ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 12/1 ojú ìwé 21-23
  • Ọpọ Ojihin Iṣẹ Ọlọrun Sii fun Ikore Yika Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọpọ Ojihin Iṣẹ Ọlọrun Sii fun Ikore Yika Ayé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ibukun Ẹkọ-iwe Gilead Tankalẹ Kari-aye
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Gileadi Nínú Ìgbàgbọ́ Mímọ́ Jùlọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ẹ̀mí Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Ló Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Wá sí Gílíádì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 12/1 ojú ìwé 21-23

Ọpọ Ojihin Iṣẹ Ọlọrun Sii fun Ikore Yika Ayé

SEPTEMBER jẹ́ oṣu ikore fun awọn àgbẹ̀, ṣugbọn iṣẹ ikore ti o tubọ ṣe pataki ju fa ogunlọgọ nla kan si Gbọngan Apejọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Jersey City, ti ó wà gẹ́lẹ́ lodikeji Odo Hudson lati New York City, ni September 8, 1991. Kilaasi kọkanlelaadọrun-un ti Watchtower Bible School of Gilead ngboyejade. Nǹkan bii 4,263 mẹmba idile Bẹtẹli ati awọn alejo ti a fiwe pe wà nibẹ, pẹlu 1,151 eniyan miiran ti a fi ìlà tẹlifoonu sopọ mọ orile-iṣẹ Brooklyn ati awọn oko ni Wallkill ati Patterson.

Ààrẹ Ile-ẹkọ Gilead, Frederick W. Franz, ti o fi iwọnba ọjọ diẹ din si ẹni ọdun 98 ṣí itolẹsẹẹsẹ naa pẹlu adura ti nwọnilọkan ṣinṣin ti ó fi ọ̀wọ̀ jijinlẹ han. Albert D. Schroeder, mẹmba Ẹgbẹ Oluṣakoso ati olubojuto iforukọsilẹ ati olukọ ile-ẹkọ naa tẹlẹri, ni o ṣe alaga itolẹsẹẹsẹ igboyejade naa. Ó rán awọn awujọ leti nipa Saamu 2:1, 2 ati awọn asọtẹlẹ miiran ti wọn sọtẹlẹ nipa akoko mímì ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ laaarin awọn orilẹ-ede yii. Ipo idarudapọ yii ti tumọsi ṣiṣi ọpọlọpọ awọn papa titun silẹ fun iṣẹ ikore naa.

Ọrọ asọye akọkọ ti ọjọ naa ni a sọ lati ẹnu George M. Couch, mẹmba Igbimọ Bẹtẹli kan. Ẹṣin ọrọ rẹ̀ ni “Ẹ Ka Awọn Ibukun Yin.” Ó rán awọn akẹkọọ Gilead naa leti pe kò figba kan rí yá ju lati bẹrẹ iṣe aṣa yii. Ó sọ pe awọn akẹkọọ naa funraawọn ni a ti bukun dajudaju ṣugbọn pe awọn ibukun wọnyi ti wá kiki lẹhin ọpọlọpọ iṣẹ aṣekara. Bakan naa, Jakọbu ẹni ọdun 97 jijakadi ni gbogbo òru pẹlu angẹli kan—gbogbo rẹ̀ nititori gbigba ibukun. (Jẹnẹsisi 32:24-32) Arakunrin Couch rọ awọn akẹkọọ naa lati maṣe fayegba awọn ironu odi ṣugbọn lati di ibukun fun awọn ẹlomiran nipa mimu alaafia ọkàn dagba nipasẹ adura ati ipinnu.

