ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 1/15 ojú ìwé 21-25
  • Máa Kọ́ Àwọn Èèyàn Lóhun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Kọ́ Àwọn Èèyàn Lóhun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Tiẹ̀ Bìkítà Nípa Wa?
  • Kí Nìdí Tá A Fi Wà Láyé?
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Séèyàn Nígbà Téèyàn Bá Kú?
  • Ìwé Tuntun Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́
  • Mọyì Àǹfààní Bàǹtà-banta Tó O Ní
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
    Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
  • Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Ṣe Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 1/15 ojú ìwé 21-25

Máa Kọ́ Àwọn Èèyàn Lóhun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an

‘Ẹ máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa kọ́ wọn.’—MÁTÍÙ 28:19, 20.

1. Báwo ni Bíbélì ṣe pọ̀ tó láyé?

BÍBÉLÌ, Ọ̀rọ̀ Jèhófà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tó pẹ́ jù lọ táwọn èèyàn ní lọ́wọ́ jù jákèjádò ayé. Ó kéré tán, wọ́n ti túmọ̀ apá kan rẹ̀ sí èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [2,300]. Tá a bá dá àwọn èèyàn tó ń gbé láyé yìí sọ́nà mẹ́wàá, ó lé ní mẹ́sàn-án lára wọn tó ní Bíbélì lédè ìbílẹ̀ wọn.

2, 3. (a) Kí nìdí táwọn èèyàn ò fi mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

2 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Àwọn kan tiẹ̀ ti kà á tán láìmọye ìgbà. Ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lóríṣiríṣi ló máa ń sọ pé inú Bíbélì làwọn ti rí ẹ̀kọ́ táwọn fi ń kọ́ni. Síbẹ̀, èrò wọn nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ò bára mu. Pabanbarì ibẹ̀ tiẹ̀ tún ni pé, èrò àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kan náà máa ń yàtọ̀ síra gan-an nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ohun tí kì í ṣòótọ́ ni wọ́n gbà gbọ́ nípa Bíbélì, ọ̀dọ̀ ẹni tó ti wá àti bó ṣe wúlò tó. Ọ̀pọ̀ ló sì kà á sí ìwé mímọ́ táwọn èèyàn kàn ń lò láti fi búra nígbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹ́jọ́ tàbí tí wọ́n fẹ́ jẹ́rìí sọ́rọ̀ nílé ẹjọ́.

3 Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó lágbára tàbí ohun tó fẹ́ kí aráyé mọ̀ ló wà nínú Bíbélì. (Hébérù 4:12) Ìdí nìyẹn tí àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi fẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Inú wa máa ń dùn láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù Kristi gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tó sọ pé: “Ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn.” (Mátíù 28:19, 20) Lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a máa ń rí àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, àmọ́ tí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tó ta kora nínú ayé yìí ti tojú sú. Wọ́n máa ń fẹ́ mọ òtítọ́ nípa irú ẹni tí Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ àtohun tí Bíbélì sọ nípa ìdí tá a fi wà láyé. Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè mẹ́ta kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè yẹ̀ wò. Nígbà tá a bá ń gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbéèrè náà yẹ̀ wò, a máa kọ́kọ́ wo àṣìṣe tó wà nínú ìdáhùn táwọn aṣáájú ìsìn máa ń fáwọn èèyàn, lẹ́yìn náà, a óò wá wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Àwọn ìbéèrè náà ni: (1) Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa wa? (2) Kí nìdí tá a fi wà láyé? (3) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà téèyàn bá kú?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Tiẹ̀ Bìkítà Nípa Wa?

4, 5. Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń rò pé Ọlọ́run ò bìkítà nípa wa?

4 Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ látorí ìbéèrè kìíní, tó sọ pé, Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa wa? Ó dunni pé ọ̀pọ̀ ló rò pé Ọlọ́run ò bìkítà nípa wa. Kí nìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé, nígbà tí wọ́n wò lọ, tí wọ́n wò bọ̀, wọ́n rí i pé ogun, ìkórìíra àti ìyà ló kúnnú ayé. Wọ́n wá ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà nípa wa, kò ní jẹ́ kírú àwọn nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.’

