Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Gileadi Nínú Ìgbàgbọ́ Mímọ́ Jùlọ
“ÀWỌN akẹ́kọ̀ọ́ wa ní a ti dálẹ́kọ̀ọ́ dáradára nínú ìgbàgbọ́ mímọ́ jùlọ.” Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí ìbẹ̀rẹ̀ níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì karùndínlọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead, tí a ṣe ní ọjọ́ Sunday, September 12, 1993. Àwọn 4,614 àlejò tí a fìwé pè àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Beteli tí wọ́n kórajọpọ̀ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ Jersey City ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn ni George Gangas ṣaájú nínú àdúrà ìbẹ̀rẹ̀. Arákùnrin Gangas ti jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé Beteli fún ọdún 65 àti ní ẹni ọdún 97 òun ni mẹ́ḿbà tí ó dàgbà jùlọ nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso.
Albert Schroeder, ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso àti alága fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, sọ pé: “Fún oṣù márùn-ún ìtòlẹ́sẹẹsẹ-ẹ̀kọ́ Gileadi ní a ti gbékarí ìgbàgbọ́ mímọ́ jùlọ.” Ṣùgbọ́n kí ni “ìgbàgbọ́ mímọ́ jùlọ” náà? Ó ṣàlàyé pé “ìgbàgbọ́ mímọ́ jùlọ” yìí, tí a mẹ́nukàn ní Juda 20, ni gbogbo òtítọ́ inú Bibeli pátá. Nítorí náà ìtòlẹ́sẹẹsẹ-ẹ̀kọ́ Gileadi ni a gbékarí Ọ̀rọ̀ Jehofa, Bibeli, tí ó jẹ́ olórí ìwé-ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Gba Ìtọ́ni Síwájú Síi
John Stuefloten ti Ìgbìmọ̀ Oko Watchtower tí ó sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Jíjàǹfààní Láti Inú Agbára-Ìdarí Àwọn Ọlọgbọ́n Ènìyàn,” ni olùbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́. Bibeli wí pé àwọn wọnnì tí “ń bá ọlọgbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Owe 13:20) Nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ-ẹ̀kọ́ Gileadi náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lo ohun tí ó rékọjá 900 wákàtí fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Arákùnrin Stuefloten bi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ léèrè pé: “Báwo ni agbára-ìdarí Jehofa yóò ṣe nípa lórí yín ní ọjọ́-iwájú? Ẹ ń lọ sí orílẹ̀-èdè 18 tí ó ní àpapọ̀ iye olùgbé tí ó tó nǹkan bíi 170 million ènìyàn. Nítorí náà báwo ni ẹ óò ṣe nípa lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn?” Nípa ríronú síwá-sẹ́yìn lórí ọgbọ́n Jehofa, àwọn míṣọ́nnárì titun náà yóò lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti di olùjọ́sìn Jehofa, Orísun ọgbọ́n tí kò ní ààlà.
“Dídi Ohun Gbogbo fún Gbogbo Ènìyàn” tí Lloyd Barry ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ̀rọ̀ lélórí, ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lée. (1 Korinti 9:22) Ní nǹkan bíi ọdún 45 sẹ́yìn, Arákùnrin Barry fúnraarẹ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní kíláàsì kọkànlá ti Gileadi. Nísinsìnyí kíláàsì karùndínlọ́gọ́rùn-ún mọrírì gbígba ìtọ́ni gbígbéṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀rí kan tí ó ní ọ̀pọ̀ ọdún ìrírí ní ilẹ̀ àjèjì yìí. Ó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí láti tètè fi ara wọn sípò àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní ìpínlẹ̀ wọn titun ní ilẹ̀ òkèèrè nípa mímọ̀ nípa àwọn àṣà àdúgbò àti kíkọ́ èdè ìbílẹ̀. Ó sọ pé wọ́n lè ṣe èyí lọ́nà dídára jùlọ nípa dídarapọ̀ mọ́ àwọn ará àdúgbò àti bíbá wọn ṣíṣẹ àti pẹ̀lú nípa kíkọ́ àṣà wọn àti mímú un lò nígbàkigbà tí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀.
