Awọn Ibukun Ẹkọ-iwe Gilead Tankalẹ Kari-aye
ẸKỌ-IWE ninu ayé ogbologboo yii ní kìkì ìníyelórí ti ó mọníwọ̀n. Niwọn bi a ti gbé e kari awọn èrò eniyan dipo otitọ Ọlọrun lọna ti ó pọ̀ julọ, kò lè funni ni ète tootọ ninu igbesi-aye. Ṣugbọn Ile-ẹkọ Gilead yàtọ̀. Ninu awọn àlàyé inasẹ-ọrọ rẹ̀ nibi ikẹkọọyege ti kilaasi Kẹtàléláàádọ́rùn-ún ti Gilead, Theodore Jaracz ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso mú un ṣe kedere pe ile-ẹkọ yii ń pese ẹkọ-iwe ti ó ní ijẹpataki gidi tootọ. Gẹgẹ bi Orin Dafidi 119:160 (NW) ti sọ, “ijẹpataki gidi ọ̀rọ̀ [Ọlọrun] jẹ́ otitọ.” Nitori naa pẹlu ara yíyágágá ni awọn awujọ olùgbọ́ ti wọn súnmọ́ 6,000 fi tẹtisilẹ si itolẹsẹẹsẹ ikẹkọọyege naa ni September 13, 1992.
Ọ̀rọ̀-àsọyé akọkọ ní òwúrọ̀ yẹn, ti Lon Schilling ti Igbimọ Oko Watchtower sọ, ni a fun ni àkọlé naa “Ẹ Maa Baa Lọ Ní Ṣiṣẹgun Ayé ati Oluṣakoso Rẹ̀.” Arakunrin Schilling kó afiyesi jọ sori Ìfihàn 12:11 ó sì ṣalaye pe ẹsẹ naa fi ọ̀nà mẹta ti a lè gbà ṣẹgun hàn: (1) Nipasẹ ẹ̀jẹ̀ Ọdọ-agutan naa, (2) nipasẹ jijẹrii, ati (3) nipa níní ẹmi ifara-ẹni-rubọ. Ó rán awọn akẹkọọ naa létí pe ọpọ ninu awọn iranṣẹ Jehofa ti fi iru ẹmi bẹẹ hàn wọn sì tilẹ ti fi imuratan dojukọ ikú ki wọn baa lè tẹpẹlẹ mọ́ iduroṣinṣin ati ipawatitọmọ wọn.
“Ẹ Daabobo Igbẹkẹle Rere Yin” ni ẹṣin-ọrọ ti John E. Barr ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso gbekalẹ. Ni ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ó jẹ́ ti ìró-ohùn ọlọ́yàyà, ó fi igbẹkẹle tọ̀tún-tòsì ti o wà laaarin Jehofa ati awọn iranṣẹ rẹ̀ we igbẹkẹle ti a mú dagba ninu igbeyawo rere kan. Ní lílo awọn kókó lati inu 2 Timoteu 1:12, 13, ó rọ awọn akẹkọọ naa lati pa igbẹkẹle wọn mọ́ nipa kíka “apẹẹrẹ awọn ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro” ninu Bibeli sí ọ̀wọ́n. Ó tẹnumọ sisọ idakẹkọọ di apá ṣiṣekoko kan ninu itolẹsẹẹsẹ ojoojumọ ó sì fi inurere ṣí awọn akẹkọọ naa létí kí wọn maṣe jẹ ki ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí wọn ni awọn ipade di ti aláfaraṣe-má-fọkànṣe ṣugbọn ki wọn maa jẹ ki ó kún fun itumọ nigba gbogbo.
William Van De Wall ti Igbimọ Ẹ̀ka Iṣẹ-isin sọ ọ̀rọ̀-àsọyé ti ó tẹle e, “Fi Àníyàn-ọkàn Onífẹ̀ẹ́ Hàn fun Awọn Ẹni Bí-àgùtàn.” Ó beere lọwọ awọn akẹkọọ ohun ti wọn yoo wọna fun lọdọ dokita idile kan ó sì rọ̀ wọn lati mú ẹmi ifọranrora-ẹni, ìyọ́nú, ati aanu kan-naa ti wọn yoo kà sí iyebiye dagba.