5 Àwọn aṣáájú ìsìn ló tún máa ń mú káwọn èèyàn rò pé Ọlọ́run ò bìkítà nípa wa. Kí ni wọ́n sábà máa ń sọ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi bá ṣẹlẹ̀? Ó dáa, àpẹẹrẹ kan rèé: Nígbà tí obìnrin kan pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ méjì tí wọ́n kéré lọ́jọ́ orí nínú jàǹbá ọkọ̀ kan, olórí ìjọ rẹ̀ sọ fún un pé, “Ọlọ́run ló fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀ torí pé ó nílò áńgẹ́lì méjì sí i lọ́run.” Nígbà táwọn olórí ìsìn bá sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé Ọlọ́run ló ń fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́ Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Jèhófà Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ o. Bíbélì sọ pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú.”—Jóòbù 34:10.

6. Ta ló fa gbogbo ìwà ibi tó wà láyé àti ìyà tó ń jẹ aráyé?

6 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa, kí ló fà á tí ìyà tó ń jẹ aráyé fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ọ̀kan lára àwọn ohun tó fà á ni pé aráyé kọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Alákòóso, wọn ò fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà òdodo rẹ̀. Láìmọ̀, ńṣe ni wọ́n fi ara wọn sábẹ́ Ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn Sátánì, torí Bíbélì sọ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Mímọ̀ tá a mọ èyí jẹ́ ká lóye ìdí tí ìwà ibi fi gbilẹ̀ láyé. Olubi ni Sátánì, oníkòórìíra ni, ẹlẹ̀tàn ni, ìkà sì tún ni. Ayé ò sì lè ṣe kó má hùwà tí ẹni tó ń ṣàkóso rẹ̀ ń hù. Abájọ tí ìwà ibi fi gbilẹ̀ láyé!

7. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé?

7 Ohun mìíràn tó fà á tí ìyà fi ń jẹ aráyé ni àìpé ẹ̀dá. Ńṣe ni ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ máa ń fẹ́ jẹ gàba lórí àwọn ẹlòmíràn, ohun tíyẹn sì sábà máa ń fà ni ogun, ìninilára àti ìpọ́njú. Bí Oníwàásù 8:9 ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí, pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” Kò mọ síbẹ̀ o, ìdí mìíràn tí ìyà fi ń jẹ aráyé ni ohun tí Bíbélì pè ní “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníwàásù 9:11) Lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe làwọn èèyàn kàn ń ṣe kòńgẹ́ nǹkan burúkú tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí wọn.

8, 9. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa wa lóòótọ́?

8 Ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà kọ́ ló ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Àmọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láyé? Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run bìkítà! A mọ̀ pé ó bìkítà nítorí pé nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ ìdí tí òun fi fàyè gbà á kí aráyé máa tọ ọ̀nà búburú. Ìdí méjì ló fi fàyè gbà á. Ìdí àkọ́kọ́ ni ọ̀ràn pàtàkì tó wà ńlẹ̀ nípa bóyá Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ, ìdí kejì sì ni ọ̀ràn nípa bóyá èèyàn á lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run títí lọ láìyẹsẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti Olódùmarè, kì í ṣe ọ̀ranyàn pé kó sọ ìdí tó fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé fún wa. Síbẹ̀, ó sọ ìdí rẹ̀ fún wa nítorí pé ó bìkítà nípa wa.

9 Ẹ jẹ́ ká tún wo ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa. Nígbà ayé Nóà, ó “dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀” nígbà tó rí i tí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ibi. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6) Lónìí, ǹjẹ́ ìyà tó ń jẹ aráyé ṣì máa ń dun Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé Jèhófà ò yí padà. (Málákì 3:6) Ó kórìíra onírúurú ìwà ìrẹ́jẹ, kò sì fẹ́ kéèyàn máa jìyà. Bíbélì fi kọ́ni pé Ọlọ́run kò ní pẹ́ fòpin sí gbogbo aburú tí ìṣàkóso èèyàn àti ìdarí Èṣù ti fà. Ǹjẹ́ ìyẹn kì í ṣe ẹ̀rí tó dájú pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa?

10. Báwo ni ìyà tó ń jẹ aráyé ṣe rí lára Jèhófà?

10 Irọ́ gbuu làwọn aṣáájú ìsìn ń pa bí wọ́n ṣe ń sọ pé Ọlọ́run ló ń fẹ́ kí gbogbo láabi tó ń ṣẹlẹ̀ sọ́mọ aráyé máa ṣẹlẹ̀. Ká sòdodo, tọkàntọkàn ni Jèhófà ń fẹ́ láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé. Ìwé 1 Pétérù 5:7 sọ pé: “[Ọlọ́run] bìkítà fún yín.” Ohun tí Bíbélì sì fi kọ́ni gan-an nìyẹn!

Kí Nìdí Tá A Fi Wà Láyé?

