Awọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead Tẹwọgba Ẹbun Iṣẹ-isin Ijihin-Iṣẹ-Ọlọrun
NI MARCH 1, 1992, awọn mẹmba 22 ti kilaasi 92 tí ń kẹ́kọ̀ọ́yege ti Watchtower Bible School of Gilead tẹwọgba ẹbun kan—ẹbun iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun. Nigba ti o ń bá kilaasi naa sọrọ, Lloyd Barry ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso sọ pe: “Ǹjẹ́ ki ẹ gba ẹbun agbayanu yẹn pẹlu ayọ ńlá, ǹjẹ́ ki ẹ sì lò ó ni mímú ayọ wá fun awọn ẹlomiran.”
Awọn alejo 4,662 ti a fi iwe késí ati awọn mẹmba idile Bethel korajọpọ ni Gbọngan Apejọ Jersey City, ni New Jersey, fun itolẹsẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege naa. Awọn eniyan 970 miiran ní awọn ilé lílò ti New York ti o jẹ ti Watchtower Society ni Brooklyn, Wallkill, ati Patterson ni a so pọ nipasẹ ìlà tẹlifoonu. Gbogbo eniyan fetisilẹ tiṣọratiṣọra bi a ti ń fun awọn akẹ́kọ̀ọ́yege naa ni imọran idagbere ti yoo ràn wọn lọwọ lati mọriri ẹbun iṣẹ-isin ojihin-iṣẹ-Ọlọrun naa lọna giga ati lati lò ó lọna ọgbọ́n.
Itolẹsẹẹsẹ naa bẹrẹ pẹlu kíkọ orin 155 pẹlu igbona ọkàn, “‘Ẹ Finúdídùntẹ́wọ́gbà Araayin Ẹnikinni Ẹnikeji’!” Lẹhin eyi, gbogbo eniyan ni a ṣilori bi Frederick W. Franz, ààrẹ Ile-ẹkọ Gilead ẹni ọdun 98, ti gba adura atọkanwa kan. Lẹhin naa, alaga, Carey Barber ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso, ki gbogbo eniyan kaabọ si itolẹsẹẹsẹ ikẹ́kọ̀ọ́yege naa ó sì wi pe: “Kò tíì fìgbà kan sí aini fun awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun Gilead ju oni lọ.” Tẹle awọn ọrọ rẹ̀, ó nasẹ ọ̀wọ́ awọn ọrọ asọye kukuru, ti wọn kún fun iranlọwọ.
Curtis Johnson ti Igbimọ Ile Bethel ni o kọ́kọ́ sọrọ, ní sisọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Ṣabojuto Ọgbà Rẹ Daradara.” Arakunrin Johnson ṣakiyesi pe nigba ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun titun wọnyi bá dé awọn ibi ayanfunni wọn, ẹnikọọkan wọn yoo ni ọgbà tẹmi kan lati ro. (1 Korinti 3:9) Awọn eniyan Jehofa yika ayé jẹ́ ọgbà tẹmi kan ti ń hu òdodo ati iyin loju gbogbo awọn orilẹ-ede. (Isaiah 61:11) ‘Bi o ṣe bojuto ọgbà tẹmi rẹ̀ ní ọjọ-ọla,’ ni olubanisọrọ naa fi itẹnumọ sọ, ‘yoo nipa lori aṣeyọrisirere rẹ ninu iṣẹ ayanfunni ijihin-iṣẹ-Ọlọrun rẹ lọna ti o ṣe kókó.’ Ki ni yoo ràn wọn lọwọ lati ṣabojuto ọgbà tẹmi wọn daradara? ‘Jehofa lè di ogiri aabo yika ọgbà tẹmi rẹ. Bi iwọ bá pinnu lati mu awọn iṣẹ titọna dagba, wà pẹkipẹki pẹlu rẹ̀ ninu adura, ati lẹhin naa ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu awọn adura rẹ.’
