ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 6/1 ojú ìwé 23-27
  • Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead Kówọnu Ọna Igbesi-aye kan Ti Ńmú Èrè Wá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead—“Àwọn Ojúlówó Míṣọ́nnárì!”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ọpọ Ojihin Iṣẹ Ọlọrun Sii fun Ikore Yika Ayé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà Kí Ẹ Sì Kún fún Ìdùnnú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 6/1 ojú ìwé 23-27

Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!

“IBI pupọ ni o wà ti a kò tíì funni ni ijẹrii nipa Ijọba naa dé ìwọ̀n kan ti o tobi,” ni N. H. Knorr sọ fun kilaasi Gilead akọkọ ní February 1, 1943, ti o jẹ́ ọjọ ti a ṣí ile-ẹkọ naa. Ó fikun un pe: “Ọgọrọọrun ati ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan sii gbọdọ wà ti a lè dé ọ̀dọ̀ wọn bi awọn oṣiṣẹ pupọ sii bá wà ni pápá. Nipa oore-ọfẹ Oluwa, pupọ sii yoo wà.”

Awọn òṣìṣẹ́ pupọ sii sì ti wà—araadọta-ọkẹ sii! Òtú awọn akede Ijọba ti ga sii lati 129,070 ni ilẹ 54 ni 1943 si 4,472,787 ni ilẹ 229 ni 1992! Ile-Ẹkọ Gilead ti pakún ijẹrii naa ti o wá yọrisi ibisi yẹn gidigidi. Lẹhin 50 ọdun ó ń baa lọ lati maa kó ipa pataki ninu dídá awọn oṣiṣẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lẹkọọ lati ṣiṣẹsin nibikibi ti a bá ti nilo wọn ninu pápá àgbáyé.

Ni March 7, 1993, 4,798 awọn alejo ti a fìwé pè ati awọn mẹmba idile Beteli U.S. ni wọn kora jọ ni Gbọngan Apejọ Jersey City, ni New Jersey, fun ikẹkọọyege ti kilaasi kẹrinlelaadọrun-un. Akoko iṣẹlẹ ti o jẹ́ akanṣe nitootọ yii tun pese anfaani lati wẹhin wo 50 ọdun Ile-Ẹkọ Gilead. Iwọ yoo ha fẹ́ lati mọ diẹ nipa itolẹsẹẹsẹ naa bi?

Lẹhin orin ibẹrẹ, George D. Gangas ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso gba adura gbigbona janjan kan. Tẹlee, lẹhin ọ̀rọ̀ àkọ́sọ lati ẹnu alaga, Carey W. Barber, awọn akẹkọọyege naa—ati gbogbo awọn ti wọn wà ni ijokoo—fetisilẹ tiṣọratiṣọra si ọ̀wọ́ awọn ọrọ-asọye kukuru.

Robert W. Wallen ni o kọkọ sọrọ, lori ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Kò Danikan Wà Lae.” Pẹlu ohùn ti ó jí pépé, ó sọ pe: ‘Ni awọn ọjọ ti ń bẹ niwaju, awọn ipo yoo dide ninu igbesi-aye yin nigba ti ẹ o nimọlara pe ẹ danikan wà gan-an, pe ẹ jinna réré si idile ati awọn ọ̀rẹ́.’ Bawo, nigba naa, ni a ṣe lè sọ pe, “Ẹ kò danikan wà lae?” Ó ṣalaye pe: ‘Nitori pe larọọwọto olukuluku yin ni ṣiṣeeṣe naa lati jumọsọrọpọ loju-ẹsẹ pẹlu Jehofa Ọlọrun yoo wà.’ Ó rọ awọn akẹkọọyege naa lati ṣìkẹ́ anfaani adura ki wọn sì lò ó lojoojumọ. Nigba naa, bi Jesu, wọn yoo lè sọ pe, ‘emi kò danikan wà.’ (Johannu 16:32) Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ti jẹ́ afunni niṣiiri tó fun awọn akẹkọọyege naa!

