ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 6/1 ojú ìwé 17-19
  • Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead—“Àwọn Ojúlówó Míṣọ́nnárì!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead—“Àwọn Ojúlówó Míṣọ́nnárì!”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ọpọ Ojihin Iṣẹ Ọlọrun Sii fun Ikore Yika Ayé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ̀mí Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Ló Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Wá sí Gílíádì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 6/1 ojú ìwé 17-19

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead—“Àwọn Ojúlówó Míṣọ́nnárì!”

“TA NI míṣọ́nnárì kan jẹ́?” Ìbéèrè yìí ni ọ̀rọ̀ olóòtú nínú ìwé agbéròyìnjáde kan ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀wádún mẹ́rin sẹ́yìn gbé dìde. Òǹkọ̀wé náà jiyàn pé àwọn míṣọ́nnárì tòótọ́ jẹ́ irinṣẹ́ fún ìṣàtúnṣe ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ọrọ̀-ajé. Bí ó ti wù kí ó rí, ní Sunday, March 5, 1995, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti Jersey City, a fúnni ní ìdáhùn kan tí ó yàtọ̀ pátápátá pẹ̀lú ìtẹnumọ́. Kí ni ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀? Ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kejìdínlọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead ni—ilé-ẹ̀kọ́ tí ó ti rán àwọn míṣọ́nnárì jáde káàkiri ayé!

Lẹ́yìn orin ìbẹ̀rẹ̀ àti àdúrà, Albert D. Schroeder ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso fi tọ̀yàyà tọ̀yàyà kí gbogbo 6,430 ènìyàn tí ó wà ní ìkàlẹ̀ káàbọ̀. Nínú ọ̀rọ̀ ìfáárà rẹ̀, Arákùnrin Schroeder mú ìdí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead fi yàtọ̀ sí àwọn mìíràn tí wọ́n pe ara wọn ní míṣọ́nnárì ṣe kedere. Ó wí pé: “Bibeli ni pàtàkì ìwé-ẹ̀kọ́ fún Gilead.” A kò kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead láti jẹ́, òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, bíkòṣe olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Wọ́n tóótun lọ́nà títayọ láti bójútó àìní tẹ̀mí àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní pápá òkèèrè.

Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀lé e jíròrò lórí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn agbègbè mìíràn nínú èyí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead ti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ “ojúlówó” míṣọ́nnárì. Charles Molohan bá wọn sọ̀rọ̀ lórí kókó-ẹ̀kọ́ náà “Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Síso Èso Àtàtà Gẹ́gẹ́ Bí Míṣọ́nnárì.” Ní fífa àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu yọ ní Kolosse 1:9, 10, Arákùnrin Molohan rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà létí pé oṣù márùn-ún wọn tí ó ti kọjá ní Gilead ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pọ̀ síi “ninu ìmọ̀ pípéye nipa Ọlọrun.” Èyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú èso jáde ní ọ̀nà méjì: nípa mímú èso ẹ̀mí Ọlọrun jáde àti nípa ṣíṣàjọpín àwọn òtítọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.

Daniel Sydlik ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni ó tẹ̀lé e pẹ̀lú ẹṣin-ọ̀rọ̀ tí ń múni ronú jinlẹ̀ náà “Máṣe Fi Ìwàláàyè Rẹ̀ Bánidọ́rẹ̀ẹ́.” Ó mẹ́nu kan ìbéèrè Jesu pé: “Kí ni ènìyàn kan yoo fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?” (Matteu 16:26) Arákùnrin Sydlik wí pé: “Àwọn ènìyàn ti fi ọkàn wọn ṣe pàṣípààrọ̀ fún ìgbésí-ayé tí ó rọrùn, onígbẹ̀fẹ́.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn wọnnì tí ìgbàgbọ́ wọn wà láàyè kò lè juwọ́sílẹ̀ lójú àdánwò tàbí ìdánwò. Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu fi hàn pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ múratán láti “fúnni,” ìyẹn ni pé, kí ó ṣe ìrúbọ, láti lè jèrè ọkàn ara rẹ̀, tàbí ìwàláàyè. A gba àwọn míṣọ́nnárì titun náà níyànjú láti fún Jehofa ní gbogbo ọkàn wọn, kí wọ́n sa gbogbo ipá wọn, nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ̀!

Lẹ́yìn èyí, William Van de Wall ti Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Iṣẹ́-Ìsìn sọ̀rọ̀ lórí kókó-ẹ̀kọ́ náà “Aposteli Paulu—Àpẹẹrẹ Kan Tí Ó Yẹ Láti Ṣàfarawé.” Arákùnrin Van de Wall ṣàlàyé pé: “Paulu mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ọ̀rúndún kìn-ínní.” Lẹ́yìn náà, lọ́nà tí ó bamu wẹ́kú, a pé àfiyèsí sí àwọn agbègbè mẹ́rin nínú èyí tí aposteli Paulu ti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn míṣọ́nnárì lónìí: (1) ojúlówó ìdàníyàn àti ìfẹ́ Paulu fún àwọn ènìyàn, (2) bí ó ṣe gbéṣẹ́ tó nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́, (3) jíjẹ́ oníwọ̀ntunwọ̀nsì tí ó kọ̀ láti gbé ara rẹ ga, (4) ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó dánilójú tí ó ní nínú Jehofa.

