Àwọn Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
NÍ FÍFARA wé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí ẹní mowó kárí ayé sí ẹni tí ń wàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà. A pe àfiyèsí sórí iṣẹ́ yìí nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kejìlélọ́gọ́rùn-ún ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead.
Ní March 1, 1997, Albert Schroeder, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pe àfiyèsí sí àpilẹ̀kọ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan nínú ìwé àtìgbàdégbà kan lédè Faransé Le Point. Ó sọ nípa ìwéwèé Roman Kátólíìkì láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé ní Ítálì. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Kí [àwọn míṣọ́nnárì Kátólíìkì] má baà dé lọ́wọ́ òfo bí wọ́n ti ń bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà du ìpínlẹ̀ wọn, Ìjọba Póòpù ti bá a débi títẹ mílíọ̀nù kan ẹ̀dà Ìhìn Rere Máàkù Mímọ́, bí àwọn ikọ̀ wọn ti ń bá àwọn ògbógi [Àwọn Ẹlẹ́rìí] pà dé nínú ‘fifi’ ìhìn rere náà ‘sóde’ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà.”
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege 48 náà wà lára àwọn tí wọ́n ti fara wé ọ̀nà jíjá fáfá tí Jésù ń gbà wàásù, ní títan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kálẹ̀. Wọ́n wá sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower ní Patterson, New York, láti ilẹ̀ mẹ́jọ. Ní oṣù márùn-ún tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Ẹ̀kọ́ wọn tún ní ìtàn ètò àjọ Ọlọ́run, àwọn apá ìgbésí ayé míṣọ́nnárì tí ó ṣeé mú lò, àti èso ẹ̀mí Ọlọ́run nínú. Gbogbo èyí jẹ́ pẹ̀lú góńgó kan lọ́kàn—láti mú wọn gbára dì fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ àjèjì, ní àwọn ilẹ̀ 17 tí a óò rán wọn lọ. Bí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ yege, àwùjọ 5,015 tí ó wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ṣàjọpín nínú ìdùnnú ayẹyẹ náà. Ìmọ̀ràn ìkẹyìn gbígbéṣẹ́ wo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Gilead wọnnì rí gbà?
Ìṣírí Tí Ó Bọ́ Sákòókò fún Àwọn Míṣọ́nnárì Tuntun
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àkọ́sọ alága, Ralph Walls, olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Àbójútó Ọ̀ràn Àwọn Òṣìṣẹ́ ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ ọ̀rọ̀ àsọyé kúkúrú àkọ́kọ́ tí ó kún fún ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ fún àwọn míṣọ́nnárì tuntun. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Rántí Láti Nífẹ̀ẹ́.” Ó tọ́ka sí i pé Bíbélì, nínú Tímótì Kejì orí 3, sọ tẹ́lẹ̀ pé, ayé yóò di ibi tí àìnífẹ̀ẹ́ ti ń pọ̀ sí i. Ó pèsè ìránnilétí tí ó bọ́ sákòókò yí fún àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà, ní ìbámu pẹ̀lú àpèjúwe ìfẹ́ tí a rí nínú Kọ́ríńtì Kíní 13:1-7: “Ẹ̀yin, gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, lè ní ju iye wákàtí tí a béèrè lọ. Ẹ lè ní ìmọ̀ púpọ̀ láti inú ìdálẹ́kọ̀ọ́ Gilead yín. Tàbí ki a fi ìtara ṣe àṣekún iṣẹ́ ní ẹ̀ka tí a yàn wá sí. Ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo ìsapá àti ìrúbọ wa yóò já sí bí a bá gbà gbé láti ní ìfẹ́.”
Ẹni tí ó sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni Carey Barber, ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tí ó gbé kókó ẹ̀kọ́ náà yẹ̀ wò, “Jèhófà Ń Ṣamọ̀nà Wa Lọ sí Ìṣẹ́gun.” Láti ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, Jèhófà Ọlọ́run ti ṣamọ̀nà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ lọ sí ìṣẹ́gun nínú pípolongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀, láìka inúnibíni sí. Ní 1931, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ṣe mọ̀ wọ́n sí nígbà náà, tẹ́wọ́ gba orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní fífa ìrora ọkàn fún àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù. Arákùnrin Barber sọ pé: “Kíláàsì kejìlélọ́gọ́rùn-ún ti àwọn míṣọ́nnárì tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ ní Gilead nísinsìnyí ní àǹfààní kíkọyọyọ láti ní ìpín ńlá nínú iṣẹ́ ológo náà ti fífún ọ̀pọ̀ ènìyàn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó ní àǹfààní láti kọ́ nípa orúkọ ọlọ́wọ̀ náà.” Wọ́n dara pọ̀ mọ́ ọ̀wọ́ 7,131 míṣọ́nnárì tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, tí wọ́n sì ti ṣèrànwọ́ láti mú iṣẹ́ wíwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbòòrò sí i láti ilẹ̀ 54 ní 1943 dé 233 ilẹ̀ lónìí.
Olùbánisọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e, Lloyd Barry, tí òun pẹ̀lú jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kọkànlá ti Gilead, ó sì ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bíi mísọ́nnárì ní Japan fún ohun tí ó lé ní ọdún 25. Ó fi ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀, “Dúró Nínú Àwọn Nǹkan Wọ̀nyí,” pèsè ìṣírí. Ó sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Ẹ óò rí ọ̀pọ̀ ìdùnnú nínú fífara dà.” Èrè wo ni ó ń wá láti inú lílo ìfaradà nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tàbí nínú iṣẹ́ àyànfúnni ti ìṣàkóso Ọlọ́run èyíkéyìí? “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìfaradà wa ń mú ọkàn àyà Jèhófà yọ̀ . . . A lè rí ìtẹ́lọ́rùn ńláǹlà láti inú pípa ìwà títọ́ mọ́ lábẹ́ ìdánwò . . . Sọ iṣẹ́ míṣọ́nnárì di iṣẹ́ ìgbésí ayé rẹ . . . Èrè rẹ yóò jẹ́ ‘o káre láé’ tí ń mú ọkàn yọ̀.” (Mátíù 25:21; Òwe 27:11) Nígbà tí ó ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá sí òpin, Arákùnrin Barry fi tọkàntọkàn dámọ̀ràn pé kí àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà “dúró nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí” nípa pípinnu láti sọ pápá míṣọ́nnárì di iṣẹ́ ìgbésí ayé wọn.—Tímótì Kíní 4:16.
“Kí Ni Ìwọ Yóò Rí?” ni ìbéèrè tí Karl Adams, tí ó ti nípìn-ín nínú kíkọ́ni ní ọ̀pọ̀ kíláàsì Gilead béèrè. Ó tọ́ka sí i pé ohun tí àwọn míṣọ́nnárì tuntun yóò rí níbi iṣẹ́ àyànfúnni wọn kò sinmi lórí ojú ìyójú wọn nìkan ṣùgbọ́n lórí ojú inú wọn pẹ̀lú. (Éfésù 1:18) Èyí ni a fi ohun tí àwọn amí Ísírẹ́lì rí nígbà tí wọ́n lọ wo Ilẹ̀ Ìlérí ṣàkàwé. Gbogbo amí 12 náà rí ohun kan náà láti ojú ìwòye ti ara, ṣùgbọ́n àwọn méjì péré ni wọ́n rí Ilẹ̀ Ìlérí náà láti ojú ìwòye Ọlọ́run. Àwọn míṣọ́nnárì pẹ̀lú lè wo nǹkan ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀ síra. Ní àwọn ilẹ̀ kan tí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ sìn, wọ́n lè rí òṣì, ìrora, àti àìsírètí. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí wọ́n hùwà pa dà lọ́nà òdì, kí wọ́n sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀. Arákùnrin Adams sọ nípa míṣọ́nnárì kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ yege ni kíláàsì kan láìpẹ́ yìí tí ó sọ pé: “Àwọn ìrírí wọ̀nyí mú kí n mọ̀ pé mo ní láti wà níhìn-ín. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí nílò ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la. Mo fẹ́ mú kí ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i.” Arákùnrin Adams mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá sí òpin nípa fífún àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà ní ìṣírí láti rí ilẹ̀ tí a yàn wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí àgbègbè tí Jèhófà ti pinnu láti sọ di apá kan Párádísè rẹ̀ àgbáyé, kí wọ́n sì ka àwọn ènìyàn tí ń bẹ níbẹ̀ sí àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ ayé tuntun lọ́la.
Wallace Liverance, tí ó ti ṣiṣẹ́ sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún ní pápá míṣọ́nnárì kí ó tó di olùkọ́ni ní Gilead, ni ó sọ ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kẹ́yìn apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí. “Fi Ìjìnlẹ̀ Òye Nínú Àwọn Àgbàyanu Iṣẹ́ Ọlọ́run Hùwà” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀. Fífi ìjìnlẹ̀ òye hùwà wé mọ́ fífi ìmòyemèrò, ìfòyemọ̀, àti làákàyè hùwà. Ìyẹn ni ohun kan tí Ọba Sọ́ọ̀lù ti Ísírẹ́lì kùnà láti ṣe.—Sámúẹ́lì Kíní 13:9-13; 15:1-22.
Ọ̀nà kan láti fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà ni nípa títẹ́wọ́ gba ìpèníjà tí mímú ara ẹni bá ipò ìgbésí ayé tuntun mu bá mú wá, títí kan kíkọ́ èdè tuntun àti sísapá láti dojúlùmọ̀ àwọn ènìyàn. Ìrírí tí àwọn míṣọ́nnárì ní, ní ti kíkojú ìpèníjà àti bíborí àwọn ìṣòro lè fún wọn lókun nípa tẹ̀mí lọ́nà tí a gbà fún Jóṣúà àti Kélẹ́ẹ̀bù lókun bí wọ́n ṣe ṣẹ́gun ilẹ̀ náà tí Ọlọ́run yàn fún wọn.
