A Bá A Yọ̀ Pé Ó “Jagun Mólú Pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà”
NÍNÚ lẹ́tà kan tí Arákùnrin Carey W. Barber kọ lọ́dún 1971, ó sọ nípa àádọ́ta ọdún àkọ́kọ́ tóun fi sin Ọlọ́run tòótọ́ náà. Ó ní: “Mo gbádùn àwọn ọdún tí mo ti fi sin Jèhófà dáadáa. Ohun tó sì jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ ni ìfararora tí mo ní pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run, ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi tó wà nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí, ìrètí tí mo ní láti jagun mólú pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi àti ẹ̀rí tí mò ń rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ń fún mi ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìdùnnú, èyí tó ń dáàbò bo ọkàn mi tó sì jẹ́ kí n ní ìrètí tó dájú, pé màá jagun mólú níkẹyìn.”
Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, Arákùnrin Barber, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró, di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Fún ọgbọ̀n ọdún tí Arákùnrin Barber fi sìn gẹ́gẹ́ bí ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ó retí ìgbà tó máa “jagun mólú pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Ohun tó mú kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ ohun tó fojú sọ́nà fún yìí ni jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ títí dìgbà tó kú ní ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún [101] ní Sunday, April 8, 2007.—1 Kọ́ríńtì 15:57.
Ọdún 1905 ni wọ́n bí Arákùnrin Carey Barber ní orílẹ̀-èdè England, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1921 nílùú Winnipeg lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ọdún méjì lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, wọ́n pe òun àti arákùnrin Norman tí wọ́n jọ jẹ́ ìbejì lọ sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York láti ṣèrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tuntun kan. Àkókò yẹn làwọn èèyàn Jèhófà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé wọn jáde fúnra wọn, èyí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìnrere Ìjọba náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Ẹ̀ka ìtẹ̀wé ni Arákùnrin Barber ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ nígbà tó dé Bẹ́tẹ́lì. Lára àwọn ìwé tó ń tẹ̀ nígbà yẹn ni àkọsílẹ̀ ṣókí táwọn agbẹjọ́rò máa ń lò nígbà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá gbẹ́jọ́ lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tó yá, Arákùnrin Barber ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, níbi tó ti ń bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọ àti iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè náà.
Àwọn ohun tí Arákùnrin Barber ti ṣe sẹ́yìn yẹn mú kó dẹni tó kúnjú ìwọ̀n dáadáa fún iṣẹ́ ìsìn. Nígbà tó sì di ọdún 1948, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò. Ó máa ń bẹ àwọn àpéjọ àtàwọn ìjọ wò káàkiri gbogbo apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó sọ pé òun máa ń gbádùn jíjáde lọ wàásù gan-an. Ìbẹ̀wò tí Arákùnrin Barber ń ṣe yìí mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará mọ̀ ọ́n. Ó jẹ́ ẹni tí nǹkan máa ń tètè yé, ó tún nítara fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, èyí sì ràn án lọ́wọ́ nígbà tó lọ sí kíláàsì kẹrìndínlọ́gbọ̀n ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ilé ẹ̀kọ́ yẹn ni òun àti Arábìnrin Sydney Lee Brewer, akẹ́kọ̀ọ́ kan tó wá láti Kánádà, ti mọra. Lẹ́yìn ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wọn, wọ́n ṣègbéyàwó, wọ́n sì gbádùn ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì wọn nígbà ìrìn àjò wọn lọ sí Chicago ní ìpínlẹ̀ Illinois, níbi tí wọ́n á ti máa bẹ àwọn ìjọ wò. Alábàákẹ́gbẹ́ tó wúlò gan-an ni Arábìnrin Barber, ó ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn gan-an fún ogún ọdún tí wọ́n fi jùmọ̀ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn àjò.
Àwọn tó mọ Arákùnrin Barber nígbà tó jẹ́ alábòójútó àgbègbè, alábòójútó àyíká tàbí láàárín ọgbọ̀n ọdún tó fi ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó sì máa ń rìnrìn-àjò káàkiri kò ní gbàgbé àwọn àsọyé tó máa ń sọ àtàwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó máa ń tani jí. A bá a yọ̀ pé ó “jagun mólú pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”