Wíwo Ayé
Àwọn Kátólíìkì Kọ̀wé Ẹ̀bẹ̀ sí Póòpù
Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung ròyìn pé, ní apá ìparí ọdún 1995, àwọn Kátólíìkì ọmọ ilẹ̀ Germany kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ kan tí ń pè fún àtúntò ṣọ́ọ̀ṣì náà. Ìwé ẹ̀bẹ̀ náà, tí nǹkan bíi mílíọ̀nù 1.6 ènìyán fọwọ́ sí, pe ìpè pé kí ṣọ́ọ̀ṣì fàyè gba àwọn àlùfáà láti gbéyàwó, kí ó fàyè gba àwọn obìnrin láti di àlùfáà, kí ó sì yí ìpinnu rẹ̀ lórí ìbálòpọ̀ takọtabo àti ìfètòsọ́mọbíbí padà. Christian Weisner, tí ó bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ kíkọ ìwé ẹ̀bẹ̀ náà, ṣàlàyé pé: “Póòpù fúnra rẹ̀ ni a ń dojú ọ̀rọ̀ kọ.” Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, Karl Lehmann, alága Ìgbìmọ̀ Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Germany ní àtakò ṣíṣe kókó kan lòdì sí ìwé ẹ̀bẹ̀ náà tí ó sọ pé yóò yọrí sí ìpín sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àwọn Kátólíìkì arọ̀mọ́pìlẹ̀ àti àwọn ayípìlẹ̀padà. Síbẹ̀síbẹ̀, Lehmann lọ gbé àbájáde ìwé ẹ̀bẹ̀ náà fún póòpù ní Vatican.
Ọdún 1995 Gba “Èlé Ìṣẹ́jú Àáyá”
Ó jọ pé àyípoyípo ayé kọ́ ni ọ̀nà tí ó ṣeé gbára lé jù lọ láti ṣírò àkókò. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ṣe sọ, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní ọ̀nà kan tí ó túbọ̀ péye láti ṣírò àkókò—átọ̀mù cesium. Átọ̀mù cesium tí a lò bí ìpìlẹ̀ agogo oní átọ̀mù náà máa ń gbọ̀n rìrì ní ìgbà 9,192,631,770 gééré láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan. Ní ìwọ̀n yìí, aago oní átọ̀mù náà kò lè ṣe ju “àṣìṣe nǹkan bí ìṣẹ́jú àáyá kan láàárín 370,000 ọdún lọ.” Ní ìfiwéra, àyípoyípo ayé lè ṣe àṣìṣe ní nǹkan bí ìlọ́po mílíọ̀nù kan, èyí tí ó jẹ́ ìdí tí a fi gbọ́dọ̀ máa ṣàfikún “èlé ìṣẹ́jú àáyá” kan látìgbàdégbà. Agbo àwọn tí ń ṣọ́ ìpéye ìdíwọ̀n àkókò kárí ayé kan pinnu láti fi irú “èlé ìṣẹ́jú àáyá” bẹ́ẹ̀ kan kún ìparí ọdún 1995. Èyí fàyè gba ìbáradọ́gba láàárín “àyípoyípo pílánẹ́ẹ̀tì wa àti bí àkókò ṣe ń lọ.” Bí ó ti wù kí ó rí, kò ṣeé ṣe fún àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ láti gboríyìn àwárí yìí. Ó ṣe tán, ìwé agbéròyìnjáde Times sọ pé “ìṣiṣẹ́ àwọn ẹ̀yà ara aago náà, tí ń lo agbára átọ̀mù, ń fara wé àràmàǹdà ìṣètò ìgbékalẹ̀ pílánẹ́ẹ̀tì lọ́nà kéréje kan ni.”