Ni sisọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Di Ireti Yin Mú Ṣinṣin” (ti a gbekari ẹsẹ-iwe ojoojumọ ti March 7), Lyman A. Swingle ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso sọrọ tẹlee lori aini naa fun awọn animọ meji—ifarada ati ireti. ‘Ẹ̀gàn, ìkóguntini, ikoriira, ifinisẹwọn, àní ikú paapaa, jẹ́ idi ti a fi nilo ifarada niha ọ̀dọ̀ awọn Kristian,’ ni o sọ. ‘Okun naa ti o rekọja eyi ti o mọniwọn eyi ti awọn Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ ti Jehofa lè fi gbéra ni awọn akoko aini kò ni ipẹkun. Eyi dajudaju múnilọ́kàn le, ni pataki ẹyin akẹkọọyege.’ Ki ni nipa ti ireti? ‘Ireti jẹ́ kòṣeémánìí,’ ni o ṣalaye. ‘Gẹgẹ bi aṣibori ti ń daabobo ori ẹni ti ó wọ̀ ọ́, bẹẹ ni ireti igbala ṣe ń ṣọ́ ti o sì ń daabobo awọn agbara ero-ori Kristian, ni mimu ki o ṣeeṣe fun un lati pa iwatitọ mọ.’—1 Tessalonika 5:8.

Olubanisọrọ ti o tẹlee, Ralph E. Walls, yan ẹṣin-ọrọ fifanimọra kan, “Bawo Ni A Ṣe Lè Salọ si Inu Ààbò ‘Ibi ti O Láàyè Daradara’?” Ki ni “ibi ti o láàyè daradara” yii? (Orin Dafidi 18:19, NW) “Ipo idande ti ń mú alaafia ọkàn ati ààbò ọkan-aya wá,” ni olubanisọrọ naa ṣalaye. Kuro ninu ki ni a nilo idande? ‘Iwọ funraarẹ—àìdójú-ìwọ̀n tìrẹ funraarẹ.’ Ó fikun un pe: ‘Pẹlupẹlu, awọn ipo-ayika ẹhin-ode ti Satani ń tapo sí.’ (Orin Dafidi 118:5) Bawo ni a ṣe lè salọ si inu ààbò ibi ti o láàyè daradara kan? ‘Nipa wíwá awọn àṣẹ Jehofa kiri ninu gbogbo ohun ti a bá ń ṣe ati nipa fifi igbagbọ gbadura ẹ̀bẹ̀ si Jehofa fun gbogbo awọn ọ̀ràn aniyan wa ninu igbagbọ.’

“Ki ni Ó Wà Niwaju?” ni ẹṣin-ọrọ ti Don A. Adams yàn. Ki ni o sì wà niwaju fun awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun titun naa? Akoko itunṣebọsipo, ni o ṣalaye. “Ọpọlọpọ ibukun ni o tun wà niwaju yin.” Gẹgẹ bi apẹẹrẹ kan, ó sọ nipa awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun meji ti wọn kọwe lẹhin ti wọn dé ibi-ayanfunni wọn pe: “Ronu nipa ọjọ ti o tíì gbadun julọ rí ninu iṣẹ-isin, bẹẹ gan-an sì ni gbogbo ọjọ rí. Awọn iwe-ikẹkọọ ti a ń kó dání kìí tó, awọn eniyan sì ń beere fun ikẹkọọ ṣáá.” Olubanisọrọ naa dari awọn ọ̀rọ̀ diẹ si idile ati ọ̀rẹ́ awọn akẹkọọyege naa: ‘Kò sí idi fun yin lati ṣaniyan nipa awọn akẹkọọyege wọnyi. Ẹ lè ràn wọn lọwọ nipa kikọ awọn ọ̀rọ̀ iṣiri si wọn.’—Owe 25:25.

