ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 4/15 ojú ìwé 8-11
  • Nígbà Tí Nǹkan Ò Bá Rí Bó O Ṣe Rò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Nǹkan Ò Bá Rí Bó O Ṣe Rò
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Nǹkan Tó Lè Má Rí Béèyàn Ṣe Rò
  • Àìsọ Ìfẹ́ Ọkàn Ẹni Síta
  • Sọ Ohun Tó O Fẹ́
  • “Yára Nípa Ọ̀rọ̀ Gbígbọ́”
  • Ǹjẹ́ A Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó Báyìí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ Bí Ìgbéyàwó Rẹ Kò Bá Rí Bó O Ṣe Rò
    Jí!—2014
  • Ó Ṣeé Ṣe Kí Ìgbéyàwó Yín Má Forí Ṣánpọ́n O!
    Jí!—2001
  • “Ẹ Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Ní Ọlá”
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 4/15 ojú ìwé 8-11

Nígbà Tí Nǹkan Ò Bá Rí Bó O Ṣe Rò

KÒ SÍ ọkọ tàbí aya tí ò lè ní ẹ̀dùn ọkàn nígbà tí nǹkan ò bá rí bó ṣe rò. Kódà, èyí lè rí bẹ́ẹ̀ bó bá tiẹ̀ dà bíi pé ìwà àwọn méjèèjì bára mu gan-an nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà. Àmọ́, kí ló dé tí ìwà àwọn kan tó dà bíi pé wọ́n bára mu fi máa ń yàtọ̀ síra gan-an lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn?

Bíbélì sọ pé àwọn tí wọ́n ṣègbéyàwó yóò ní “ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28, Bíbélì The New English Bible) Ohun kan tó sábà máa ń fa díẹ̀ lára èyí ni àìpé àwa ẹ̀dá èèyàn. (Róòmù 3:23) Ó sì lè jẹ́ nítorí pé ọkọ tàbí aya tàbí àwọn méjèèjì ò tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. (Aísáyà 48:17, 18) Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ pé ohun tí ò ní lè ṣeé ṣe lẹnì kan ń fọkàn sí pé òun á rí lọ́dọ̀ ẹni táwọn jọ ń fẹ́ra táwọn bá di tọkọtaya. Èyí lè fa àìgbọ́ra-ẹni-yé láàárín wọn tí wọ́n bá di tọkọtaya tán, ó sì lè dá wàhálà ńlá sílẹ̀.

Àwọn Nǹkan Tó Lè Má Rí Béèyàn Ṣe Rò

Nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra sọ́nà, ó ṣeé ṣe kó o ti fọkàn ro bó o ṣe fẹ́ kí nǹkan rí láàárín ìwọ àti ọkọ rẹ tàbí aya rẹ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó, bó sì ṣe rí fún ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn nìyẹn. Ronú ná nípa bó o ṣe retí pé kí nǹkan máa lọ láàárín ìwọ àti ọkọ rẹ tàbí aya rẹ. Ǹjẹ́ nǹkan rí bó o ṣe rò? Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, má sọ pé ó ti kọjá àtúnṣe. Tẹ́ ẹ bá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, á ṣeé ṣe fún yín láti ṣàtúnṣe, láti mú kí nǹkan tó wọ́ padà tọ́.a (2 Tímótì 3:16) Àmọ́, ó máa dáa kó o padà ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó o ti fọkàn rò nípa bó o ṣe fẹ́ kí nǹkan rí nínú ìgbéyàwó yín.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan rò pé lẹ́yìn ìgbéyàwó àwọn, ńṣe làwọn àtẹni táwọn bá fẹ́ á máa fẹ́ra àwọn lójú nímú nígbà gbogbo bíi tàwọn tọkọtaya inú ìtàn àròsọ. Ìwọ náà sì lè rò pé ìwọ àtẹni tó o bá fẹ́ á jọ máa wà pa pọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà tàbí pé wẹ́rẹ́ lẹ ó máa yanjú gbogbo èdèkòyedè tó bá wáyé. Ọ̀pọ̀ rò pé táwọn bá ti lè ṣègbéyàwó, kò tún ní jẹ́ dandan fáwọn mọ́ láti máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Nítorí pé àwọn ohun téèyàn máa ń retí yìí kì í sábà rí béèyàn ṣe rò, ó dájú pé àwọn kan á rí ìjákulẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 3:16.