Daniel Sydlik ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso sọrọ lọna ti o ń runisoke lori ẹṣin-ọ̀rọ̀ naa “Ohun Gbogbo Ni Ó Ṣeeṣe fun Ọlọrun.” Ó rán awọn akẹkọọ naa létí pe Abrahamu ati Sara ti fi ireti ti bíbí ọmọkunrin kan ni ọjọ ogbó wọn ti ó jọbi pe kò lè ṣeeṣe rẹ́rìn-ín. Ọpọ ninu awọn ileri Ọlọrun jọbi pe kò lè ṣeeṣe ni oju-iwoye eniyan; ṣugbọn gẹgẹ bi angẹli naa ti bi Abrahamu leere, “Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA?” (Genesisi 18:14) Arakunrin Sydlik gba awọn akẹkọọ naa niyanju lati fi igbagbọ hàn ninu agbara Ọlọrun lati ṣe ohun ti kò lè ṣeeṣe, kí wọn maṣe jẹ ki igbagbọ yẹn pòórá tabi gbò lae, laika adanwo yoowu ti wọn lè dojukọ sí.
Awọn Olukọni Pese Imọran
Awọn olukọni mejeeji ti Gilead sọrọ tẹle e. Lakọọkọ, Jack D. Redford gbé ẹṣin-ọrọ naa “Ṣiṣe Orukọ Rere Pẹlu Ọlọrun” kalẹ. Ó mú èrò naa jade pe, ohun ti ń di orukọ rere tabi buburu ni ẹni naa ti ó gbé e wọ̀. Ó ṣe iyatọ ifiwera iru awọn orukọ bii Adamu, Nimrodu, Jesibeli, Saulu, ati Judasi pẹlu iru awọn orukọ bii Noa, Abrahamu, Rutu, Paulu, ati Timoteu. Orukọ kọọkan ní ọpọlọpọ ohun ti ó tan mọ́ ọn nitori ipa-ọna igbesi-aye ẹni ti ó jẹ́ ẹ. Ó beere lọwọ awọn akẹkọọ iru orukọ ti wọn yoo ní ní ọdun 10, 100 ọdun, tabi 1,000 ọdun paapaa si isinsinyi—eyi ti ó jẹ́ ti aláṣetì tabi oníràáhùn ni tabi ti oluṣotitọ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan? Kó afiyesi jọ sori ojutuu ati gongo ilepa dipo sori awọn iṣoro, ni imọran ti ó fun wọn.
“Bawo Ni Iwọ Ti Daabobo Igbagbọ Rẹ Tó?” ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ti ń ru ironu soke tí Ulysses V. Glass gbekalẹ. Ó fi igbagbọ ti ó lagbara wé atọ́ka-ọ̀nà daradara kan ti ó sábà maa ń tọka si ọ̀nà títọ́. Atọ́ka-ọ̀nà ti ó wà ninu ọkọ̀ kan ni pápá irin-tútù miiran yatọ si ti ilẹ̀-ayé lè nipa lé lori, iru awọn pápá bẹẹ ni a sì nilati sọ di alailagbara. Bakan naa, ayé ogbologboo yii ń mú ọpọlọpọ agbara-idari jade ti ó lè mú igbagbọ wa ṣáko tabi sọ ọ́ di alailagbara bi a bá gbà wọn láàyè. Gẹgẹ bi o ti kilọ fun kilaasi naa lodisi iru awọn agbara-idari bẹẹ, Arakunrin Glass tún gboriyin fun wọn fun mímọ bi iṣarasihuwa ati imọlara awọn ẹlomiran ti jẹ́ ẹlẹgẹ́ tó.
