Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn ní “Ilé Òkúta”
Ìtumọ̀ orúkọ orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè ní Áfíríkà ni “Ilé Òkúta.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ nípa Sìǹbábúwè nítorí omi odò tó ń ti òkè gíga ya wálẹ̀ níbẹ̀, ìyẹn Victoria Falls, àti onírúurú ẹranko tó wà níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ní gbogbo ilẹ̀ tó wà lápá gúúsù aṣálẹ̀ tó ń jẹ́ Sàhárà ní Áfíríkà, Sìǹbábúwè lèèyàn á ti rí àwọn tó tóbi jù lọ lára ilé àtàwọn nǹkan míì táwọn èèyàn ìgbà láéláé kọ́. Òkè olókùúta kan la ilẹ̀ náà já lágbedeméjì. Ojú ọjọ́ kò gbóná jù kò sì tutù jù lórí òkè náà, èyí tó mú kí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá táwọn ewéko ibẹ̀ sì tutù yọ̀yọ̀. Nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìlá èèyàn ló ń gbé ní Sìǹbábúwè.
KÍ NÌDÍ tí wọ́n fi pe orúkọ orílẹ̀-èdè yìí ní Ilé Òkúta? Bó ṣe jẹ́ rèé: Bí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Adam Renders ṣe ń lọ káàkiri láti ṣàwárí nǹkan ní àwọn pápá gbalasa tó wà ní Áfíríkà, ó rí i pé ilé bàmùbàmù tí wọ́n fi koríko bò lórí ló pọ̀ jù níbẹ̀. Àmọ́ lọ́dún 1867, ó rí àwọn àwókù ilé àtàwọn nǹkan ńláńlá míì tí wọ́n fi òkúta kọ́ káàkiri orí ilẹ̀ tó fẹ̀ tó ẹgbẹ̀sán [1,800] éékà. Àwókù ìlú ńlá kan ni, orúkọ tí wọ́n sì ń pe ìlú náà báyìí ni Sìǹbábúwè Ńlá.
Àwókù ìlú yìí wà ní gúúsù ìlú tá a mọ̀ sí Masvingo báyìí. Àwọn ògiri kan níbẹ̀ ga ju mítà mẹ́sàn-án [ọgbọ̀n ẹsẹ̀ bàtà] lọ, ńṣe ni wọ́n kàn to òkúta tí wọ́n fi kọ́ àwọn ògiri náà léra wọn láìfi sìmẹ́ǹtì sí i. Ilé gogoro kan tó rí rìbìtì wà nínú àwókù ìlú náà tí gíga rẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi mítà mọ́kànlá [ẹsẹ̀ bàtà márùndínlógójì], fífẹ̀ rẹ̀ nísàlẹ̀ sì jẹ́ mítà mẹ́fà [ogún ẹsẹ̀ bàtà]. Títí di ìsinsìnyí, kò sẹ́ni tó mọ ìdí tí wọ́n fi kọ́ ilé gogoro tó rí rìbìtì yìí. Nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn àwókù ilé tó wà ní ìlú náà, wọ́n rí i pé ọ̀rúndún kẹjọ Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti kọ́ wọn, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé àwọn èèyàn ti gbé inú ìlú náà fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn.
Orúkọ tí wọ́n ń pe ilẹ̀ Sìǹbábúwè tẹ́lẹ̀ ni Rhodesia. Ìgbà tí wọ́n gbòmìnira kúrò lábẹ́ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1980 ni wọ́n yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sìǹbábúwè. Ẹ̀yà Shona àti ẹ̀yà Ndebele jẹ́ méjì pàtàkì lára àwọn ẹ̀yà tó wà níbẹ̀, àmọ́ ẹ̀yà Shona ló pọ̀ jù. Àwọn ará Sìǹbábúwè ní aájò àlejò, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ sì ti rí i pé bó ṣe rí nìyẹn bí wọ́n ṣe ń wàásù láti ilé délé. Kódà nígbà míì, káwọn ará Sìǹbábúwè tó mọ irú èèyàn tí ẹni tó kanlẹ̀kùn jẹ́ ni wọ́n á ti sọ pé, “ẹ wọlé, ẹ jọ̀wọ́ ẹ jókòó.” Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Sìǹbábúwè ò fọ̀rọ̀ Bíbélì ṣeré rárá, táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fi dandan lé e pé káwọn ọmọ wọn jókòó kí wọ́n máa gbọ́.