Awọn olukọ ile-ẹkọ naa ni wọn sọrọ tẹlee. Jack D. Redford yan ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Maṣe Reti Ohunkohun Lati Ọ̀dọ̀ Ẹnikẹni.” Ọ̀kan lara awọn ipenija ti awọn akẹkọọyege naa yoo dojukọ ni wíwà ni irẹpọ pẹlu awọn eniyan, ni ó ṣalaye. Ki ni o lè ṣeranlọwọ? “Ẹ gbojufo awọn àléébù wọn dá. Ẹ maṣe reti ohun pupọ jù lati ọ̀dọ̀ awọn eniyan miiran. Ẹ maṣe maa reti ẹkunrẹrẹ ìwọ̀n ohun ti ẹ kàsí ẹ̀tọ́ yin. Ẹ fààyè silẹ fun àìpé ninu awọn eniyan miiran, inurere yii yoo sì ràn yin lọwọ lati wà ni irẹpọ. Agbara-iṣe yin lati wà ni irẹpọ pẹlu awọn eniyan miiran ni yoo jẹ́ ìwọ̀n idagbadenu yin.” (Owe 17:9) Dajudaju, fifi imọran ọlọgbọn yii silo yoo ran awọn akẹkọọyege naa lọwọ lati ṣe itunṣebọsipo àṣeyege lati baà lè jẹ́ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji!

“Awa ni iṣura yii ninu ohun eelo amọ̀,” ni 2 Korinti 4:7 sọ. Ulysses V. Glass, olubojuto iforukọsilẹ Ile-Ẹkọ Gilead, ṣalaye lori koko-ọrọ yii bi o ti ń sọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Gbẹkẹle Awọn Arakunrin Yin Oluṣotitọ, Ti Wọn Dáńgájíá.” Ki ni awọn “ohun eelo amọ̀” naa? “Iwọnyi gbọdọ tọkasi awọn eniyan alaipe,” ni o sọ. Ki ni “iṣura” naa? “Iṣẹ-ojiṣẹ Kristian wa ni,” ni o ṣalaye. (2 Korinti 4:1) Ki ni a sì nilati ṣe pẹlu iṣura yii? “Iṣura ti Jehofa ti fi lé wa lọwọ ni a kò nilati fi pamọ. Nitori naa, ẹyin ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lọ́la ọ̀wọ́n, ẹ pín iṣura yẹn nibikibi ti ẹ bá lọ, ki ẹ sì kọ́ ọpọlọpọ miiran ni bi a tií pín in kiri.”

Akoko ìṣàárò ni o jẹ́ nigba ti Albert D. Schroeder gori pepele, nitori pe oun ni olubojuto iforukọsilẹ Ile-Ẹkọ Gilead nigba ti o bẹrẹ. “Ilaji Ọgọrun-un Ọdun Idalẹkọọ Iṣakoso Ọlọrun” ni ẹṣin-ọrọ rẹ̀. “Jehofa mọ bi a tii pese idanilẹkọọ gbigbeṣẹ, eyi ni ó sì ti ṣe,” ni o sọ. Bawo? Arakunrin Schroeder tọka si idanilẹkọọ ti a rígbà nipasẹ awọn ile-ẹkọ meji ti a dasilẹ ni 50 ọdun sẹhin—Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun ati Ile-Ẹkọ Gilead. Ó ṣalaye pe irin-iṣẹ ṣiṣeyebibye ninu pipese ìmọ̀ pipeye ti jẹ́ Bibeli New World Translation. Ó mú un dá awọn akẹkọọyege loju pe: “Ẹ lè lọ sibi iṣẹ-ayanfunni ilẹ okeere yin pẹlu igbọnkanle nla pe Society yoo maa pese ìmọ̀ pipeye nipa awọn ète Jehofa fun yin daradara.”

