Ìròyìn Nípa Ilẹ̀ Áfíríkà
Iye Orílẹ̀-èdè: 57
Iye Èèyàn: 802,232,357
Iye Akéde: 1,043,396
Iye Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: 1,903,665
Rwanda Nígbà kan, àwọn kan tó ń kọjá lọ rí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lójú títì. Wọ́n mú ìwé náà lọ fún alàgbà kan nínú ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n ń lọ. Alàgbà náà fara balẹ̀ ka ìwé náà, ó sì wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ìmọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì ti ń pọ̀ sí i, ó kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀ ó sì ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn ìyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara bá àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì. Àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lára àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì yẹn fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀ wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Alàgbà tó rọ́pò rẹ̀ pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí. Òun náà sì tún kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀. Ó ti ń lọ sípàdé déédéé báyìí, ó sì ti sọ pé òun fẹ́ di akéde ìjọba Ọlọ́run. Ìyàwó rẹ̀ ṣèrìbọmi ní ìpàdé àkànṣe kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ó yani lẹ́nu gan-an pé ìwé kan táwọn kan rí lójú títì ló mú kí gbogbo èyí ṣẹlẹ̀!
Côte d’Ivoire Nígbà tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Berenger ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nílùú Abidjan tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè yẹn, ó kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin kan tó ń ta búrẹ́dì. Owó já bọ́ lọ́wọ́ obìnrin náà kò sì mọ̀. Iye owó ọ̀hún jẹ́ 5,000 franc owó ilẹ̀ Faransé. Bí Berenger ti mú owó náà nílẹ̀ láti lọ fún ẹni tó ni owó náà ni obìnrin mìíràn yọ lọ́kàn-án tó sì ń pariwo pé, “Mú owó yẹn fún mi, èmi ni mo ni ín!” Àmọ́ nígbà tí Berenger ní kí obìnrin náà sọ iye tí owó náà jẹ́, ńṣe ló bínú tó sì bá tiẹ̀ lọ. Berenger wá sáré bá obìnrin tówó náà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé obìnrin náà sọ pé òun kò sọ owó nù, ó tún sọ fún Berenger pé, “O fẹ́ dọ́gbọ́n jà mí lólè ni.” Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òótọ́ ni Berenger ń sọ tó sì ń tẹnu mọ́ ọn, ló bá yẹ àpò rẹ̀ wò, ó wá rí i pé lóòótọ́ lòun ti sọ 5,000 franc nù, iye tó tóó ra àádọ́ta búrẹ́dì.
Berenger sọ pé: “Mo fún un ní owó náà, mo sì sọ fún un pé ohun tó jẹ́ kí n fún un lówó rẹ̀ ni pé Ọlọ́run mi, Jèhófà, kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti jẹ́ olóòótọ́. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ mi ó sì sọ pé: ‘Bí gbogbo èèyàn bá jẹ́ olóòótọ́ bí ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, gbogbo èèyàn ló máa jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí láyé mi tí màá rí ọ̀dọ́ kan tó ṣe irú nǹkan yìí.’ Mo fún un ní ìwé ìléwọ́ kan, obìnrin náà sì ṣèlérí pé látìgbà yẹn lọ, òun á máa fetí sílẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́jọ́ yẹn, 50 franc péré ni mo ní lọ́wọ́. Síbẹ̀, mo láyọ̀ pé mo ṣe ohun tó tọ́.”
Democratic Republic of Congo Eugene, tó jẹ́ alàgbà, ń ṣiṣẹ́ ìtọ́jú àyíká àti iṣẹ́ olùṣọ́ ní ṣọ́ọ̀bù dáyámọ́ńdì kan. Ó sọ pé: “Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ọkùnrin kan wá síbẹ̀, ó fẹ́ ta dáyámọ́ńdì tí owó rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [$22,000] owó dọ́là. Àmọ́, páálí kékeré tó kó dáyámọ́ńdì náà sí bọ́ sílẹ̀ nínú àpò rẹ̀. Ó wá a káàkiri, àmọ́ kò rí i. Lọ́jọ́ kejì, ọ̀gá rẹ̀ àtẹnìkan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lọ sí òpópónà náà, wọ́n sì wá páálí kékeré náà kiri títí, àmọ́ wọn kò rí i. Ẹ̀yìn ìyẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbálẹ̀ iwájú ìta, bí mo ṣe rí páálí kékeré tí dáyámọ́ńdì náà wà nínú rẹ̀ nìyẹn níwájú ṣọ́ọ̀bù wa! Mo mú un mo sì sáré lọ bá ọ̀gá mi tó jẹ́ ará Belgium. Ó yà á lẹ́nu gan-an pé mo mú un wá. Mo sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí àti pé mo níbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn. Ìṣòtítọ́ mi wú ẹni tó ni dáyámọ́ńdì náà lórí gan-an débi tó fi sọ pé, ‘Mi ò rírú eléyìí rí!’
“Ọ̀kan lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ fún mi pé, ‘Eugene, o ti jẹ́ ká gbayì sí i!’
“Mo fèsì pé: ‘O ṣeun! Jèhófà ló ni gbogbo ògo yìí, nítorí pé òun ló kọ́ mi láti máa ṣòótọ́.’”