Wọ́n Ń Kéde Ìhìn Tó Ń Ranni Lọ́wọ́ Tó sì Ń Tuni Nínú
Ọ̀rọ̀ méjì náà, “éèdì” àti “ọ̀dá” kì í wọ́n lẹ́nu àwọn oníròyìn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa Sìǹbábúwè. Àkóbá tó pọ̀ ni àrùn éèdì tó ń tàn kálẹ̀ ti ṣe fáwọn èèyàn àti ọrọ̀ ajé àwọn ilẹ̀ tó wà ní gúúsù aṣálẹ̀ tó ń jẹ́ Sàhárà ní Áfíríkà. Láwọn ilẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbàtọ́jú nílé ìwòsàn ló jẹ́ nítorí àrùn éèdì. Àrùn náà sì ti ṣe ọ̀pọ̀ ìdílé lọ́ṣẹ́.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ran àwọn tó ń gbé ní Sìǹbábúwè lọ́wọ́ nípa wíwàásù fún wọn pé ohun tó lè mú kéèyàn gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó dára jù lọ ni pé kó máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àárín àwọn méjì tí wọ́n ti ṣègbéyàwó ni ìbálòpọ̀ tí í ṣe ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ mọ sí. Bíbélì tún ní Ọlọ́run kórìíra kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lò pọ̀, bákan náà, òfin Jèhófà ka ìfàjẹ̀sínilára àti fífi oògùn líle ṣe fàájì léèwọ̀. (Ìṣe 15:28, 29; Róòmù 1:24-27; 1 Kọ́ríńtì 7:2-5; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Àwọn Ẹlẹ́rìí tún ń kéde ìhìn rere jákèjádò Sìǹbábúwè pé ojúlówó ìrètí wà pé láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run á mú gbogbo àìsàn kúrò.—Aísáyà 33:24.
Pípèsè Ìrànwọ́
Láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá, ọ̀dá ti ṣe ọṣẹ́ tó pọ̀ ní Sìǹbábúwè. Àwọn ẹranko tó wà nínú igbó ń ṣubú lulẹ̀ nítorí pé wọn ò rí oúnjẹ jẹ wọn ò sì rí omi mu. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún màlúù ló ti kú. Àìmọye éékà igbó tí igi gẹdú wà ni iná ti jó. Ọ̀pọ̀ ọmọdé àtàgbàlagbà ni àìjẹunrekánú ti pa. Kódà omi odò ńlá tí wọ́n ń pè ní Zambezi ti lọ sílẹ̀ débi pé kò lè yí ẹ̀rọ iná mànàmáná tó bó ṣe yẹ.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá nǹkan kan ṣe sí ìṣòro tí ọ̀dá náà fà fáwọn ará wọn. Wọ́n yan ìgbìmọ̀ mẹ́jọ láti bójú tó ètò pípèsè ìrànwọ́ fáwọn ará lónírúurú ibi lórílẹ̀-èdè náà. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń bẹ àwọn ìjọ wò láti wo ohun táwọn ará nílò, wọ́n á wá fi èyí tó ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó àgbègbè yẹn létí. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá, a ti pín ìwọ̀n àgbàdo tó wúwo ju ọ̀kẹ́ kan [20,000] àpò ìrẹsì, ìwọ̀n ẹja gbígbẹ tó wúwo tó igba [200] àpò ìrẹsì àti ìwọ̀n ẹ̀wà olóyin tó wúwo tó igba àpò ìrẹsì. Àwọn ará wa pèsè ẹ̀fọ́ gbígbẹ táwọn ará ibẹ̀ ń pè ní mufushwa, tí ìwọ̀n rẹ̀ wúwo tó ọgọ́rùn-ún àpò ìrẹsì. A tún pín ọ̀pọ̀ aṣọ táwọn ará fi ṣèrànwọ́ àti owó.” Alábòójútó arìnrìn-àjò míì sọ pé: “Nígbà tí mo ronú nípa gbogbo ohun tójú wa rí kí ìjọba ilẹ̀ Sìǹbábúwè àti ti ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà tó lè fọwọ́ sí i pé ká máa kó àwọn ohun ìrànwọ́ tá a nílò gan-an wọ̀nyí wọlé, àti bó ṣe jẹ́ pé ìgbà gbogbo ni kì í fi bẹ́ẹ̀ sí epo ọkọ̀, mo rí i pé bá a ṣe ń rí àwọn ohun ìrànwọ́ yìí kó lọ jẹ́ ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ tí Jésù sọ pé Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé a nílò àwọn ohun wọ̀nyí.”—Mátíù 6:32.
