ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 6/1 ojú ìwé 24-27
  • Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà Kí Ẹ Sì Kún fún Ìdùnnú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà Kí Ẹ Sì Kún fún Ìdùnnú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Gbà Wọ́n Níyànjú Láti Má Ṣe Jẹ́ Kí Iná Ayọ̀ Wọn Kú
  • Ìrírí Amọ́kànyọ̀ àti Ìfọ̀rọ̀wáni-Lẹ́nuwò
  • Ẹ̀mí Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Ló Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Wá sí Gílíádì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Látorí Akẹ́kọ̀ọ́ Aláṣeyọrí Sórí Mísọ́nnárì Aláṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìfẹ́ Sún Wọn Láti Ṣiṣẹ́ Sìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Ọgọ́ta Ọdún Rèé Tó Ti Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Níṣẹ́ Míṣọ́nnárì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 6/1 ojú ìwé 24-27

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà Kí Ẹ Sì Kún fún Ìdùnnú

ÀKÓKÒ ayọ̀ ni ìgbà tẹ́nì kan bá ṣàṣeyọrí iṣẹ́ pàtàkì tó dáwọ́ lé. Irú àkókò bẹ́ẹ̀ ni àkókò ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege tó wáyé ní March 13, 1999, ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower, tó wà ní Patterson, New York, jẹ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìdínláàádọ́ta ti kíláàsì kẹrìndínláàádọ́fà ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead.

Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ látẹnu Theodore Jaracz, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì keje ilé ẹ̀kọ́ Gilead, tó sì tún jẹ́ alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà, tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Sáàmù 32:11, tó sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú, ẹ̀yin olódodo.” Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa kún fún ayọ̀ níbi ayẹyẹ yìí, ó wí pé: “Ohun tó fà á tí a fi ń kún fún ayọ̀ ní àkókò yìí ni nítorí ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn tí wọ́n ní ọkàn-àyà dídúró ṣinṣin, títí kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gilead wa.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣètò láti wá sí ilé ẹ̀kọ́ Gilead, tí wọ́n sì ti yọ̀ǹda ara wọn láti tóótun fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì, Jèhófà ló mú kí gbogbo rẹ̀ kẹ́sẹ járí. (Òwe 21:5; 27:1) Ìyẹn ní Arákùnrin Jaracz tẹnu mọ́ pé ó jẹ́ ìdí fún ‘yíyọ̀ nínú Jèhófà.’

Lára àwọn tó wà níkàlẹ̀ ní gbọ̀ngàn àpéjọ ti Patterson ni àwọn ìbátan àti àlejò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè méjìlá láti wá wo ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ yìí. Bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáta èèyàn ó lé méjìdínnígba [5,198] tó wà níjòókòó—títí kan àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn, Patterson, àti Wallkill, tí a fi ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ àti ti amóhùnmáwòrán so pọ̀—ti ń retí ohun tí ọpọ́n sún kàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó hàn gbangba pé ìdùnnú gbabẹ̀ kan.

A Gbà Wọ́n Níyànjú Láti Má Ṣe Jẹ́ Kí Iná Ayọ̀ Wọn Kú

Bí Arákùnrin Jaracz ti mú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ tó sọ wá sópin, ó ké sí ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn olùbánisọ̀rọ̀ márùn-ún, tí wọ́n ti múra ọ̀rọ̀ ìyànjú tí a gbé ka Ìwé Mímọ́ sílẹ̀, kì í ṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead nìkan ní ọ̀rọ̀ yìí wà fún o, ó tún wà fún gbogbo àwọn tó wà níkàlẹ̀.

