Awọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead Kówọnu Ọna Igbesi-aye kan Ti Ńmú Èrè Wá
“IRU aṣeyẹ alayọ wo ni eyi jẹ́, ikẹkọọyege kilaasi àádọ́rùn ún ti Gilead!” Pẹlu awọn ọrọ wọnni, alaga, Karl F. Klein ti Ẹgbẹ Oluṣakoso, nasẹ itolẹsẹẹsẹ ikẹ́kọ̀ọ́yege naa. Ni riranti igba ti Watchtower Bible School of Gilead bẹrẹ, o fikun un pe: “Ta ni o ti lè ronu, lẹhin lọhun ni 1943, nigba ti kilaasi akọkọ ti Gilead kẹkọọyege pe 48 ọdun lẹhin naa awa yoo ṣì maa pade pọ fun ikẹkọọyege kilaasi miiran sibẹ—ti àádọ́rùn-ún?”
Sibẹ, ni March 3, 1991, ọjọ olóoru kan lọna ti o ṣajeji ni New Jersey, iye ti o ju 4,000 awọn alejo ti a fiwe kési ati awọn mẹmba idile Bethel korajọ pọ ni Gbọngan Apejọ Jersey City, ni odikeji odo gan an lati New York City, fun ikẹkọọyege awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun titun wọnyii. Ṣaaju ki wọn to kówọnu igbesi-aye ojihin-iṣẹ Ọlọrun, awọn akẹkọọyege naa yoo gba imọran ìdágbére ni ọjọ ikẹkọọyege wọn yii.
Itolẹsẹẹsẹ naa bẹrẹ pẹlu orin kan. Lẹhin iyẹn, gbogbo awọn ti wọn wà nibẹ ni wọn ni imọlara jijinlẹ nigba ti Frederick W. Franz, ẹni ọdun 97 ti o jẹ aarẹ Watchtower Bible School of Gilead naa, gba adura ibẹrẹ. Nigba naa, lẹhin awọn ọrọ akiyesi àkọ́sọ lati ẹnu alaga, awọn akẹkọọyege naa—ati gbogbo awọn ti wọn wà nibẹ—feti silẹ pẹlu ifẹ ọkan si ọ̀wọ́ awọn ọrọ asọye kukuru, ti wọn gbeṣẹ.
Max H. Larson ti Igbimọ Ile-iṣẹ Ẹrọ sọrọ lakọọkọ, lori ẹṣin-ọrọ naa “Awọn Alajumọṣiṣẹpọ Pẹlu Jehofa.” Lẹhin pipe afiyesi si aaki ipanimọ laaye ti Noa ati idile rẹ kọ́, o wipe: ‘Lonii Jehofa nko araadọta ọkẹ idile kari aye jọpọ̀, o si pete lati mu idile nla yii la ipọnju nla kọja.’ Bawo? Họwu, nipasẹ aaki ode oni naa—paradise tẹmi! Ó rán awọn akẹkọọyege naa leti pe, ‘Ẹyin nlọ si oniruuru apa ilẹ-aye, nibi ti ẹyin yoo ti jẹ alajumọṣiṣẹpọ pẹlu Jehofa ninu kikọ aaki ode oni naa.’ Ni mimura wọn silẹ fun ohun ti o wà niwaju, o wipe: ‘Yoo gba iṣẹ ni iha ọdọ tiyin. Yoo gba suuru. Ẹyin yoo ṣalabaapade awọn ìdènà. Nihin-in ni ẹyin yoo ti nilo awọn oye iṣẹ ti idalẹkọọ yin ti fun yin.’
Daniel Sydlik, mẹmba kan lara Ẹgbẹ Oluṣakoso, ti ba awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun alakooko pipẹ ni Japan ati Costa Rica sọrọ laipẹ yii. Ni sisọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Tiyin Ni Ọna Igbesi-aye kan Ti Nmu Èrè Wa,” ó ṣajọpin diẹ lara awọn idamọran ti o le ranni lọwọ ti oun ti ri kojọ lati ọdọ awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun alaṣeyọri si rere wọnyi. Ó ṣalaye pe arabinrin kan sọ diẹ lara imọran ti iya rẹ ti fi fun un pe: ‘Nifẹẹ iṣẹ-isin papa. Bá awọn eniyan ṣọ̀rẹ́. Ṣajọpin igbesi-aye rẹ pẹlu awọn ẹlomiran, yoo si tumọ si ayọ fun ọ.’ Arabinrin miiran wipe: ‘La awọn ọdun já, awa ti wá mọriri pe bi awa ko ba reti ohun pupọ ju lati ọdọ awọn ẹlomiran, awa ki yoo ní ìjákulẹ̀ pẹlu irọrun. Iṣe oninurere ati onironu eyikeyi ti o ba wa si ọna wa ni itumọ pupọpupọ jubẹẹ lọ fun wa.’ Fifi iru imọran ti o gbeṣẹ bẹẹ silo dajudaju yoo ran awọn akẹkọọyege naa lọwọ lati di awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun alaṣeyọri si rere funraawọn.