Tẹ̀lée, Dean Songer ti Ìgbìmọ̀ Ilé-Iṣẹ́-Ẹ̀rọ sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ fífanimọ́ra náà “A Sọ Yín Dòmìnira Kúrò Lẹ́nu Ìlà-Iṣẹ́.” Lẹ́yìn ohun tí ó ju ọdún 35 nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún, Arákùnrin Songer lóye ohun tí ó túmọ̀sí láti gbé ìgbésí-ayé tí ó kó àfiyèsí jọ sórí góńgó pàtó kan, tí kò lọ́júpọ̀, ní pípọkànpọ̀ sórí iṣẹ́ tí ó wà lọ́wọ́, tí ó bọ́ lọ́wọ́ àwọn àníyàn ohun ti ara. Ìyẹn sì ni olórí ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀ràn rẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Àwọn akọrin nínú tẹ́ḿpìlì Jehofa ni a sọ dòmìnira kúrò lẹ́nu àwọn ìlàiṣẹ́ tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi mìíràn kí wọ́n baà lè fí araawọn jìn fún àkànṣe iṣẹ́-àyànfúnni wọn lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. (1 Kronika 9:33) Ní ìfarajọra, àwọn mísọ́nnárì Gileadi ni a ti sọ dòmìnira kúrò lẹ́nu irú àwọn kókó-ọ̀ràn lásán bíi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kí wọ́n baà lè pọkànpọ̀ sórí àkànṣe iṣẹ́-ìsìn wọn. Arákùnrin Songer fi ìṣílétí yìí parí ọ̀rọ̀ pé: “Ẹ kó ojú-ìwòye yín nípa ìgbésí-ayé jọ sórí góńgó pàtó kan kí ìgbésí-ayé yín má sì lọ́júpọ̀. Ẹrù-iṣẹ́ yín gẹ́gẹ́ bí àwọn wọnnì tí a sọ dòmìnira kúrò lẹ́nu ìlà-iṣẹ́ ni láti wà lẹ́nu iṣẹ́ náà lọ́sàn-án àti lóru, ní yíyin Jehofa.”
Daniel Sydlik mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni ó tẹ̀lée pẹ̀lú ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Kíkọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbádùn Ìgbésí-Ayé Jùlọ.” Ó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí “kìí ṣe láti kọ́ni ní ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ nìkan ni ṣùgbọ́n láti jẹ́ aláìṣojo tó láti fi ohun tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣe láti mú ìgbésí-ayé wọn bá ìfẹ́-inú Ọlọrun mu hàn wọ́n.” Àwọn olùkọ́ rere gbọ́dọ̀ tanijí kí wọ́n sì runisókè. “Ẹ jẹ́ kí àìní láti kọ́ àwọn ènìyàn láti mú ìlànà ìwàrere Kristian dàgbà jẹ yín lọ́kàn dípò wíwulẹ̀ kọ́ni ní àwọn òfin àti ìlànà,” ní ó sọ tí ó sì fikún un ní ìparí pé: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ̀yin ará ọ̀wọ́n, ẹ kọ́ araayín kí ẹ sì kọ́ àwọn ẹlòmíràn bí a tií ní ìfẹ́, nítorí pé òun ni àmùrè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—1 Korinti 13:1-3; Kolosse 3:14.
Lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀ oṣù, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà mú ìfẹ́ gíga dàgbà ní pàtàkì fún àwọn olùkọ́ wọn méjì ní Gileadi. Jack Redford, tí òun fúnraarẹ̀ jẹ́ míṣọ́nnárì kan tẹ́lẹ̀rí, kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Ti Ṣe Yíyàn tí Ó Tọ̀nà.” Ní ayé àwọn Ju ìgbàanì, ṣáájú dídi Kristian aposteli kan, Paulu ní ipò, iyì, agbára-ìdarí, àti ààbò níti ọ̀ràn-ìnáwó. Ṣùgbọ́n ní Fillipi 3:8, Paulu ṣàpèjúwe gbogbo èyí gẹ́gẹ́ bíi “ìgbẹ́,” tàbí “pàǹtírí,” ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ Phillips. Ọkàn rẹ̀ wà nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà, ó sì ṣe yíyàn tí ó tọ̀nà. Ní ìfiwéra, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú aráyé lónìí fihàn nípa yíyàn wọn nínú ìgbésí-ayé pé àwọn ka àwọn ohun-ìní wọn nípa ti ara sí èyí tí ìníyelórí rẹ̀ túbọ̀ ga ju ìyè àìnípẹ̀kun lọ. Àwọn míṣọ́nnárì Gileadi ti ṣe yíyàn tí ó tọ̀nà. Jack Redford parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Kò sí ohun tí ayé Eṣu lè nawọ́ rẹ̀ sí yín tí ó tó ohun tí ẹ lè fi wé iṣẹ́-ìsìn míṣọ́nnárì. Ẹ bójútó àǹfààní aláìṣeédíyelé yẹn, kí ẹ sì jẹ́ kí ayé bójútó pàǹtírí rẹ̀!”
Fún ọdún 32 tí ó ti kọjá, Ulysses Glass ti jẹ́ olùkọ́ ní Gileadi. Ó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìmọ̀ràn ìdágbére díẹ̀ pẹ̀lú ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Ọlọrun Nìkan ni Ó lè Ṣẹ̀dá Igi Kan,” ní gbígbé ọ̀rọ̀-àsọyé rẹ̀ karí Orin Dafidi 1:3. Kò tíì ṣeéṣe fún ọgbọ́n-iṣẹ́-ẹ̀rọ òde-òní rí láti ṣe ẹ̀dà igi kan, tí Ọlọrun wéwèé. Ní ọ̀nà kan, àwọn Kristian tòótọ́ dàbí àwọn igi, tí Jehofa gbìn tí ó sì ń bomirin. Arákùnrin Glass ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni a ti ń “fomirin déédéé láti inú ojúsun àwọn omi afúnni-ní-ìyè tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun,” bíi àwọn igi nínú igbó ṣúúrú tàbí paradise tẹ̀mí fún oṣù márùn-ún. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, wọ́n gbọ́dọ̀ dáàbobo “ètò-ìṣiṣẹ́ gbòǹgbò-igi tẹ̀mí wọn kúrò lọ́wọ́ jàm̀bá èyíkéyìí.” A gbà wọ́n níyànjú láti ‘máa mu omi ìyè láti ọ̀dọ̀ Jehofa nìṣo nítorí pé Ọlọrun nìkanṣoṣo ni ó lè ṣẹ̀dá igi kan.’
Carey Barber, mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni ó sọ ọ̀rọ̀ àsọkágbá. Lẹ́yìn 70 ọdún nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún, Arákùnrin Barber lè fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà “Fún Jehofa ní Ìfọkànsìn tí A Yàsọ́tọ̀ Gedegbe.” Ọ̀pọ̀ jaburata nínú aráyé kò tíì fún Jehofa ní ìfọkànsìn tí a yàsọ́tọ̀ gedegbe. (Deuteronomi 5:9) Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí Arákùnrin Barber ti fihàn, láìka àìpé wa sí, “ó rọrùn gbáà láti farajìn pátápátá fún Ọlọrun.” Ó fikún un pé: “Kò sí ẹni tí ó lè sọ níti gidi pé: ‘Eṣu ni ó mú mi ṣe é.’” Ṣùgbọ́n Eṣu lè ṣẹ́gun wa bí a bá kùnà láti gbéjàkò ó. (Jakọbu 4:7) Mímú ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ Jehofa ni ọ̀nà tí ó gba iwájú jùlọ tí a lè gbà gbéjàko Satani àti ayé rẹ̀ kí a sì fún Jehofa ní ìfọkànsìn tí a yàsọ́tọ̀ gedegbe.