Tẹle e, Lloyd Barry sọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Ẹ Maa Yọ̀ Ninu Oluwa Nigba Gbogbo.” (Filippi 4:4) Pẹlu ohun ti o ju ọdun 25 ti iriri ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Japan lati lò gẹgẹ bi orisun isọfunni, ó ni awọn idamọran diẹ lati ran awọn akẹ́kọ̀ọ́yege naa lọwọ lati gbadun ẹbun iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun. Ó ṣalaye pe: ‘Ẹyin yoo rí i pe ayọ ti ẹ ni ninu iṣẹ-isin Ọlọrun ń ràn yin lọwọ lati ṣẹ́pá ọpọlọpọ awọn másùnmáwo ati boya awọn iṣoro ti ara diẹ ti ẹ dojukọ paapaa.’ (Owe 17:22) Ó rán awọn akẹ́kọ̀ọ́yege naa leti pe wọn lè ṣalabaapade awọn ipò-àfilélẹ̀ ati ipò-àyè ti o yatọ gan-an si ohun ti o ti mọ́ wọn lara. Wọn lè nilati kọ́ èdè titun. ‘Ẹyin lè nilati ṣiṣẹ kára ni kikẹkọọ èdè naa. Ṣugbọn nigba ti ẹyin bá lè jumọsọrọpọ falala pẹlu awọn eniyan naa ni èdè tiwọn, eyi pẹlu yoo fikun ayọ yin.’
Ni gbigbe ẹṣin-ọrọ naa kalẹ “Tẹju Rẹ Mọ́ Èrè Naa,” Eldor Timm ti Igbimọ Ile-iṣẹ Ẹ̀rọ sọrọ tẹle e. Ki ni èrè naa? Ìyè ainipẹkun ni! Lati jere rẹ̀ a gbọdọ pa oju wa mọ́ sara rẹ̀. Olubanisọrọ naa jiroro awọn ibaradọgba ati iyatọ diẹ laaarin awọn Kristian lẹnu eré-ìje fun ìyè ati awọn saresare ninu ìfagagbága eré ẹlẹ́sẹ̀ ti ọrundun kìn-ín-ní. Bii ti awọn saresare naa, awọn Kristian gbọdọ ṣe idalẹkọọ tokuntokun, pa awọn ilana mọ́, ki wọn sì bọ́ awọn ẹrù titẹwọn tí ń dẹ́rùpani kuro. Ṣugbọn laidabi awọn saresare gidi, awọn Kristian wà ninu eré-ìje abẹmiidije wọn sì ń wá èrè kan ti o jẹ́ ainipẹkun. Dipo níní olùgbẹyẹ kanṣoṣo, gbogbo eniyan ti wọn bá sá eré-ìje fun ìyè dé opin ni yoo gba èrè. Arakunrin Timm pari-ọrọ pe: ‘Lati jere èrè ìyè, a gbọdọ wà ni alaafia pẹlu Jehofa, Olufunni ni èrè naa. Ki a sì lè wà ni alaafia pẹlu Jehofa, a nilati wà ni alaafia pẹlu awọn arakunrin wa.’
Milton Henschel ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso sọrọ tẹle e lori ẹṣin-ọrọ naa “Nipa Suuru Ati Itunu Iwe Mimọ, Ki A Lè Ni Ireti.” (Romu 15:4) ‘Fun oṣu marun-un ti o ti kọja,’ ni olubanisọrọ naa fi bẹrẹ, ‘ọwọ́ yin ti dí pẹlu Bibeli. Isunmọra pẹkipẹki giga ni a ti gbéró. Ẹyin ni ireti alagbara. Bi ẹ ti ń lọ si awọn ibi iṣẹ ayanfunni yin, ẹ jọwọ ranti idi tí ireti yin fi lagbara tobẹẹ. Ó jẹ́ nitori pe ẹ ti duro pẹkipẹki ti Iwe Mimọ.’ Lati fi apẹẹrẹ ti akọsilẹ Bibeli kan ti o fun ireti niṣiiri hàn, olubanisọrọ naa tọka si Awọn Onidajọ ori 6 si 8, eyi ti o ṣàtúnsọ bi a ti fi aṣẹ fun Gideoni niṣẹ lati dá Israeli nide kuro lọwọ itẹloriba awọn ara Midiani. Lẹhin jijiroro akọsilẹ naa ati ijẹpataki rẹ̀ fun ọjọ wa, ó sọ pe: ‘Nigba ti ẹ bá ni anfaani naa lati sunmọ Iwe Mimọ pẹkipẹki ki ẹ sì ronu nipa awọn nǹkan wọnyi, ó n tù yin lara. Ẹyin ní iṣiri.’