Milton G. Henschel, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, sọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Ju Ẹni ti O Ṣẹgun Lọ.” Arakunrin Henschel fa ẹṣin-ọrọ rẹ̀ yọ lati inu ẹṣin-ọrọ ọdun fun 1943: “Ju ẹni ti o ṣẹgun lọ nipa ẹni ti o fẹ́ wa.” (Romu 8:37) Ó jẹ́ ẹṣin-ọrọ ṣiṣewẹku kan, ni o ṣalaye, nitori pe laaarin Ogun Agbaye II, awọn arakunrin wa ni ọpọlọpọ orilẹ-ede ń niriiri inunibini pupọ. Arakunrin Henschel ka awọn àyọkà diẹ lati inu itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ti o jiroro ẹṣin-ọrọ ọdun yẹn ó sì ṣalaye rẹ̀ lẹhin naa pe: “Ọrọ-ẹkọ Ilé-Ìṣọ́nà [January 15, 1943 (Gẹẹsi)] yii ni awọn kilaasi Gilead akọkọ kẹkọọ rẹ̀ ninu oṣu February, ó sì mura wọn silẹ fun ohun ti o wà niwaju.” Ọpọ ninu awọn akẹkọọyege naa la 50 ọdun ti o ti kọja já ti fi araawọn hàn gẹgẹ bi aṣẹgun ṣaaju akoko yii, ni o ṣalaye. Awọn kilaasi kẹrinlelaadọrun-un ń kọ́? “Ẹ duro ti Jehofa pẹkipẹki, ẹ faramọ ifẹ rẹ̀ pẹkipẹki, ijagunmolu yin ni a sì mú dájú.”

Tẹle awọn ọrọ-asọye akoko owurọ, alaga ṣajọpin awọn ikini diẹ ti a gbà lati oniruuru ilẹ. Nigba naa ni akoko ti awọn tọkọtaya 24 naa ti ń fi ìyánhànhàn reti wá tó—pípín awọn iwe-ẹri. Họwu, awọn akẹkọọ Gilead naa ti di akẹkọọyege lọna ti a fàṣẹ si nisinsinyi! Wọn ti wá lati orilẹ-ede marun-un, ṣugbọn awọn iṣẹ-ayanfunni wọn ń gbé wọn lọ si ilẹ 17, ti ó ní Hong Kong, Taiwan, Mozambique, ati awọn apakan iha Ila-oorun Europe ninu.

Lẹhin akoko idawọduro diẹ kan, itolẹsẹẹsẹ ọ̀sán bẹrẹ pẹlu Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà ti a ké kuru, ti a dari lati ọwọ́ Robert L. Butler. Lẹhin naa awọn akẹkọọyege naa tun diẹ lara awọn iriri wọn titayọ ti wọn ti gbadun nigba ti wọn ń jẹrii lẹbaa Wallkill, New York sọ. Itolẹsẹẹsẹ naa fi ọ̀kan lara awọn ohun ti o mú wọn wá si Gilead hàn laiṣiyemeji—ifẹ wọn jijinlẹ fun iṣẹ-ojiṣẹ pápá.

Tẹle itolẹsẹẹsẹ awọn akẹkọọ, ọpọ ninu awujọ naa ń ṣe kayeefi boya itolẹsẹẹsẹ naa yoo gbé ohun kan jade lakanṣe lati ṣayẹyẹ 50 ọdun Ile-Ẹkọ Gilead. A kò já wọn kulẹ!—Wo apoti ti o bá a rìn, “Ṣiṣatunyẹwo 50 Ọdun Ile-Ẹkọ Gilead.”

Ni 50 ọdun sẹhin, Arakunrin Knorr fihàn pe oun jẹ́ onigbagbọ ati aríran. Idaniloju rẹ̀ pe Ile-Ẹkọ Gilead yoo kẹsẹjari ni a sọ jade ninu ọ̀rọ̀ akọsọ rẹ̀ fun kilaasi akọkọ, nigba ti o sọ pe: “A gbagbọ pe, ni ibamu pẹlu orukọ rẹ̀, ‘okiti ẹ̀rí’ kan yoo jade lọ lati ibi yii si gbogbo apa ayé ati pe iru ẹ̀rí bẹẹ yoo duro gẹgẹ bi ohun irannileti si ògo Ọlọrun ti a kò lè parun lae. Ẹyin gẹgẹ bi ojiṣẹ ti a fi joye yoo fi igbẹkẹle yin kikun sinu Ẹni Giga Julọ naa, ni mímọ̀ pe oun yoo ṣọ́ yin yoo sì dari yin ni gbogbo akoko aini, ẹyin yoo sì mọ pẹlu pe oun tun jẹ́ Ọlọrun ibukun.”a