Àwọn Ọmọ Ọwọ́ àti Ìmọ̀ Ẹ̀rọ
Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail ti Kánádà ròyìn pé: “Àwọn ọmọdé púpọ̀ sí i ń ní ìmọ̀ nípa kọ̀m̀pútà kí wọ́n tó mọ̀wé kà.” Àwọn ọmọ ọwọ́ mélòó kan tí kò tilẹ̀ tí ì mọ ìrìn í rìn tàbí mọ ọ̀rọ̀ í sọ ti ń lo kọ̀m̀pútà. Àní a ti ń kọ́ àwọn ọmọdé tí kò tí ì lè dá jókòó ní òye iṣẹ́ ẹ̀rọ nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ẹsẹ̀ àwọn òbí wọn. Ìkánjú láti fi òye kọ̀m̀pútà yé àwọn ọmọdé sábà ń wáyé láti ọwọ́ àwọn òbí tí ń hára gàgà pé kí àwọn ọmọ wọ́n ta yọ nílé ẹ̀kọ́. Láfikún, ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ tí ń ṣe ìgbékalẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún lílò lórí kọ̀m̀pútà ń kókìkí àwọn ìmújáde wọn bí èèlò ìrànwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọdé. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn òbí kan ń ṣiyè méjì nípa ìtẹnumọ́ tí a ń gbé karí àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rọ, kàkà kí ó jẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn, ní irú ọjọ́ orí kékeré bẹ́ẹ̀. Ìyá kan sọ pé: “Kò yẹ kí a mú àjọṣepọ̀ dàgbà pẹ̀lú kọ̀m̀pútà, tàbí, ó kéré tán, n kò rò pé ó yẹ kí a ṣe bẹ́ẹ̀.”
Ojútùú Rírọrùn
Iye òkú ènìyàn tí a ń yọ̀ǹda láti máa là fi ṣe ìwádìí ìṣègùn ní Japan ti ń pọ̀ sí i ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Daily Yomiuri ṣe sọ, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀kọ́ sọ pé, “akẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn méjì nílò ara òkú kan, akẹ́kọ̀ọ́ ìtọ́jú eyín mẹ́rin sì nílò [ọ̀kan], tí ó sọ iye ara òkú tí a nílò jákèjádò orílẹ̀-èdè náà lọ́dún kan di 4,500.” Ṣùgbọ́n èé ṣe tí àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i fi ń yọ̀ǹda ara òkú wọn ju iye tí a nílò lọ? Lára àwọn ìdí tí a tọ́ka sí ni àìnílẹ̀ tó fún gbígbẹ́ sàréè àti ìdè ìdílé tí ń dẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ Àrùn AIDS Ré Kọjá 500,000 ní United States
Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé, ní October 31, 1995, àròpọ̀ iye ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn AIDS tí a ròyìn ní United States ré kọjá ìlà ìdajì mílíọ̀nù, fún ìgbà àkọ́kọ́. Nínú iye yìí, àrùn náà ti pa 311,381—ìpín 62 nínú ọgọ́rùn-ún. Ìṣẹ̀lẹ̀ ìdágùdẹ̀ míràn ni ti ìbísí àrùn AIDS nípasẹ̀ ìbẹ́yàkejì lò pọ̀. Ìwé ìròyìn náà tọ́ka sí i pé, láti 1981 sí 1987, ìpíndọ́gba ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn AIDS jẹ́ kìkì ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún, ṣùgbọ́n láti 1993 sí 1995, iye yẹn ti ga dé ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún.
Àwọn Tí Ń Sọ Ìjíròrò Lórí Ìsokọ́ra Kọ̀m̀pútà Dàṣà
Lílo ìsokọ́ra ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà fún ẹ̀rọ tẹlifóònù ti dá àrùn tuntun kan sílẹ̀ tí a ń pè ní “Ìṣiṣẹ́gbòdì Ìsọdàṣà Ìsokọ́ra Ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ṣe sọ, “púpọ̀ sí i àwọn tí ń nírìírí ìpani-bí-ọtí náà ń wá ìrànwọ́ àwọn agbo alátìlẹyìn àti àwọn olùṣètọ́jú láti wo ìsúnniṣe tipátipá wọn sàn.” Dókítà Ivan Goldberg, oníṣègùn ọpọlọ kan ní New York, ni ó dá Ẹgbẹ́ Alátìlẹyìn Àwọn Òjìyà Ìṣiṣẹ́gbòdì Ìsọdàṣà Ìsokọ́ra Ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀ náà sílẹ̀, láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí “ń tiraka láti bọ́” lọ́wọ́ ojú ọ̀nà márosẹ̀ ìfìsọfúniránṣẹ́ náà. Lára àwọn àmì tí a fi ń dá àrùn náà mọ̀ ni “àìgbọdọ̀máṣe ti lílo àkókò púpọ̀ sí i lórí Ìsokọ́ra ẹ̀rọ náà láti ní ìtẹ́lọ́rùn, àti ìfọkànyàwòrán tàbí àlá asán nípa Ìsokọ́ra náà.” Ìwé ìròyìn náà wí pé, Goldberg ti rí gbà “ju 20 ìdáhùnpadà lọ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n sọ pé Ìsokọ́ra náà ti dabarú ìgbésí ayé àwọn.”