Ẹni tó kọ́kọ́ bá àwùjọ sọ̀rọ̀ ni William Malenfant, akẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kẹrìnlélọ́gbọ̀n ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead, tó wá ń sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ní ìbámu pẹ̀lú ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “‘Gbogbo Rẹ̀’ Kì í Ṣe Asán!” tí a gbé ka ìwé Oníwàásù 1:2, ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ ohun tí Sólómọ́nì ń sọ ni pé, ohun gbogbo, pátá ni asán?” Ìdáhùn náà ni pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́. Ohun tó ń tọ́ka sí ni àwọn ohun tí ènìyàn ń ṣe tí kò jẹ́ kó ka ìfẹ́ Ọlọ́run sí, àwọn ohun tí èèyàn ń lépa tó yàtọ̀ sí ìfẹ́ Ọlọ́run—gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn ló jẹ́ asán.” Ní ìyàtọ̀ pátápátá, jíjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà, kì í ṣe asán; bẹ́ẹ̀ sì ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, àti fífi kọ́ àwọn ẹlòmíràn kì í ṣe asán. Ọlọ́run kò gbàgbé irú akitiyan bẹ́ẹ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń ṣe. (Hébérù 6:10) Lóòótọ́, bí àjálù yóò bá tiẹ̀ já lu àwọn tí wọ́n ti rí ojú rere Ọlọ́run, àwọn ènìyàn náà yóò jẹ́ àwọn “tí a dì sínú àpò ìwàláàyè lọ́dọ̀ Jèhófà.” (1 Sámúẹ́lì 25:29) Èrò yìí mà múni lọ́kàn yọ̀ o! Rírántí àwọn kókó wọ̀nyí lè ran gbogbo àwa olùjọsìn Jèhófà lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí iná ayọ̀ wa kú.

John Barr, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, fi àsọye rẹ̀ fún kíláàsì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege níṣìírí, ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé náà ni “Rírí Ayọ̀ Nínú Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Tí A Yàn fún Ọ.” Ó fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì jẹ́ ohun tó máa ń mú ọkàn Jèhófà Ọlọ́run yọ̀. “Ó jẹ́ apá kan ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn fún ayé. Ó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sórí ilẹ̀ ayé yìí. Jésù ni míṣọ́nnárì títóbilọ́lá jù lọ, òun ni òléwájú àwọn míṣọ́nnárì.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míṣọ́nnárì ní láti ronú nípa àwọn ìyípadà tí Jésù ní láti ṣe kó tó lè kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àǹfààní tí iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì Jésù mú wá ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo ẹni tó bá tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Gẹ́gẹ́ bí Arákùnrin Barr ti sọ, èyí jẹ́ nítorí pé ó jẹ́ dídùn inú Jésù láti máa ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run àti pé ó tún nífẹ̀ẹ́ ọmọ aráyé. (Òwe 8:30, 31) Arákùnrin Barr rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà láti rọ̀ mọ́ iṣẹ́ tí a yàn fún wọn, kó má wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ìfaradà nìkan, ṣùgbọ́n kó jẹ́ nítorí pé dídùn inú wọn ni láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó gba kíláàsì náà níyànjú pé: “Ẹ gbára lé Jèhófà; òun kì yóò sì já yín kulẹ̀.”—Sáàmù 55:22.

Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí olùbánisọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e, ìyẹn ni Lloyd Barry, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ ni, “Rírìn ní Orúkọ Jèhófà Títí Láé.” Níwọ̀n bí ó ti sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní Japan lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkànlá ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead, Arákùnrin Barry sọ díẹ̀ nínú àwọn ìrírí tí àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí ní, ó sì ṣàlàyé àwọn ìpèníjà tí wọ́n dojú kọ. Ìmọ̀ràn tó ṣeé mú lò wo ló ní fún kíláàsì tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege? “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ máà jẹ́ kí ipò tẹ̀mí yín yingin. Bákan náà, ẹ kọ́ èdè àti àṣà ibi tí ẹ ń lọ. Ẹ máa báwọn èèyàn ṣàwàdà. Ẹ gbájú mọ́ iṣẹ́ táa rán yín; ẹ máà jẹ́ kó rẹ̀ yín, ẹ má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀.” Arákùnrin Barry sọ fún àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege pé, níbi tí a óò ràn wọ́n lọ ní ilẹ̀ òkèèrè, wọn yóò bá ọ̀pọ̀ èèyàn pàdé tí wọn yóò máa rìn ní orúkọ onírúurú ọlọ́run àti òrìṣà, ó wá rán wọn létí ọ̀rọ̀ Míkà, tó sọ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) Àpẹẹrẹ àwọn míṣọ́nnárì ìṣáájú ti jẹ́ orísun agbára fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti máa bá a nìṣó ní rírìn ní orúkọ Jèhófà àti fífi ẹ̀mí òótọ́ sìn ín.