“Ẹ ni ipamọra fun gbogbo eniyan,” ni 1 Tẹsalonika 5:14 (NW) wi. Leon Weaver ti Igbimọ Ẹka Iṣẹ-ipese sọrọ lori ẹsẹ Bibeli yii bi oun ti ṣe nsọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Jẹ́ Onisuuru Ninu Gbogbo Awọn Igbokegbodo Yin.” Awọn wo ni “gbogbo” naa siha ọdọ awọn ti awa gbọdọ lo suuru ní ninu? Olubanisọrọ naa dahun pe: ‘Awọn wọnni ti ẹyin yoo bá pade ninu iṣẹ-isin pápá. Awọn arakunrin ati arabinrin ninu ijọ yin titun. Awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ẹlẹgbẹ yin. Awọn wọnni ti wọn wà ni ẹ̀ka. Olubaṣegbeyawo yin. Ara yin.’ Eeṣe ti a fi nilati jẹ onisuuru ninu gbogbo awọn igbokegbodo wa? Olubanisọrọ naa ṣalaye pe, ‘Ẹyin arakunrin ati arabinrin, suuru ńdín ikimọlẹ ati aniyan kù. Suuru ṣafikun alaafia. Suuru mu ki ireti wà laaye. Suuru ran wa lọwọ lati pa ayọ wa mọ ninu ṣiṣiṣẹsin.’
Albert D. Schroeder, mẹmba kan lara Ẹgbẹ Oluṣakoso ati olubojuto iforukọsilẹ akọkọ ti Ile-ẹkọ Gilead, sọrọ tẹle e. Ni sisọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Maa Baa Lọ Ni Titẹle Awokọṣe Yin—Jesu Kristi,” ó gbé awọn ọrọ rẹ kari Filipi ori 2 “Ẹ pa ẹmi ironu ero-ori yii [“Ẹ maa ni eyi lọkan,” alaye eti iwe] ninu yin eyi ti o wa ninu Kristi Jesu pẹlu,” ni ẹsẹ 5 (NW) wi. Olubanisọrọ naa ṣalaye pe, ‘Eyi fihan pe a nilati ní ironu ti o wà deedee, ani gẹgẹ bi Jesu funraarẹ ti ní ironu ti o wà deedee.’ Ni bibẹrẹ pẹlu ẹsẹ 6, ó ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ti o gbadun mọni tẹle e, ni fifihan pe Pọọlu kọkọ funni ni awọn ẹri pe Jesu ní ironu ti o wà deedee (ẹsẹ 6 si 8) ati lẹhin naa o wa ṣetolẹsẹẹsẹ awọn ọna ti Jehofa gba san ere fun un fún ipa-ọna onigbọran rẹ (ẹsẹ 9 si 11). Ó pari ọrọ pe, ‘Eyi ni apakan anfaani yin, lati maa waasu Oluwa Jesu Kristi, ni riran awọn miiran lọwọ lati ni ẹmi ironu ero-ori kan naa ti oun ni.’