John E. Barr ti Ẹgbẹ Oluṣakoso sọrọ tẹle e lori ẹṣin ọrọ naa “Ẹ Ni Ifẹ Laaarin Araayin.” Awọn ọmọlẹhin Jesu muratan lati kú fun araawọn ẹnikinni keji. “Ẹyin ha nimọlara pe iru ifẹ yii ńrú jade ninu ọkan-aya yin bi?” ni ó beere lọwọ awọn akẹkọọ naa. Ó sọ pe, ‘laisi ifẹ yii, a kò jẹ́ ohunkohun. Kò ju bẹẹ lọ.’ (1 Kọrinti 13:3) Arakunrin Barr ṣetolẹsẹẹsẹ awọn ọna gbigbeṣẹ kan lati fi ifẹ han. Ó fun awọn akẹkọọ naa niṣiiri lati ba awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ẹlẹgbẹ wọn lo pẹlu ọ̀wọ̀, ni wíwá ọna ọgbọn-ẹwẹ nigba gbogbo lati sọ awọn nǹkan. Ó gbà wọn nimọran pe, ‘ẹ gbagbe awọn ọran ti kò tó nǹkan,’ ni fifa ọ̀rọ̀ 1 Peteru 4:8 yọ. Ó ṣakiyesi pe awọn ọjọ ounjẹ sise ti awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun paapaa jẹ́ akoko ti wọn lè fi ifẹ han nipa wiwo iṣẹ naa gẹgẹ bi eyi ti ó ju iṣẹ alafaraṣe lasan lọ. Ó rán awọn akẹkọọ naa leti pe: “A kò dẹkun jíjẹ awọn arakunrin ati arabinrin wa ni gbese ifẹ lae.”—Roomu 13:8.

“Bawo Ni O Ṣe Nigbọkanle Tó?” ni ẹṣin ọrọ fifanilọkan mọra tí David A. Olson ti Igbimọ Ẹka Iṣẹ-isin sọrọ lé lori. Ó tẹnumọ agbegbe meji ti igbọkanle: ninu Jehofa ati eto-ajọ rẹ̀, eyi ti a ni ailonka awọn idi fun (Owe 14:6; Jeremaya 17:8); ati ninu ara-ẹni. Awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ni idi fun iwọn igbọkanle ara-ẹni, iru bii ipilẹ wọn gẹgẹ bi ojiṣẹ ati igbẹkẹle ti Jehofa ati eto-ajọ rẹ̀ ni ninu wọn. Apọsiteli Pọọlu fi iru igbọkanle fun awọn idi ti o farajọ eyi han. (1 Kọrinti 16:13; Filipi 4:13) Bi o ti wu ki o ri, Arakunrin Olson kilọ lodisi idara ẹni loju jù ti ayé ngbe lárugẹ, gẹgẹ bi a ti ṣapẹẹrẹ rẹ̀ nipasẹ onkọwe olokiki kan ẹni ti a rohin rẹ̀ pe o sọ pe: “Mo ngba ọrọ araami sọ niye igba. Ó nfi adidun kún ijumọsọrọpọ mi.” Bi o ti wu ki o ri, igbọkanle ti a mu wà deedee pẹlu irẹlẹ lè tanna ran igbọkanle ninu awọn ẹlomiran. Dajudaju eyi jẹ́ otitọ ninu ọran Pọọlu.—Filipi 1:12-14.

Lyman A. Swingle ti Ẹgbẹ Oluṣakoso ṣí awọn akẹkọọ naa létí tẹle e: “Ẹ Lọ Sinu Pápá Ti A Nilati Kore, Ẹyin Akẹkọọyege Gilead!” Ó sọ pe eyi jẹ́ ọjọ ikore fun Ile-ẹkọ Gilead ati fun ẹgbẹ́ ará kari aye, bi awọn akẹkọọyege yoo ti jade lọ ti wọn yoo sì darapọ mọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn akẹkọọyege ti iṣaaju ti wọn ṣì wà lẹnu iṣẹ ojihin iṣẹ Ọlọrun—awọn kan lati kilaasi akọkọ, ekeji, ati ẹkẹta ti awọn ọdun 1940! Arakunrin Swingle kiyesi pe nigba naa lọhun-un kò sí ẹnikankan ti ó mọ pe iṣẹ ojihin iṣẹ Ọlọrun yoo maa baa lọ fun 50 ọdun miiran, tabi pe ijọba Nazi, Fascist, ati awọn idena miiran si iṣẹ wiwaasu lati ọwọ ijọba yoo wolulẹ. Ó beere pe, “bi a ba ni ibẹru ọlọwọ lori ohun ti Jehofa Ọlọrun ti ṣe nigba ti ó ti kọja, ki ni nipa ọjọ-ọla?” Ó pari ọrọ rẹ̀ pẹlu ikesini arunisoke si awọn akẹkọọ naa pe: “Ẹ Lọ Si Pápá!”

