Látorí Akẹ́kọ̀ọ́ Aláṣeyọrí Sórí Mísọ́nnárì Aláṣeyọrí
NÍGBÀ tí Will ń sọ̀rọ̀ nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí òun àti aya rẹ̀, Patsy, ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà tán gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead, pẹ̀lú ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ ó wí pé: “N kò tí ì gbà gbọ́ pé a ní àǹfààní yìí!” Zahid àti Jeni gbà pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n wí pé: “Àǹfààní ńlá ni ó jẹ́ fún wa láti wà níhìn-ín.” Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ náà. Wàyí o, wọ́n ń hára gàgà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́, níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà ní September 6, 1997, wọ́n rí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ gbà tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí níbi iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a ń rán wọn lọ.
Theodore Jaracz, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ni alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ó tọ́ka sí i pé—pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì àti àwọn aṣojú ẹ̀ka 48 ti Watch Tower Society—ọ̀rẹ́ àti ẹbí láti Kánádà, Yúróòpù, Puerto Rico, àti United States pésẹ̀ láti fi ìtìlẹ́yìn àti ìfẹ́ wọn dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú. Arákùnrin Jaracz ṣàlàyé pé lọ́pọ̀ ìgbà ni a ti pín ọkàn àwọn míṣọ́nnárì tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù rán jáde níyà kúrò lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn góńgó ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ kó wọnú ìṣèlú. Ní ìyàtọ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ti Gilead ń ṣe ohun tí a rán wọn láti ṣe. Wọ́n ń fi Bíbélì kọ́ni.
Lẹ́yìn náà, Robert Butler láti ọ́fíìsì Society ní Brooklyn sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Mú Kí Ọ̀nà Rẹ Yọrí Sí Rere.” Ó ṣàlàyé pé bí àwọn ènìyàn tilẹ̀ ń fi èrè owó tàbí nǹkan ti ará mìíràn díwọ̀n àṣeyọrí, ohun tí ó ṣe pàtàkì ní ti gidi ni bí Ọlọ́run ṣe ń díwọ̀n àṣeyọrí. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù yọrí sí rere, kì í ṣe nítorí pé ó yí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ lọ́kàn pa dà, bí kò ṣe nítorí pé ó jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú iṣẹ́ tí a yàn fún un. Jésù mú ògo wá fún Jèhófà, kò sì jẹ́ kí ayé kó àbààwọ́n bá òun. (Jòhánù 16:33; 17:4) Gbogbo Kristẹni ni ó lè ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí.
Robert Pevy, tí ó jẹ́ míṣọ́nnárì ní Ìlà Oòrùn tẹ́lẹ̀ rí, rọ̀ wọ́n pé, “Ẹ Fi Ara Yín Ṣe Ẹrú fún Gbogbo Ènìyàn.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ míṣọ́nnárì aláṣeyọrí. Kí ni àṣírí rẹ̀? Ó fi ara rẹ̀ ṣe ẹrú fún gbogbo ènìyàn. (Kọ́ríńtì Kíní 9:19-23) Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé: “Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead tí ó bá ní irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ kò ní wo iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìgbésí ayé tí ń gbéni dé ipò gíga, òkúta àtẹ̀gùn kan sí àwọn ipò pàtàkì nínú ètò àjọ náà. Míṣọ́nnárì kan yóò lọ síbi iṣẹ́ tí a yàn fún un pẹ̀lú ète kan ṣoṣo—láti sìn, nítorí ohun tí ẹrú ń ṣe nìyẹn.”
Ní gbígbé ìmọ̀ràn rẹ̀ ka Kọ́ríńtì Kejì orí 3 àti 4 ní pàtàkì, Gerrit Lösch ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú láti “Máa Tan Ògo Jèhófà Gẹ́gẹ́ Bíi Dígí.” Ó rán wọn létí pé ìmọ̀ Ọlọ́run dà bí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn sí Kristẹni kan nígbà tí ó bá ṣí ọkàn àyà rẹ̀ payá láti gbà á. A ń tan ìmọ́lẹ̀ yẹn nípa wíwàásù ìhìn rere náà àti nípa pípa ìwà rere mọ́. Ó sọ pé: “Nígbà míràn o lè nímọ̀lára ìkù-díẹ̀-káàtó. Nígbà tí irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ bá wáyé, gbára lé Jèhófà, ‘kí agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run.’” (Kọ́ríńtì Kejì 4:7) Ní sísọ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí a kọ sínú Kọ́ríńtì Kejì 4:1 jáde, Arákùnrin Lösch rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a yàn yín sí. Ẹ jẹ́ kí dígí yín túbọ̀ máa tàn yanran!”
