Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Yẹra Fún Àṣejù?
TÁ A bá ń sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kò sẹ́ni tá a lè fi wé Jèhófà. “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀,” kì í sì í ṣèdájọ́ lọ́nà rírorò, nítorí pé àánú ló fi ń ṣe gbogbo ìdájọ́ rẹ̀. (Diutarónómì 32:4) Ó ń lo ìfẹ́ rẹ̀ lọ́nà tó bá ìlànà òdodo mu nítorí ó máa ń ṣe ohun gbogbo níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin pípé tó fi lélẹ̀. (Sáàmù 89:14; 103:13, 14) Nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, ó dá wọn ní pípé, lọ́nà tí wọ́n á fi lè máa ṣe ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àṣejù ò sí lọ́rọ̀ wọn. Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó wọlé dé ló fa “àbùkù” tàbí àìpé tí kò jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Diutarónómì 32:5.
Bí àpẹẹrẹ: Tẹ́nì kan bá gun kẹ̀kẹ́ kan tàbí tó wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí táyà rẹ̀ wú kùǹdù lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó dájú pé àbùkù ara táyà náà ò ní mú kó lọ geere. Ó tiẹ̀ léwu láti máa gun irú kẹ̀kẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ tàbí láti wà nínú irú ọkọ̀ bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbọ́dọ̀ tún táyà náà ṣe kó tó bà jẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ tàbí kó tó jò. Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Àìpé wa lè mú ká má wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nígbà míì. Tá a bá lọ jẹ́ kí àbùkù wa yìí máa pọ̀ sí i bí ìgbà tí ibi tó wú lára táyà yẹn ń wú sí i, ìrìn àjò ìgbésí ayé wa lè má lọ geere, ó tiẹ̀ lè léwu pàápàá.
Nígbà míì ó ṣeé ṣe kí àṣejù wọ bá a ṣe ń lo àwọn ànímọ́ rere tàbí ẹ̀bùn tá a ní. Bí àpẹẹrẹ, òótọ́ ni pé Òfin Mósè sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe ìṣẹ́tí sí aṣọ wọn, àmọ́ àwọn Farisí ìgbà ayé Jésù fẹ́ fi hàn pé àwọn yàtọ̀ sáwọn èèyàn tó kù, wọ́n wá ti àṣejù bọ tiwọn, wọ́n “sọ ìṣẹ́tí ẹ̀wù wọn di títóbi.” Ohun tó mú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ fi hàn pé àwọn jẹ́ olódodo ju àwọn èèyàn tó kù lọ.—Mátíù 23:5; Númérì 15:38-40.
Lóde òní, kò sóhun táwọn kan ò lè ṣe láti pàfiyèsí síra wọn káwọn èèyàn sáà lè mọ̀ pé wọ́n wà ńbẹ̀, kódà wọn ò kọ̀ láti ṣe ohun tó máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fáwọn èèyàn. Àfi bíi pé wọ́n ń sọ pé: “Ẹ wò mí! Ẹ má lẹ́ ò rí mi, èèyàn pàtàkì lèmi náà!” Àmọ́ ṣíṣe àṣejù nínú èrò, ìṣe àti aṣọ wíwọ̀ kò yẹ Kristẹni rárá.
Má Ya Ọ̀lẹ Má sì Ṣiṣẹ́ Àṣekúdórógbó
Ẹni yòówù ká jẹ́ àti ibi yòówù ká máa gbé, iṣẹ́ tó dáa máa ń mú ká láyọ̀ pé à ń fayé wa ṣe nǹkan kan. Ńṣe ni Ọlọ́run dá wa pé ká máa rí ìdùnnú nínú iṣẹ́ ọwọ́ wa. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Ìdí nìyí tí Bíbélì fi sọ pé kò dáa kéèyàn máa ṣọ̀lẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sojú abẹ níkòó pé: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.” (2 Tẹsalóníkà 3:10) Kò sí àní-àní pé ìṣẹ́ yóò ṣẹ́ ẹni tó bá ń ṣọ̀lẹ, kò ní láyọ̀, kò sì ní rí ojú rere Ọlọ́run.
Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá ti àṣejú bọ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ṣíṣe, wọ́n di oníṣẹ́ àṣekúdórógbó, wọ́n sọra wọn dẹrú iṣẹ́. Tí wọ́n bá ti jáde nílé láàárọ̀, ó tún di ọ̀gànjọ́ òru. Wọ́n lè máa sọ pé torí àtijẹ àtimu ìdílé làwọn kúkú fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ìdílé wọn lè máa jìyà iṣẹ́ àṣekúdórógbó tí wọ́n ń ṣe yìí. Ìyàwó ilé kan tí ọkọ rẹ̀ máa ń jókòó ti iṣẹ́ nígbà tó yẹ kó ti wà nílé sọ pé: “Kí ọkọ mi máa wà pẹ̀lú èmi àtàwọn ọmọ pé mi ju gbogbo ohun amáyédẹrùn tá a ní nínú ilé wa lọ.” Ó yẹ káwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó ronú jinlẹ̀ lórí ìrírí tí Sólómọ́nì Ọba ní. Ó sọ pé: “Èmi, àní èmi, sì yíjú sí gbogbo iṣẹ́ mi tí ọwọ́ mi ti ṣe, àti sí iṣẹ́ àṣekára tí mo ti ṣiṣẹ́ kárakára láti ṣe ní àṣeparí, sì wò ó! asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 2:11.
