ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 12/15 ojú ìwé 23-25
  • Ẹ Máa Wo Ọ̀ràn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Wò Ó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Wo Ọ̀ràn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Wò Ó
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Máa Wo Ọ̀ràn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Wò Ó
  • Àmọ̀ràn Tó Gbéṣẹ́ Nípa Wíwo Ọ̀ràn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Wò Ó
  • Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí Ìjọba Náà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ̀mí Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Ló Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Wá sí Gílíádì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà Kí Ẹ Sì Kún fún Ìdùnnú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìfẹ́ Sún Wọn Láti Ṣiṣẹ́ Sìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 12/15 ojú ìwé 23-25

Ẹ Máa Wo Ọ̀ràn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Wò Ó

ỌJỌ́ tó móoru tí oòrùn sì mú ganrín-ganrín ni September 14, 2002, nílùú New York, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, àwọn èrò ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti ogún ó lé kan [6,521], ló pé jọ sí Ibùdó Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Patterson àti ibi méjì mìíràn tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú náà. Àwọn èrò yìí wá síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kẹtàléláàádọ́fà ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti wá, wọ́n sì ti fi odindi oṣù márùn-ún gbára dì fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlógún tá a yàn wọ́n sí.

Carey Barber, tó ti lé lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún tó sì jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló ṣalága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ó sọ pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta ọdún báyìí tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti bẹ̀rẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló sì ti gbabẹ̀ lọ sẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Arákùnrin Barber sọ pé: “Àsọdùn kọ́ tá a bá sọ pé àbájáde ńláǹlà ló ti tinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn jáde. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọlọ́kàn tútù ló ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn mímọ́ àti iṣẹ́ ìsìn mímọ́ rẹ̀ nítorí ìrànlọ́wọ́ táwọn míṣọ́nnárì tá a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ fún wọn.”

Kí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tó wá sí Gílíádì ni wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ sí mímú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Ó lé ní ọdún kan tí tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà fi kọ́ èdè Chinese kí wọ́n lè mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ China àmọ́ tí wọ́n ń gbé ní Kánádà. Tọkọtaya mìíràn fúnra wọn kọ́ èdè Albania, wọ́n sì wá ṣí lọ sí ilẹ̀ Albania láti lọ bójú tó iye èèyàn púpọ̀ sí i tó ń fìfẹ́ hàn sí Bíbélì níbẹ̀. Àwọn mìíràn ní kíláàsì náà wá láti Hungary, Guatemala àti Dominican Republic, ìyẹn ni àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ ń gbé nítorí ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n nílò níbẹ̀.

Kó tó di pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ sáwọn ibi tá a ti yanṣẹ́ fún wọn ní Áfíríkà, Ìlà Oòrùn Yúróòpù, Àárín Gbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà àti Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Éṣíà, a rọ gbogbo wọn láti máa ro ti Ọlọ́run nínú ohun gbogbo tí wọ́n bá ń ṣe.

Ẹ Máa Wo Ọ̀ràn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Wò Ó

Lẹ́yìn tí Arákùnrin Barber parí ọ̀rọ̀ tó fi ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó ké sí Maxwell Lloyd, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ pé “Ẹ Máa Wo Ọ̀ràn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Wò Ó.” Arákùnrin Lloyd mẹ́nu kan àpẹẹrẹ Dáfídì àti ti Ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn Jésù. (1 Sámúẹ́lì 24:6; 26:11; Lúùkù 22:42) Lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ náà ti rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí létí pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ti fi odidi oṣù márùn-ún gbáko kọ́ ti fún wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa wíwo ọ̀ràn lọ́nà tí Ọlọ́run gbà ń wò ó, ó wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Tẹ́ ẹ bá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn níbi tá a ti ṣẹ̀ṣẹ̀ yanṣẹ́ fún yín, ṣé ẹ máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa wo ọ̀ràn lọ́nà tí Ọlọ́run gbà ń wò ó?” Nígbà tọ́rọ̀ bá kan fífún àwọn èèyàn nímọ̀ràn, ó sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ pé, ‘Lójú tèmi, mo ronú pé . . . ’ Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ọ̀ràn. Tẹ́ ẹ bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ẹ óò di ojúlówó ìbùkún fáwọn tẹ́ ẹ máa bá pàdé níbi tá a ti yanṣẹ́ fún yín.”

