Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Báwo ló ṣe yẹ ká lóye ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé opó kan gbọ́dọ̀ jẹ́ “aya ọkọ kan” kó tó lè dẹni tó yẹ láti rí ìrànlọ́wọ́ gbà nínú ìjọ Kristẹni?—1 Tímótì 5:9.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ opó ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ, gbólóhùn náà, “aya ọkọ kan” ní láti tọ́ka sí ipò tí obìnrin náà wà kó tó di opó. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ìgbà kan ṣoṣo péré ni opó náà ti ní láti ṣègbéyàwó kó tó lè rí ìrànwọ́ gbà? Àbó lè jẹ́ pé nǹkan míì ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?a
Àwọn kan sọ pé àwọn opó tí wọ́n ṣègbéyàwó lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn. Òótọ́ ni pé nínú ọ̀pọ̀ àṣà ìbílẹ̀ àti ní àwọn àwùjọ kan, àwọn èèyàn máa ń ka opó tó bá wà láìlọ́kọ míì sẹ́ni tó jẹ́ oníwà mímọ́ gan-an. Àmọ́, irú èrò bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sóhun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú àwọn lẹ́tà míì tó kọ. Bí àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni ní ìlú Kọ́ríńtì, ó jẹ́ kó yéni yékéyéké pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé opó kan yóò láyọ̀ gan-an tó bá wà láìlọ́kọ mìíràn, síbẹ̀ ó sọ pé “ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹni tí ó bá fẹ́, kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39, 40; Róòmù 7:2, 3) Láfikún síyẹn, nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ pé: “Mo fẹ́ kí àwọn opó tí ó kéré ní ọjọ́ orí ṣe ìgbéyàwó.” (1 Tímótì 5:14) Nítorí náà, wọn ò fojú burúkú wo opó kan tó bá yàn láti ní ọkọ mìíràn.
Kí wá ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì yẹn túmọ̀ sí? Inú ẹsẹ kan ṣoṣo yìí ni ọ̀rọ̀ náà “aya ọkọ kan” ti fara hàn nínú Bíbélì. Nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí gan-an ni “obìnrin tó jẹ́ ti ọkùnrin kan.” Ó yẹ ká kíyè sí i pé, gbólóhùn yìí jọ èyí tí Pọ́ọ̀lù lò láwọn ìgbà bíi mélòó kan nínú àwọn ìwé tó kọ. Gbólóhùn ọ̀hún ni “ọkọ aya kan,” tàbí “ọkùnrin tó jẹ́ ti obìnrin kan” gẹ́gẹ́ bí èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣe pè é. (1 Tímótì 3:2, 12; Títù 1:6) Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn náà “ọkọ aya kan” nígbà tó ń sọ àwọn ohun tó máa mú kẹ́nì kan yẹ fún ipò alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ yẹn ká, ohun tí gbólóhùn náà túmọ̀ sí ní ti gidi ni pé kí ọkùnrin kan tó lè yẹ lẹ́ni tí wọ́n máa gbéṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni, tó bá ti ṣègbéyàwó, kò ní jẹ́ oníṣekúṣe, á sì dúró ti aya rẹ̀ nígbà ìṣòro, yóò sì tún jẹ́ aláìlẹ́gàn.b Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ohun kan náà yìí ni gbólóhùn inú 1 Tímótì 5:9 ń sọ, ìyẹn ni pé kí opó kan tó lè yẹ lẹ́ni tó máa rí ìrànwọ́ gbà nínú ìjọ, ó ti gbọ́dọ̀ jẹ́ aya tí kì í ṣe oníṣekúṣe tó sì dúró ti ọkọ rẹ̀ gbágbáágbá nígbà tí ọkọ náà wà láàyè, ó sì ti gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí kò ní ìwà àìmọ́ kankan. Irú opó yìí náà ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó tún gbọ́dọ̀ láwọn ànímọ́ mìíràn tó mẹ́nu kàn nínú ẹsẹ tó tẹ̀ lé e.—1 Tímótì 5:10.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àṣà fífẹ́ ọkọ̀ púpọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, ìyẹn ni pé kí obìnrin kan jẹ́ aya ọkùnrin bíi mélòó kan lákòókò kan náà kì í ṣohun tí wọ́n fàyè gbà rárá ní gbogbo ilẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù lákòókò àwọn àpọ́sítélì. Nítorí náà, kò dájú pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn tó fi ń kọ̀wé sí Tímótì, kì í sì í ṣe nítorí àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ló ṣe sọ̀rọ̀ yìí.
b Tó o bá fẹ́ rí ibi tá a ti jíròrò kókó yìí, wo Ilé Ìṣọ́ October 15, 1996, ojú ìwé 17, àti “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú ẹ̀dà ti March 1, 1981, ojú ìwé 30.