ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/15 ojú ìwé 8-11
  • Àwọn Ìṣòro Tá À Ń Borí Kí Ìhìn Rere Tó Lè Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìṣòro Tá À Ń Borí Kí Ìhìn Rere Tó Lè Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Onírúurú Orílẹ̀-Èdè Pawọ́ Pọ̀ Láti Pèsè Oúnjẹ Tẹ̀mí
  • Irú Ìrìn Àjò Kan Bẹ́ẹ̀ Tá A Lọ
  • Àwọn Ìrírí Tó Dùn Mọ́ni
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/15 ojú ìwé 8-11

Àwọn Ìṣòro Tá À Ń Borí Kí Ìhìn Rere Tó Lè Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn

BÍ ỌKỌ̀ akẹ́rù wa ṣe ń lọ, a rí ibi táwọn sójà ti ń yẹ àwọn ọkọ̀ tó ń kọjá lọ kọjá bọ̀ wò lọ́ọ̀ọ́kán. Nǹkan bí ọgọ́ta sójà ló wà ńbẹ̀. Ọkùnrin wà lára wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni obìnrin àtàwọn ọmọ tí ò tíì pé ogún ọdún. Àwọn kan nínú wọn wọṣọ ológun, àwọn kan ò sì wọ̀. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló gbé ìbọn arọ̀jò-ọta dání. Ó dà bíi pé àwa ni wọ́n ń dúró dè. Wọ́n ń jagun abẹ́lé lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè náà.

Ọjọ́ mẹ́rin la ti lò lójú ọ̀nà, àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tá a sì kó wúwo tó igba [200] àpò sìmẹ́ǹtì. Bá a ṣe rí wọn, a ń ronú pé ṣé wọ́n á jẹ́ ká kọjá báyìí? Ṣé wọn ò ní sọ pé ká fáwọn lówó? Kí la máa sọ tí wọn á fi tètè gbà pé èèyàn àlàáfíà ni wá?

Ọkùnrin kan lára àwọn sójà náà tí ìbọn yínyìn ń gùn yìnbọn sókè ká lè mọ̀ pé òun lọ̀gá. Nígbà tó tajú kán rí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká wa, ó ní ká kó o fóun. Nígbà tá ò tètè dá a lóhùn, ó fọwọ́ ṣàpèjúwe bí ẹni ń dúńbú ara rẹ̀ láti fi hàn pé pípa lòún á pa wá tá ò bá ṣe ohun tóun sọ. La bá kó o fún un.

Lójijì, obìnrin kan tó wọṣọ ológun gbé ìbọn rẹ̀ ó sì wá bá wa. Òun ni wọ́n ń pè ní akọ̀wé wọn. Ìlú le gan-an, ó fẹ́ ká wá nǹkan kan fóun náà bó ti wù kó kéré mọ. Lẹ́yìn náà, sójà míì ṣí ilé epo ọkọ̀ wa ó sì rọ́ epo kúnnú gálọ́ọ̀nù rẹ̀. Nígbà tá à ń sọ fún un pé kò yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní iṣẹ́ tí wọ́n rán òun lòún ń jẹ́. Ńṣe la kàn ń wò ó, kò sí nǹkan tá a lè ṣe. Ohun tá a kàn ń gbà ládùúrà ni pé káwọn tó kù má sọ pé àwọn náà fẹ́ rọ epo.

Níkẹyìn, wọ́n jẹ́ ká kọjá, a sì ń bá ìrìn àjò wa lọ. Ìgbà tá a kúrò lọ́dọ̀ wọn lọkàn èmi àtẹnì kejì mi tó balẹ̀. Kò rọrùn láti kọjá láwọn ibi tí wọ́n ti máa ń yẹ ọkọ̀ wò bẹ́ẹ̀, nítorí ńṣe ló máa ń kóni lọ́kàn sókè, àmọ́ kò ṣàjèjì sí wa mọ́. Láàárín oṣù April ọdún 2002 sí oṣù January ọdún 2004, ìgbà méjìdínlógún la ti rìnrìn àjò láti èbúté ìlú Douala tó wà ní Kamẹrúùnù lọ sí Bangui, tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè Central African Republic. Ìrìn àjò ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà yẹn máa ń kún fún ewu àtàwọn ohun tó ń yani lẹ́nu.a

Joseph àti Emmanuel tí wọ́n máa ń wakọ̀ lọ síbẹ̀ déédéé sọ pé àwọn ìrìn àjò náà ti kọ́ àwọn lọ́pọ̀ ẹ̀kọ́. Wọ́n ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń rí i pé ohun tó dáa ni pé ká gbàdúrà sínú, ká wá fọkàn balẹ̀. Onísáàmù sọ pé: ‘Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, àyà kì yóò fò mí. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?’ Irú èrò yẹn làwa náà máa ń gbìyànjú láti ní. Ó dá wa lójú pé Jèhófà mọ̀ pé ìdí tá a fi ń rìnrìn àjò ni ká lè mú ìhìn tó ń fúnni nírètí táwọn èèyàn nílò gan-an lọ fún wọn.”—Sáàmù 56:11.