Ọgbọ́n wo làwọn alábòójútó arìnrìn-àjò pàápàá ń ta sí i bí wọ́n ṣe ń bẹ àwọn ará wò láwọn àgbègbè tí ọ̀dá ti ṣọṣẹ́? Ńṣe làwọn kan lára wọn máa ń gbé oúnjẹ táwọn àti ìdílé tí wọ́n bá dé sọ́dọ̀ wọn máa jẹ dání. Ọ̀kan nínú àwọn alábòójútó náà sọ pé, lọ́jọ́ kan, àwọn arábìnrin kan ń rò ó bóyá káwọn ṣíwọ́ lóde ìwàásù káwọn lè lọ tò sórí ìlà láti gba ohun tí ìjọba fẹ́ fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àmọ́ wọ́n pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ, wọ́n ń wo bí Ọlọ́run á ṣe yanjú ìṣòro náà. Ẹ jẹ́ mọ̀ pé ìjọba ò kó nǹkan wá lọ́jọ́ yẹn.
Ètò wà pé káwọn ará ṣèpàdé ìjọ lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, àwọn arábìnrin wọ̀nyí sì tún ní láti pinnu èyí tí wọ́n máa ṣe. Ṣé wọ́n á lọ sípàdé ni, àbí wọ́n á lọ dúró de ohun tí ìjọba fẹ́ fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? Wọ́n yàn láti ṣe ohun tó yẹ kó gbawájú, wọ́n lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. (Mátíù 6:33) Báwọn ará ṣe ń kọ orin tí wọ́n máa fi parí ìpàdé náà, wọ́n gbọ́ tí ọkọ̀ akẹ́rù kan ń bọ̀. Ohun tí ọkọ̀ náà kó wá ni ohun táwọn arákùnrin tó wà nínú ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ kó wá fún wọn! Inú àwọn ará tó lọ sípàdé lọ́jọ́ náà dùn gan-an, wọ́n sì mọrírì ìrànlọ́wọ́ náà gidigidi.
Àwọn Èèyàn Gbọ́ Ìwàásù Nítorí Ìfẹ́ Táwọn Ẹlẹ́rìí Fi Hàn sí Wọn
Inúure táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe sáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí mú kí wọ́n láǹfààní láti wàásù fáwọn èèyàn dáadáa. Lọ́jọ́ kan, alábòójútó arìnrìn-àjò kan àtàwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà lágbègbè ìlú Masvingo wà lóde ẹ̀rí. Alábòójútó yìí tajú kán rí ọmọbìnrin kan tó wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì, àwọn Ẹlẹ́rìí náà sì kíyè sí i pé ara rẹ̀ ò yá rárá nítorí pé kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa, ohùn rẹ̀ sì ń gbọ̀n. Orúkọ rẹ̀ ni Hamunyari, èyí tó túmọ̀ sí “Ṣé Ojú Ò Tì Ẹ́ Ni?” lédè Shona. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà gbọ́ pé àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ ni wọ́n fi í sílẹ̀ níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń lọ sórí òkè láti lọ ṣèsìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí fìfẹ́ ran ọmọbìnrin náà lọ́wọ́ wọ́n sì mú un lọ sí abúlé kan tó wà nítòsí.
Àwọn kan tó ń gbé lábúlé náà mọ Hamunyari, wọ́n sì ránṣẹ́ sáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n wá mú un. Àwọn ará abúlé náà sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó mú Hamunyari lọ síbẹ̀ pé: “Ìsìn tòótọ́ nìyí. Irú ìfẹ́ tó yẹ káwọn Kristẹni máa fi hàn rèé.” (Jòhánù 13:35) Káwọn Ẹlẹ́rìí náà tó kúrò níbẹ̀, wọ́n fún Hamunyari ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ sí I Nípa Bíbélì?a
Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, alábòójútó arìnrìn-àjò náà bẹ ìjọ tó wà lágbègbè ibi tí Hamunyari ń gbé wò. Ó wá lọ sílé Hamunyari láti mọ̀ bóyá ó délé láyọ̀ àtàlàáfíà. Inú àwọn ará ilé Hamunyari dùn gan-an láti rí alábòójútó náà àtàwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò yẹn. Àwọn òbí rẹ̀ sọ pé: “Ẹ̀yin lẹ̀ ń ṣe ìsìn tòótọ́. Ẹ gba ẹ̀mí ọmọ wa tí wọ́n fi sílẹ̀ lójú ọ̀nà pé kó kú là.” Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn òbí Hamunyari ti béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì tí Hamunyari ń lọ pé: “Ṣé ojú ò tiẹ̀ tì yín ni, bí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀, tẹ́ ẹ fi já a jù sílẹ̀ pé bó bá lè kú kó kú?” Àwọn Ẹlẹ́rìí náà bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ará ilé Hamunyari sọ̀rọ̀ Bíbélì, wọ́n sì fún wọn ní àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Wọ́n ní káwọn Ẹlẹ́rìí náà padà wá láti máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn kan nínú ìdílé náà tí wọ́n ti ń ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀ ò ta kò wọ́n mọ́ báyìí. Kódà, ọkọ ẹ̀gbọ́n Hamunyari tó jẹ́ olórí nínú ṣọ́ọ̀ṣì kan ládùúgbò náà sọ pé kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Kíkọ́ Àwọn Ilé Ìjọsìn
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, akéwì kan kọ̀wé pé: “Ọlọ́run, . . . òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi. . . . Ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí ó sì rí táútáú, níbi tí omi kò sí.” (Sáàmù 63:1) Bọ́rọ̀ ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn ní Sìǹbábúwè. Òùngbẹ tara ń gbẹ wọ́n, àmọ́ òùngbẹ tẹ̀mí tún ń gbẹ wọ́n, ìyẹn ni pé wọ́n fẹ́ mọ̀ nípa Ọlọ́run àti inú rere rẹ̀. Wàá rí i pé bó ṣe rí nìyẹn tó o bá wo ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè náà. Nígbà tórílẹ̀-èdè náà gbòmìnira lọ́dún 1980, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] Ẹlẹ́rìí ló wà níbẹ̀. Ìjọ tó sì wà níbẹ̀ jẹ́ ọ̀rìnlénírínwó ó dín mẹ́rin [476]. Àmọ́ ní báyìí, lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27], iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ti di ìlọ́po mẹ́ta, iye ìjọ tó wà níbẹ̀ sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po méjì.
