ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/15 ojú ìwé 32
  • “Ó Wú Mi Lórí Gan-an Ni Bó Ṣe Dúró Gbọn-in Gbọn-in”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ó Wú Mi Lórí Gan-an Ni Bó Ṣe Dúró Gbọn-in Gbọn-in”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/15 ojú ìwé 32

“Ó Wú Mi Lórí Gan-an Ni Bó Ṣe Dúró Gbọn-in Gbọn-in”

ÒǸKỌ̀WÉ náà Günter Grass, ọmọ ilẹ̀ Jámánì tó gba Ẹ̀bùn Ẹ̀yẹ Nobel lórí ìwé kíkọ lọ́dún 1999, tẹ ìwé ìtàn ìgbésí ayé ẹ̀ jáde lọ́dún 2006. Nínú ìwé náà, ó sọ nípa bí ìjọba ṣe sọ òun di ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ kan ní ilẹ̀ Jámánì. Òǹkọ̀wé yìí sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan nínú ìwé náà pé ó ṣe ohun tó wú òun lórí gan-an tóun ò yéé rántí àní lóhun tó lé ní ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn ìgbà náà. Ọkùnrin tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí dá wà ni o láìsí onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ nítòsí, síbẹ̀ kò jẹ́ kí inúnibíni mi ìgbàgbọ́ òun rárá.

Ìgbà kan wà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá Grass lẹ́nu wò, tí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde nínú ìwé ìròyìn tó ń jẹ́ Frankfurter Allgemeine Zeitung. Nígbà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà, ó sọ̀tàn ọkùnrin àrà ọ̀tọ̀ yìí tó sọ pé ó kọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun. Òǹkọ̀wé Grass ní ọkùnrin yìí “ò fara mọ́ èyíkéyìí nínú ètò ìṣèlú tó wà láwùjọ, yálà ti Násì, ti Kọ́múníìsì, tàbí ti Ìjọba Àjùmọ̀ní. Ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.” Òǹkọ̀wé Grass ò rántí orúkọ Ẹlẹ́rìí yìí, ó sáà pè é ní ọ̀gbẹ́ni A-kì-í-ṣerú-nǹkan-bẹ́ẹ̀. Àmọ́, àwọn tó ń ṣèwádìí nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé Joachim Alfermann lorúkọ ọkùnrin náà. Àìmọye ìgbà ni wọ́n lu Alfermann yìí bí ẹni lu bàrà, tí wọ́n sì hàn án léèmọ̀, kí wọ́n tó wá fi í sí àhámọ́ aládàáwà. Síbẹ̀, Alfermann ò yẹhùn rárá. Ó kọ̀ jálẹ̀ láti gbé ohun ìjà ogun.

Òǹkọ̀wé Grass ní: “Ó wú mi lórí gan-an ni bó ṣe dúró gbọn-in gbọn-in. Mo bi ara mi pé: Báwo lọkùnrin yìí ṣe ń lè fara da gbogbo ẹ̀? Ọgbọ́n wo ló ń ta sí i?” Nígbà tí wọ́n sa gbogbo ipá wọn títí lórí Alfermann, síbẹ̀ tí ò jẹ́ kí mìmì kan mi ìdúróṣinṣin òun sí Ọlọ́run, wọ́n gbé e lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Stutthof lóṣù February ọdún 1944. Ní April ọdún 1945, àwọn kan dá Alfermann sílẹ̀, bí kò ṣe bógun yẹn lọ nìyẹn. Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó dúró ṣinṣin ló jẹ́ títí tó fi kú lọ́dún 1998.

Alfermann jẹ́ ọ̀kan péré lára nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá ó lé irínwó [13,400] Ẹlẹ́rìí tí wọ́n hàn léèmọ̀ gan-an nítorí ìgbàgbọ́ wọn nílẹ̀ Jámánì àtàwọn orílẹ̀-èdè tí ìjọba Násì gbógun jà. Bẹ́ẹ̀, àṣẹ tí Bíbélì pa ni wọ́n tẹ̀ lé tí wọ́n kò fi dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú, tí wọ́n sì kọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun. (Mátíù 26:52; Jòhánù 18:36) Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé igba [4,200] Ẹlẹ́rìí ni wọ́n kó lọ sí onírúurú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ó dín mẹ́wàá [1,490] lára wọn ló sì kú. Dòní olónìí, dídúró tí wọ́n dúró ṣinṣin lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ṣì ń wú ọ̀pọ̀ èèyàn tó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí gan-an.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Joachim Alfermann

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́