Onírúurú Orílẹ̀-Èdè Pawọ́ Pọ̀ Láti Pèsè Oúnjẹ Tẹ̀mí

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà lápá ibí tá à ń sọ yìí nílẹ̀ Áfíríkà máa ń fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kí wọ́n bàa lè rí oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n nílò la ṣe ń kó àwọn ìwé wọ̀nyí lọ fún wọn. (Mátíù 5:3; 24:14) Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù, tó wà nílùú Douala máa ń kówèé ránṣẹ́ sáwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó lé ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] àtàwọn míì tó nífẹ̀ẹ́ sí i ní Kamẹrúùnù àti orílẹ̀-èdè mẹ́rin míì tó wà nítòsí rẹ̀.

Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti ń kó àwọn ìwé náà wá sí Kamẹrúùnù. Orílẹ̀-èdè England, Finland, Jámánì, Ítálì àti Sípéènì ni wọ́n sì ti máa ń tẹ èyí tó pọ̀ jù lára wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n bá tẹ̀ ẹ́ tán, wọ́n á wá fi ọkọ̀ òkun kó o wá láti orílẹ̀-èdè Faransé. Àpótí ràgàjì tí wọ́n fi ń kẹ́rù ránṣẹ́ ni wọ́n fi máa ń kó àwọn ìwé náà wá, ó sì sábà máa ń dé sí èbúté tó wà ní Douala lọ́sẹ̀ méjì méjì.

Wọ́n á wá gbé àpótí ràgàjì náà sẹ́yìn ọkọ̀ akẹ́rù, wọ́n á sì gbé e lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Kamẹrúùnù. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́ níbẹ̀ á wá yọ àwọn ìwé náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ láti fi wọ́n ránṣẹ́ síbi tó yẹ. Kì í ṣe nǹkan tó rọrùn láti kó àwọn ìwé náà lọ síbi tó jìn gan-an láwọn orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ ìyẹn jẹ́ ara iṣẹ́ mímú ìhìn rere náà lọ sí “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tọkàntọkàn ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ń lò láti máa fi ọkọ̀ akẹ́rù kó àwọn ìwé náà lọ síbẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrìn àjò tí kò rọrùn ni. Báyìí ni àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ṣe ń tẹ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́wọ́ déédéé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Áfíríkà.

Irú Ìrìn Àjò Kan Bẹ́ẹ̀ Tá A Lọ

Ọkọ̀ akẹ́rù la fi máa ń kówèé lọ sí Kamẹrúùnù, Chad, Equatorial Guinea, Gabon àti Central African Republic. Jẹ́ ká bá àwọn tó máa ń kó ìwé náà lọ rìnrìn àjò ná. Fojú inú wò ó pé ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ awakọ̀, ẹ sì ti múra tán láti rìnrìn àjò tí kò ní rọrùn, tó máa gba ọjọ́ mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Awakọ̀ mẹ́fà ló máa ń para pọ̀ rìnrìn àjò yìí. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ní ìmí tó sì dáńgájíá. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tó ní sùúrù kí wọ́n sì múra lọ́nà tó buyì kúnni. Àwọn kan lára wọn máa ń wọ aṣọ ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn míì sì máa ń wọ ṣẹ́ẹ̀tì, wọ́n á wá fi táì lé e. Láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, táwọn aṣọ́bodè bá rí àwọn awakọ̀ náà, wọ́n máa ń sọ pé: “Ẹ wo bí ọkọ̀ ṣe mọ́ tó, ẹ tún wo báwọn awakọ̀ ṣe múra dáadáa. Kò yàtọ̀ sí àwòrán tá a máa ń rí nínú ìwé wọn.” Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì ju ìrísí àwọn awakọ̀ náà lọ ni bí wọ́n ṣe múra tán láti kó ẹrù lọ síbikíbi táwọn èèyàn ti nílò wọn.—Sáàmù 110:3.

Nǹkan bí aago mẹ́fà àárọ̀ la gbéra ní ìlú Douala ká má bàa kó sínú sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ nílùú tó ń yára fẹ̀ sí i yẹn. Lẹ́yìn tá a gba orí afárá tó wà nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọjá tá a sì ti kúrò ní Douala, a dorí kọ apá ìlà oòrùn láti lọ síbi tá a kọ́kọ́ fẹ́ jáwèé sí, ìyẹn Yaoundé tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.