Ìfọ̀rọ̀ Wáni Lẹ́nu Wò
Apá tí ó tẹ̀ lé e nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ní ọ̀wọ́ ìfọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò nínú. Harold Jackson fọ̀rọ̀ wá Ulysses Glass lẹ́nu wò, akọ̀wé àti olùkọ́ni fún ìgbà pípẹ́ ní Ilé Èkọ́ Gilead, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún 85 nísinsìnyí. Ọ̀pọ̀ míṣọ́nnárì tí wọ́n ṣì wà ní pápá rántí àwọn ọdún tí ó ti fi ìṣòtítọ́ kọ́ni, tí ó sì dáni lẹ́kọ̀ọ́. Mark Noumair ni ọpọ́n sún kàn, olùkọ́ni ní Gilead, tí ó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn ní ilẹ̀ àjèjì ní Áfíríkà kí ó tó di òṣìṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead. Ó fọ̀rọ̀ wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu wò nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní oṣù márùn-ún tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́. Ìrírí wọn fi hàn kedere pé àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà ní ìpínlẹ̀ àdúgbò.
Lẹ́yìn náà, Robert Ciranko àti Charles Molohan bá àwọn ọkùnrin onírìírí tí wọ́n wà ní ilé ẹ̀kọ́ mìíràn ní àwọn ilé náà sọ̀rọ̀, ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka. Ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti fífi kún ìṣọ̀kan ìjọ wà lára ìmọ̀ràn wọn fún kíláàsì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege. Wọ́n sọ pé kò yẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege gbin èrò òdì sọ́kàn nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n múra tán láti tẹ́wọ́ gba ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀. Ó dájú pé fífi ìmọ̀ràn yí sílò yóò ran àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà lọ́wọ́ láti bójú tó iṣẹ́ àyànfúnni wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Paríparí rẹ̀, Theodore Jaracz, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, bá àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà, “Ta Ni Ń Ní Ipa Ìdarí Lórí Ara Wọn?” Ó ṣàlàyé pé nígbà tí àwa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni bá fi èso ti ẹ̀mí hàn, a lè ní ipa rere lórí àwọn ẹlòmíràn. Ó sọ pé: “Àwọn míṣọ́nnárì tí ètò àjọ Jèhófà ti rán jáde ti ní àkọsílẹ̀ tí ó ṣeé gbóríyìn fún ní ti ipa tí wọ́n ní lórí àwọn ènìyàn lọ́nà rere, nípa tẹ̀mí.” Lẹ́yìn náà, ó mẹ́nu kan àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí àwọn tí a ti ràn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ sìn Ọlọ́run nítorí àpẹẹrẹ rere tí àwọn míṣọ́nnárì fi lélẹ̀ ti sọ. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ kí ẹ pa orúkọ rere tí àwọn ènìyàn Jèhófà ti ṣe mọ́, kí ẹ sì máa bá a nìṣó láti kan ilẹ̀kùn àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ibi iṣẹ́ tí a yàn fún un yìn ní ilẹ̀ àjèjì ní wíwá àwọn ẹni yíyẹ kiri . . . Bákan náà, nípa ìwà títọ́, ìwà mímọ́ yin, ẹ dènà ẹ̀mí ayé yìí, kí ẹ sì máa ní ipa rere lórí àwọn ènìyàn sí ìyìn àti ọlá Jèhófà.”
Ní kíkásẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nílẹ̀, alága ka ìkíni tí a fi ránṣẹ́ láti itòsí àti ọ̀nà jíjìn, lẹ́yìn náà, ó fún wọn ní dípílómà wọn, ó sì kéde ibi tí a rán wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ka ìpinnu kíláàsì náà ní sísọ ọpẹ́ wọn jáde fún ìtọ́ni tí a pèsè. Ó ṣe kedere pé, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kejìlélọ́gọ́rùn-ún mú kí gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ túbọ̀ pinnu láti máa tẹ̀ síwájú ní kíkéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Kíláàsì Kejìlélọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Yege
Ní ìlà tí ó wà nísàlẹ̀ yí, a fi nọ́ńbà sí ìlà láti iwájú lọ sí ẹ̀yìn, a sì kọ orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Duffy, C.; Alexis, D.; Harff, R.; Lee, J.; Corey, V.; Nortum, T.; Mora, N.; Journet, F. (2) Djupvik, L.; Singh, K.; Hart, B.; Kirkoryan, M.; Lee, S.; Rastall, S.; Zoulin, K.; Kollat, K. (3) Singh, D.; Pitteloud, J.; Pitteloud, F.; Bokoch, N.; Torma, C.; Muxlow, A.; Richardson, C.; Nortum, D. (4) Harff, J.; Journet, K.; Barber, A.; Loberto, J.; Loberto, R.; Muxlow, M.; Mora, R.; Hart, M. (5) Torma, S.; Rastall, A.; Diaz, R.; Diaz, H.; Weiser, M.; Weiser, J.; Kirkoryan, G.; Zoulin, A. (6) Alexis, R.; Barber, D.; Djupvik, H.; Duffy, C.; Kollat, T.; Richardson, M.; Bokoch, S.; Corey, G.