Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí Bíbélì ò ti sọ nǹkan kan nípa àṣà nína ife ọtí sókè láti fi kan tẹ́lòmíì, kí nìdí tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í ṣe é?
Nína ife ọtí wáìnì (tàbí ọtí míì) sókè láti fi kan tẹlòmíì jẹ́ àṣà kan tó ti wà tipẹ́tipẹ́ táwọn èèyàn ń ṣe jákèjádò ayé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń ṣe é níbì kan lè yàtọ̀ sí ti ibòmíì. Àdúrà lẹni tó bá sọ fẹ́lòmíì pé kó jẹ́ káwọn jọ fi ife ọtí kanra sábà máa fi ń ṣe, ìyẹn àdúrà fún ayọ̀, ìlera tó péye, ẹ̀mí gígùn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn tó kù lè ṣàmín àdúrà tàbí kí wọ́n na ife ọtí tiwọn náà sókè kí wọ́n sì wá mu díẹ̀ ńbẹ̀. Lójú àwọn kan, àṣà yìí ò burú, nǹkan àyẹ́sí lásán ni wọ́n kà á sí. Àmọ́ ìdí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í ṣe é.
Kì í ṣe pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ò fẹ́ káwọn ẹlòmíì ní ayọ̀ àti ìlera ara o. Ó ṣe tán, nínú lẹ́tà tí ìgbìmọ̀ olùdarí ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní kọ sáwọn ìjọ, wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan parí rẹ̀ téèyàn lè túmọ̀ sí “kí ara yín ó lé o” tàbí “àlàáfíà fún yín o.” (Ìṣe 15:29) Àwọn olùjọsìn tòótọ́ kan sì sọ fún àwọn ọba tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn pé: “Kí olúwa mi . . . kí ó wà pẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin” tàbí “Kí ọba kí ó pẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—1 Àwọn Ọba 1:31; Nehemáyà 2:3.
Àmọ́, báwo ni àṣà nína ife ọtí sókè láti fi kan tẹlòmíì ṣe bẹ̀rẹ̀? Ilé Ìṣọ́ January 1, 1968 lédè Gẹ̀ẹ́sì fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica ti ọdún 1910, ìdìpọ̀ 13, ojú ìwé 121, ó ní: “Bóyá ni ò fi ní jẹ́ pé inú àṣà mímu ọtí láti fi júbà àwọn òrìṣà àtàwọn òkú, tí wọ́n máa ń ṣe láyé ọjọ́un, ni àṣà fífi ọtí ṣàdúrà pé kéèyàn ní ìlera ti wá. Táwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù bá ń jẹun, wọ́n máa ń ta ọtí silẹ̀ fáwọn òrìṣà wọn, wọ́n sì máa ń mu ọtí láti fi júbà àwọn òrìṣà náà àtàwọn òkú níbi àsè wọn.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà fi kún un pé: “Ó sì jọ pé mímu ọtí láti fi ṣàdúrà pé kéèyàn ní ìlera wà lára ohun táwọn èèyàn ayé ọjọ́un máa ń ṣe tí wọ́n bá ń mutí gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí òrìṣà wọn.”
Ṣé bó ṣì ṣe rí láyé ìsinsìnyí náà nìyẹn? Ìwé International Handbook on Alcohol and Culture ti ọdún 1995 tó dá lórí ọtí líle àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú àṣà títa wáìnì, ẹ̀jẹ̀ tàbí nǹkan míì bẹ́ẹ̀ tí wọ́n kà sí mímọ́ sílẹ̀ fáwọn òrìṣà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ, láti fi ṣàdúrà fẹ́nì kan pé, ‘kí ẹ̀mí rẹ gùn!’ tàbí ‘kí ara rẹ le!’ ni àṣà fífi ife ọtí ẹni kan tẹlòmíì láti fi ṣàyẹ́sí ti wá.”
Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo àṣà tàbí nǹkan tó wá látinú àwọn ìsìn èké ayé ọjọ́un tàbí tó bá ohun tí wọ́n ń ṣe nínú àwọn ìsìn náà mu ló burú tí olùjọsìn tòótọ́ bá lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni pómégíránétì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa tó dá lórí Bíbélì sọ pé: “Ó dà bíi pé wọ́n tún máa ń lo pómégíránétì gẹ́gẹ́ bí àmì mímọ́ láàárín àwọn abọgibọ̀pẹ̀ ayé àtijọ́.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ní kí wọ́n hun àwòrán pómégíránétì sí ìṣẹ́po etí ẹ̀wù àlùfáà àgbà, kí wọ́n sì fi àwòrán pómégíránétì ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn ọwọ̀n bàbà tó wà nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́. (Ẹ́kísódù 28:33; 2 Àwọn Ọba 25:17) Àpẹẹrẹ míì ni òrùka ìgbéyàwó. Àwọn onísìn kan ló máa ń lò ó láyé ìgbà kan, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni ò mọ̀ bẹ́ẹ̀ lóde òní. Ńṣe ni wọ́n kàn ka fífi òrùka ìgbéyàwó sọ́wọ́ sí ohun tó fi hàn pé ẹni kan ti ṣègbéyàwó.
