ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 1/1 ojú ìwé 29
  • Otitọ Bibeli Borí Òfin-Àtọwọ́dọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Otitọ Bibeli Borí Òfin-Àtọwọ́dọ́wọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Onígbàjámọ̀ Tún Ìrònú Ti Kò Tọna Ṣe
  • A Bá A Yọ̀ Pé Ó “Jagun Mólú Pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 1/1 ojú ìwé 29

Awọn Olùpòkìkí Ijọba Ròhìn

Otitọ Bibeli Borí Òfin-Àtọwọ́dọ́wọ́

ÒFIN-ÀTỌWỌ́DỌ́WỌ́ isin lè ta gbòǹgbò jinlẹ gan-an. Araadọta ọ̀kẹ́ nímọ̀lára pe kò tọ̀nà lati yí ìsìn ẹni padà. Sọọlu, ẹni tí ó di apọsteli Pọọlu, lọna tí ó hàn gbangba nímọ̀lára lọ́nà kan naa, niwọnbi oun ti wipe: ‘Mo ní ìtara lọpọlọpọ sí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ awọn baba mi [ju ọpọ ninu awọn ojúgbà mi lọ].’ Ṣugbọn nigbati a fi otitọ hàn án, oun yípadà kuro ninu isin awọn Júù ó sì di Kristian kan. (Galatia 1:13-16) Ọpọlọpọ lonii ti wá mọ̀ dájú pe otitọ Bibeli wá lati orísun kan tí ó gaju òfin àtọwọ́dọ́wọ́. Ṣakiyesi bí otitọ Bibeli ṣe ṣẹgun ní Italy.

Obinrin kan ṣalaye: “Arabinrin mi ati emi dàgbà ninu idile títóbi kan pẹlu awọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ọlọ́jọ́ pípẹ́ ti isin Katọlik, a sì jẹ́ Katọlik olùfọkànsìn gan-an. Gẹgẹbi àkókò ti ńlọ, mo ṣègbéyàwó. Lẹhin naa mo pàdánù ọkọ mi mo sì ńdágbé gẹgẹbi opó fun ọpọlọpọ ọdun pẹlu awọn ọmọ mi. Ọmọbinrin aburo ọkọ mi ńkọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìsìn, oun sì maa nbeere awọn ibeere Bibeli lọwọ alufaa nigbagbogbo, ṣugbọn oun kò rí awọn ìdáhùn tí ńtẹ́nilọ́rùn kankan gbà.

“Nigbati mo ńṣèbẹ̀wò sí ìlú ìbílẹ̀ mi, mo bá awọn Ẹlẹrii Jehofa pade fun igba akọkọ mo sì tẹ́wọ́gbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan. Gbogbo awọn Katọlik alábàákẹ́gbẹ́ mi tẹlẹri fi mi ṣẹlẹ́yà fun kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Emi kò rẹ̀wẹ̀sì, bí ó ti wù kí ó rí. Fun ìgbà àkọ́kọ́, mo ní Bibeli kan, kò sì sí ẹni tí ó lè gbà á kuro ní ọwọ́ mi. Arabinrin mi pẹlu tún mú ìdúró fun Jehofa, ati ní ohun tí ko to ọdun meji, awa mejeeji ṣe baptism.

“Mo sọkun nigbati mo kọ́kọ́ jáwọ́ kuro ninu ṣọọṣi nitori pe mo bẹ̀rù lati pa awọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí wọn ti ta gbòǹgbò ninu mi fun 76 ọdun tì. Ṣugbọn nisinsinyi mo láyọ̀ lati rìn ninu awọn ọ̀nà Jehofa mo sì nsa gbogbo ìpa mi lati ran awọn ẹlomiran lọwọ lati jáde kuro ninu òkùnkùn tẹ̀mí!”—Fiwe 1 Peteru 2:9.

Onígbàjámọ̀ Tún Ìrònú Ti Kò Tọna Ṣe

Onígbàjámọ̀ kan ní Japan kúndùn sísọ̀rọ̀ nipa awọn ẹ̀mí eṣu ati UFO [awọn ohun tí ńfò tí a kò dámọ̀] nigbati ó bá ńgé irun awọn oníbàárà. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹhin tí oun bẹ̀rẹ̀ lati kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, oun lóye bí àṣà yii ti jẹ́ eléwu tó. Nitori naa oun késí awọn oníbàárà rẹ̀ dípò bẹẹ lati darapọ̀ mọ́ ọn ninu ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀. Oun jẹ́rìí fun awọn ọ̀dọ́ oníbàárà nipa ìṣẹ̀dá. Ní gbogbo ọsẹ oun nbeere fun Bibeli ati awọn ẹ̀dá ìwé naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lati ọwọ́ Ẹlẹrii naa tí ó ńkẹ́kọ̀ọ́ pẹlu rẹ̀ kí oun baa lè fi wọn sóde sọdọ awọn oníbàárà rẹ̀.

Bí ó tilẹ jẹ́ pe kii ṣe Ẹlẹrii sibẹ, oun fi ohun tí ó kọjá 30 ọwọ́ awọn Bibeli ati ìwé Walaaye Titilae sóde láàárín ọdun ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àkọ́kọ́. Ohun tí ó ju 25 ènìyàn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli gẹgẹ bi ìyọrísí ìjẹ́rìí aláìjẹ́ bí àṣà rẹ̀. Nigba miiran awọn tí wọn pọ̀ tó mẹ́wàá yoo kópa ninu àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀. Nisinsinyi meje ninu awọn wọnni tí ó ti jẹ́rìí fun nigbati ó ńgé irun wọn ni wọn ti tún ìrònú wọn ti ko tọna ṣe wọn sì jẹ́ awọn Ẹlẹrii Jehofa tí a ti baptisi!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́