pé ìpàdé lo ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan, máa lo ìṣẹ́jú díẹ̀ ní gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́ láti ṣàlàyé ètò oúnjẹ tẹ̀mí tó ò ń gbádùn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpàdé ìjọ àti àpéjọ. Fi ìtara sọ àwọn àǹfààní tó o máa ń jẹ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpàdé àti àpéjọ wọ̀nyí. (Hébérù 10:24, 25) Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ti lè bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé báyìí, ó ṣeé ṣe kó dẹni tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

16, 17. Àwọn ohun wo ni akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ lè pinnu láti lépa kọ́wọ́ rẹ̀ sì tẹ̀ nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

16 Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè pinnu láti lépa àwọn ohun tọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ̀ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, gbà á níyànjú pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ tàbí ìbátan rẹ̀. Tún gbà á nímọ̀ràn pé kó pinnu láti ka Bíbélì látòkèdélẹ̀. Tó o bá ràn án lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì déédéé kó sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀, èyí á ràn án lọ́wọ́ fún ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, o lè gbà á níyànjú pé bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kó máa fi ó kéré tán, ẹsẹ Bíbélì kan tó dáhùn ìbéèrè pàtàkì kan sọ́kàn nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí tó wà nínú ìwé náà. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á di “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tímótì 2:15.

17 Gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó máa ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì tó bá lò nígbà tó bá ń dáhùn ìbéèrè táwọn èèyàn bi í nípa ohun tó gbà gbọ́, kó má kàn máa sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lórí tàbí kó kàn sọ ohun tó wà nínú rẹ̀ lọ́rọ̀ ara rẹ̀. Tẹ́ ẹ bá jọ fi dánra wò ní ṣókí, á ràn án lọ́wọ́. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń fi dánra wò, kó o ṣe ìbátan rẹ̀ tàbí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́. Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣe ń ṣàlàyé, fi hàn án bó ṣe lè fi “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” dá àwọn tó bi í ní ìbéèrè lóhùn.—1 Pétérù 3:15.

18. Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá kúnjú ìwọ̀n láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ìrànlọ́wọ́ wo lo tún lè ṣe fún un?

18 Tó bá yá, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè kúnjú ìwọ̀n láti lọ sóde ẹ̀rí. Jẹ́ kó yé e pé àǹfààní ńlá lẹni tí wọ́n bá jẹ́ kó máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí ní. (2 Kọ́ríńtì 4:1, 7) Táwọn alàgbà bá ti pinnu pé akẹ́kọ̀ọ́ náà kúnjú ìwọ̀n láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ràn án lọ́wọ́ láti múra ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tó rọrùn sílẹ̀ kó o sì bá a ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Máa bá a ṣiṣẹ́ déédéé nínú onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ ìwàásù kó o sì kọ́ ọ bó ṣe lè múra ìpadàbẹ̀wò tó múná dóko sílẹ̀ àti bó ṣe lè ṣe é. Tó bá rí i pé ìwọ alára ń ṣe bẹ́ẹ̀, òun náà á fẹ́ gbìyànjú dáadáa.—Lúùkù 6:40.

“Gba Ara Rẹ àti Àwọn Tí Ń Fetí sí Ọ Là”

19, 20. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe, kí sì nìdí?

19 Kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Àmọ́, ohun tó lè fúnni láyọ̀ bíi kéèyàn ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ò pọ̀. (1 Tẹsalóníkà 2:19, 20) Dájúdájú, àǹfààní ńlá la ní láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń ṣe jákèjádò ayé!—1 Kọ́ríńtì 3:9.

20 Láìpẹ́, Jèhófà yóò tipasẹ̀ Jésù Kristi àtàwọn áńgẹ́lì alágbára mú ìparun wá sórí “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹsalóníkà 1:6-8) Ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu o. Ǹjẹ́ o lè fi ṣe ìpinnu rẹ pé, ó kéré tán, wàá ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí wàá máa darí nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bó o ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ yìí, wàá láǹfààní láti “gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:16) Ní báyìí, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kíákíá kí wọ́n lè máa ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?

• Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni?

• Báwo lo ṣe lè fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

• Àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo ló múná dóko jù lọ?

• Báwo lo ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè dẹni tí yóò máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ǹjẹ́ ò ń lo ìwé yìí lọ́nà tó múná dóko?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìjíròrò ṣókí lè mú kẹ́nì kan fẹ́ láti ní ìmọ̀ Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Kí lo lè ṣe láti jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ̀ pé inú Bíbélì làwọn ohun tó ń kọ́ ti wá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́