ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ìrékọjá?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fáwọn Júù láti má ṣe jẹ “ohunkóhun tí ó ní ìwúkàrà” nígbà ìrékọjá, kí nìdí tí Jésù fi lo wáìnì nígbà tó dá Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé èròjà tó máa ń mú kí àkàrà wú wà nínú wáìnì?—Ẹ́kísódù 12:20; Lúùkù 22:7, 8, 14-20.

Ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jèhófà dá àjọ̀dún Ìrékọjá sílẹ̀, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń ṣèrántí Ìjádelọ wọn kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Nígbà tí Jèhófà ń sọ bí wọ́n ṣe máa ṣe é, ó ní: “Ẹ má jẹ ohunkóhun tí ó ní ìwúkàrà. Ní gbogbo ibùgbé yín, àkàrà aláìwú ni kí ẹ jẹ.” (Ẹ́kísódù 12:11, 20) Irú búrẹ́dì tí wọ́n máa jẹ lákòókò àjọ̀dún Ìrékọjá nìkan ni Ọlọ́run sọ. Kò sọ̀rọ̀ nípa wáìnì.

Olórí ìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ lo ìwúkàrà ni pé, ńṣe ni wọ́n kánjú jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Ẹ́kísódù 12:34 sọ pé: “Àwọn ènìyàn náà gbé ìyẹ̀fun àpòrọ́ wọn kí ó tó di wíwú, pẹ̀lú ọpọ́n ìpo-nǹkan wọn tí wọ́n fi aṣọ àlàbora wé sórí èjìká wọn.” Bó ṣe jẹ́ pé wọn kì í lo ìwúkàrà lákòókò àjọ̀dún Ìrékọjá tí wọ́n ń ṣe lẹ́yìn náà, èyí rán àwọn àtọmọdọ́mọ wọn létí pé ńṣe ni wọ́n kánjú jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì.

Nígbà tó yá, àwọn èèyàn sábà máa ń ka ìwúkàrà sóhun tó dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìdíbàjẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó jẹ́ oníṣekúṣe nínú ìjọ Kristẹni, ó béèrè pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìṣùpọ̀ di wíwú?” Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: “Ẹ mú ògbólógbòó ìwúkàrà kúrò, kí ẹ lè jẹ́ ìṣùpọ̀ tuntun, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ aláìní amóhunwú. Nítorí, ní tòótọ́, a ti fi Kristi ìrékọjá wa rúbọ. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a pa àjọyọ̀ mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ògbólógbòó ìwúkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà aláìwú ti òtítọ́ inú àti òtítọ́.” (1 Kọ́ríńtì 5:6-8) Àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú nìkan la lè lò láti ṣàpẹẹrẹ ẹran ara Jésù tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.—Hébérù 7:26.

Nígbà tó yá, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í lo wáìnì lákòókò Ìrékọjá. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí wọ́n padà dé láti ìgbèkùn nílẹ̀ Bábílónì ni wọ́n fi èyí kún un. Kò sí àkọsílẹ̀ kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé Ọlọ́run ta ko ohun tí wọ́n ṣe yìí, ìdí nìyẹn tí kò fi burú pé Jésù lo wáìnì nígbà oúnjẹ Ìrékọjá. Wọ́n ní láti fi ohun amú-nǹkan-wú sínú ìyẹ̀fun tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì kó tó lè wú. Àmọ́, wáìnì ayé ọjọ́un kò nílò kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ fi èròjà yìí sí i kó tó di pé ó le. Wáìnì tó wá látinú èso àjàrà kò nílò irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan tó máa ń mú wáìnì le ti wà nínú èso àjàrà fúnra rẹ̀. Kò lè sí omi àjàrà tí kò tíì di ọtí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe Ìrékọjá, torí pé kò sọ́gbọ́n tí kò fi ní le sí i látìgbà tí wọ́n bá ti kórè rẹ̀ nígbà ìwọ́wé títí dìgbà tí wọ́n máa ń ṣe Ìrékọjá nígbà ìrúwé.

Nítorí náà, lílò tí Jésù lo wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ lákòókò Ìrántí ikú rẹ̀ kò ta ko ìtọ́ni Ọlọ́run lọ́nàkọnà pé wọn ò gbọ́dọ̀ lo ìwúkàrà nígbà Ìrékọjá. A lè lo wáìnì pupa èyíkéyìí gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń ṣàpẹẹrẹ “ẹ̀jẹ̀ iyebíye” Kristi, tí kò bá ti ní ohun amú-nǹkan-dùn nínú tàbí ohun tó máa mú kó túbọ̀ le sí i.—1 Pétérù 1:19.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́