Àṣà lílo wáìnì nígbà ìjọsìn ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan, nígbà táwọn ọkùnrin ìlú Ṣékémù bá ìjọsìn Báálì débì kan, wọ́n “wọnú ilé ọlọ́run wọn lọ, wọ́n sì jẹ, wọ́n sì mu, wọ́n sì pe ibi wá sórí Ábímélékì” ọmọ Gídíónì. (Àwọn Onídàájọ́ 9:22-28) Ǹjẹ́ o rò pé ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lára àwọn èèyàn náà á bá wọn lọ́wọ́ nínú ọtí mímu láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ lílọ sílé òrìṣà wọn láti gbé Ábímélékì ṣépè? Nígbà tí Ámósì ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà kan tí ọ̀pọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó ní: ‘Wọ́n nà gbalaja lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo pẹpẹ, wáìnì àwọn tí a bu ìtanràn lé ni wọ́n sì ń mu nínú ilé ọlọ́run wọn.’ (Ámósì 2:8) Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ń sin Ọlọ́run tòótọ́ á jẹ́ bá wọn lọ́wọ́ sí èyí, yálà wọ́n ta wáìnì náà sílẹ̀ láti fi rúbọ sí òrìṣà ni o, tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn mu ún lójúbọ òrìṣà? (Jeremáyà 7:18) Àbí, ṣé ẹni tó jẹ́ olùjọsìn tòótọ́ lára wọn á jẹ́ gbé ife wáìnì rẹ̀ sókè láti fi ṣépè pé kí òrìṣà má jẹ́ kó dáa fẹ́nì kan tàbí kó fi ṣàdúrà pé kó jẹ́ káyé ẹni náà dáa?
Nígbà míì, àwọn olùjọsìn Jèhófà pàápàá máa ń gbé ọwọ́ sókè ọ̀run láti tọrọ ìbùkún. Ní tiwọn, Ọlọ́run tòótọ́ ni wọ́n ń gbé ọwọ́ wọn sókè sí. Bí àpẹẹrẹ, a kà á nínú Bíbélì pé: “Sólómọ́nì sì dúró níwájú pẹpẹ Jèhófà . . . ó sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run wàyí; ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: ‘Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ . . . ǹjẹ́ kí ìwọ fúnra rẹ gbọ́ ní ibi tí o ń gbé, ní ọ̀run, kí o sì gbọ́, kí o sì dárí jì.’” (1 Àwọn Ọba 8:22, 23, 30) Bákan náà, “Ẹ́sírà fi ìbùkún fún Jèhófà . . . gbogbo àwọn ènìyàn [sì] dáhùn pé, ‘Àmín! Àmín!’ pẹ̀lú gbígbé ọwọ́ wọn sókè. Nígbà náà ni wọ́n tẹrí ba mọ́lẹ̀, wọ́n sì wólẹ̀ fún Jèhófà ní ìdojúbolẹ̀.” (Nehemáyà 8:6; 1 Tímótì 2:8) Ó dájú pé bí àwọn olóòótọ́ wọ̀nyẹn ṣe na ọwọ́ wọn sókè ọ̀run, kì í ṣe pé wọ́n ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ ọlọ́run oríire, ìyẹn òrìṣà táwọn kan gbà pé ó máa ń jẹ́ kéèyàn ṣoríire.—Aísáyà 65:11.
Ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú àṣà nína ife ọtí wáìnì sókè lónìí lè má mọ̀ pé ńṣe làwọn ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ òrìṣà, bákan náà sì ni wọn ò lè sọ ìdí tí wọ́n fi ń na ife ọtí wáìnì sókè ọ̀run. Àmọ́, bó ṣe jẹ́ pé wọn ò ronú lórí ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí wọ́n tó máa ṣe é ò fi hàn pé àwọn Kristẹni tòótọ́ pẹ̀lú ní láti máa lọ́wọ́ nínú rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń yẹra fún ṣíṣe àwọn nǹkan kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ máa ń gbọ́wọ́ lé oókan àyà wọn tàbí kí wọ́n bẹ́rí níwájú àsíá tàbí àmì orílẹ̀-èdè. Lójú tiwọn, ìyẹn kì í ṣe ìjọsìn. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í dí àwọn tó ń ṣe é lọ́wọ́, àmọ́ àwọn alára kì í ṣe é. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ pé tí wọ́n bá ti mọ ìgbà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa wáyé, wọ́n máa ń fọgbọ́n yẹra fún un láti má ṣe ohun tó máa bí àwọn èèyàn nínú. Àmọ́ bó ti wù kó rí, ìpinnu wọn ni pé àwọn ò ní ṣe ohun tó máa fi hàn pé àwọn jọ́sìn orilẹ̀-èdè wọn, bíi kíkí àsíá, èyí tó lòdì sí ohun tí Bíbélì sọ. (Ẹ́kísódù 20:4, 5; 1 Jòhánù 5:21) Ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní lè má ka àṣà nína ife ọtí wọn sókè kí wọ́n sì fi kan tẹlòmíì sí ṣíṣe ìjọsìn. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí ọ̀pọ̀ ìdí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí wọn kì í fi í lọ́wọ́ nínú àṣà yìí tó jẹ́ pé inú ìsìn èké ayé ọjọ́un ló ti wá, tó tún jẹ́ pé láyé ìsinsìnyí pàápàá, kò yàtọ̀ sí kéèyàn máa tọrọ nǹkan lọ́wọ́ àwọn òrìṣà.—Ẹ́kísódù 23:2.