Awọn ọrọ idagbere wo ni awọn olukọni ile-ẹkọ naa yoo ni fun awọn akẹkọọ wọn? Jack D. Redford sọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Agbara Ironu Yoo Síji Bò Yin.” (Owe 2:10, 11, NW) Ó ṣalaye pe, ‘Bi ẹyin ti njade lọ nisinsinyi,’ ayọ yin ki yoo sinmi lori ẹni ti ẹ jẹ́ tabi ohun ti ẹ ní tabi otitọ naa pe ẹyin jẹ akẹkọọyege Gilead paapaa. Ayọ yin yoo sinmi lori bi ẹ ṣe nronu. Bi ẹyin ba lo agbara ironu yin ti ẹ si fi imọ yin silo, ẹyin yoo layọ.’ Ni fifi ijẹpataki agbara ironu hàn, oun ṣalaye pe: ‘Ironu jẹ iyatọ laaarin igbesẹ ti o tọna ati eyi ti ko tọna. Ohun ti ẹ rò ni npinnu ohun ti ẹ ṣe.’ J. D. Redford pari ọrọ pẹlu awọn ọrọ iṣiri wọnyi fun awọn akẹkọọ naa pe: ‘Ọpọlọpọ awọn eniyan ọlọgbọloye gan an ni wọn wà ninu aye ti wọn jẹ ẹni ti kò le ronu daradara, ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn sì wà ti wọn jẹ ọlọgbọnloye niwọnba ti wọn si di ọjafafa ninu rironu daradara. Nitori naa ẹ jere ìjáfáfá yẹn. Ẹ jẹ́ onipinnu lati lo ero inu yin. Ẹ lo imọ yin. Ẹ koju awọn iṣoro. Ẹ fi iwa ọrẹ́ bá awọn eniyan ṣepọ. Ẹ tẹwọgba ọla aṣẹ. Ẹ jẹ́ amesojade ninu iṣẹ yin. Ẹ farada á ninu iṣẹ ti a yàn yin sí.’
Ulysses V. Glass, alaboojuto iforukọsilẹ ile-ẹkọ naa, yan ẹṣin-ọrọ naa “Jehofa Nti Ọwọ Wa Lẹhin,” ti a gbé kari Saamu 37:23, 24 (NW). Ó sọrọ akiyesi pe, ‘Mo gbọdọ gboriyin fun kilaasi yii, lori ifẹ ọkan wọn ninu kikẹkọọ.’ O rán wọn leti diẹ lara awọn iranlọwọ ti Jehofa ti pese fun itilẹhin wọn—Ọrọ Ọlọrun, ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu labẹ idari Jesu lati fi itumọ ati oye fun Iwe mimọ, awọn itẹjade oniruuru, awọn ipade, ati apejọpọ. O nbaa lọ pe, ‘Awọn iranlọwọ ti ẹ ti lo ninu ikekọọ yin, dabi ọpa ati ọ̀gọ. A nilo wọn fun itilẹhin tẹmi wa, wọn si tun nran wa lọwọ lati sọrọ pẹlu aṣẹ ni tita atare Ọrọ Ọlọrun sọdọ awọn miiran,’ Ni ipari oun ni awọn ọrọ imọran wọnyi fun awọn akẹkọọ naa: ‘Bi ọkan yin ba kún fun ifẹ fun awọn eniyan, awọn ọkan alailabosi yoo dahun pada. Ẹyin yoo ṣaṣeyọri si rere ninu iṣẹ-ojiṣẹ yin, ẹyin yoo si mọ pe Jehofa nti ọwọ yin lẹhin.’
Olubanisọrọ ti o kẹhin ninu itolẹsẹẹsẹ owurọ ni Carey W. Barber ti Ẹgbẹ Oluṣakoso, ẹni ti o yan ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Bá Ẹnu Ilẹkun Tóóró Wọle.” Ni sisọrọ lori Luuku 13:23, 24 (NW), o ṣakiyesi pe: ‘Ọpọlọpọ nfẹ awọn ibukun iye, ṣugbọn iwọnba diẹ ni o muratan lati fi tokuntokun lo ara wọn de gongo lati gbà wọn.’ Ki ni nipa ti wa? ‘O dara ki a bere lọwọ ara wa, “Ki ni aworan ẹnu ilẹkun tóóró yii tumọ si fun mi gẹgẹ bi ẹnikan?”’ Awọn wọnni ti wọn kuna lati gba ẹnu ilẹkun tóóró wọle kuna, ki i ṣe nitori pe ko ṣeeṣe, ṣugbọn nitori pe wọn ko muratan lati lo ara wọn de gongo. Olubanisọrọ naa ṣalaye pe, ‘Jehofa ko beere ohun pupọ ju lọwọ wa.’ Ó pari ọrọ pe, ‘Pẹlu iranlọwọ Jehofa, njẹ ki gbogbo wa fi tayọtayọ lo agbara ti o pọ tó de gongo lati rúnra gba ẹnu ilẹkun tóóró naa kọja sinu aye titun ti iye, alaafia, ayọ, ati idunnu ainipẹkun si ogo ayeraye Jehofa!’