11. Kí làwọn onísìn sábà máa ń sọ nípa ìdí téèyàn fi wà láyé?

11 Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè kejì tọ́pọ̀ èèyàn máa ń béèrè yẹ̀ wò. Ìbéèrè ọ̀hún ni, Kí nìdí tá a fi wà láyé? Báwọn onísìn ṣe sábà máa ń dáhùn ìbéèrè náà ni pé: Ilé ayé, fúngbà díẹ̀ ni. Wọ́n sọ pé gbogbo èèyàn kàn wá nájà láyé ni, pé tó bá yá, èèyàn á padà lọ sọ́run. Àwọn olórí ìjọ kan tiẹ̀ ń fi kọ́ni pé Ọlọ́run máa payé rẹ́ lọ́jọ́ kan. Nítorí irú àwọn ẹ̀kọ́ báwọ̀nyí, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ó kúkú sàn káwọn ní gbogbo ohun táwọn bá lè ní nínú ayé yìí nítorí táwọn bá ti kú, ó parí náà nìyẹn. Àmọ́, kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa ìdí tá a fi wà láyé?

12-14. Kí ni Bíbélì fi kọ́ni nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé àti fún aráyé?

12 Ọlọ́run ní ohun àgbàyanu kan lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé àti fún aráyé. Ọlọ́run “kò wulẹ̀ dá [ilẹ̀ ayé] lásán,” ńṣe ni “ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Ohun tá a mọ̀ yìí nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé àti fún aráyé lè jẹ́ ká mọ ìdí tá a fi wà láyé.

13 Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní àti ìkejì jẹ́ ká rí i pé ńṣe ni Jèhófà fara balẹ̀ dá ilẹ̀ ayé kéèyàn lè máa gbé inú rẹ̀. Nígbà tó parí dídá ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, ó rí i pé gbogbo ohun tóun dá ló “dára gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ọlọ́run fi ọkùnrin àtobìnrin àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, sínú ọgbà Édẹ́nì ẹlẹ́wà ó sì dá ọ̀pọ̀ oúnjẹ síbẹ̀ lóríṣiríṣi. Ó wá sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ní kí wọ́n bí àwọn ọmọ tó jẹ́ pípé bí àwọn alára, kí wọ́n sì mú kí ọgbà ẹlẹ́wà tó jẹ́ ilé wọn tí wọ́n ń gbé gbòòrò dé gbogbo ayé. Ó tún ní kí wọ́n máa fìfẹ́ jọba lórí àwọn ẹranko.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28.

14 Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn ni pé káwọn èèyàn pípé máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn ni pé ká wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ohun tí Bíbélì sì fi kọ́ni gan-an nìyẹn!

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Séèyàn Nígbà Téèyàn Bá Kú?

15. Kí ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀sìn tó wà láyé fi ń kọ́ni nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà téèyàn bá kú?

15 Ní báyìí, ìbéèrè kẹta tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè lọpọ́n sún kàn. Ìbéèrè ọ̀hún ni, Kí ló ń ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà téèyàn bá kú? Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹ̀sìn tó wà láyé ló fi ń kọ́ni pé nǹkan kan wà nínú èèyàn tó máa ń jáde kúrò nínú ara lẹ́yìn tí ara bá kú, wọ́n ní nǹkan ọ̀hún á wá máa wà láàyè lọ níbòmíràn. Di bá a ti ń sọ yìí, àwọn ẹ̀sìn kan ṣì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa ń fìyà ayérayé jẹ àwọn èèyàn búburú nínú ibi tí wọ́n pè ní ọ̀run àpáàdì. Ṣóòótọ́ nìyẹn? Kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa ipò táwọn òkú wà?

16, 17. Bí Bíbélì ṣe sọ, kí ni ipò táwọn òkú wà?

16 Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá,” wọn ò lè ríran, wọn ò lè gbọ́ràn, wọn ò lè sọ̀rọ̀, wọn ò lè mọ̀ tí nǹkan kan bá kàn wọ́n lára, wọn ò sì lè ronú. Síwájú sí i, wọn kò lè rí owó ọ̀yà, ìyẹn owó iṣẹ́, gbà mọ́. Àbí, báwo ni wọ́n ṣe lè rówó iṣẹ́ gbà? Àwọn tó jẹ́ pé wọn ò lè ṣe nǹkan kan mọ́! Bíbélì tún sọ pé: “Ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé,” tó túmọ̀ sí pé wọn ò lè nífẹ̀ẹ́ èèyàn mọ́, wọn ò lè kórìíra èèyàn mọ́, wọn ò sì lè jowú ẹnikẹ́ni.—Oníwàásù 9:5, 6, 10.