Ìtànṣán Oòrùn Ń Ṣàlékún Ìlànà Ìwà Híhù
Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal ròyìn pé, mímú kí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí ń wọnú ilé pọ̀ sí i ń yọrí sí “ìbísí nínú ìṣèmújáde” àti “ìdínkù nínú iye ọjọ́ ìpaṣẹ́jẹ.” Ìṣètò ìgbékalẹ̀ ilé tí ń mú kí ìtànṣán oòrùn wọlé síbi iṣẹ́, tí a pète gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti má ṣe lo okun dànù ń yọrí sí èrè ńlá àti ìmúsunwọ̀n ìlànà ìwà híhù àwọn òṣìṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ilé iṣẹ́ ńlá náà, Àjọ Lockheed, ṣí ilé iṣẹ́ tuntun kan ní Sunnyvale, California, ìṣètò ìgbékalẹ̀ ìkọ́lé rẹ̀ “dín gbogbo okun tí ó náni kù sí ìdajì.” Bí ó ti wù kí ó rí, ilé iṣẹ́ Lockheed kò retí pé àwọn òṣìṣẹ́ yóò gbádùn àyíká wọn tuntun tó bẹ́ẹ̀ tí “ìpaṣẹ́jẹ lọ sílẹ̀” ní ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún. A ti ṣàkíyèsí àǹfààní jíjẹ́ kí ìtànṣán oòrùn púpọ̀ sí i wọlé lọ́dọ̀ àwọn aláràtúntà ọjà. Oníwóróbo kan rí i pé ọjà rẹ̀ ń tà “lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ” níbi ìtajà tí ń lo ìmọ́lẹ̀ oòrùn dípò ìmọ́lẹ̀ àtọwọ́dá.
Ayé Kan Tí Ń Ṣọ́ Ẹ̀ṣọ́ Lórí Omi
Ismail Serageldin, igbákejì ààrẹ Báńkì Àgbáyé nípa àyíká, ti kìlọ̀ pé: “Àwọn ogun ọ̀rúndún tí ń bọ̀ yóò jẹ́ nítorí omi.” Gẹ́gẹ́ bí Serageldin ṣe wí, 80 orílẹ̀-èdè ti ní àìtó omi tí ń wu ìlera àti ọrọ̀ ajé wọn léwu báyìí. Ṣùgbọ́n ìṣòro náà kì í ṣe ti àìsí omi púpọ̀ tó lórí ilẹ̀ ayé. Onímọ̀ nípa omi, Robert Ambroggi, sọ pé: “Àpapọ̀ ìwọ̀n omi mímọ́ gaara lórí Ilẹ̀ Ayé pọ̀ ju gbogbo ohun tí a lè ronú pé gbogbo ẹ̀dá ènìyàn nílò lọ.” Ọ̀pọ̀ jù lọ atótónu jẹ́ nítorí àìfọgbọ́n lo omi. Ìdajì omi tí a fi ń rinlẹ̀ oko ń wọlẹ̀ lọ tàbí oòrùn ń fà á. Ìpèsè omi láàárín ìlú ń jo ìpín 30 sí 50 nínú ọgọ́rùn-ún omi dà nù, ó tilẹ̀ ń jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà míràn. Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “Àkókò náà ń bọ̀ tí a gbọ́dọ̀ fojú wo omi bí ohun ọrọ̀ níníye lórí, bí epo, kì í ṣe nǹkan ọ̀fẹ́ bí afẹ́fẹ́.”