Ohun mìíràn tó lè má rí bí ẹnì kan ṣe rò ni pé, tóun bá sáà ti lè ṣègbéyàwó, òun á di aláyọ̀. Òótọ́ ni pé téèyàn bá ní ọkọ tàbí aya, èyí lè mú ayọ̀ ńlá wá fún un. (Òwe 18:22; 31:10; Oníwàásù 4:9) Àmọ́ ṣé táwọn méjì bá ti lè di tọkọtaya, ọ̀rọ̀ ìbínú ò lè wáyé láàárín wọn mọ́ nìyẹn? Àwọn tó rò bẹ́ẹ̀ sábà máa ń rí ìjákulẹ̀ nígbà tí wọ́n bá rí i pé ibi táwọn fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀!

Àìsọ Ìfẹ́ Ọkàn Ẹni Síta

Kì í ṣe gbogbo ohun téèyàn ń retí lọ́dọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ̀ ló jẹ́ ohun tí kò ṣeé ṣe. Àwọn míì jẹ́ ohun tó yẹ kéèyàn retí. Àmọ́, èdèkòyédè lè wáyé nítorí àwọn nǹkan kan tí ẹnì kan ń retí látọ̀dọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ̀. Ẹnì kan tó máa ń gba àwọn tọkọtaya nímọ̀ràn sọ àkíyèsí rẹ̀, ó ní: “Mo rí àwọn tọkọtaya tó máa ń bínú síra wọn nítorí pé ọ̀kan nínú wọn ò rí ohun tó ń retí lọ́dọ̀ ẹnì kejì, tó sì jẹ́ pé ẹnì kejì ò mọ̀ pé ó ń fẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀.” Kó o lè mọ bí èyí ṣe máa ń ṣẹlẹ̀, wo àpèjúwe yìí.

Ká sọ pé nígbà kan, Olú àti Bọ́lá ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Ibi tí Olú ń gbé jìn gan-an sílùú Bọ́lá. Kí wọ́n tó ṣègbéyàwó, Bọ́lá rí i pé nǹkan ò ní fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fóun tóun bá kó lọ sí ibòmíì nítorí pé ojú máa ń ti òun. Àmọ́ ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé tóun bá kó dé ọ̀dọ́ Olú, Olú á ran òun lọ́wọ́ kí ara òun lè mọlé ládùúgbò náà. Bí àpẹẹrẹ, Bọ́lá nírètí pé ńṣe lòun á máa wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ táwọn á sì jọ máa kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa pọ̀ títí tóun á fi dojúlùmọ̀ wọn. Àmọ́ Olú ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ló kàn máa ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, táá wá fi Bọ́lá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé àdúgbò náà sílẹ̀ lòun nìkan. Ó wá ń ṣe Bọ́lá bíi pé Olú pa òun tì. Èyí yà á lẹ́nu, ó sì ń rò ó nínú ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé kò yẹ kí Olú mọ̀ pé ojú máa ń tì mí ni?’

Ǹjẹ́ ohun tí ò ṣeé ṣe ni Bọ́lá ń fẹ́ kí ọkọ òun ṣe fóun? Rárá o. Ohun tó kàn ń fẹ́ ni pé kó ran òun lọ́wọ́ kí ara òun lè mọlé níbi tóun ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé yẹn. Ojú máa ń ti Bọ́lá gan-an tó bá pàdé ọ̀pọ̀ èèyàn tí ò mọ̀ rí. Àmọ́ kò sọ fún Olú. Nítorí náà Olú ò mọ̀. Kí ni Bọ́lá máa ṣe tí Olú ò bá ṣe nǹkan tó ń fẹ́? Ó lè máa dùn ún lọ́kàn kínú sì máa bí i. Tó bá wá yá, ó lè rò pé ọ̀rọ̀ òun ò jẹ Olú lọ́kàn rárá.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìjákulẹ̀ àti ẹ̀dùn ọkàn fún ìwọ náà nígbà tí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ ò bá ṣe ohun tó ò ń retí lọ́dọ̀ rẹ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe?