Gbogbo àwọn awakọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà ló máa sọ fún ẹ bó ṣe máa ń ṣòro tó láti wa ọkọ̀ tó kó ìwé tó wúwo tó igba [200] àpò sìmẹ́ǹtì. Wọ́n ń bá ìrírí wọn lọ, wọ́n ní, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìṣòro ní ọjọ́ mẹ́ta tá a kọ́kọ́ wakọ̀ lórí títì ọlọ́dà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní láti wà lójú fò ká sì pọkàn pọ̀ dáadáa. Àmọ́ lójijì la kan òjò ńlá kan, ibẹ̀ sì ni ọ̀nà eléruku ti bẹ̀rẹ̀. A ò rọ́ọ̀ọ́kán dáadáa, ọ̀nà yẹn ń yọ̀, a ò sì lè sáré torí ọ̀nà tó rí gbágungbàgun. Nígbà tọ́jọ́ pofírí, a dúró láti wá nǹkan síkùn. Lẹ́yìn náà, a kásẹ̀ síwájú ọkọ̀, a sì sùn síbi tá a jókòó sí nínú ọkọ̀ náà. Bó ṣe máa ń rí tá a bá lọ ìrìn àjò yìí nìyẹn o!

Ilẹ̀ mọ́ tàìmọ́, a tún mú ìrìn àjò wa pọ̀n. Ẹnì kan lára wa ń fara balẹ̀ ṣàkíyèsí bí ọ̀nà náà ṣe rí. Ojú ẹsẹ̀ ló máa ń sọ fún wa tó bá rí i pé a ti ń sún mọ́ kòtò ẹ̀gbẹ́ títì. A mọ̀ pé tí ọkọ̀ náà bá kó sí kòtò, ó lè gba ọjọ́ mélòó kan ká tó lè yọ ọ́. Nígbà tó yá, a dé orílẹ̀-èdè Central African Republic. Ọ̀nà tó wà ńbẹ̀ náà ò sí dáa tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ẹgbẹ̀ta ó lé àádọ́ta kìlómítà [650] tá a rìn tẹ̀ lé e, a kọjá láwọn ìgbèríko tí ewéko ibẹ̀ tutù yọ̀yọ̀ tó sì jẹ́ ilẹ̀ olókè. Bí ọkọ̀ wa ṣe ń rọra gba àwọn abúlé tó wà níbẹ̀ kọjá, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọdé, àwọn àgbàlagbà àtàwọn obìnrin tó pọnmọ ń juwọ́ sí wa. Ọkọ̀ tó wà lójú títì ò pọ̀ nítorí ogun abẹ́lé tó ń lọ lọwọ́. Nítorí náà, ńṣe làwọn èèyàn máa ń dájú bò wá bá a ṣe ń kọjá.

Àwọn Ìrírí Tó Dùn Mọ́ni

Ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ wa tó ń jẹ́ Janvier sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan táwọn ní í ṣe pọ̀, àwọn sábà máa ń dúró láwọn abúlé láti sinmi díẹ̀ káwọn sì fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Ó ní: “Gbogbo ìgbà tá a bá ti dé abúlé Baboua la máa ń gbìyànjú láti bá òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn kan tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀, a sì máa ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì díẹ̀. Ẹni tá à ń wí yìí nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń kéde gan-an ni. Kódà lọ́jọ́ kan, a ṣètò pé kí òun àti ìdílé rẹ̀ wo fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa Nóà. Àwọn ọ̀rẹ́ wọn àtàwọn aládùúgbò wọn pẹ̀lú wá, ká sì tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, àwọn òǹwòran ti kún ilé náà fọ́fọ́, tínú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń wo fídíò náà. Gbogbo wọn ló ti gbọ́ ìtàn Nóà rí, àmọ́ nígbà tí wọ́n wo fídíò yìí, ìtàn yẹn wá yé wọn sí i. Inú wa dùn gan-an ni pé wọ́n mọrírì fídíò náà tó bẹ́ẹ̀. Nígbà tí wọ́n wò ó tán, wọ́n gbọ́únjẹ olóyinmọmọ fún wa láti fìmoore hàn, wọ́n sì sọ pé ká sùn mọ́jú. A ò dúró ṣá o, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la kúrò ńbẹ̀ torí ibi tá à ń lọ ṣì jìn. Àmọ́ inú wa dùn pé a kéde ìhìn rere fún wọn.”

