Obìnrin Olóòótọ́ Kan
OHUN kan ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí tó dán ìṣòtítọ́ obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nelma wò. Ìlú Cruzeiro do Sul lórílẹ̀-èdè Brazil lobìnrin náà ti ń ṣiṣẹ́ aṣerunlóge. Lẹ́yìn tí omíyalé wáyé lágbègbè wọn, ọ̀kan lára àwọn tó máa ń ṣerun fún fi àwọn aṣọ kan ta á lọ́rẹ. Nígbà tí Nelma ń yẹ àwọn aṣọ náà wò, ó rí owó nínú àwọn àpò ara ṣòkòtò kan. Tá a bá ṣẹ́ owó náà sí dọ́là, ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan owó dọ́là, tó ń lọ sí nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹgbàárin [128,000] náírà.
Ṣẹ́ ẹ rí i, owó tí Nelma rí lápò ṣòkòtò yìí jẹ́ owó oṣù tó máa gbà fún oṣù méje, ó sì nílò owó gan-an lásìkò yẹn. Ìdí ni pé omíyalé ti ba ilé rẹ̀ jẹ́, ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún sì ti jẹ́ kí bàbá rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀ pàdánù ọ̀pọ̀ lára nǹkan ìní wọn. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, owó tó rí yìí tó láti fi tún ilé rẹ̀ ṣe, á sì tún ṣẹ́ kù láti fi ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́. Àmọ́, ẹ̀rí ọkàn Nelma tó ti fi Bíbélì kọ́ ò jẹ́ kó sọ pé Ọlọ́run ló bọ́tà búrẹ́dì òun, kó wá sọ owó olówó di tirẹ̀.—Hébérù 13:18.
Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, Nelma jí lọ síbi iṣẹ́ láti lọ bá obìnrin oníṣòwò tó fún un láṣọ. Nígbà tí Nelma rí obìnrin náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ gan-an fún aṣọ tó fi tá a lọ́rẹ. Ó sọ fún un pé òun rí owó lápò ṣòkòtò kan lára àwọn aṣọ náà, àmọ́ òun fẹ́ dá owó náà padà. Inú obìnrin yìí dùn gan-an láti rí owó náà. Owó tó ti tọ́jú láti fi sanwó àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ni. Obìnrin náà sọ pé: “Olóòótọ́ èèyàn bíi tìẹ ṣọ̀wọ́n láyé yìí.”
Àwọn kan gbà pé kò sí èrè nínú kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́ ìṣòtítọ́ jẹ́ ìwà tó dára lójú àwọn tó ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ dùn. (Éfésù 4:25, 28) Nelma sọ pé: “Ká ní mi ò dá owó ọ̀hún padà ni, ẹ̀rí ọkàn mi kò ní jẹ́ kí n lè sùn.”