Ẹni tí ọpọ́n sún kàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gilead, Lawrence Bowen. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé ìbéèrè náà dìde pé, “Kí Lo Fẹ́ Dà? Ó fi hàn pé àṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sinmi lórí ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Gbígbáralé Jèhófà pátápátá ló mú kí Ásà Ọba ṣẹ́gun ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ọ̀tá rẹ̀, tí ó tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ ọkùnrin. Síbẹ̀, wòlíì Asaráyà rán an létí pé ó ní láti gbára lé Ọlọ́run, ó sọ pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà pẹ̀lú rẹ̀.” (2 Kíróníkà 14:9-12; 15:1, 2) Níwọ̀n bí orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, ti túmọ̀ sí pé ó lè di ohunkóhun tí ó bá fẹ́ láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ—yálà kí ó di Olùpèsè, Adáàbòboni, tàbí kó tiẹ̀ di Amúdàájọ́ṣẹ pàápàá—àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n bá gbára lé Jèhófà, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ yóò ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ wọn. (Ẹ́kísódù 3:14) Arákùnrin Bowen mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá sí ìparí nípa sísọ pé: “Ẹ má ṣe gbàgbé pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá ti ń sọ ète Jèhófà di ète tiyín, òun yóò mú kí ẹ di ohunkóhun tí ó bá fẹ́ láti lè ṣe iṣẹ́ tí ó yàn fún yín.”

Ẹni tí ó báni sọ̀rọ̀ kẹ́yìn nínú apá yìí lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni Wallace Liverance, ẹni tó ti jẹ́ míṣọ́nnárì rí, tó ti wá di olóòtú ilé ẹ̀kọ́ náà báyìí. Àsọyé rẹ̀, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yè Nínú Rẹ, Kí Ó sì Nípa Lórí Rẹ,” pe àfiyèsí sí ìhìn iṣẹ́, tàbí ìlérí Ọlọ́run tí kò lè yẹ̀, tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ní ìmúṣẹ. (Hébérù 4:12) Ó nípa lórí ìgbésí ayé àwọn tí wọ́n bá yọ̀ǹda fún un pé kí ó nípa lórí àwọn. (1 Tẹsalóníkà 2:13) Báwo ni a ṣe lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yè, kó sì nípa lórí ìgbésí ayé wa? Nípa fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni. Arákùnrin Liverance rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà létí àwọn ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead, èyí tó ní kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣíṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí, àti báa ṣe lè fi sílò nínú. Ó ṣàyọlò àwọn ọ̀rọ̀ Albert Schroeder, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ tó dá Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead sílẹ̀ ní ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn: “Nípa lílo àyíká ọ̀rọ̀, ẹnì kan lè lóye agbára tẹ̀mí kíkún, tó péye, tí Ọlọ́run mú wà lárọ̀ọ́wọ́tó nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.” Lílo ọ̀nà yìí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń mú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, kí ó sì nípa lórí ẹni.

Ìrírí Amọ́kànyọ̀ àti Ìfọ̀rọ̀wáni-Lẹ́nuwò

Lẹ́yìn táa sọ àsọyé tán, àwọn ìrírí amọ́kànyọ̀ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ dá àwùjọ náà lára yá. Lábẹ́ ìdarí Mark Noumair, tó jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀, tó sì jẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gilead báyìí, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ ìrírí bí wọ́n ṣe jẹ́rìí ní onírúurú ipò, wọ́n sì ṣe é han àwùjọ. Ó ṣeé ṣe fáwọn kan láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ náà, kí wọ́n sì máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, nítorí pé wọ́n ń kíyè sí àwọn ipò wọn, ọ̀rọ̀ ẹnu wọn, wọ́n sì ń fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Nípa báyìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ‘ń fiyè sí ara wọn nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ wọn’ wọ́n sì ṣe tán láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jèrè ìgbàlà.—1 Tímótì 4:16.

Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin onírìírí tó ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ ẹ̀ka táa ṣe ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower ló fúnni ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó ṣeé mú lò, wọ́n sì jẹ́ ká rí bí ayọ̀ iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ti pọ̀ tó. Arákùnrin Samuel Herd àti Robert Johnson tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ lórílé-iṣẹ́ darí ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò tó tani jí pẹ̀lú àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Society ní Bolivia, Zimbabwe, Nicaragua, Central African Republic, Dominican Republic, Papua New Guinea, àti Cameroon.