Ni 50 ọdun lẹhin naa, Ile-Ẹkọ Gilead ṣì Ń Ṣaṣeyọri! Awọn akẹkọọyege ti kilaasi kẹrinlelaadọrun ní anfaani titẹle awọn akẹkọọyege ti o ju 6,500 lọ ti wọn ti gba iwaju wọn. Ǹjẹ́ ki wọn fi igbẹkẹle wọn sinu Ẹni Giga Julọ bi wọn ti ń ṣe ipa tiwọn ninu kíkó “okiti ẹ̀rí” ti yoo duro gẹgẹ bi ohun irannileti jọ pelemọ fun ògo Jehofa Ọlọrun.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ni èdè Heberu ede-isọrọ naa “Gilead” tumọsi “Okiti Ẹ̀rí.”—Genesisi 31:47, 48.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

Awọn Akojọ Isọfunni Nipa Kilaasi

Aropọ iye awọn akẹkọọ: 48

Iye awọn orilẹ-ede ti a ṣoju fun: 5

Iye awọn orilẹ-ede ti a pín wọn sí: 17

Ipindọgba ọjọ-ori: 32

Ipindọgba iye ọdun ninu otitọ: 15.3

Ipindọgba iye ọdun ninu iṣẹ-isin alakooko  kikun: 9.6

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

ṢIṢATUNYẸWO 50 ỌDUN ILE-ẸKỌ GILEAD

Ọ̀nà ti o sàn wo ni ìbá tun wà lati gbà wẹ̀hìn pada wo ìtàn Gilead ju nipasẹ iriri awọn wọnni ti wọn lo igbesi-aye wọn fun un—awọn akẹkọọyege, awọn olukọ, ati awọn miiran ti wọn ṣeranwọ lati ṣeto rẹ̀ ni iṣaaju? Awọn awujọ ni inu wọn dùn bi wọn ti fetisilẹ si apá naa “Ṣiṣatunyẹwo 50 Ọdun Ile-Ẹkọ Gilead,” ti a dari lati ọwọ́ Theodore Jaracz.

Ki ni awọn ipo-ayika ti o ṣamọna si fifidii ile-ẹkọ naa mulẹ? Arakunrin Schroeder ṣalaye pe oun ati awọn olukọ meji miiran ni a fun ni oṣu mẹrin pere lati ṣeto ile-ẹkọ naa. “Ṣugbọn nigba ti yoo fi di Monday, February 1, 1943, a ti ṣetan fun iyasimimọ.”

Bawo ni o ti rí fun awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun akọkọ ti a rán jade? Arakunrin Henschel pada ranti pe: “A jẹ́ ki ẹ̀ka ìkẹ́rù Society di gbogbo awọn ohun-ìní wọn ti wọn fẹ́ lati mú dani pẹlu wọn sinu àpótí. Nigba ti awọn àpótí naa dé ibi ti wọn ń lọ, wọn fi tiṣọratiṣọra ṣí wọn, wọ́n sì kó awọn ohun-ìní wọn jade. Ṣugbọn sibẹ wọn lo àpótí naa lati ṣe ohun-eelo inu ile.” Asẹhinwa-asẹhinbọ, ni ó sọ, Society ṣeto fun ile awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti a mura rẹ̀ silẹ lọna ti o mọniwọn.

Tẹlee lori itolẹsẹẹsẹ naa, awọn akẹkọọyege ti awọn kilaasi Gilead ibẹrẹpẹpẹ ti wọn jẹ́ mẹmba idile Beteli U.S. nisinsinyi sọrọ nipa awọn iranti wọn, awọn imọlara wọn, ati awọn iriri wọn. Ọ̀rọ̀ wọn gbún ọkan-aya gbogbo awọn ti wọn wà ni ijokoo nitootọ.