Sọ Ohun Tó O Fẹ́

Inú rẹ lè bà jẹ́ tí o kò bá rí ohun tó ò ń retí. (Òwe 13:12) Àmọ́ nǹkan kan wà tó o lè ṣe. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “O lè yí àwọn ẹlòmíràn lérò padà tó o bá gbọ́n tó o sì ń sọ̀rọ̀ tó fọgbọ́n yọ.” (Òwe 16:23, Bíbélì Contemporary English Version) Nítorí náà, tó o bá rí i pé ọkọ rẹ tàbí aya rẹ ò tíì ṣe ohun kan tó ò ń retí lọ́dọ̀ rẹ̀, tí nǹkan náà kì í sì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe, bá a sọ ọ́.

Wá àkókò tó wọ̀ láti bá a sọ̀rọ̀ ọ̀hún. Ibi tó yẹ ni kó o ti bá a sọ ọ́, kó o sì lo ọ̀rọ̀ tó tura. (Òwe 25:11) Má fìbínú sọ̀rọ̀, kó o sì sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Rántí pé ńṣe ló fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ àtohun tó ò ń retí pé kó ṣe fún ẹ, kì í ṣe pé o fẹ́ fẹ̀sùn kàn án.—Òwe 15:1.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe èyí? Ṣé kò yẹ kí ẹni tó bá jẹ́ olùgbatẹnirò fòye mọ ohun tí ọkọ rẹ̀ tàbí aya rẹ̀ ń fẹ́ ni? Ṣó o rí i, ó lè jẹ́ pé ojú ọ̀tọ̀ ni ọkọ rẹ tàbí aya rẹ fi ń wo ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ kó jẹ́ pé inú rẹ̀ máa dùn láti ṣe ohun tó o fẹ́ tó o bá sọ fún un. Sísọ tó o sọ fún un kó tó ṣe é kò fi hàn pé kì í gba tẹni rò, kò sì fi hàn pé àárín yín ò gún.

Nítorí náà, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti bá aya rẹ tàbí ọkọ rẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ. Nínú àpèjúwe tá a sọ lẹ́ẹ̀kan, ì bá dáa kí Bọ́lá sọ fún Olú pé: “Ojú máa ń tì mí gan-an tí mo bá rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́ ṣẹ́ ẹ lè máa ràn mí lọ́wọ́ títí màá fi dojúlùmọ̀ wọn?”

“Yára Nípa Ọ̀rọ̀ Gbígbọ́”

Wàyí o, gba ibòmíràn wo ọ̀rọ̀ yìí. Ká ní ọkọ rẹ tàbí aya rẹ ní ẹ̀dùn ọkàn nítorí pé o kò ṣe nǹkan kan tó ń fẹ́, bẹ́ẹ̀, ohun náà ò kọjá agbára rẹ. Tó bá sọ pé òun fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, gbọ́ ohun tó bá sọ! Má ṣe wá àwíjàre. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19; Òwe 18:13) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.

Wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ro bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ọkọ rẹ tàbí aya rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá [aya yín] gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀,” tàbí ká sọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì J. B. Phillips ṣe sọ ọ́, “kí ẹ̀yin ọkọ gbìyànjú láti mọ aya tẹ́ ẹ̀ ń bá gbé.” (1 Pétérù 3:7) Ó yẹ káwọn aya náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Rántí pé bó ti wù kí ìwà ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ fẹ́ra bára mu tó, ẹ ò lè máa ní èrò kan náà nípa gbogbo nǹkan. (Wo àpótí tó ní àkọlé náà, “Wọ́n Ń Wo Òréré Kan Náà, Àmọ́ Bí Kálukú Wọn Ṣe Rí I Yàtọ̀ Síra.”) Àǹfààní sì lèyí jẹ́, nítorí pé kò ní jẹ́ pé èrò kan ṣoṣo lẹ ó máa rí gbé yẹ̀ wò tẹ́ ẹ bá ń jíròrò. Ìdílé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ ti wá, àṣà ìbílẹ̀ yín sì lè má dọ́gba, èyí tó lè mú kí ohun tí kálukú yín ń fẹ́ yàtọ̀. Nítorí náà, ẹ lè nífẹ̀ẹ́ ara yín gan-an, síbẹ̀ kí ohun tí kálukú yín nífẹ̀ẹ́ sí yàtọ̀ síra.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lè mọ ìlànà ipò orí tó wà nínú Bíbélì lámọ̀dunjú. (Éfésù 5:22, 23) Àmọ́, báwo ni ọkọ á ṣe lo ipò orí nínú ìdílé, báwo ni aya á sì ṣe fi ìtẹríba hàn? Ǹjẹ́ ẹ̀yin méjèèjì ń jẹ́ kí ìlànà Bíbélì yìí máa tọ́ yín sọ́nà, ṣé ẹ sì ń sa gbogbo ipá yín láti fi sílò?

