Ǹjẹ́ Ẹ̀rù Ọjọ́ Ọ̀la Ń Bà Ọ́?
ONÍRÚURÚ nǹkan ló ń mú kẹ́rù máa bá àwa èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rù máa ń ba àwọn kan nítorí pé wọn ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé yìí lọ́jọ́ iwájú. Ìwé ìròyìn Time ti April 3, 2006 sọ pé: “Àwọn nǹkan bí ìgbì ooru gbígbóná, ìjì líle, omíyalé, iná tó ń jo nǹkan nílé lóko, àti òkìtì yìnyín ńláńlá tó ń yọ́, fi hàn pé gbogbo àyíká wa ti bà jẹ́ gan-an.”
Ní oṣù May ọdún 2002, àjọ Ètò Àbójútó Àyíká ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè gbé ọ̀rọ̀ pàtàkì kan jáde tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ipò Tí Ayé Wà-Apá Kẹta.” Àwọn tó ṣètìlẹyìn fún àjọ yìí tó fi rí ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí kó jọ lé ní ẹgbẹ̀rún kan. Bí ìròyìn kan ṣe sọ, ọ̀rọ̀ pàtàkì tí wọ́n gbé jáde yìí sọ pé: “Pẹ̀lú bí ipò ilé ayé yìí ṣe rí, a gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe nítorí pé àwọn ohun tá à ń ṣe lónìí ń ṣàkóbá tó pọ̀ gan-an fáwọn igbó, òkun, odò, òkè ńláńlá, àwọn ẹranko inú igbó àtàwọn ohun agbẹ́mìíró míì. Bẹ́ẹ̀ láìsí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ilé ayé yìí ò ní ṣeé gbé fún ìran òde òní àti tẹ̀yìnwá ọ̀la.”
Ńṣe ni bíbàjẹ́ tí gbogbo àyíká wa ń bà jẹ́ wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń mú kẹ́rù máa bá àwọn èèyàn. Ọkàn àwọn èèyàn jákèjádò ayé ò balẹ̀ nítorí àwọn apániláyà. Igbákejì ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti orílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Èèyàn kì í lè sùn gbádùn lóru nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń páni láyà téèyàn ò mọ ìgbà àti ọ̀nà tó máa gbà ṣẹlẹ̀.” Àní ìròyìn téèyàn ń gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n pàápàá máa ń kó ìpayà báni!
Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń tẹpá mọ́ṣẹ́ ló ń bẹ̀rù pé kí iṣẹ́ má lọ bọ́ lọ́wọ́ àwọn. Bí wọ́n sì ṣe ń dá àwọn òṣìṣẹ́ dúró lẹ́nu iṣẹ́, táwọn ilé iṣẹ́ ń kógbá wọlé, táwọn òṣìṣẹ́ ń bára wọn díje, táwọn agbanisíṣẹ́ ń fiṣẹ́ pá àwọn òṣìṣẹ́ wọn lórí, ń jẹ́ kẹ́rù máa bá àwọn òṣìṣẹ́ pé ìgbàkigbà niṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn. Ẹ̀rù ń ba àwọn ọ̀dọ́ pàápàá pé àwọn ojúgbà àwọn lè ta àwọn nù. Ó tún lè máa ṣe àwọn ọmọ bíi pé òbí àwọn ò nífẹ̀ẹ́ àwọn dénú. Ipa wo ni ipò tí ayé yìí wà ń ní lórí àwọn ọmọ? Obìnrin kan tọ́kàn rẹ̀ ò balẹ̀, tóun náà ní ọmọ, sọ pé: “Nígbà míì, ẹ̀rù àtijáde sígboro máa ń ba àwọn ọmọ.” Ọ̀pọ̀ àwọn òbí lọkàn wọn ò sì balẹ̀ nítorí ipa tí ìwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn ń hù nínú ayé lè ní lórí àwọn tó jẹ́ èèyàn wọn, àgàgà àwọn ọmọ wọn.
Ẹ̀rù sábà máa ń bá àwọn àgbàlagbà pé káwọn má lọ ṣubú látorí àtẹ̀gùn ilé tàbí pé káwọn èèyànkéèyàn má lọ ṣe àwọ́n léṣe lójú pópó. Bẹ́ẹ̀ ni o, “wọ́n ti fòyà ohun tí ó ga, àwọn ohun ìpayà sì wà ní ọ̀nà.” (Oníwàásù 12:5) Bákan náà, ẹ̀rù àwọn àìsàn líle máa ń bani. Gbígbọ́ tá à ń gbọ́ nípa àrùn jẹjẹrẹ, àrùn gágá tó lè gbẹ̀mí ẹni, àtàwọn àrùn míì tó ń ranni lè mú ká máa bẹ̀rù pé a lè kó àrùn tuntun tàbí àrùn burúkú míì tó lè dá wa gúnlẹ̀ tàbí tó lè gbẹ̀mí àwa àti ìdílé wa. Táwọn tára wọn jí pépé bá ṣàìsàn tí wọ́n sì di aláìlera, ẹ̀rù lè máa bà wá pé kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ má lọ ṣẹlẹ̀ sí àwa tàbí àwọn èèyàn wa. Ó sì máa ń dunni gan-an nígbà téèyàn bá rí i lójú aláìsàn kan pé kò nírètí kankan.
Bó ṣe jẹ́ pé onírúurú nǹkan ló ń mú kẹ́rù máa bá àwa èèyàn, ǹjẹ́ ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà tá a fi lè ní ìrètí pé nǹkan máa dáa lọ́jọ́ ọ̀la? Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tó lè mú ká nírètí pé ọjọ́ ọ̀la máa dáa? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
© Jeroen Oerlemans/Panos Pictures