Gbogbo eniyan ni o yánhànhàn lati gbọ imọran idagbere tí awọn olukọ meji pataki fun ile-ẹkọ naa yoo ní fun awọn akẹkọọ. Jack Redford kọkọ sọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Ṣe Ohun Ti Ó Tọ̀nà.” Ó rán awọn akẹ́kọ̀ọ́yege leti pe: ‘Ni Gilead a dá yin lẹ́kọ̀ọ́ yékéyéké ninu ohun ti ó tọna ni ibamu pẹlu Iwe Mimọ. Nisinsinyi ẹ ń lọ sí ibi ayanfunni ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ti ń peninija. A sì mọ pe ó ṣeeṣe ki ẹ rí awọn ọran iṣoro didiju loju ọ̀nà naa. Laika eyi si, ati laika awọn imọlara tiyin funraayin si, a mọ pe ẹ lè ṣe ohun ti o tọna.’ Ki ni yoo ṣeranwọ? Fun ohun kan, nini oju-iwoye titọna nipa awọn ẹlomiran ni. Olubanisọrọ naa sọ pe: ‘Maṣe reti ijẹpipe lara aipe.’ Nini oju-iwoye titọna nipa awọn ipò-àyè tí ń danniwo lè ṣeranwọ pẹlu. ‘Gbogbo wa ni a ni awọn akoko ti nǹkan dánmọ́rán ati awọn akoko ti nǹkan kò dánmọ́rán ninu igbesi-aye,’ ni o sọ. ‘Ẹnikẹni lè bojuto awọn akoko ti nǹkan kò dánmọ́rán. Bí o ṣe bojuto awọn akoko ti nǹkan kò dánmọ́rán ni yoo pinnu boya iwọ lo ifarada ninu iṣẹ-isin ojihin-iṣẹ-Ọlọrun.’—Jakọbu 1:2-4.
Olubojuto iforukọsilẹ ile-ẹkọ naa, Ulysses Glass, yan ẹṣin-ọrọ naa “Ireti Wo Ni Ó Wà Fun Ọjọ-ọla?” Ni ìró ohùn bii ti baba, ó fun awọn akẹ́kọ̀ọ́yege naa niṣiiri lati maa jẹ́ ki ireti wọn tàn yòò. (Owe 13:12) ‘Ibẹrẹ ipadanu ireti lè ṣoro lati ṣakiyesi,’ ni o ṣalaye. ‘Awọn ipo ayika lè mú ki a di ẹni ti araawa gbà lọ́kàn dipo ibatan wa pẹlu Ọlọrun. A lè ṣaisan tabi nimọlara ìbánilò ti kò tọ́ lati ọdọ awọn miiran. Awọn kan lè ni awọn nǹkan ti ara ju eyi ti a ní lọ tabi lè ni awọn iyọrisi didara ju ninu iṣẹ-ojiṣẹ wọn, a sì lè di òjòwú bakan ṣáá. Bi a bá jẹ́ yọnda iru awọn nǹkan bẹẹ lati lé wa bá, laipẹ ijotiitọ gidi ireti Ijọba yoo ṣá ninu ọkan-aya ati ero-inu wa, a sì lè dawọ lilo ifarada ninu eré-ìje fun ìyè naa duro.’ Ki ni a lè ṣe? ‘Igbesẹ pato ni a gbọdọ gbé bi a bá nilati mú ireti wa sọjí. A gbọdọ fi awọn ileri didaju ti Ọlọrun kún ero-inu ati ọkan-aya wa ki a sì yi gbogbo afiyesi wa si otitọ gidi ti Ijọba Ọlọrun. A sì gbọdọ mu ijumọsọrọpọ wa pẹlu Jehofa padabọsipo, nitori eyi yoo ṣamọna si ayọ dajudaju.’