Awọn olori olutọni meji fun Ile-ẹkọ Gilead ba kilaasi kọkanlelaadọrun-un sọrọ lẹhin naa fun ìgbà ikẹhin. Jack D. Redford sọrọ lori ẹṣin ọrọ naa “Ẹ Gba Imọ.” Ó sọ fun awọn akẹkọọ naa pe, Ile-ẹkọ Gilead ńkọ́ni ni imọ ati oye, ṣugbọn wọn gbọdọ gba ọgbọn, lile lo imọ wọn ni ọna ti ó tọ́. Ó rọ awọn akẹkọọ naa lati pa igbagbọ atọwọdọwọ naa pe wọn ti kọ gbogbo ohun ti ó yẹ ni kíkọ́ ni Gilead tì. “Ohun ti ẹ kọ lẹhin ile-ẹkọ naa ni ó ṣe pataki.” Lara ohun ti wọn gbọdọ mọ sibẹ ni: lati ba awọn eniyan lò pẹlu alaafia, jijẹ ẹni ti ó lè sọ pe “foriji mi” fun alabaaṣegbeyawo, fun awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ẹlẹgbẹ wọn, ati fun awọn arakunrin ati arabinrin adugbo; ẹ mọ bi a tii ṣọra nipa gbigbẹkẹle irisi akọkọ ati lati mọ pe olukuluku iṣoro ni ó lọjupọ, ti nbeere oye awọn ayika ipo ti ó jinlẹ ṣaaju fifunni ni imọran ọlọgbọn; ati lati bọwọ fun awọn arakunrin adugbo fun agbara ti wọn ni lati ṣe akoso awọn ipo ayika ti ó ṣoro.—Owe 15:28; 16:23; Jakobu 1:19.

Ulysses V. Glass, olubojuto iforukọsilẹ fun Ile-ẹkọ Gilead, fi Filipi 3:16 ṣe ẹṣin ọrọ asọye rẹ̀. Ó gboriyin fun kilaasi naa fun itẹsiwaju ti wọn ti ni ó sì gba wọn niyanju lati maa baa lọ ni oju ìlà pẹlu iwe mimọ yẹn. Nigba ti awọn akẹkọọ naa nilati maa baa lọ ni gbigba imọ pipeye, ó ṣakiyesi pe, wọn kò le mọ ohun gbogbo tan lae. Ó ṣapejuwe koko naa pẹlu aago ọrun ọwọ ti ó maa ngbe nọmba nikan yọ. Ẹni ti ó ni ín lè mọ bi ó ṣe lè mu un ṣiṣẹ laimọ bi ó ti nṣiṣẹ gan-an. Bakan naa, awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun kò gbọdọ foju tín-ín-rín awọn wọnni ti wọn lè ma ni imọ ti o jinlẹ tó wọn, ṣugbọn sibẹ ti wọn mọ ohun ti ó ṣe pataki—bi a tii bẹru Jehofa. (Owe 1:7) Ó rán kilaasi naa leti ijẹpataki pipa ‘oju aláìgùn’ mọ.’ (Matiu 6:22, NW) Oju tẹmi ni a lè dí lọwọ gan-an gẹgẹ bi a ti lè ṣe si oju ti ara. Fun apẹẹrẹ, awọn kan ni oju-iwoye ti kò gbooro—ti ó jẹ́ eyi ti ó nko afiyesi jọ kiki sori kulẹkulẹ diẹ lati ri gbogbo aworan naa—nigba ti awọn miiran, ni idakeji, rí kiki awọn ọran ti ó farahan ti a kò sì pín ọkàn wọn niya lae kuro ninu awọn ọran pataki ti wọn nilati bojuto.