Angola Nígbà tí arákùnrin João tó jẹ́ míṣọ́nnárì tó ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká ṣèbẹ̀wò sí ìgbèríko kan, ó fẹ́ fi fídíò DVD kan han àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ àtàwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Orúkọ fídíò náà ni Noah Walked With God—David Trusted in God. Arákùnrin náà gbé ẹ̀rọ amúnáwá kan dání, ẹ̀rọ gbohùngbohùn méjì, àti epo bẹntiróòlù, ó tún gbé kọ̀ǹpútà rẹ̀ kékeré dání. Ní abúlé àkọ́kọ́, ó dé sí ilé kan tí wọ́n fi amọ̀ kọ́, ó sì sọ pé òun máa fi fídíò kan hàn lálẹ́. Ó sọ pé: “Ẹnú yà mí nígbà tí mo rí nǹkan bí ogójì dín méjì èèyàn tí wọ́n gbé àga, bẹ́ǹṣì, òkúta, agolo mílíìkì, àtàwọn nǹkan mìíràn láti fi jókòó. Àyè tó wà nínú ilé náà kò tiẹ̀ tó láti gba ìdajì àwọn tó wá. Nítorí náà, ìta la ti wo fídíò náà. Ìràwọ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ lójú ọ̀run, mo sì gbé kọ̀ǹpútà mi sórí àwọn búlọ́ọ̀kù alámọ̀ bíi mélòó kan. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá síbẹ̀ jókòó sórí àwọn aṣọ Áfíríkà aláràbarà tí wọ́n tẹ́ sílẹ̀.” Kò pẹ́ tí gbogbo àgbègbè náà fi gbọ́ nípa fídíò náà, ọ̀pọ̀ èèyàn sì wá sáwọn abúlé tí arákùnrin João ṣèbẹ̀wò sí. Ó sọ pé: “Nígbà tí fídíò náà parí, kò sẹ́ni tó fẹ́ lọ sílé mọ́. Ọ̀pọ̀ wọn sọ pé alẹ́ ọjọ́ yẹn ni alẹ́ táwọn gbádùn jù lọ láyé àwọn, wọ́n sì dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà fún ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí yìí.” Láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí arákùnrin João fi bẹ àwọn àwùjọ tó wà ní ìgbèríko náà wò, iye àwọn tó wo fídíò DVD náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti àádọ́rin dín méjì [1,568] èèyàn!
Gánà Obìnrin kan tó ń jẹ́ Vida tó máa ń ṣòwò nǹkan oko ní ìlú Accra kò fẹ́ láti kó ẹ̀fọ́ wá fún àwọn tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Gánà. Kí nìdí? Pásítọ̀ rẹ̀ ti sọ fún un pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kórìíra àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Nítorí náà, nígbà tí Vida kọ́kọ́ kó nǹkan oko náà wá, ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tí gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé oúnjẹ níbẹ̀ ń kí i tẹ̀ríntẹ̀rín àti pẹ̀lú ọ̀yàyà tí wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Láàárín àwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó dojúlùmọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, ó sì kíyè sí i pé gbogbo wọn ló ń ṣe dáadáa sí òun, ó wá mọ̀ pé irọ́ ni pásítọ̀ òun pa.
Vida fẹ́ láti mọ̀ sí i, nítorí náà, ó ní kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ìwé kà. Láàárín oṣù mẹ́fà péré, Vida mọ béèyàn ṣe lè kàwé ó sì ń ka Bíbélì rẹ̀ fúnra rẹ̀. Ní ìpàdé àgbègbè kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, ó ṣèrìbọmi. Láìka yẹ̀yẹ́ táwọn ará ilé Vida àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi ṣe sí, ó ti ran mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan lọ́wọ́ láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.
Etiópíà Ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Awoke kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó rẹ̀ ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá. Síbẹ̀, nígbà tó ń rìnrìn àjò lọ sí ibì kan ní orílẹ̀-èdè rẹ̀ fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù méjì, ó pinnu láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí kàn. Nígbà tó débẹ̀, wọ́n ní kó lọ sí ọ́fíìsì tí ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa ti ń ṣiṣẹ́. Arábìnrin náà ti ń gbàdúrà pé kí arákùnrin kan wá ran ìjọ náà lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé ọkùnrin kan ń béèrè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó rántí àdúrà rẹ̀. Bó ṣe rí Awoke, tó múra dáadáa, tó sì dùn ún wò, ó ti gbà pé arákùnrin tóun ń gbàdúrà pé kó wá nìyẹn. Tayọ̀tayọ̀ ló fi sáré lọ bá a tó sì kí i tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Nítorí pé inú arábìnrin yẹn ti dùn kọjá àlà, Awoke kò lè sọ bóun ṣe jẹ́, kò sì fẹ́ ba ayọ̀ arábìnrin náà jẹ́ nígbà tó ń sọ fún àwọn ará nípa bí Awoke ṣe jẹ́. Awoke lọ sí gbogbo ìpàdé lákòókò tó fi wà níbẹ̀. Nígbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ parí, tí àkókò tó fún un láti lọ, àwọn arábìnrin kan pè é kó wá jẹun ọ̀sán lọ́dọ̀ àwọn, wọ́n sì ní kó gbàdúrà sórí oúnjẹ náà. Ó rántí bí ìyàwó rẹ̀ ṣe máa ń gbàdúrà sórí oúnjẹ wọn nílé, tó máa ń borí, tó sì máa ń gbàdúrà lórúkọ Jésù. Àdúrà àti oúnjẹ náà lọ́ geerege. Bí wọ́n ṣe ṣe dáadáa sí Awoke nígbà tó wà níbẹ̀ jọ ọ́ lójú gan-an, ló bá pinnu pé òun yóò di arákùnrin gidi. Nígbà tó padà délé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ kan láìpẹ́ yìí. Inú ìyàwó rẹ̀ dùn gan-an, Awoke sì ń retí ìgbà tóun máa láǹfààní láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fún ìjọ tó lọ yẹn.