Wá Gbọ́ Àkànṣe Àsọyé Kan
O Lè Nífọ̀kànbalẹ̀ Nínú Ayé Tó Kún Fún Ìdààmú Yìí!
A ó sọ àsọyé Bíbélì yìí jákèjádò ayé láwọn orílẹ̀-èdè tó ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] lọ. Ọjọ́ Sunday, April 15, 2007 ni àsọyé náà yóò wáyé ní ọ̀pọ̀ jù lọ ibi tá a ó ti sọ ọ́. Ẹ̀kọ́ wo lo máa rí kọ́ níbẹ̀? Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tá a ó kọ́ níbẹ̀ rèé:
Kí nìdí tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé kò fi ní ìfọ̀kànbalẹ̀?
Ìgbà wo gan-an ló di pé ayé kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ mọ́?
Ibo la ti lè rí ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀, báwo la sì ṣe lè rí i?
Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí tó o bá wà níbi àsọyé Bíbélì pàtàkì yìí tá a ó sọ láwọn ibi púpọ̀ kárí ayé. Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ó ti sọ àsọyé yìí láwọn ibi tó pọ̀ jù lọ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè rẹ yóò dùn láti jẹ́ kó o mọ àkókò tí a ó sọ ọ́ àti ibi tá a ó ti sọ ọ́. Tayọ̀tayọ̀ la fi pè ọ́ pé kó o wá síbi àsọyé Bíbélì yìí tó bá àkókò mu tó sì máa fún ọ níṣìírí.