Kìkì díẹ̀ lára àwọn ìjọ wọ̀nyí ló ní ilé ìjọsìn. Lóṣù January ọdún 2001, méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] péré lára àwọn ìjọ tí iye wọn lé ní ẹgbẹ̀rin [800] ló ní ilé ìjọsìn tá à ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìjọ náà ló ń ṣèpàdé lábẹ́ igi tàbí nínú ilé alámọ̀ kékeré tí wọ́n fi koríko bò lórí.
Fífi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ń fi owó ṣètìlẹ́yìn tí wọ́n sì ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ kára ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Sìǹbábúwè láti dáwọ́ lé ètò kan tó mú kí ọ̀pọ̀ ìjọ tó wà níbẹ̀ lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kékeré, àmọ́ tó bójú mu. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lókè òkun tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé ṣètò ara wọn, wọ́n sì lọ sí Sìǹbábúwè láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará ibẹ̀ tó yọ̀ǹda ara wọn. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń gbé ní Sìǹbábúwè kọ̀wé pé: “A dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láti bá wa kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lẹ́wà ní Sìǹbábúwè. A tún dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ fi owó ṣètìlẹ́yìn lábẹ́ ètò Òwò Àkànlò fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, èyí tó mú kí iṣẹ́ yìí ṣeé ṣe.”
Níbì kan lápá ìlà oòrùn Sìǹbábúwè, ó lé ní àádọ́ta [50] ọdún táwọn Ẹlẹ́rìí fi ṣèpàdé ìjọ lábẹ́ igi oṣè ńlá kan. Nígbà tí wọ́n wá sọ fáwọn alàgbà ìjọ pé wọ́n máa kọ́ ilé ìjọsìn, ńṣe ni ọ̀kan lára wọn bú sẹ́kún. Nínú ìjọ kan tó wà nítòsí, alàgbà kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91] sọ pé: “Ó pẹ́ tí mo ti ń bẹ Jèhófà pé kó ṣe irú nǹkan báyìí fún wa!”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń yára kọ́ àwọn ilé ìjọsìn tó lẹ́wà wọ̀nyí parí. Ẹnì kan tó kíyè sí èyí sọ pé: “Ó ní láti jẹ́ pé bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́lé lọ́sàn-án, Ọlọ́run náà ń bá yín kọ́ ọ lóru!” Àwọn èèyàn tún kíyè sí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà àti bí inú wọn ṣe ń dùn. Títí di báyìí, ó lé ní àádọ́ta dín nírínwó [350] Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ti kọ́ káàkiri ilẹ̀ Sìǹbábúwè. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [534] ìjọ láti máa ṣèpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n fi bíríkì kọ́ tó sì dúró dáadáa.
Iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn tó ṣe pàtàkì gan-an kò dáwọ́ dúró ní Sìǹbábúwè. Bá a ṣe ń ronú nípa gbogbo nǹkan tá a ti gbé ṣe, dájúdájú Jèhófà lọpẹ́ yẹ, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìbùkún wọ̀nyí ti wá. Bẹ́ẹ̀ ni, “bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.”—Sáàmù 127:1.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
SÌǸBÁBÚWÈ
HARARE
Masvingo
Sìǹbábúwè Ńlá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ilé rìbìtì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tí ìjọ Concession ń lò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn ará ìjọ Lyndale níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tuntun
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwókù ilé àti àtẹ̀gùn: ©Chris van der Merwe/AAI Fotostock/age fotostock; ilé rìbìtì: ©Ingrid van den Berg/AAI Fotostock/age fotostock