Ọrọ ti ó kẹhin ni owurọ ni a pe ni “Dídámọ̀ Ati Ṣíṣiṣẹ́ Pẹlu Eto-ajọ Jehofa,” ti Theodore Jaracz ti Ẹgbẹ Oluṣakoso sọ. Arakunrin Jaracz sọ pe nigba ti ó jẹ́ pe ẹgbẹẹgbẹrun eto-ajọ ati ẹgbẹ́ awujọ ni wọn wà ninu aye, kiki ọ̀kan ninu awọn wọnyi ni ko pilẹṣẹ pẹlu ayé. Bawo ni a o ti da eyi ti nṣoju fun Jehofa mọ? Ọrọ Ọlọrun pese awọn ami idanimọ naa. Bibeli fihan pe iṣẹda ti ọrun rẹ̀ ni a ṣetojọ lọna giga. (Saamu 103:20, 21; Aisaya 40:26) Eto-ajọ Jehofa ti ori ilẹ-aye ni a tun lè dá mọ̀ nipa iwaletoleto rẹ̀ ati bakan naa nipa yiya sọtọ gedegbe kuro ninu ayé, rirọ timọtimọ mọ awọn ilana Bibeli rẹ̀, ipele giga ti ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ niti ọna iwahihu, ati ifẹ laaarin awọn mẹmba rẹ̀. Arakunrin Jaracz rọ awọn akẹkọọ Gilead lati ran ọpọlọpọ bi ó ba ti lè ṣeeṣe tó lọwọ ni ibi ti a yan wọn sí lati da eto-ajọ Jehofa mọ̀ lọna ti ó ba Iwe mimọ mu. Ni isopọ pẹlu iyẹn, ó ṣe ifilọ arunisoke kan pe: Ile-ẹkọ Gilead ni yoo pọ sii ni ilọpo meji laipẹ si nǹkan bii 50 akẹkọọ ni kilaasi kẹtalelaadọrun-un! Pẹlupẹlu, Imugbooro Ile-ẹkọ Gilead ni Germany yoo bẹrẹ ni nǹkan bi akoko kan naa. Atẹwọ lọ rẹrẹ ó sì dun ketekete!

Gẹgẹ bi ipari owurọ naa, gbogbo awọn akẹkọọ 24 ti Gilead gba iwe ẹ̀rí. Laipẹ wọn yoo wà ni oju ọna wọn lọ si orilẹ-ede 12 ọtọọtọ yika ayé. Kilaasi naa gbe ipinnu atọkanwa kan kalẹ, ni didupẹ lọwọ Ẹgbẹ Oluṣakoso ati idile Bẹtẹli. Lẹhin ounjẹ ọsan, Arakunrin Charles J. Rice ti Igbimọ Oko Watchtower dari Ikẹkọọ Ilé-ìṣọ́nà ti a ké kuru. Lẹhin naa awọn akẹkọọyege naa ṣeto fun itolẹsẹẹsẹ kan ti ó jípépé, ni ṣiṣe aṣefihanni diẹ lara awọn iriri ti wọn ní ninu iṣẹ-isin pápá lakooko idanilẹkọọ oloṣu marun-un wọn ni Wallkill, New York. Lẹhin iyẹn, awọn akede ti wọn ṣoju fun awọn ijọ adugbo melookan gbe awokẹkọọ kan kalẹ ti akọle rẹ jẹ́ Awọn Ewe Ti Wọn Ranti Ẹlẹdaa Wọn Nisinsinyi.

Lati pari itolẹsẹẹsẹ naa, Arakunrin George Gangas, ẹni ọdun 95 ti ó jẹ́ mẹmba Ẹgbẹ Oluṣakoso, gba adura atanijipẹpẹ si Jehofa bi ó ti maa nṣe. Awọn awujọ naa lọ pẹlu ẹmi yiyagaga, ẹnikọọkan laiṣiyemeji ni a sun lati ni ipin ti ó tubọ npọ sii ninu iṣẹ ikore kari ayé naa.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Awọn Akojọ Isọfunni Nipa Kilaasi

Iye awọn orilẹ-ede ti a ṣoju fun: 6

Iye awọn orilẹ-ede ti a pin wọn si: 12

Iye awọn akẹkọọ: 24

Iye awọn tọkọtaya: 12

Ipindọgba ọjọ-ori: 33.4

Ipindọgba iye ọdun ninu otitọ: 16.13

Ipindọgba iye ọdun ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun: 11.3

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kilaasi kọkanlelaadọrun-un ti Ngboyejade ti Watchtower Bible School of Gilead

Ninu akọsilẹ lẹsẹẹsẹ ni isalẹ, awọn ìlà ni a to nọmba rẹ̀ lati iwaju lọ sẹhin a sì to awọn orukọ lẹsẹẹsẹ lati osi si ọtun ni ìlà kọọkan.

(1) McDowell, A.; Youngquist, L.; Skokan, B.; Wargnier, N.; Miller, Y.; Muñoz, M. (2) Bales, M.; Perez, D.; Attick, E.; Vainikainen, A.; Mostberg, K. (3) DePriest, D.; DePriest, T.; Perez, R.; Wargnier, J.; Muñoz, J.; Miller, J. (4) McDowell, S.; Bales, D.; Skokan, M.; Attick, C.; Youngquist, W.; Vainikainen, J.; Mostberg, S.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́