Ohun Pàtàkì Kan Tá A Ó Ṣèrántí Rẹ̀ Lọ́jọ́
Monday, April 2!
Ní alẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ohun pàtàkì kan wáyé. Jésù gbé ife wáìnì kan fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n mu ún, bákan náà ló sì pín ìṣù búrẹ́dì aláìwú kan láàárín wọn. Ìtọ́ni wo ló wá fún wọn? Ó ní: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa ń pàdé pọ̀ láti ṣèrántí ikú Jésù. Ọ̀nà tó sì sọ pé ká máa gbà ṣe é lálẹ́ ọjọ́ tó sọ gbólóhùn yẹn là ń gbà ṣe é. Lọ́dún yìí, Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá yóò bẹ̀rẹ̀ ní Monday, April 2, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Tayọ̀tayọ̀ la fi pè ọ láti dara pọ̀ mọ́ wa nírọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ká lè jọ ṣèpàdé tá a fi ń rántí ikú Jésù yìí. Jọ̀wọ́, béèrè ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò ti ṣe é àti àkókò tí wọ́n yóò ṣe é.