Awakọ̀ míì tó ń jẹ́ Israel rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí wọ́n tún ń lọ sílùú Bangui. Ó ní: “Bá a ṣe ń sún mọ́ Bangui sí i, bẹ́ẹ̀ làwọn ibi táwọn sójà ti gbégi dínà ń pọ̀ sí i. Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ lára wọn ò lejú mọ́ wa, wọ́n sì rántí pé àwọn ti máa ń rí ọkọ̀ wa. Wọ́n ní ká wá jókòó, inú wọn sì dùn nígbà tá a fún wọn láwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Ìwé jọ wọ́n lójú gan-an ni, ńṣe ni wọ́n máa ń kọ orúkọ wọn àtorúkọ ẹni tó fún wọn sí i, àtọjọ́ tó fún wọn. Ìdí mìíràn táwọn kan lára àwọn sójà náà ò fi lejú mọ́ wa ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ìbátan wọn kan.”

Joseph tó jẹ́ awakọ̀ tó ti pẹ́ jù lẹ́nu iṣẹ́ ọkọ̀ wíwà ka ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dé ibi tí wọ́n ń lọ gan-an sí apá tó gbádùn mọ́ni jù nínú ìrìn àjò náà. Ó sọ nípa ìgbà kan tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ, ó ní: “Nígbà tó ku kìlómítà mélòó kan ká dé ìlú Bangui, a pe àwọn ará lórí tẹlifóònù pé a ti fẹ́ẹ̀ dé o. Nígbà tá a dé Bangui, ńṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé wa kiri ìlú náà bá a ṣe ń gba àwọn ìwé àṣẹ tó yẹ ká gbà. Nígbà tá a débẹ̀, gbogbo àwọn tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ló jáde wá kí wa tí wọ́n sì dì mọ́ wa. Àwọn ará látàwọn ìjọ tó wà nítòsí wá ràn wá lọ́wọ́. Láàárín wákàtí mélòó kan, a já òbítíbitì páálí tí Bíbélì, ìwé, ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ìròyìn wà nínú rẹ̀ tán, a sì tò wọ́n sí ibi tá à ń já ìwé sí.”

Joseph ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà míì, a tún máa ń kó bàtà, aṣọ àtàwọn nǹkan ọmọdé táwọn ará fún àwọn ará wa tó wà lórílẹ̀-èdè olómìnira ti Kóńgò. Inú wa máa ń dùn gan-an ni nígbà tá a bá rí àwọn ará tó ní ìmọrírì yìí bí wọ́n ṣe ń rẹ́rìn-ín músẹ́ nígbà tá a bá kó o fún wọn!”

A sinmi fún ọjọ́ kan. Lẹ́yìn náà, a ṣe àwọn ohun tó yẹ lára ọkọ̀ wa, a sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa padà sílé. A mọ̀ pé ìrìn àjò yẹn ò ní rọrùn, àmọ́ ìrírí gbígbádùnmọ́ni tá a ní ta yọ ìṣòro yòówù ká ní lójú ọ̀nà.

Ọ̀nà tó jìn gan-an, òjò ńlá, ọ̀nà gbágungbàgun, táyà tó máa ń jò tàbí kí ọkọ̀ bà jẹ́, àwọn nǹkan wọ̀nyí lè fẹ́ fi ìrìn àjò náà sú àwọn awakọ̀ náà. Ìgbà gbogbo làwọn ẹhànnà sójà máa ń mú kí nǹkan ṣòro fún wọn. Síbẹ̀, kò sóhun tó ń fún wọn láyọ̀ tó àǹfààní tí wọ́n ní láti máa mú ìhìn rere lọ sáwọn ibi jíjìnnà réré ní Áfíríkà àti bí wọ́n ṣe ń rí i tó ń tún ayé àwọn tó ń gbà á ṣe.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìwé tí wọ́n máa ń kó lọ yìí ló mú kí ará abúlé kan tọ́nà rẹ̀ jìn gan-an ní Central African Republic nítòsí orílẹ̀-èdè Sudan lè máa ka Bíbélì lédè rẹ̀. Ìyàwó rẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, àwọn ọmọ wọn sì ń jàǹfààní ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.b Àwọn ìdílé yìí àti ọ̀pọ̀ àwọn míì láwọn ìgbèríko yẹn ń rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà déédéé, bíi tàwọn ará wọn tó wà láwọn ìlú ńláńlá. Ẹ ò rí i pé nǹkan ayọ̀ ni!

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní báyìí, ìjọba orílẹ̀ èdè méjèèjì yìí ti rí sí i pé ààbò túbọ̀ wà lójú ọ̀nà Douala sí Bangui.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

KAMẸRÚÙNÙ

Douala

CENTRAL AFRICAN REPUBLIC

Bangui

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Joseph

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Emmanuel

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Central African Republic, tó wà nílùú Bangui

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Wọ́n ń já ìwé nínú ọkọ̀ akẹ́rù nílùú Bangui

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́