Sísùn Láìnírora
Lẹ́tà ìròyìn Tufts University Diet & Nutrition Letter ròyìn pé àwọn oògun orí àtẹ kan lè fa àìróorunsùntó. “Ìyẹ́n jẹ́ nítorí pé àwọn díẹ̀ lára àwọn oògùn apàrora tí a mọ̀ dunjú ní kaféènì tí ó pọ̀ tó ti inú ife kọfí kan, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.” A sábà máa ń fi kaféènì—amúniṣàfikún ìgbéṣẹ́ṣe fúngbà díẹ̀ tí ń yọ́ṣẹ́ ṣe—sínú aspirin àti àwọn egbòogi apàrora mìíràn, kí ìṣiṣẹ́ wọ́n lè túbọ̀ lágbára. Ní ti gidi, àwọn oríṣi gbígbajúmọ̀ kan ní tó 130 mílígíráàmù kaféènì nínú ẹyọ hóró egbòogi méjì. Ìyẹ́n “fi púpọ̀ ju 85 mílígíráàmù tí ó wà nínú abọ́dé ife” kọfí “kan lọ.” Lẹ́tà ìròyìn náà tìtorí bẹ́ẹ̀ dámọ̀ràn pé kí a máa ṣàyẹ̀wò bébà pélébé ara egbòogi apàrora nítorí “àwọn èròjà tí ó lè jà padà” láti mọ̀ bóyá ó ní kaféènì nínú.
“Ìbúgbàù Àrùn Ikọ́ Fée”
Ìwé agbéròyìnjáde Indian Express ròyìn pé oríṣiríṣi àrùn ikọ́ fée (TB) tuntun tí kò gbóògùn ń pa 10,000 ènìyàn ní India lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Kraig Klaudt ti Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe wí, India “jókòó lórí àgbá ẹ̀tù TB.” Kárí ayé, bílíọ̀nù 1.75 ènìyàn ní kòkòrò àrùn ikọ́ fée. Àwùjọ àwọn ògbóǹkangí kan, tí wọ́n wá láti 40 orílẹ̀-èdè tí wọ́n kóra jọ pọ̀ fún ìpàdé kan tí ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn ìṣègùn náà, The Lancet, ti ilẹ̀ Britain ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀, sọ pé, àwọn ilé iṣẹ́ egbòogi kò fẹ́ láti ná iye owó tí ó pọn dandan sórí ṣíṣe egbòogi tuntun jáde, nítorí ọ̀pọ̀ jaburata àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń jẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó túbọ̀ ṣaláìní, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.
Àwọn Olè Tí A Kò Jẹ Níyà
Ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica ròyìn pé, ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ oníṣirò ti 1994, ní Ítálì, “àwọn tí wọ́n bá jalè ní àǹfààní ìpín 94 nínú ọgọ́rùn-ún láti lọ láìjìyà,” àti pé, “àwọn tí wọ́n bá digun jalè ní àǹfààní ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún láti lọ láìjìyà.” Wọ́n rí iye náà fà yọ láti inú ìròyìn tí àwọn aláṣẹ ètò ìdájọ́ rí gbà láti ọwọ́ àwọn agbófinró. Bí a bá fi ọ̀pọ̀ ìjalè tí a kì í fi sun ọlọ́pàá kún un, ìwọ̀n ìpín nínú ọ̀rún ìwà ọ̀daràn tí ń lọ láìjìyà yóò túbọ̀ ga sí i.
Ìrísí Ìdílé Ń Yí Padà ní Ítálì
Ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica ti Ítálì ròyìn pé, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan nípa ìdílé ní Ítálì ṣe fi hàn, púpọ̀ sí i àwọn tí kò ṣègbéyàwó ń gbé pọ̀, púpọ̀ sí i àwọn lọ́kọláya sì ń yapa tàbí ṣèkọ̀sílẹ̀. Lọ́dọọdún, a ń ṣe nǹkan bí 18,000 ìgbéyàwó tí, ó kéré pin, ọ̀kan lára àwọn alábàágbéyàwó náà ń tún ìgbéyàwó ṣe. Àwọn ìsopọ̀ ìgbéyàwó tuntun wọ̀nyí sábà máa ń túmọ̀ sí ìdílé tí a mú gbòòrò, tí ń ní àwọn ọmọ tí a bí nínú ìgbéyàwó ìṣáájú nínú. Ìtẹ̀sí yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú ìbísí nínú iye ìdílé olóbìí kan, ń yára yí ìrísí ìdílé àbáláyé ilẹ̀ Ítálì padà kánmọ́kánmọ́.