Ọ̀rọ̀-àsọyé ti ó kẹhin ni òwúrọ̀ ni a sọ lati ẹnu Albert D. Schroeder, mẹmba Ẹgbẹ́ Oluṣakoso kan. Ó fun awọn akẹkọọ naa niṣiiri lati “Pa Ẹmi Ijihin-iṣẹ-Ọlọrun Mọ́,” ní gbigboriyin fun wọn fun fifi iru ẹmi ijihin-iṣẹ-Ọlọrun kan-naa hàn gẹgẹ bi kilaasi akọkọ ti ṣe tipẹtipẹ sẹhin ni 1943, nigba ti oun ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi olubojuto iforukọsilẹ fun ile-ẹkọ naa. Ó sọ pe wọn jẹ́ eniyan ti ọkàn wọn darí si ọ̀dọ̀ awọn eniyan, oniwaasu ní ọ̀nà adanida, ti wọn fẹ́ ki ẹmi Ọlọrun dari awọn. Ẹ maa baa lọ lati mú ẹmi yẹn dagba, ní lilo New World Translation daradara ninu idakẹkọọ, ni ó rọ̀ wọn. Ó pari ọ̀rọ̀ pẹlu ijiroro ẹlẹsẹẹsẹ ti Orin Dafidi 24 gẹgẹ bi apẹẹrẹ.
Tẹle iyẹn, awọn akẹkọọ Gilead naa di akẹkọọyege Gilead! A fi iwe-ẹri wọn lé wọn lọwọ bi a ti ń ka ibi iṣẹ-ayanfunni ojihin-iṣẹ-Ọlọrun wọn jade ketekete, ti awọn awujọ olùgbọ́ sì ń pàtẹ́wọ́ gidigidi.
Ni ọ̀sán, Calvin Chyke ti Igbimọ Ile-iṣẹ-ẹrọ dari Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà. Itolẹsẹẹsẹ awọn akẹkọọ ti ó dunmọni ninu tẹle e, eyi ti ó farapẹ́ iriri awọn akẹkọọ naa ninu pápá lakooko ẹkọ oloṣu marun-un naa ti ó sì tun gbé aworan slide ti diẹ lara awọn orilẹ-ede ti a yàn wọn sí jade lakanṣe. Ni afikun, tọkọtaya agbalagba kan ni a fọrọwalẹnuwo, wọn sì ṣajọpin diẹ lara ọgbọ́n ati iriri ti wọn ti jere lati ọpọlọpọ ọdun gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ-Ọlọrun. Ọ̀sàn naa pari pẹlu awokẹkọọ ti ó bágbàmu kan ti a fun ni àkọlé naa Ẹ Maṣe Jẹ Ki Á Tàn Yin Jẹ Tabi Fi Ọlọrun Ṣẹlẹya.
Awọn awujọ olùgbọ́ naa ni a mú jí pépé, ti a mú ninudun lati rí ohun ti ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ninu otitọ Ọlọrun lè ṣe wọn sì layọ lati mọ pe awọn anfaani iru ẹkọ-iwe bẹẹ ni a o maa nimọlara rẹ̀ niṣo kari-aye. Bi awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun 48 wọnyi ṣe ń tuka lọ si ibi iṣẹ-ayanfunni wọn, ọpọlọpọ adura ni ó tẹle wọn, tí ń fi ireti atọkanwa ati igbọkanle pé awọn oluṣotitọ wọnyi yoo jẹ́ ibukun fun awọn eniyan Ọlọrun nibikibi ti wọn bá lọ hàn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
Awọn Akojọ Isọfunni Nipa Kilaasi
Iye awọn orilẹ-ede ti a ṣoju fun: 7
Iye awọn orilẹ-ede ti a pín wọn sí: 18
Iye awọn akẹkọọ: 48
Iye awọn tọkọtaya: 24
Ipindọgba ọjọ-ori: 32.8
Ipindọgba iye ọdun ninu otitọ: 15.3
Ipindọgba iye ọdun ninu iṣẹ-isin alakooko kikun: 10.4
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
KILAASI AWỌN AKẸKỌỌYEGE GILEAD TI A MÚ GBOORO
Ni June 21, 1992, awujọ awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun 24 kẹkọọyege lati kilaasi kẹrin ti Ile-ẹkọ Gilead ti a Mu Gbooro ni Selters/Taunus, Germany. Kilaasi naa, ti ó ní tọkọtaya 11 ati awọn arabinrin 2 ti wọn kò tíì lọ́kọ ninu ti wọn wá lati orilẹ-ede meje, ti wọn ní ipindọgba ọdun 32 ni ọjọ-ori, ọdun 14 lati ìgbà iribọmi, ati ọdun iṣẹ-isin 8.5 ninu iṣẹ́ ajihinrere alakooko kikun. Iye ti ó ju 2,000 lọ ni wọn wá sí ibi ikẹkọọyege naa.
