‘Wọ́n Ń gbèrú Nígbà Orí Ewú’
Ọ̀PỌ̀ àwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó wà lágbègbè Òkun Mẹditaréníà ló ń gbin ọ̀pẹ déètì sí àgbàlá wọn. Igi ẹlẹ́wà ni ọ̀pẹ déètì yìí jẹ́, èso rẹ̀ sì máa ń dùn gan-an ni. Yàtọ̀ síyẹn, ó rọ́kú, ó sì máa ń so èso fún èyí tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ.
Láyé ọjọ́un, Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì fi ọ̀rọ̀ ewì ṣàpèjúwe ìrísí ọmọbìnrin Ṣúlámáítì arẹwà pé ó dá bí igi ọ̀pẹ. (Orin Sólómọ́nì 7:7) Ìwé náà, Plants of the Bible [Àwọn Igi Tí Bíbélì Mẹ́nu Kàn], sọ pé: “Ohun tí wọ́n ń pe igi ọ̀pẹ lédè Hébérù ni ‘tàmâr.‘ . . . Àwọn Júù sì wá ń lò ó láti fi ṣàpèjúwe ohun tó nìyí tàbí tó lẹ́wà, wọ́n sì tún fi ń sọ ọmọbìnrin lórúkọ.” Bí àpẹẹrẹ, Támárì lorúkọ arẹwà obìnrin kan tó jẹ́ ọbàkan Sólómọ́nì. (2 Sámúẹ́lì 13:1) Àwọn òbí kan tiẹ̀ ṣì ń sọ ọmọbìnrin wọn ní Támárì lóde òní.
Àmọ́, àwọn arẹwà obìnrin nìkan kọ́ ni wọ́n fi ń wé igi ọ̀pẹ o. Onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Olódodo yóò yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ; gẹ́gẹ́ bí kédárì ní Lẹ́bánónì, òun yóò di ńlá. Àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà, nínú àwọn àgbàlá Ọlọ́run wa, wọn yóò yọ ìtànná. Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú, wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀.”—Sáàmù 92:12-14.
Ọ̀pọ̀ ọ̀nà làwọn tó ti dàgbà àmọ́ ti wọ́n ṣì ń fi ìṣòtítọ́ bá ìjọsìn Ọlọ́run nìṣó fi dà bí igi ọ̀pẹ ẹlẹ́wà yìí. Bíbélì ní: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Lóòótọ́, ara wọn lè má fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán mọ́ nítorí pé àgbà ti dé, síbẹ̀ wọ́n ṣì lè jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí bí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń fúnni lókun àti agbára. (Sáàmù 1:1-3; Jeremáyà 17:7, 8) Ọ̀rọ̀ alárinrin tó máa ń tẹnu àwọn àgbà jáde àti àpẹẹrẹ àtàtà tí wọ́n jẹ́ máa ń fún àwọn èèyàn níṣìírí gan-an, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ méso jáde látọdún dé ọdún. (Títù 2:2-5; Hébérù 13:15, 16) Dájúdájú, àwọn àgbàlagbà lè máa méso jáde bí igi ọ̀pẹ lọ́jọ́ ogbó wọn.