Karl Adams, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ àti alábòójútó Gilead, sọ̀rọ̀ lórí kókó gbígbádùnmọ́ni gan-an náà, “Níbo Ni Jèhófà Wà?” Kì í ṣe ibi tí Ọlọ́run wà nínú àgbáálá ayé ni ìbéèrè yí ń tọ́ka sí, bí kò ṣe ìjẹ́pàtàkì ríronújinlẹ̀ lórí ojú ìwòye Jèhófà àti bí ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ti ṣe kókó tó. Ó wí pé: “Lábẹ́ másùnmáwo, ẹnì kan tí ó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá lè gbàgbé ìyẹn.” (Jóòbù 35:10) Ọjọ́ wa lónìí ńkọ́? Ní ọdún 1942, àwọn ènìyàn Ọlọ́run nílò ìtọ́sọ́nà. Iṣẹ́ ìwàásù náà ha ti ń kógbá nílẹ̀ bí, àbí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ṣì wà láti ṣe? Kí ni ìfẹ́ Jèhófà fún àwọn ènìyàn rẹ̀? Bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìdáhùn náà túbọ̀ ṣe kedere. Arákùnrin Adams sọ pé: “Kí ọdún náà tó parí, ètò ti wà nílẹ̀ fún Watchtower Bible School of Gilead.” Dájúdájú, Jèhófà ti bù kún iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì tí ilé ẹ̀kọ́ yẹn rán jáde.
Mark Noumair ni olùkọ́ kejì tí yóò sọ̀rọ̀. Nínú àsọyé rẹ̀, tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Lo Tálẹ́ǹtì Rẹ?,” ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti lo ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti gbà ní Gilead gbàrà tí wọ́n bá ti gúnlẹ̀ sí ibi tí a rán wọn lọ. Ó wí pé: “Ẹ bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀. Ẹ dàpọ̀ mọ́ wọn. Ẹ hára gàgà láti kọ́ àṣà ìbílẹ̀ wọn, ìtàn wọn, àti ohun tí ń pa àwọn ará orílẹ̀-èdè náà lẹ́rìn-ín. Bí ẹ bá ti lè tètè kọ́ èdè náà tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ti rọrùn fún yín tó láti mú ara yín bá ipò ibẹ̀ mu.”
Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Onítara Rí Ayọ̀ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wọn
Ní àfikún sí fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ wọn nígbà tí wọ́n wà ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead, a yan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sí ìjọ àdúgbò 11. Lópin ọ̀sẹ̀, wọ́n fi ìtara lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìwàásù. Wallace Liverance tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ àti alábòójútó Gilead ké sí díẹ̀ lára wọn láti ṣàjọpín àwọn ìrírí wọn pẹ̀lú àwùjọ. Ayọ̀ wọn hàn gbangba bí wọ́n ṣe ń sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí ní ilé ìrajà, ní ibi ìgbọ́kọ̀sí, ní àgbègbè iṣẹ́ ajé, lójú pópó, àti láti ilé dé ilé. Àwọn kan lára wọn wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà bá àwọn tí ń sọ èdè àjèjì tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìjọ wọn, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, sọ̀rọ̀. Ó kéré tán, láàárín oṣù márùn-ún ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn, àwọn mẹ́ńbà kíláàsì kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún náà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́wàá, wọ́n sì darí wọn.
Àwọn Míṣọ́nnárì Ọlọ́jọ́ Pípẹ́ Ṣàjọpín Àṣírí Àṣeyọrí Wọn
Lẹ́yìn apá gbígbádùnmọ́ni yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, fún àǹfààní kíláàsì náà, Patrick Lafranca àti William Van de Wall ké sí àwọn méje kan tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka láti ṣàkópọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti kọ́ nínú iṣẹ́ ìgbésí ayé míṣọ́nnárì wọn. Wọ́n ṣí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà létí pé ibi iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a yàn wọ́n sí wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, kí wọ́n sì pinnu láti dúró síbi tí a yàn wọ́n sí. Wọ́n sọ nípa ìyọrísí rere tí àwọn míṣọ́nnárì tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ ní Gilead ti ní lórí iṣẹ́ náà ní àwọn ilẹ̀ míràn.
Kí ni ó ran àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka wọ̀nyí lọ́wọ́ láti sìn fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì aláyọ̀, tí ń méso jáde? Wọ́n ṣiṣẹ́ pa pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àdúgbò, wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Wọ́n fi ara wọn fún kíkọ́ èdè náà gbàrà tí wọ́n ti dé ibi tí a yàn wọ́n sí. Wọ́n kọ́ láti jẹ́ ẹni tí ó mọwọ́ yí pa dà àti ẹni tí ó lè mú ara rẹ̀ bá àṣà ìbílẹ̀ àdúgbò mu. Charles Eisenhower, akẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì àkọ́kọ́ ti Gilead, tí ó ti jẹ́ míṣọ́nnárì fún ọdún 54, ṣàjọpín “àṣírí” márùn-ún tí àwọn míṣọ́nnárì aláṣeyọrí ti kọ́: (1) Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, (2) kọ́ èdè náà, (3) jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, (4) máa ṣe ohun tí ó lè mú kí àlàáfíà wà nínú ilé míṣọ́nnárì, àti (5) gbàdúrà sí Jèhófà déédéé. Kì í ṣe ìmọ̀ràn tí ó gbéṣẹ́ tí wọ́n rí gbà nìkan ni ó mú orí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wú bí kò ṣe ayọ̀ tí ó hàn gbangba pé àwọn míṣọ́nnárì onírìírí wọ̀nyí ní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bí Armando àti Lupe ti sọ ọ́, “inú wọ́n dùn nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé wọn.”
Lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, ó ku àwíyé kan ṣoṣo. Albert Schroeder, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, yan “Olóòótọ́ Ìríjú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣí Ìṣura Iyebíye Òtítọ́ Payá,” gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀. Níwọ̀n bí Bíbélì ti jẹ́ lájorí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ gbọ́ ohun tí ó ní í sọ. Arákùnrin Schroeder fi hàn pé, nígbà tí iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ lórí Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures ní 50 ọdún sẹ́yìn, àwọn ẹni àmì òróró mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Atúmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun kò wá ìtẹ́wọ́gbà ènìyàn ṣùgbọ́n wọ́n gbára lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́. (Jeremáyà 17:5-8) Ṣùgbọ́n, láìpẹ́ yìí, àwọn ìjìnmì kan ti kan sáárá sí ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tí Bíbélì New World Translation fi lélẹ̀. Nínú lẹ́tà kan sí Society, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan kọ̀wé pé: “Mo mọ ojúlówó ìtẹ̀jáde tí mo bá rí i, ‘Ìgbìmọ̀ Atúmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun’ yín sì ti ṣe iṣẹ́ tí ó pegedé.”
Lẹ́yìn àsọyé yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gba dípúlómà wọn, a sì kéde ibi tí a rán wọn lọ fún àwùjọ. Ó jẹ́ àkókò arùmọ̀lárasókè fún àwọn mẹ́ńbà kíláàsì náà. Bí aṣojú kíláàsì náà ti ń ka lẹ́tà ìmọrírì, orí ọ̀pọ̀ nínú wọ́n wú, omi sì lé ròrò sójú wọn. Àwọn kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ní mímọ̀ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni a óò fi darí ẹ̀kọ́ Gilead, díẹ̀ ti ṣí lọ sí àwọn ìjọ tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti lè mú kí wọ́n dáńgájíá sí i nínú sísọ ọ́. Àwọn mìíràn ti ṣí lọ sí ibi tí àìní gbé pọ̀ fún àwọn aṣáájú ọ̀nà, yálà ní orílẹ̀-èdè wọn tàbí ní ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn mìíràn sì ti múra sílẹ̀ nípa kíka ìrírí, ṣíṣe ìwádìí, tàbí wíwo fídíò Society náà, To the Ends of the Earth, léraléra.
Inú Will àti Patsy, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, dùn jọjọ nítorí ọkàn ìfẹ́ ara ẹni tí a fi hàn sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. “Àwọn tí kò tilẹ̀ mọ̀ wá rí rárá dì mọ́ wa, wọ́n sì yà wá ní fọ́tò. Ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso bọ̀ wá lọ́wọ́, ó sì wí pé, ‘Ẹ mórí wa wú!’” Kò sí iyè méjì nípa rẹ̀, a nífẹ̀ẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún gan-an ni. A ti kọ́ wọn dáradára. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti gbà ní Gilead yóò fún wọn láǹfààní láti lè ti orí akẹ́kọ̀ọ́ aláṣeyọrí bọ́ sórí mísọ́nnárì aláṣeyọrí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Ìsọfúnni Oníṣirò Nípa Kíláàsì
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣojú fún: 9
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 18
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48
Iye àwọn tọkọtaya: 24
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33
Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 16
Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kíláàsì Kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Yege
Nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìsàlẹ̀ yí, a fi nọ́ńbà sí ìlà láti iwájú wá sí ẹ̀yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Bunn, A.; Dahlstedt, M.; Campaña, Z.; Boyacioglu, R.; Ogando, G.; Nikonchuk, T.; Melvin, S. (2) May, M.; Mapula, M.; Lwin, J.; Hietamaa, D.; Hernandez, C.; Boyacioglu, N.; Sturm, A.; Melvin, K. (3) Thom, J.; Mapula, E.; Nault, M.; Teasdale, P.; Wright, P.; Pérez, L.; Shenefelt, M.; Pak, H. (4) Murphy, M.; Campaña, J.; Stewart, S.; Cereda, M.; Reed, M.; Pérez, A.; Teasdale, W.; Pak, J. (5) Stewart, D.; Wright, A.; Cereda, P.; Nikonchuk, F.; Reed, J.; Hietamaa, K.; Ogando, C.; Shenefelt, R. (6) Murphy, T.; Hernandez, J.; Nault, M.; Bunn, B.; Thom, R.; Dahlstedt, T.; Lwin, Z.; May, R.; Sturm, A.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ibo là ń lọ?