Lẹ́yìn èyí ni ọpọ́n sún kan Gerrit Lösch, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkòrí náà “Mo Wà Pẹ̀lú Rẹ,” ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò tí Jèhófà máa ń sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ pé “Mo wà pẹ̀lú rẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 26:23, 24; 28:15; Jóṣúà 1:5; Jeremáyà 1:7, 8) Àwa náà lè ní irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ nínú Jèhófà lọ́jọ́ tòní tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí i. Arákùnrin Lösch sọ pé: “Ṣé ominú ń kọ yín pé bóyá lẹ máa ráwọn èèyàn tẹ́ ẹ máa bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ẹ má gbàgbé o, Jèhófà ti sọ pé, ‘Mo wà pẹ̀lú rẹ.’ Ṣé ẹ̀rù ń bà yín pé ẹ lè máà ní àwọn nǹkan tara tó pọ̀ tó? Jèhófà ti sọ pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’” (Hébérù 13:5) Nígbà tí Arákùnrin Lösch fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí ìlérí tí Jésù ti ṣe pé òun á wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn òun olóòótọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn náà.—Mátíù 28:20.

Lawrence Bowen, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ̀rọ̀ lórí àkòrí náà, “Ṣé Wàá Rí Ààbò Nígbà Tí Àdánwò Tó Dà Bí Iná Bá Dé?” Ó sọ pé látìgbà tí ọ̀ràn tó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì ti wáyé ni gbogbo àwọn tó fẹ́ láti fún Jèhófà ní ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ gédégbé ti ń dojú kọ onírúurú ìṣòro, àti àdánwò tó dà bí iná nígbà míì. Ó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ to kẹ́kọ̀ọ́ yege nímọ̀ràn pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, tó jẹ́ pé gbígbára lé Jèhófà pátápátá ló fún un ní ààbò tòótọ́, tó sì jẹ́ kó lè fara da àwọn àdánwò tó dà bí iná tí Jèhófà fàyè gbà kí ìgbọràn rẹ̀ bàa lè di pípé. (Hébérù 5:8, 9) A lè fi Jèhófà wé alágbẹ̀dẹ tó ń fọ wúrà mọ́, tó mọ bó ṣe yẹ kóun fínná mọ́ ọn tó láti yọ ìdàrọ́ inú rẹ̀ kúrò. Àmọ́ ṣá o, ìgbàgbọ́ tá a bá fi iná dán wò máa ń pèsè ààbò ju wúrà tá a ti yọ́ mọ́ lọ. Kí nìdí? Arákùnrin Bowen ní “ìdí èyí ni pé ìgbàgbọ́ tá a ti yọ́ mọ́ lè fara da àdánwò èyíkéyìí, ó sì ń fún wa lágbára láti ní ìfaradà títí ‘dé òpin.’”—Mátíù 24:13.

Olùkọ́ mìíràn nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, tó ń jẹ́ Mark Noumair, béèrè pé: “Ṣé Àwọn Èèyàn Á Fẹ́ràn Rẹ?” Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lórí 1 Sámúẹ́lì 2:26, tó sọ pé Sámúẹ́lì jẹ́ ẹni tí a “fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.” Lẹ́yìn tí Arákùnrin Noumair, tó ti lo ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Áfíríkà, mẹ́nu ba àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì tán, ó sọ pé: “Ẹ̀yin náà lè di ẹni tí Ọlọ́run fẹ́ràn gan-an bẹ́ ò bá jáwọ́ nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé yín lọ́wọ́. Ó ti yàn yín sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó ṣeyebíye.” Lẹ́yìn náà ni Arákùnrin Noumair wá fún kíláàsì tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà nímọ̀ràn pé kí wọ́n ka iṣẹ́ tá a yàn fún wọn sí ẹrù iṣẹ́ mímọ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n sì máa ronú lọ́nà ti Ọlọ́run bí wọ́n ṣe ń bá iṣẹ́ tá a yàn fún wọn náà lọ.

Láàárín àkókò tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́ náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí láǹfààní tó pọ̀ láwọn òpin ọ̀sẹ̀ láti sọ fáwọn ará àdúgbò náà nípa “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” tó wà nínú Bíbélì. (Ìṣe 2:11) Kódà, ó ṣeé ṣe fún wọn láti sọ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí ní onírúurú èdè mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wallace Liverance, tóun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n sì sọ àwọn ìrírí wọn lábẹ́ àkòrí náà “‘Àwọn Ohun Ọláńlá Ọlọ́run’ Ń Mú Káwọn Èèyàn Ṣe Ohun Tó Tọ́.” Ó sọ pé: “Ẹ̀mí ló mú káwọn èèyàn tó wà ní yàrá òkè ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ nípa ‘àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.’ Ẹ̀mí yìí kan náà ló ń ṣiṣẹ́ láàárín àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí.” Àwọn mìíràn tiẹ̀ ti bá a débi pé wọ́n kọ́ èdè tuntun láti lè wàásù fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i.