A Yàn Wọ́n Gẹ́gẹ́ bíi Míṣọ́nnárì
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti òwúrọ̀ wá sí ìparí pẹ̀lú yíyan iṣẹ́ fún gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 46 náà lọ́nà tí a fàṣẹ sí gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Àwọn tọkọtaya 23 náà gba ìwé-ẹ̀rí tí ó sọ lápákan pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà “tóótun lọ́nà àkànṣe láti lọ́wọ́sí iṣẹ́ onímọ̀-ẹ̀kọ́, ní mímú ìfẹ́-inúrere tẹ̀síwájú àti ṣíṣiṣẹ́ fún ire àlàáfíà pípẹ́títí àti òfin ètò àti òdodo pípé láàárín gbogbo ènìyàn.” Ó dájú pé kíláàsì karùndínlọ́gọ́rùn-ún ti Gileadi yóò sakun láti ṣàṣeparí iṣẹ́-àpèrán tí a gbéga yìí ní àwọn orílẹ̀-èdè 18 tí a ti yàn wọ́n sí. Àwọn iṣẹ́ àyànfúnni náà gbòòrò la ayé já ó sí ní àwọn orílẹ̀-èdè ní Asia, Africa, Europe, Latin America, àti Caribbean nínú.
Ní ọ̀sán, lẹ́yìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìsọ́nà tí a kékúrú tí Charles Woody ti Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka-Iṣẹ́ Iṣẹ́-Ìsìn darí, àwọn àkẹ́kọ̀ọ́yege Gileadi titun náà ṣe ìgbékalẹ̀ ìtòlẹ́ṣẹẹsẹ akẹ́kọ̀ọ́ wọn, pẹ̀lú ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Gileadi ti Múra Wa Sílẹ̀ Láti Kọ́ni Gẹ́gẹ́ bíi Míṣọ́nnárì.” Àkókò-ìjókòó náà wá sí ìparí pẹ̀lú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà “Àwọn Yíyàn tí Ó Dojúkọ Wá.”
Lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń runisókè yìí, àwọn míṣọ́nnárì titun náà ti ṣetán nísinsìnyí láti di ẹni tí a rán lọ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé láti ṣàjọpín “ìgbàgbọ́ mímọ́ jùlọ” náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn Àkójọ Ìsọfúnni Nípa Kíláàsì
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 7
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 18
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 46
Iye àwọn tọkọtaya: 23
Ìpíndọ́gba ọjọ́-orí: 30.06
Ìpíndọ́gba iye ọdún nínú òtítọ́: 12.92
Ìpíndọ́gba iye ọdún nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 9.4
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kíláàsì Karùndínlọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́yege
Nínú àkọsílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ ní ìsàlẹ̀, àwọn ìlà ni a tò láti iwájú lọ sẹ́yìn a sì to àwọn orúkọ lẹ́sẹẹsẹ láti òsì sí ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Buelow, D.; Donzé, V.; Innes, S.; Fulk, N.; Billingsby, M.; Hoddinott, L.; Nygren, B.; Eriksson, L. (2) Boker, J.; Thomas, M.; Stedman, S.; Billingsby, D.; Waugh, I.; Purves, M.; Luttrell, M. (3) Jacobsen, T.; Boker, J.; Martínez, L.; Nilsson, E.; Purves, P.; Holt, L.; Larsen, M.; Jones, L. (4) Numminen, P.; Numminen, H.; Buelow, M.; Olson, W.; Holt, S.; Donzé, G.; DesJardins, C.; DesJardins, D. (5) Larsen, K.; Martínez, D.; Nygren, P.; Waugh, P.; Jones, D.; Hoddinott, J.; Thomas, G. (6) Innes, B.; Fulk, R.; Eriksson, A.; Nilsson, S.; Stedman, J.; Olson, K.; Jacobsen, F.; Luttrell, J.