ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 4/15 ojú ìwé 30
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1999
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Kọfí Espresso—Ògidì Kọfí
    Jí!—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 4/15 ojú ìwé 30

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó yẹ kí Kristẹni máa mu àwọn ohun mímu tó ní èròjà kaféènì tàbí kó máa jẹ ohun jíjẹ tó ní èròjà kaféènì?

Bíbélì ò ní kí Kristẹni má mu kọfí, tíì, àwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò, ṣokoléètì tàbí àwọn ohun mímú míì tó ní èròjà kaféènì. Ṣùgbọ́n o, àwọn ìlànà wà nínú Bíbélì tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ìdí táwọn kan kì í fi í mu àwọn ohun tó ní èròjà kaféènì, tí wọn kì í sì í jẹ ohun tó ní èròjà kaféènì.

Ìdí kan pàtàkì táwọn míì fi máa ń yẹra fún ohun tó bá ti ní èròjà kaféènì ni pé, wọ́n gbà pé èròjà kaféènì wà lára àwọn èròjà tó ń mú kí ìṣesí èèyàn yí padà nítorí pé ó máa ń nípa lórí ọpọlọ èèyàn. Ìdí mìíràn ni pé ó lè di bárakú sí èèyàn lára. Ìwé atọ́nà kan táwọn onímọ̀ nípa oògùn òyìnbó máa ń lò sọ pé: “Téèyàn bá ń mu tàbí tó ń jẹ ohun tó ní èròjà kaféènì púpọ̀ fúngbà pípẹ́, ó lè máa dùn mọ́ọ̀yàn, kó sì wá di bárakú séèyàn lára débì pé èèyàn ò ní lè ṣe kó má mu ún tàbí kó má jẹ ẹ́. Téèyàn bá sì wá fi í sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, tí kò fi í sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀, ó lè fa àìbalẹ̀ ọkàn, ẹ̀fọ́rí, ìkanra àti ìfòyà, ó sì lè mú kí òòyì máa kọ́ni tàbí kó fa àwọn nǹkan mìíràn bẹ́ẹ̀.” Àwọn onímọ̀ tiẹ̀ ti ń gbèrò àtifi àwọn nǹkan wọ̀nyí kun ohun tí ìwé Diagnostic and Statistical Manual of Mental Disorders tó sọ̀rọ̀ nípa ìtọ́jú àrùn ọpọlọ sọ pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá ṣíwọ́ lílo oògùn olóró. Tó fi hàn pé wọ́n fẹ́ ka èròjà kaféènì náà sí oògùn olóró. Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni kan fi wò ó pé kò dára káwọn máa mu ohun tó ní èròjà kaféènì, nítorí pé wọn ò fẹ́ kí ohunkóhun di bárakú fáwọn, wọ́n sì fẹ́ jẹ́ ẹni tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu.—Gálátíà 5:23.

Àwọn kan gbà pé èròjà kaféènì lè ṣàkóbá fún ìlera èèyàn àti fún oyún inú. Àwọn Kristẹni sì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn,’ ìdí rèé tí wọn kì í lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó bá máa ké ẹ̀mí wọn kúrú. Níwọ̀n bí Bíbélì sì ti pa á láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn, wọ́n máa ń yẹra fún àwọn ohun tó lè ṣèpalára fún oyún inú.—Lúùkù 10:25-27.

Ǹjẹ́ ìbẹ̀rù pé èròjà kaféènì lè ṣèpalára fún ìlera èèyàn lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀? Àwọn kan sọ pé èròjà kaféènì máa ń fa onírúurú àìsàn, àmọ́ àwọn mìíràn sọ pé irọ́ ni. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tó ń ṣèwádìí tiẹ̀ sọ pé kọfí dáa fára. Lọ́dún 2006, ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Àyẹ̀wò táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kọ́kọ́ ṣe fi hàn pé [èròjà kaféènì] lè fa àrùn jẹjẹrẹ inú àpò ìtọ̀, ẹ̀jẹ̀ ríru, àtàwọn àìsàn mìíràn. Àmọ́, àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, àwọn àyẹ̀wò náà tiẹ̀ tún fi hàn pé èròjà kaféènì ń ṣe àwọn àǹfààní kan fún ara. Ó dà bíi pé èròjà kaféènì máa ń dènà àwọn àrùn bíi, àrùn Parkinson tó máa ń mú kí ọwọ́ àti ẹsẹ̀ máa gbọ̀n, àrùn àtọ̀gbẹ, àìsàn tó ń mú kí arúgbó máa ṣarán, òkúta inú àpò òróòro, àárẹ̀ ọkàn, àìsàn tó ń ba ẹ̀dọ̀ èèyàn jẹ́, àti àwọn àrùn jẹjẹrẹ kan.” Nígbà tí ìwé ìròyìn kan ń sọ̀rọ̀ nípa mímu tàbí jíjẹ ohun tó ní èròjà kaféènì, ó sọ pé: “Ohun tó ti dáa jù ni pé kéèyàn jẹ́ kó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì.”

Ńṣe ló yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan pinnu ohun tóun máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. Kí ìpinnu ọ̀hún sì wà níbàámu pẹ̀lú òye rẹ̀ lórí àlàyé tó bóde mu táwọn èèyàn ti tẹ̀ jáde nípa èròjà kaféènì, kí ìpinnu náà sì tún wà níbàámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì tó ṣeé ṣe kó jẹ mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, bí aláboyún kan tó jẹ́ Kristẹni bá wò ó pé èròjà kaféènì lè ṣèpalára fún oyún inú òun, ó lè sọ pé òun ò ní mu ohunkóhun tàbí jẹ ohunkóhun tó bá ní èròjà kaféènì. Tí Kristẹni kan bá sì rí i pé bóun ò bá rí ohun mímu tó ní èròjà kaféènì mu déédéé ara òun kì í balẹ̀ tàbí pé òun máa ń ṣàìsàn, ó lè dáa kó jáwọ́ nínú rẹ̀, tàbí ó kéré tán, kó fi í sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ ná. (2 Pétérù 1:5, 6) Kí àwọn Kristẹni mìíràn má ta ko ìpinnu tó bá ṣe, kí wọ́n má sì fi tipátipá mú un ṣe ohun táwọn ń fẹ́.

Ìpinnu yòówù kó o ṣe lórí ọ̀rọ̀ ohun mímu tó ní èròjà kaféènì àti lórí ọ̀rọ̀ ohun jíjẹ tó ní èròjà kaféènì, fi àmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́