Àmọ̀ràn Tó Gbéṣẹ́ Nípa Wíwo Ọ̀ràn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Ń Gbà Wò Ó

Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, Gary Breaux àti William Young, tí wọ́n wà lára ìgbìmọ̀ ẹ̀ka ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ ẹ̀ka láwọn ilẹ̀ táwọn míṣọ́nnárì ti ń sìn ní lọ́ọ́lọ́ọ́, wọ́n tún fọ̀rọ̀ wá tọkọtaya kan tó ti lo ọdún mọ́kànlélógójì nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì lẹ́nu wò. Ohun kan tí wọ́n kíyè sí ni pé: “Àwọn míṣọ́nnárì tí ò bá sọ pé dandan àwọn gbọ́dọ̀ ní àwọn nǹkan tara tó pọ̀ rẹpẹtẹ ló máa ń pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ náà ni wọ́n máa ń gbájú mọ́. Wọ́n mọ̀ pé ohun tó gbé àwọn wá ni láti wàásù ìhìn rere náà àti láti mú káwọn èèyàn mọ Jèhófà.”

David Splane, tó tún jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ló kágbá ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nílẹ̀ pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé “Ibi Tẹ́ Ẹ̀ Ń Lọ Ò Jìnnà!” Kí lóhun tó sọ yìí túmọ̀ sí, nígbà tó jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ayé ni wọ́n ń rán àwọn mẹ́rìndínláàádọ́ta tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà lọ? Ó ṣàlàyé pé: “Ibi yòówù kó o wà lórí ilẹ̀ ayé, ilé Ọlọ́run ni wà á máa wà ní gbogbo ìgbà tó o bá ṣì jẹ́ olóòótọ́.” Òdodo ọ̀rọ̀, gbogbo àwọn Kristẹni olóòótọ́, láìka ibi tí wọ́n ń gbé sí, ló ń sìn lápá ibì kan nínú tẹ́ńpìlì ńlá tàbí ilé tẹ̀mí Ọlọ́run, tá a dá sílẹ̀ nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi ní ọ̀rúndún kìíní. (Hébérù 9:9) Ẹ wò bó ṣe jẹ́ ìtura ńláǹlà tó fáwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ láti mọ̀ pé Jèhófà ò jìnnà sí gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé! Bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé náà ló ṣe nífẹ̀ẹ́ gbogbo wa àti iṣẹ́ ìsìn wa sí I, láìfi ti ibi yòówù ká máa gbé pè. Nítorí náà, tó bá kan ọ̀ràn ìjọsìn, a ò jìnnà síra wa, a ò sì jìnnà sí Jèhófà àti Jésù.

Lẹ́yìn tí wọ́n ka àwọn ìwé ìkíni tí wọ́n rí gbà láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, tí wọ́n ka ibi tá a yan olúkúlùkù sí, tí wọ́n sì ka lẹ́tà ìdúpẹ́ tí kíláàsì náà kọ fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí gbà ní Gílíádì tán, alága wá mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà wá sópin. Ó rọ àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà láti máa bá iṣẹ́ rere tí wọ́n ń ṣe nìṣó kí wọ́n sì máa yọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—Fílípì 3:1.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

ÌSỌFÚNNI ONÍṢIRÒ NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tá a ṣojú fún: 14

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 19

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 46

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 35.0

Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 17.2

Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 13.7

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Kíláàsì Kẹtàléláàádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Ligthart, M.; Hosoi, S.; Berktold, A.; Liem, C.; Aoki, J. (2) Baglyas, J.; Bouqué, S.; Bossi, A.; Alton, J.; Escobar, I.; Escobar, F. (3) Stoica, A.; Stoica, D.; Freimuth, S.; Karlsson, M.; LeBlanc, R. (4) Bianchi, R.; Bianchi, S.; Kaminski, L.; Joseph, L.; Paris, S.; LeBlanc, L. (5) Paris, M.; Skidmore, B.; Horton, J.; Horton, L.; Skidmore, G. (6) Liem, B.; Alton, G.; Quirici, E.; Langlois, M.; Steininger, S.; Aoki, H. (7) Langlois, J.; Steininger, M.; Bossi, F.; Kaminski, J.; Bouqué, J.; Ligthart, E.; Hosoi, K. (8) Baglyas, J.; Quirici, M.; Karlsson, L.; Freimuth, C.; Berktold, W.; Joseph, R.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́