Lẹ́yìn ìrírí àti ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò, Gerrit Lösch, akẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kọkànlélógójì ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead, tó ti wá di mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso báyìí, ló sọ ọ̀rọ̀ àsọparí lórí kókó amúnironú-jinlẹ̀ náà, “Ìwọ Ha Jẹ́ ‘Ẹni Tó Fani Lọ́kàn Mọ́ra’ Bí?” Arákùnrin Lösch kọ́kọ́ rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà létí pé Jésù, Ọmọ Ọlọ́run pípé, làwọn èèyàn kò kà sí ẹni tó fani lọ́kàn mọ́ra, dípò èyí ṣe ni ‘wọ́n tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, wọ́n sì kà á sí aláìjámọ́ nǹkan kan.’ (Aísáyà 53:3) Nítorí náà kò yani lẹ́nu lónìí pé ní ọ̀pọ̀ àgbègbè ayé ni a kì í ti í ka àwọn míṣọ́nnárì sí. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ní ọ̀pọ̀ ọdún tí Dáníẹ́lì fi wà ní Bábílónì, ìgbà mẹ́ta ni Ẹlẹ́dàá tipasẹ̀ áńgẹ́lì kan pe Dáníẹ́lì ní “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi.” (Dáníẹ́lì 9:23; 10:11, 19) Kí ló sọ Dáníẹ́lì di irú ẹni bẹ́ẹ̀? Kò fi ìlànà Bíbélì báni dọ́rẹ̀ẹ́ rárá nígbà tó ń mú ara rẹ̀ bá àṣà Bábílónì mu; kì í lọ́wọ́ nínú ìwà àbòsí, kò lo ipò rẹ̀ fún àǹfààní ara rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ló jẹ́ onítara akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 1:8, 9; 6:4; 9:2) Ó tún máa ń gbàdúrà déédéé sí Jèhófà, ó sì ṣe tán láti fi ògo àṣeyọrí rẹ̀ fún Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 2:20) Nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè jẹ́ ẹni tó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi, kò pọndandan kí wọ́n jẹ́ bẹ́ẹ̀ lójú àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ bẹ́ẹ̀ lójú Jèhófà Ọlọ́run.

Láti mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó gbéni ró yìí wá sópin, alága ka díẹ̀ nínú wáyà tí wọ́n tẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyè àti ìkíni táwọn èèyàn fi ránṣẹ́. Lẹ́yìn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tọkọtaya mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlélógún gba ìwé ẹ̀rí dípúlómà wọn, a sì kéde orílẹ̀-èdè tí a ràn wọ́n lọ. Láti kádìí ètò ọ̀hún, ẹnì kan tó ṣojú fún kíláàsì náà ka lẹ́tà tí kíláàsì náà kọ sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso àti ìdílé Bẹ́tẹ́lì, èyí tí wọ́n fi sọ ìmọrírì wọn fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà àti ètò tí a fi mú wọn gbára dì láti oṣù márùn-ún tó ti kọjá sẹ́yìn.

Bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ti wá sópin, igbe “ayọ̀ yíyọ̀, àní pẹ̀lú ìdúpẹ́” ló gba àárín àwùjọ náà kan.—Nehemáyà 12:27.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìsọfúnni Oníṣirò Nípa Kíláàsì

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 10

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yanni sí: 19

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48

Iye àwọn tọkọtaya: 24

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33

Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 16

Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 13

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Kíláàsì Kẹrìndínláàádọ́fà Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Nínú orúkọ tó wà nísàlẹ̀ yìí, a fi nọ́ńbà sí wọn láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì tó orúkọ wọn láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Deakin, D.; Puopolo, M.; Laguna, M.; Davault, S.; Dominguez, E.; Burke, J. (2) Gauter S.; Vazquez, W.; Seabrook, A.; Mosca, A.; Helly, L.; Breward, L. (3) Brandon, T.; Olivares, N.; Coleman, D.; Scott, V.; Petersen, L.; McLeod, K. (4) McLeod, J.; Thompson, J.; Luberisse, F.; Speta, B.; Lehtimäki, M.; Laguna, J. (5) Gauter, U.; Dominguez, R.; Helly, F.; Smith, M.; Beyer, D.; Mosca, A. (6) Scott, K.; Seabrook, V.; Speta, R.; Coleman, R.; Breward, L.; Davault, W. (7) Smith, D.; Lehtimäki, T.; Petersen, P.; Thompson, G.; Vazquez, R.; Beyer, A. (8) Luberisse, M.; Deakin, C.; Brandon, D.; Puopolo, D.; Olivares, O.; Burke, S.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́