“Lẹhin ti mo gba ikesini lati wá si kilaasi akọkọ, mo gbọ́ pe mama mi ni àrùn jẹjẹrẹ. Ṣugbọn niwọn bí ohun ti ń ṣe aṣaaju-ọna bọ̀ lati ẹni ọdun 16, ó fi tagbaratagbara gbà mi nimọran lati tẹwọgba ikesini naa. Nitori naa pẹlu ero-imọlara ti a rú pọ̀ ati igbẹkẹle ninu Jehofa, mo rinrin-ajo lọ si South Lansing. Mo gbadun idanilẹkọọ Gilead patapata mo sì mọriri rẹ̀ jinlẹ-jinlẹ. Mama mi pari ipa-ọna igbesi-aye rẹ̀ ni ìgbà diẹ lẹhin ikẹkọọyege mi.”—Charlotte Schroeder, ó ṣiṣẹsin ni Mexico ati ni El Salvador.

“Niwọn bi Jehofa ti bojuto mi ná ni apa ilẹ̀-ayé ti mo wà, mo finu dà á rò pe ibikibi ti mo bá lọ ṣì jẹ́ ilẹ̀-ayé rẹ̀, oun yoo sì bojuto mi. Nitori naa mo layọ gidigidi lati tẹwọgba ikesini si kilaasi akọkọ naa.”—Julia Wildman, ṣiṣẹsin ni Mexico ati El Salvador.

“Agbayanu ni! A lè sọrọ ni gbogbo ẹnu ọ̀nà. Ni oṣu akọkọ, mo fi iwe 107 sode mo sì dari ikẹkọọ Bibeli 19. Ni oṣu keji mo ni ikẹkọọ Bibeli 28. Dajudaju, awọn ohun kan wà ti a nilati mú araawa bá mu—ooru, ọ̀rinrin, ìdun. Ṣugbọn agbayanu anfaani ni ó jẹ́ lati wà nibẹ. Ohun kan ti emi yoo maa ṣìkẹ́ nigba gbogbo ni.”—Mary Adams, kilaasi keji, nipa iṣẹ-ayanfunni rẹ̀ ni Cuba.

“Ipo oju-ọjọ ni ọ̀kan lara awọn idena ńlá ti a nilati bá jà ni Alaska. Ni ariwa ó tutù gan-an ni, pẹlu ìwọ̀n ìgbóná-ìtutù ti ń lọ silẹ de 60 lori iwọn Fahrenheit ati tutù jù bẹẹ lọ. Awọn abule India ati awọn ibi àdádó diẹ ni iha guusu ila-oorun Alaska ni a dé yala nipa ọkọ̀ oju-omi tabi ọkọ̀ ofuurufu.”—John Errichetti, kilaasi kẹta.

“Fun mi Gilead jẹ́ ikesini kan lati ọ̀dọ̀ Jehofa wá nipasẹ eto-ajọ rẹ̀ ti ori ilẹ̀-ayé lati fun ipo tẹmi wa lokun ki o sì fi ọ̀nà igbesi-aye ti o jẹ agbayanu hàn wá.”—Mildred Barr, kilaasi kọkanla, ó ṣiṣẹsin ni Ireland.

Awọn ifọrọwanilẹnuwo ti o tubọ dunmọni tẹle—Lucille Henschel (kilaasi kẹrinla, ó ṣiṣẹsin ni Venezuela), Margareta Klein (kilaasi ogún, ó ṣiṣẹsin ni Bolivia), Lucille Coultrup (kilaasi kẹrinlelogun, ó ṣiṣẹsin ni Peru), Lorraine Wallen (kilaasi kẹtadinlọgbọn, ó ṣiṣẹsin ni Brazil), William ati Sandra Malenfant (kilaasi kẹrinlelọgbọn, wọn ṣiṣẹsin ni Morocco), Gerrit Lösch (kilaasi kọkanlelogoji, ó ṣiṣẹsin ni Austria), ati David Splane (kilaasi kejilelogoji, ó ṣiṣẹsin ni Senegal).