A ò gbọ́dọ̀ ṣàṣejù ní ìhà méjèèjì tá a sọ yìí, ìyẹn ni pé, kò yẹ ká ya ọ̀lẹ, síbẹ̀ ó yẹ ká máa rántí pé tá a bá sọra wa dẹrú iṣẹ́, tá à ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó, a ò ní láyọ̀, kódà ó lè ṣèpalára tó jù bẹ́ẹ̀ lọ fún wa.—Oníwàásù 4:5, 6.
Ní Èrò Tó Tọ́ Nípa Ìgbádùn Jíjẹ
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò wa yìí, “àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:2, 4) Lílépa adùn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí Sátánì máa ń lò jù láti fi tan àwọn èèyàn lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn eré àṣenajú àti eré ìdárayá tí wọ́n ki àṣejù bọ̀, irú bí eré ìdárayá eléwu táwọn kan máa ń ṣe láti fi mú ara wọn lórí yá, túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i. Ńṣe ni irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ àtàwọn tó ń ṣe wọ́n ń pọ̀ sí i. Kí wá nìdí tírú àwọn eré eléwu bẹ́ẹ̀ fi dohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọn ò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nígbèésí ayé máa ń wá ohun tó máa mú wọn lórí yá. Kí wọ́n lè máa rí irú ìmóríyá tí wọ́n ń wá yìí déédéé, wọ́n sábà máa ń ti orí ṣíṣe eré ìdárayá eléwu kan bọ́ sórí èyí tó túbọ̀ léwu jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́ àwọn Kristẹni olóòótọ́ kì í ṣe eré ìdárayá eléwu nítorí pé wọ́n ka ẹ̀mí sí iyebíye, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run tó fi í fúnni.—Sáàmù 36:9.
Nígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àtobìnrin àkọ́kọ́, ibo ló fi wọ́n sí? Inú ọgbà Édẹ́nì ni, èyí tó túmọ̀ sí “Ìgbádùn” tàbí “Adùn” nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8) Ó hàn gbangba pé ara ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ni pé kọ́mọ aráyé máa gbádùn ara wọn.
Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa nípa béèyàn ṣe lè ní èrò tó yẹ nípa ìgbádùn jíjẹ. Ìfẹ́ Jèhófà ló fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, kò sì ṣíwọ́ títẹ̀lé àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run. Ó wá àyè láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àní nígbà tó rẹ̀ ẹ́ pàápàá. (Mátíù 14:13, 14) Nígbà tí wọ́n pè é síbi àsè, ó lọ, ó sì tún wáyè láti sinmi àti láti tu ara rẹ̀ lára. Ó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá òun máa ń fojú tí ò dáa wo òun nítorí àwọn nǹkan tóun ń ṣe yẹn. Àwọn ọ̀tá náà sọ nípa rẹ̀ pé: “Wò ó! Ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alájẹkì, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún mímu wáìnì.” (Lúùkù 7:34; 10:38; 11:37) Àmọ́ Jésù ò gbà pé fífọkàn sin Ọlọ́run sọ pé kéèyàn má jẹ̀gbádùn rárá.
Ó ṣe kedere pé ọlọgbọ́n ni wá tá ò bá ṣàṣejù nídìí eré àṣenajú. Tó bá jẹ́ pé ìgbádùn jíjẹ àti eré ìnàjú lẹnì kan kà sí pàtàkì jù nígbèésí ayé, ìyẹn ò lè mú kó ní ojúlówó ayọ̀. Ó tiẹ̀ lè mú kó pa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ tì, títí kan àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kéèyàn má gbádùn ara rẹ̀ rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yẹ ká máa ṣàríwísí àwọn tí wọ́n ń jẹ̀gbádùn níwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Oníwàásù 2:24; 3:1-4.
Jẹ́ Oníwọ̀ntúnwọ̀nsì Kó O Lè Láyọ̀
Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jákọ́bù 3:2) Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn máa ṣẹlẹ̀ sí àwa náà bá a ṣe ń gbìyànjú láti yẹra fún àṣejù nínú àwọn ohun tá à ń ṣe. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tí a ó fi máa ṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì? Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa yẹ ara wa wò láti mọ ibi tá a ti ń ṣe dáadáa àti ibi tá a kù sí. Èyí ò rọrùn láti ṣe nítorí pé a lè máa ṣàṣejù nínú àwọn ohun kan ká má sì mọ̀. Nítorí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká sún mọ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí ká sì máa gba ìmọ̀ràn tó péye. (Gálátíà 6:1) A lè ní kí ọ̀rẹ́ wa kan tá a fọkàn tán tàbí alàgbà kan tó nírìírí nínú ìjọ fún wa ní irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ìmọ̀ràn wọn tó dá lórí Bíbélì àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táwa alára ń kà lè dà bíi “dígí” tá a ó máa fi wo ara wa láti mọ bá a ṣe ń ṣe sí lójú Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí.—Jákọ́bù 1:22-25.
Inú wa dùn pé ó ṣeé ṣe fún wa láti yẹra fún ìwà àṣejù. Tá a bá pinnu pé a fẹ́ yẹra fún ìwà àṣejù tá a sì ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a ó lè yẹra fún un, èyí á sì mú ká jẹ́ aláyọ̀. Ìyẹn á mú kí àárín àwa àtàwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa máa dára sí i, àá sì lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn tá à ń wàásù fún. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń túbọ̀ fara wé Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ tó ń ṣe nǹkan ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Éfésù 5:1.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
©Greg Epperson/age fotostock