Síwájú sí i, ẹ lè ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa àwọn ohun mìíràn. Irú àwọn nǹkan bíi: Ta ni yóò máa ṣe oríṣi àwọn iṣẹ́ ilé kan pàtó? Ìgbà wo lẹ óò máa lọ kí àwọn ìbátan yín, báwo sì ni àkókò tí ẹ óò fi máa wà pẹ̀lú wọn á ṣe pọ̀ tó? Báwo làwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ṣe lè fi hàn pé ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run làwọn fi ń ṣáájú? (Mátíù 6:33) Lórí ọ̀rọ̀ ti owó níná, téèyàn ò bá ṣọ́ra, á ti jẹ gbèsè kó tó mọ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ẹni tí kì í ná ìná àpà kẹ́ ẹ sì wá bí ẹ ó ṣe lówó nípamọ́. Báwo lẹ ṣe lè ṣe é? Ńṣe ló yẹ kẹ́ ẹ jọ jíròrò irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Tẹ́ ẹ bá jọ jíròrò rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n, àǹfààní ńlá lẹ máa rí níbẹ̀.

Irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kí àárín yín tòrò, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé títí di báyìí, àwọn ohun kan ò tíì rí bẹ́ ẹ ṣe rò. Tẹ́ ẹ bá jọ ń jíròrò, á lè túbọ̀ ṣeé ṣe fún yín láti fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”—Kólósè 3:13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó wúlò fún àwọn lọ́kọláya wà nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

WỌ́N Ń WO ÒRÉRÉ KAN NÁÀ, ÀMỌ́ BÍ KÁLUKÚ WỌN ṢE RÍ I YÀTỌ̀ SÍRA

‘Finuwoye ogunlọgọ awọn arinrin-ajo ti wọn ń wo iran ilẹ daradara kan. Bi o tilẹ jẹ pe gbogbo awọn eniyan naa ń wo iran kan-naa, ẹnikọọkan ń rí i ní ọ̀nà ti o yatọsira. Eeṣe? Nitori pe olukuluku duro si ibi ti o yatọsira. Kò si ẹni meji ti ó duro si ipo kan-naa ni pato. Siwaju sii, kìí ṣe gbogbo eniyan ni wọn ń wo apa ibi kan-naa ninu iran naa. Olukuluku rí apá kan ti o yatọ gẹgẹ bi eyi ti ń ru ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ soke ni pataki. Ohun kan-naa ni o jẹ́ otitọ ninu igbeyawo. Ani nigba ti wọn bá bá araawọn mu gan-an, kò si awọn tọkọtaya meji ti wọn ni oju-iwoye kan-naa lori awọn ọ̀ràn. Ijumọsọrọpọ ní ninu isapa naa lati pa ero pọ ki wọn si fi imọ ṣọkan. Eyi ń beere fun fifi akoko silẹ lati sọrọ.’—Ilé-Ìṣọ́nà August 1, 1993, ojú ewé 4.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

OHUN TÓ O LÈ ṢE BÁYÌÍ

• Tún àwọn ohun tó ò ń retí gbé yẹ̀ wò. Ǹjẹ́ nǹkan tó ṣeé ṣe ni? Ṣé kì í ṣe pé ohun tó ò ń retí lọ́dọ̀ ọkọ rẹ tàbí aya rẹ ti pọ̀ jù?—Fílípì 2:4; 4:5.

• Tún èrò rẹ ṣe tó bá jẹ́ pé nǹkan tí ò lè ṣeé ṣe lò ń retí. Bí àpẹẹrẹ, dípò kó o máa sọ pé, “Ọ̀rọ̀ ìbínú ò lè wáyé láàárín wa láéláé,” pinnu pé ńṣe lẹ óò máa sapá láti fi pẹ̀lẹ́tù yanjú èdèkòyedè tó bá wáyé.—Éfésù 4:32.

• Ẹ bára yín jíròrò àwọn ohun tẹ́ ẹ̀ ń retí látọ̀dọ̀ ara yín. Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ kan pàtàkì nínú kíkọ́ bẹ́ ẹ ṣe lè máa fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bá ara yín lò.—Éfésù 5:33.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

“Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́” tí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ bá ń bá ọ sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́