Ki ni nipa ti awọn arakunrin ti wọn ṣiṣẹsin gẹgẹ bi olukọ? Ọpọ ninu wọn ni a fi ọ̀rọ̀ wá lẹnu wo pẹlu—Russell Kurzen, Karl Adams, Harold Jackson, Fred Rusk, Harry Peloyan, Jack Redford, ati Ulysses Glass. Wọn ronu síwá-sẹ́hìn lori anfaani wọn, ni fifi bi o ti ṣe nipa lori wọn titi di oni yii hàn.

Awọn ẹ̀rí ti ń munilayọ si igbeṣẹ awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti a dá lẹkọọ ni Gilead ni a pese lati ẹnu Lloyd Barry, ẹni ti o ṣiṣẹsin ni Japan. Ni 1949, nigba ti a rán awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun 15 lọ sibẹ, iye awọn akede ti wọn wà ni gbogbo Japan kere si 10. Ṣugbọn ni ọdun 44 lẹhin naa, iye ti ó lé ni 175,000 awọn olupokiki Ijọba ni wọn wà ni ilẹ yẹn! Nigba naa ni Robert Wallen wá sọ nipa aṣeyọri titayọ ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan ti ní ninu ríran awọn eniyan lọwọ wá sinu otitọ, titikan arabinrin ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan ti o ti wà ni Panama fun ohun ti o ju 45 ọdun lọ ti ó sì ti ran 125 eniyan lọwọ dori koko iyasimimọ ati iribọmi.

Otente gbogbo itolẹsẹẹsẹ naa ni a dé nigba ti a késí gbogbo awujọ ti wọn jẹ́ akẹkọọyege Gilead lati wá siwaju sori pepele. O jẹ́ akoko ti o gbún ọkàn ni kẹ́ṣẹ́ nitootọ. Ìgbáyìì awọn arakunrin ati arabinrin—89 ninu idile Beteli ni afikun si awọn akẹkọọyege ti ń ṣebẹwo—tò wọ́ọ́rọ́wọ́ gba àárín ìlà kọja lọ sori àtẹ̀gùn ti wọn gbà gun ori pepele. Awọn arakunrin ti wọn ti ṣiṣẹsin gẹgẹ bi olukọ la awọn ọdun kọja darapọ mọ́ wọn, ati lẹhin naa kilaasi kẹrinlelaadọrun-un—gbogbo wọn jẹ́ nǹkan bi 160!

“Iṣẹ Ile-Ẹkọ Gilead ninu dídá awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lẹkọọ fun ilẹ ajeji ha ti ní aṣeyọri kan bi?” ni Arakunrin Jaracz beere. “Bẹẹni tí ń dún kíkankíkan ni ẹ̀rí 50 ọdun ti o ti kọja jẹ́!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Kilaasi Kẹrinlelaaadọrun tí Ń Kẹkọọyege Lati Watchtower Bible School of Gilead

Ninu akọsilẹ lẹsẹẹsẹ ni isalẹ, awọn ìlà ni a tò lati iwaju lọ sẹhin a sì to awọn orukọ lẹsẹẹsẹ lati òsì sí ọ̀tún ni ìlà kọọkan.

(1) De La Garza, C.; Borg, E.; Arriaga, E.; Chooh, E.; Purves, D.; Fosberry, A.; Delgado, A.; Drescher, L. (2) Scott, V.; Fridlund, L.; Kettula, S.; Copeland, D.; Arriaga, J.; Thidé, J.; Olsson, E.; Widegren, S. (3) Delgado, F.; Keegan, S.; Leinonen, A.; Finnigan, E.; Fosberry, F.; Halbrook, J.; Berglund, A.; Jones, P. (4) Watson, B.; Frias, C.; Chooh, B.; Halbrook, J.; Purves, J.; Finnigan, S.; Jones, A.; Cuccia, M. (5) Scott, G.; Copeland, D.; Drescher, B.; De La Garza, R.; Leinonen, I.; Keegan, D.; Watson, T.; Kettula, M. (6) Widegren, J.; Borg, S.; Cuccia, L.; Berglund, A.; Olsson, B.; Frias, J.; Fridlund, T.; Thidé, P.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́