17 Ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò táwọn òkú wà ṣe kedere, ó sì rọrùn-ún lóye. Ohun tó sọ náà ni pé, téèyàn bá ti kú, ó ti daláìsí nìyẹn, a ò lè rí i níbikíbi mọ́. Ohun tí àwọn tó gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé sọ kì í ṣe òótọ́ o. Téèyàn bá kú, kò sí nǹkan kan tó máa ń kúrò nínú ara láti máa wà láàyè nìṣó kí wọ́n lè tún un bí nínú ara mìíràn. Ohun tá a lè fi wé rèé: Bí iná àbẹ́là ni ẹ̀mí wa ṣe rí. Bí wọ́n bá fẹ́ iná àbẹ́là kan pa, èèyàn ò lè rí iná tí wọ́n fẹ́ pa yẹn gan-an níbòmíràn. Ó ti kú, kò sí níbì kankan mọ́.

18. Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá mọ̀ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan, kí ló yẹ kó mọ̀ kó sì gbà?

18 Tá a bá rò ó dáadáa, a óò rí i pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn mọ òtítọ́ nípa ipò táwọn òkú wà. Bí àpẹẹrẹ, tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ti mọ̀ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan mọ́, ó yẹ kó lè gbà lọ́wọ́ kan pé bó ti wù káwọn baba ńlá òun burú tó kí wọ́n tó kú, òkú wọn ò lè dààmú òun. Ó tún yẹ kó mọ̀ kíákíá pé àwọn èèyàn òun tó ti kú ò lè mọ nǹkan kan lára mọ́, pé wọn ò lè gbọ́ràn mọ́, wọn ò lè sọ̀rọ̀ mọ́, wọn ò lè ríran mọ́, wọn ò sì lè ronú mọ́. Tí òye ìyẹn bá ti lè yé e, á mọ̀ pé kì í ṣe pé wọ́n wà nínú ìnira nínú ibi tí wọ́n ń pè ní pọ́gátórì tàbí pé wọ́n ń joró nínú ibi tí wọ́n ń pè ní ọ̀run àpáàdì. Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé àwọn òkú tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run yóò jíǹde. Ẹ ò rí i pé ìrètí àgbàyanu nìyẹn!—Jòhánù 5:28, 29.

Ìwé Tuntun Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́

19, 20. Kí ni ojúṣe àwa Kristẹni, kí sì ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye dìídì ṣe pé ká máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

19 Mẹ́ta péré la gbé yẹ̀ wò lára òbítíbitì ìbéèrè táwọn èèyàn máa ń béèrè. Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbéèrè náà ṣe kedere, ó sì rọrùn-ún lóye. Ẹ ò rí i pé ohun ayọ̀ ló jẹ́ láti sọ òtítọ́ Bíbélì wọ̀nyí fún àwọn tó fẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni! Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìbéèrè pàtàkì tún wà táwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ ń wá ìdáhùn sí. Ojúṣe àwa Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìdáhùn sírú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

20 Kì í ṣe ohun tó rọrùn láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ Bíbélì lọ́nà tó ṣe kedere tó sì máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ìdí nìyẹn tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fi dìídì ṣe ìwé kan tá a ó máa lò lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni tá à ń ṣe. (Mátíù 24:45-47) Orúkọ ìwé náà ni Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ó ní ojú ewé ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́rìnlélógún [224].

21, 22. Kí ni díẹ̀ lára àwọn apá pàtàkì tó wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

21 A mú ìwé yìí jáde ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lọ́dún 2005 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2006. Onírúurú apá pàtàkì ló wà nínú ìwé náà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ ìṣáájú wà nínú rẹ̀ ní ojú ìwé 1 sí 5, ọ̀rọ̀ ìṣáájú náà sì ń jẹ́ kó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó lè rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti ṣàlàyé àwọn àwòrán àti ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. O tún lè lo àlàyé kan tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú yìí láti fi ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bí yóò ṣe máa wá orí àti ẹsẹ Bíbélì.