“Jẹ́ Kí Jehofa Wádìí Rẹ Wò Nínú Iṣẹ́-Àyànfúnni Rẹ́ Titun” ni kókó-ẹ̀kọ́ tí Lyman A. Swingle ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso jíròrò. Ní lílo ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ ti ọjọ́ náà, Orin Dafidi 139:16, Arákùnrin Swingle sọ pé, gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì titun, wọn yóò dojúkọ ìṣòro nínú iṣẹ́-àyànfúnni wọn àti pé Jehofa mọ ojútùú rẹ̀. Ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ tọ̀ ọ́ lọ, ẹ bá a sọ̀rọ̀ nígbà tí ẹ bá ní ìṣòro. Gbìyànjú láti mọ ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́-inú rẹ̀.”

Lẹ́yìn náà John E. Barr ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ̀rọ̀ lórí kókó-ẹ̀kọ́ náà “Ìgbàgbọ́ Yín Ń Dàgbà Síi Lọ́nà Bíbùáyà.” (2 Tessalonika 1:3) Ní Luku 17:1, a kà pé Jesu wí pé: “Ó jẹ́ ohun tí kò ṣeé yẹ̀sílẹ̀ pé awọn okùnfà ìkọ̀sẹ̀ níláti wá.” Àwọn kan ti kọsẹ̀ nítorí àkópọ̀ ànímọ́ àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n Arákùnrin Barr fún àwọn míṣọ́nnárì náà ní ìṣírí láti ní ìgbàgbọ́ tí wọ́n nílò láti lè dáríjini. Níti tòótọ́, nínú àyíká-ọ̀rọ̀ yìí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ti bẹ̀bẹ̀ pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Luku 17:2-5) Onírúurú àwọn àtúnṣebọ̀sípò níti ìṣètò tún lè dán ìgbàgbọ́ àwọn míṣọ́nnárì wò. Arákùnrin Barr béèrè pé: “A ha ti ní ìgbàgbọ́ láti tẹ́wọ́gba àwọn wọ̀nyí bí, àbí wọn yóò di òkè ìṣòro?”

Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú láti ẹnu àwọn olùkọ Gilead méjì ni ó tẹ̀lé e. Jack Redford rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà láti di ìṣarasíhùwà rere mú. Ó sọ nípa míṣọ́nnárì kan tí ó fi iṣẹ́-àyànfúnni rẹ̀ sílẹ̀ ní ìhùwàpadà sí mímú tí àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mú un bínú. Bí ó ti wù kí ó rí, Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa lòdì sí yíyára bínú láìnídìí. (Oniwasu 7:9) Ó gbaniníyànjú pé: “Ẹ ni ìṣarasíhùwà tí ó tọ́. Ẹ máa fi ìdáríjì hàn fún àṣìṣe àti àìpé àwọn mìíràn tí ó wà ní àyíká yín.”

U. V. Glass, akọ̀wé Gilead, lẹ́yìn náà béèrè pé: “Ẹ ha ti ṣetán láti kojú ‘ìgbà àti ọ̀ràn àìròtẹ́lẹ̀’ bí”? (Oniwasu 9:11, NW) Arákùnrin Glass sọ pé: “Ọ̀nà tí a ń gbà gbé ìgbésí-ayé wa sábà máa ń yípadà, díẹ̀ lára wọn sì lè kó ìdààmú báni gidigidi.” Láìròtẹ́lẹ̀ àwọn míṣọ́nnárì kan ti dojúkọ ìlera tí kò dára, àìsàn, àti ìṣòro ìdílé, tí ó sì sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún àwọn kan láti fi iṣẹ́-àyànfúnni wọn sílẹ̀. Arákùnrin Glass wí pé: “Láìka ohun tí ọ̀ràn àìròtẹ́lẹ̀ náà lè jẹ́ sí, a mọ̀ pé Jehofa mọ̀ ọ́n ó sì bìkítà. Bí a bá gbáralé e, a mọ̀ pé a óò jagunmólú!”

Àwíyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Tí A Yà Sọ́tọ̀ fún Iṣẹ́-Ìsìn Míṣọ́nnárì” ni ó parí ọ̀wọ́ àwọn àwíyé ti òwúrọ̀ náà. Theodore Jaracz ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso dáhùn ìbéèrè tí a gbé dìde ní ìbẹ̀rẹ̀, ìyẹn ni pé, “Ta ni míṣọ́nnárì kan jẹ́?” Ní ìdáhùn, ó jíròrò Ìṣe orí 13 àti 14 nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì ti Paulu àti Barnaba. Ní kedere, iṣẹ́ náà kò darí àfiyèsí sí àwọn ìṣòro ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, bíkòṣe sórí ‘pípolongo ìhìnrere.’ (Ìṣe 13:32) Arákùnrin Jaracz béèrè pé: “Ẹ kò ha gbà pé Paulu àti Barnaba fi irú ẹni tí ojúlówó míṣọ́nnárì níláti jẹ́ hàn bí?” Robert Tracy míṣọ́nnárì onírìírí láti Mexico ni a késí láti ṣàjọpín díẹ̀ lára àwọn ìrírí amọ́kànyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ náà dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí Arákùnrin Schroeder pín dípúlómà fún 48 akẹ́kọ̀ọ́yege. Inú àwùjọ náà dùn púpọ̀ láti gbọ́ orúkọ àwọn ilẹ̀ 21 tí a yan àwọn míṣọ́nnárì náà sí: Barbados, Benin, Bolivia, Central African Republic, Costa Rica, Côte d’Ivoire, Ecuador, Equatorial Guinea, Estonia, Guinea-Bissau, Honduras, Latvia, Leeward Islands, Mauritius, Mozambique, Nicaragua, Paraguay, Peru, Senegal, Taiwan, àti Venezuela.

Lẹ́yìn àkókò ìsinmi fún oúnjẹ ọ̀sán, àwùjọ náà padà sórí ìjókòó wọ́n sì gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ amárayágágá ti Ilé-Ìṣọ́nà, tí Robert P. Johnson ti Ẹ̀ka Iṣẹ́-Ìsìn darí. Àwọn mẹ́ḿbà kíláàsì kejìdínlọ́gọ́rùn-ún náà dáhùn àwọn ìbéèrè náà. Ọ̀wọ́ àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò gbígbádùnmọ́ni tí àwọn mẹ́ḿbà òṣìṣẹ́ Gilead darí ni ó tẹ̀lé e. A fún àwùjọ náà ní ìṣírí ńláǹlà bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ti ń ṣàjọpín àwọn ìrírí wọn ní pápá tí wọ́n sì ń sọ ìmọ̀lára wọn nípa iṣẹ́-àyànfúnni wọn ní ilẹ̀ òkèèrè jáde.

Fún ọdún mẹ́fà àbọ̀, Gilead wà ní ibi ilé lílò Watchtower Society tí ó wà ní Wallkill, New York. Bí ó ti wù kí ó rí, ní April 1995, ilé-ẹ̀kọ́ náà ṣí lọ sí Watchtower Educational Center titun ní Patterson, New York. Báwo ni ìmọ̀lára ìdílé Beteli ní Wallkill ti rí nípa ìyípadà yìí? Ní ibi ìkẹ́kọ̀ọ́yege yìí a fi ọ̀rọ̀ wá díẹ̀ lára àwọn tí ó wá láti Wallkill lẹ́nu wò. Àwọn ọ̀rọ̀ arùmọ̀lárasókè wọn mú kí ó ṣe kedere pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Gilead ti gbin ohun mánigbàgbé kan sí wọn lọ́kàn. Ní kedere, àwọn ọkùnrin àti obìnrin onímùúratán yìí jẹ́ ojúlówó míṣọ́nnárì—onírẹ̀lẹ̀, ẹlẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ, tí wọ́n ń dàníyàn jíjinlẹ̀ nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.

Bí ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà ti ń lọ sí òpin, gbogbo àwọn tí ó wà ní ìkàlẹ̀ ní ìdánilójú pé Ilé-Ẹ̀kọ́ Gilead yóò máa báa nìṣó láti máa ṣàṣeyọrí ohun tí ó ti ń ṣe fún èyí tí ó lé ní 50 ọdún—pípèsè àwọn ojúlówó míṣọ́nnárì!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]

Àkójọ Ìsọfúnni Nípa Kíláàsì:

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 8

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 21

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48

Ìpíndọ́gba ọjọ́-orí: 32.72

Ìpíndọ́gba iye ọdún nínú òtítọ́: 15.48

Ìpíndọ́gba iye ọdún nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 10.91

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Kíláàsì Kejìdínlọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́yege

Nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó wà nísàlẹ̀, a fi nọ́ḿbà sí àwọn ìlà láti iwájú lọ sí ẹ̀yìn, a sì to orúkọ lẹ́sẹẹsẹ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún ní orí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Eszlinger, A.; Mann, T.; Rivera, G.; Baruero, M.; Vaz, M.; Durga, K.; Silweryx, H.; Alvarado, D. (2) Toth, B.; Segarra, S.; Hart, R.; Rooryck, I.; Escobar, P.; Ejstrup, J.; Sligh, L.; Rivera, E. (3) Archard, D.; Snaith, S.; Marciel, P.; Koljonen, D.; Waddell, S.; Blackburn, L.; Escobar, M.; Archard, K. (4) Hart, M.; Toth, S.; Koljonen, J.; Bergman, H.; Mann, D.; Blackburn, J.; Park, D.; Vaz, F. (5) Segarra, S.; Sligh, L.; Leslie, L.; Bergman, B.; Baruero, W.; Alvarado, J.; Leslie, D.; Park, D. (6) Silweryx, K.; Eszlinger, R.; Waddell, J.; Snaith, K.; Durga, A.; Rooryck, F.; Ejstrup, C.; Marciel, D.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́