Karl Klein ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso sọ ọrọ awiye ìkẹ́kọ̀ọ́yege naa. Ẹṣin-ọrọ rẹ̀ ni “Eeṣe Ti O Fi Gbọdọ Jẹ Onirẹlẹ?” Ki si ni idahun si ibeere yẹn? ‘Nitori pe ó jẹ́ ohun ti o tọ́ ti ó sì ba idajọ ododo mu lati ṣe, ohun ọlọgbọn ati onifẹẹ lati ṣe,’ ni o ṣalaye ninu awọn ọrọ rẹ ti o fi bẹrẹ. Awujọ naa ni a fa lọkan mọra bi oun ti ń jiroro awọn apẹẹrẹ mẹrin ti ẹmi irẹlẹ ti a ṣe daradara lati farawé: (1) Jehofa Ọlọrun, ẹni ti o lẹmii irẹlẹ dajudaju nigba ti o ń bá Abrahamu ati Mose lo (Genesisi 18:22-33; Numeri 14:11-21; Efesu 5:1); (2) Jesu Kristi, ẹni ti o ‘rẹ araarẹ silẹ ti o sì di onigbọran titi dé oju iku lori opo igi idaloro’ (Filippi 2:5-8; 1 Peteru 2:21); (3) aposteli Paulu, ẹni ti o ‘ṣe ẹrú fun Oluwa pẹlu ero-inu rirẹsilẹ gidigidi julọ’ (Iṣe 20:18, 19; 1 Kọrinti 11:1); ati (4) ‘awọn wọnni ti ń mú ipo iwaju laaarin wa,’ iru bii ààrẹ akọkọ ti Society, Arakunrin Russell, ẹni ti o kọwe nigba kan ri pe: “Iṣẹ naa ninu eyi ti o ti wu Oluwa lati lo talẹnti wa rirẹlẹ kò fi pupọ jẹ ti ifipilẹlelẹ bi o ti ri pẹlu ìṣàtúnkọ́, atunṣebọsipo, imuṣọkan.” (Heberu 13:7) Arakunrin Klein to awọn idi alagbara fun jíjẹ́ onirẹlẹ lẹsẹẹsẹ siwaju sii. Dajudaju, kikọbiara si imọran lati jẹ́ onirẹlẹ yoo ran awọn akẹ́kọ̀ọ́yege naa lati lo ẹbun iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun pẹlu ọgbọ́n!
Tẹle awọn ọrọ wọnyẹn, alaga ṣajọpin awọn ìkíni ti a rigba lati oniruuru apa ilẹ̀-ayé. Akoko tó wàyí fun awọn akẹ́kọ̀ọ́yege lati gba iwe-ẹri wọn. Wọn ti wá lati orilẹ-ede meje—Canada, Finland, France, Mauritius, ilu Netherlands, Sweden, ati United States. Ṣugbọn ibi ayanfunni ijihin-iṣẹ-Ọlọrun wọn mu wọn lọ si awọn orilẹ-ede 11—Bolivia, Estonia, Grenada, Guatemala, Honduras, Hungary, Mauritius, Peru, Togo, Turkey, ati Venezuela.
Lẹhin isinmi ranpẹ, itolẹsẹẹsẹ ọ̀sán bẹrẹ pẹlu Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà ti a ké kuru ti Joel Adams ti Igbimọ Ẹka Iṣẹ-isin dari. Lẹhin iyẹn, awọn akẹ́kọ̀ọ́yege naa ṣe aṣefihan diẹ ninu awọn iriri iṣẹ-isin pápá ti wọn ti gbadun ni akoko ile-ẹkọ naa. Nikẹhin, awokẹkọọ naa Eeṣe Ti O Fi Nilati Bọwọ Fun Iṣeto Atọrunwa? ni a gbekalẹ fun igbeniro gbogbo awọn awujọ, ti o ni awọn akẹ́kọ̀ọ́yege naa ninu.
Loootọ, awọn akẹ́kọ̀ọ́yege wọnyi lọ sẹnu awọn iṣẹ ayanfunni wọn ni ilẹ àjèjì pẹlu imọran ati iṣiri ti yoo ràn wọn lọwọ lati lo ẹbun iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun wọn lati mu ayọ wá kì í ṣe kìkì fun araawọn ṣugbọn fun awọn ẹlomiran bakan naa.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 22]
Awọn Akojọ Isọfunni Nipa Kilaasi
Iye awọn orilẹ-ede ti a ṣoju fun: 7
Iye awọn orilẹ-ede ti a pín wọn sí: 11
Aropọ iye awọn akẹkọọ: 22
Ipindọgba ọjọ-ori: 33.4
Ipindọgba iye ọdun ninu otitọ: 16.7
Ipindọgba iye ọdun ninu iṣẹ-isin alakooko kikun: 11.8
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kilaasi 92 tí Ń kẹ́kọ̀ọ́yege lati Watchtower Bible School of Gilead
Ninu akọsilẹ lẹsẹẹsẹ ni isalẹ, awọn ìlà ni a to nọmba rẹ̀ lati iwaju lọ sẹhin a sì to awọn orukọ lẹsẹẹsẹ lati osì si ọtun ni ìlà kọọkan.
(1) Chan Chin Wah, M.; Bouancheaux, N.; Chapman, B.; Östberg, A.; Cole, L.; Jackson, K.; Meerwijk, A. (2) Smith, J.; Wollin, K.; Chapman, R.; Gabour, N.; Chan Chin Wah, J.; Smith, C.; Edvik, L. (3) Bouancheaux, E.; Östberg, S.; Cole, K.; Jackson, R.; Gabour, S.; Edvik, V.; Meerwijk, R.; Wollin, G.