22 A kọ ìwé náà lọ́nà tó ṣe kedere tó sì rọrùn-ún lóye. A sapá gan-an láti kọ ọ́ lọ́nà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ á fi wọ akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kàn nípa bíbi í ní ìbéèrè níbi tó bá ti ṣeé ṣe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí tó wà nínú ìwé náà ló ní àwọn ìbéèrè kan ní ìbẹ̀rẹ̀ tá a fi nasẹ̀ rẹ̀, àpótí kan sì wà ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni.” Inú àpótí yìí ni ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tá a fi nasẹ̀ orí kọ̀ọ̀kan wà, àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé ìdáhùn náà kà. Àwọn àwòrán mèremère àti ọ̀rọ̀ tá a kọ síbi àwọn àwòrán náà àti àwọn àpèjúwe téèyàn lè finú yàwòrán rẹ̀ tó wà nínú ìwé yìí á ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó jẹ́ tuntun sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó rọrùn-ún lóye la fi kọ ìwé yìí, síbẹ̀, a tún ṣe àfikún kan sí ìparí rẹ̀. Àfikún yìí túbọ̀ ṣàlàyé tó jinlẹ̀ lórí mẹ́rìnlá lára àwọn orí tó wà nínú ìwé náà. Ẹ lè lo èyí bí akẹ́kọ̀ọ́ bá lóun fẹ́ àfikún àlàyé lórí ohun tó ń kọ́.

23. Àwọn àbá wo la fún wa nípa bá a ṣe lè lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

23 A ṣe ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lọ́nà tó fi máa ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn tó kàwé púpọ̀ àtàwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé àtàwọn èèyàn látinú onírúurú ẹ̀sìn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan ò bá ní ìmọ̀ Bíbélì rárá, ẹ lè má parí orí kan lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ẹ má ṣe máa fi ìkánjú ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o gbìyànjú láti jẹ́ kí ẹ̀kọ́ náà wọ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́kàn. Bí àpèjúwe kan tá a lò nínú ìwé náà ò bá yé e, ṣàlàyé rẹ̀ tàbí kó o lo àpèjúwe míì. Máa múra sílẹ̀ dáadáa, sa gbogbo ipá rẹ láti lo ìwé náà lọ́nà tó múná dóko, kó o sì máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tímótì 2:15.

Mọyì Àǹfààní Bàǹtà-banta Tó O Ní

24, 25. Àwọn àǹfààní bàǹtà-banta wo ni Jèhófà fún àwa èèyàn rẹ̀?

24 Jèhófà ti fún àwa èèyàn rẹ̀ ní àǹfààní bàǹtà-banta. Ó jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa òun. A ò gbọ́dọ̀ fojú kéré àǹfààní ńlá yẹn o! Ó ṣe tán, Ọlọ́run ń jẹ́ káwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ̀ nípa ohun tóun fẹ́ ṣe, àmọ́ kò fi han àwọn agbéraga. Ohun tí Jésù sọ nípa èyí ni pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Mátíù 11:25) Àǹfààní ńlá ni pé a wà lára àwọn onírẹ̀lẹ̀ tó ń sin Jèhófà Ọbá Aláṣe Ayé Àtọ̀run.

25 Àǹfààní mìíràn tí Ọlọ́run fún wa ni pé ká máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ nípa òun. Ẹ jẹ́ ká rántí pé àwọn kan ń sọ pé Ọlọ́run ṣe ohun tí kò ṣe, wọ́n ń fi irọ́ kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run. Ìyẹn sì mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ní èrò tí kò tọ́ nípa Jèhófà, wọ́n ń rò pé ẹni tí kò bìkítà tí kò sì láàánú ni. Ǹjẹ́ o múra tán láti ran àwọn tó ń ní èrò tí kò tọ́ nípa Jèhófà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní èrò tó tọ́? Ṣé o sì ń hára gàgà láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ o fẹ́ káwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ níbi gbogbo mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, máa fi hàn pé o jẹ́ ẹni tó ń ṣègbọràn sí Jèhófà nípa fífi ìtara wàásù kó o sì máa fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí àwọn kókó pàtàkì-pàtàkì kọ́ àwọn èèyàn. Àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ gbọ́dọ̀ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an.

Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?

• Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa?

• Kí nìdí tá a fi wà láyé?

• Kí ló ń ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà téèyàn bá kú?

• Èwo ló wù ọ́ jù nínú onírúurú apá pàtàkì tó wà nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Bíbélì fi kọ́ni pé ìyà tó ń jẹ aráyé á dópin

[Àwọn Credit Line]

Ọmọbìnrin tó wà lókè lápá ọ̀tún: © Bruno Morandi/age fotostock; obìnrin tó wà lápá òsì: AP Photo/Gemunu Amarasinghe; ìsàlẹ̀, àwọn tógun lé kúrò nílùú: © Sven Torfinn/Panos Pictures

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn olódodo yóò wà láàyè títí láé nínú Párádísè

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́