Tẹle awọn ọrọ akiyesi wọnyi, alaga jiṣẹ awọn ikini ti a ri gbà lati oniruuru apa ibi ni ilẹ-aye. Akoko naa tó wàyí fun awọn akẹkọọyege naa lati gba iwe ẹri ikẹkọọyege wọn. Awọn akẹkọọ naa ti wá lati awọn ilẹ orilẹ-ede mẹfa—Canada, Finland, Germany, Great Britain, Switzerland, ati United States. Bi o ti wu ki o ri, awọn iṣẹ ayanfunni wọn yoo gbé wọn lọ si iru awọn ilẹ bii Argentina, Benin, Bolivia, Dominican Republic, Papua New Guinea, Peru, St. Lucia, ati Taiwan. Bawo si ni awọn akẹkọọyege naa ti nimọlara ni ọjọ ikẹkọọyege wọn? Ninu lẹta arumọlara soke kan ti a kọ si Ẹgbẹ Oluṣakoso ati idile Bethel, wọn sọ ni apakan pe: “A ni igbọkanle ninu itilẹhin Ẹgbẹ Oluṣakoso, idile Bethel, ati gbogbo eto-ajọ Jehofa. Gẹgẹ bi a ti ndoju kọ awọn idanwo ti nbẹ niwaju, itilẹhin yẹn ni ohun kan ti awa yoo ka a si iṣura. Fun eyi awa nitootọ kun fun imoore.”
Lẹhin isinmi ranpẹ kan, itolẹsẹẹsẹ ọsan bẹrẹ pẹlu Ikẹkọọ Ilé-ìṣọ́nà ti a ké kuru, ti a dari lati ọwọ Karl A. Adams. Lẹhin iyẹn, awọn akẹkọọ naa ṣe aṣefihan awọn iriri igbesi-aye gidi ti o niiṣe pẹlu dide inu ọkan-aya ninu kikọni ni ẹkọ Ọrọ Ọlọrun. Nikẹhin, gbogbo awọn ti wọn wá, papọ pẹlu awọn akẹkọọyege kilaasi àádọ́rùn-ún naa, gbadun awokẹkọọ ti o bá ìgbà mu kan ti o ni akọle Yẹra fun Awọn Aniyan Aye, ti awọn akede adugbo gbekalẹ.
Alaga naa, Karl Klein, gba ẹnu gbogbo eniyan sọ nigba ti o sọ ninu awọn ọrọ akiyesi rẹ ipari pe: “Nitootọ o ti dara fun wa lati wà nihin-in ni ọjọ kẹta oṣu March 1991 yii!” Itolẹsẹẹsẹ ti o gbadun mọni naa pari lẹhin naa pẹlu orin ipari kan, ti adura lati ẹnu Harold J. Dies tẹle e.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Awọn Akojọ Isọfunni nipa Kilaasi
Iye awọn ilẹ orilẹ-ede ti a ṣoju fun: 6
Iye awọn ilẹ orilẹ-ede ti a pín wọn si: 10
Aropọ iye awọn akẹkọọ: 24
Ipindọgba ọjọ-ori: 31.2
Ipindọgba iye ọdun ninu otitọ: 15
Ipindọgba awọn ọdun ninu iṣẹ-isin alakooko kikun: 11
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kilaasi Àádọ́rùn-ún ti Nkẹkọọyege lati Watchtower Bible School of Gilead
Ninu akọsilẹ lẹsẹẹsẹ ni isalẹ, awọn ila ni a to nọmba rẹ lati iwaju lọ sẹhin a sì to awọn orukọ lẹsẹẹsẹ lati osi si ọtun ni ila kọọkan. (1) Miller, M.; Helenius, S.; Marsh, L.; Kleeman, A.; Loosli, Y.; Nizan, H. (2) Skogen, R.; Nutter, D.; Noack, E.; Diehl, L.; Hair, J. (3) Marsh, C.; Helenius, H.; Loosli, M.; Danio, A.; Danio, A.; Nizan, D. (4) Miller, L.; Noack, J.; Hair, L.; Kleeman, W.; Skogen, D.; Diehl, S.; Nutter, W.