Arakunrin Jaracz ṣí itolẹsẹẹsẹ naa pẹlu ijiroro kan nipa Owe 11:24, eyi ti ó sọ pe: “Ẹnikan wà tí ń túká, sibẹ ó ń bí sii.” Ó sọ pe awọn akẹkọọ naa ni wọn yoo túká laipẹ wọn yoo sì gbé ibisi larugẹ dajudaju.
Ọ̀rọ̀-àsọyé afunniniṣiiri ti a gbekari Bibeli ni a sọ lati ẹnu Richard Kelsey, oluṣekokaari Igbimọ Ẹ̀ka ti Germany; Wolfgang Gruppe ti Ẹ̀ka Iṣẹ-isin; Werner Rudtke ati Edmund Anstadt, ti awọn pẹlu jẹ́ mẹmba Igbimọ Ẹ̀ka; ati awọn olukọni meji, Dietrich Förster ati Lothar Koemmer. Albert Schroeder ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso funni ni ọrọ-awiye fifanilọkanmọra akọkọ ti a fun ni àkọlé naa “Ẹ Maa Baa Lọ Lati Jẹ Olùwá Awọn Okùta Iyebiye Tẹmi Kiri.” Otente itolẹsẹẹsẹ naa ni fífi awọn ibi iṣẹ-ayanfunni si awọn orilẹ-ede 11 ni Africa, Àárín Gbùngbùn America, ati Iha Ila-oorun Europe léni lọwọ, lẹhin eyi ti akẹkọọyege kan ka lẹta ti kilaasi naa kọ si Ẹgbẹ́ Oluṣakoso ti o ń fi imọriri atọkanwa hàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kilaasi Kẹtàléláàádọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead
Ninu akọsilẹ lẹsẹẹsẹ ni isalẹ, awọn ìlà ni a tò nọmba wọn lati iwaju lọ sẹhin a sì to awọn orukọ lẹsẹẹsẹ lati òsì sí ọ̀tún ni ìlà kọọkan.
(1) Hitesman, C.; West, P.; Evans, D.; Hipps, M.; Simonelli, N.; Wood, S.; Corkle, M.; Flores, C.; Thomas, J. (2) Jones, M.; Nissinen, J.; Sponenberg, M.; Zachary, K.; Ravn, G.; Backman, M.; Wettergren, A.; Evans, D.; Flores, R.; Caporale, G. (3) Simonelli, N.; Rechsteiner, M.; Rechsteiner, M.; Ruiz-Esparza, L.; Gerbig, B.; Simpson, C.; Zanewich, C.; Zachary, B.; Ricketts, L.; (4) Simpson, J.; Backman, J.; Corkle, G.; Gerbig, M.; Ricketts, B.; Bagger-Hansen, L.; Jones, A.; Zanewich, K.; Ravn, J.; Hipps, C. (5) Sponenberg, S.; Hitesman, A.; Caporale, L.; Ruiz-Esparza, S.; Thomas, R.; Bagger-Hansen, B.; Wood, M.; West, M.; Wettergren, C.; Nissinen, E.