ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 11/1 ojú ìwé 17-21
  • “Tèmi Ni Fàdákà, Tèmi Sì Ni Wúrà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Tèmi Ni Fàdákà, Tèmi Sì Ni Wúrà”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibo Ni Wọ́n Ti Ń Rówó Ṣe Iṣẹ́ Náà?
  • A Ń Tẹ Àwọn Ìwé Wa Jáde ní Èdè Irínwó Ó Lé Mẹ́tàdínlógójì [437]
  • A Ń Mú Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Èdè Dára Sí I
  • Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Wọni Lọ́kàn
  • “Àwa Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run”
  • Gbogbo Wọn Ń Fi “Ọkàn Kan” Sin Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Rí Ayọ̀ Nínú “Àǹfààní Ìfúnni Onínúrere”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Fífúnni Ní Nǹkan Látọkàn Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • ‘Ẹ Jẹ́ Ká Gbé Àwọn Ọrẹ Ẹbọ Wá fún Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 11/1 ojú ìwé 17-21

“Tèmi Ni Fàdákà, Tèmi Sì Ni Wúrà”

NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Kírúsì Ọba Páṣíà dá àwọn èèyàn Ọlọ́run nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún làwọn tó padà sílùú Jerúsálẹ́mù láti tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́, èyí tó ti wó palẹ̀. Àwọn tó padà wá yìí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, àwọn èèyàn tó ń bínú wọn tí wọ́n wà láyìíká wọn ò sì fẹ́ kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Ìyẹn ló mú káwọn kan lára àwọn tó ń kọ́ tẹ́ńpìlì náà bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá làwọn á lè parí iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí.

Àmọ́, Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Hágáì mú un dá àwọn tó ń kọ́ ilé náà lójú pé Òun wà pẹ̀lú wọn. Ọlọ́run sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.” Ohun tí Hágáì sọ fáwọn kọ́lékọ́lé tí wọ́n ń ronú nípa ipò àìní tí wọ́n wà ni pé: “‘Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” ( Hágáì 2:7-9) Kò tíì pé ọdún márùn-ún tí Hágáì sọ ọ̀rọ̀ tó gbéni ró yìí tí wọ́n fi kọ́ ilé náà tán.—Ẹ́sírà 6:13-15.

Ọ̀rọ̀ tí Hágáì sọ yìí tún ń fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lákòókò tiwa yìí níṣìírí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ìṣẹ́ bàǹtàbanta tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà. Lọ́dún 1879 nígbà tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde, tí wọ́n pè ní Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence nígbà yẹn, ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀ ni pé: “A gbà pé JÈHÓFÀ ni alátìlẹyìn ‘Zion’s Watch Tower,’ nígbà tó sì jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ìwé ìròyìn yìí kò ní tọrọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni kò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn fáwọn. Nígbà tí ẹni tó sọ pé: ‘Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà,’ kò bá lè pèsè owó tá a nílò mọ́ láti tẹ̀ ẹ́ jáde, a ó mọ̀ pé àkókò tó nìyẹn láti dáwọ́ ìtẹ̀jáde náà dúró.”

Kò sì sígbà kan rí tá a dáwọ́ títẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ dúró. Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ni ẹ̀dá àkọ́kọ́ tá a tẹ̀ jáde, èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan sì ni nígbà yẹn. Lóde òní, iye tá à ń tẹ̀ jáde nínú ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan jẹ́ mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n, àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta dín méjìlélógún [28,578,000], ó sì jẹ́ ní èdè mọ́kànlélọ́gọ́jọ [161].a Ìwé ìròyìn Jí! tó ṣìkejì ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ wà ní ọgọ́rin [80] èdè, ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tí à ń tẹ̀ jáde sì jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin [34,267,000].

Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dáwọ́ lé lónìí, ìdí tí wọ́n fi ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde náà ni wọ́n sì fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, ìyẹn ni láti gbé Jèhófà ga pé òun ni Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run àti láti kéde ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. (Mátíù 24:14; Ìṣípayá 4:11) Ìdánilójú táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní lóde òní kò yàtọ̀ sí èyí tí ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́dún 1879. Wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ń ti iṣẹ́ àwọn lẹ́yìn àti pé owó yóò wà láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá fọwọ́ sí. Àmọ́, ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ibo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń rí owó ṣe àwọn iṣẹ́ wọn? Irú àwọn iṣẹ́ wo ni wọ́n sì ń gbé ṣe kí wọ́n lè máa wàásù ìhìn rere náà kárí ayé?

Ibo Ni Wọ́n Ti Ń Rówó Ṣe Iṣẹ́ Náà?

Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wàásù fún gbogbo èèyàn, ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń bì wọ́n ni pé: “Ṣé ẹ̀ ń gbowó lórí iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe yìí ni?” Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ni pé rárá o, wọn kì í gbowó. Ńṣe ni wọ́n ń yọ̀ǹda àkókò wọn. Àwọn oníwàásù yìí ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí bí wọ́n ti ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe pé ọ̀la á dára. Ìdí tí wọ́n sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n mọyì ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn, wọ́n sì tún mọyì bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe tún ayé tiwọn fúnra wọn ṣe tó sì jẹ́ kí èrò wọn nípa ìgbésí ayé túbọ̀ dára sí i. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fẹ́ láti sọ àwọn ohun rere yìí fáwọn èèyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù fi lélẹ̀ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Láìsí àní-àní, wíwù tó ń wù wọ́n láti jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà àti Jésù ń mú kí wọ́n náwó lápò ara wọn kí wọ́n lè máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, kódà àwọn tó ń gbé níbi tó jìnnà réré.—Aísáyà 43:10; Ìṣe 1:8.

Gbígbòòrò tí iṣẹ́ ìwàásù yìí ń gbòòrò sí i àtàwọn ohun tí wọ́n ń ṣe kí iṣẹ́ náà lè kẹ́sẹ járí, irú bíi títẹ àwọn ìwé jáde, kíkọ́ àwọn ọ́fíìsì, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ilé àwọn míṣọ́nnárì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ń gba owó tó pọ̀ gan-an. Ibo ni owó náà ti ń wá? Owó tí wọ́n ń ná sórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ń wá látinú ọrẹ àtọkànwá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sọ pé káwọn ará ìjọ wọn mú iye owó báyìí wá láti fi bójú tó àwọn ìgbòkègbodò tó ń lọ nínú ẹ̀sìn wọn kárí ayé, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sọ pé káwọn èèyàn sanwó àwọn ìwé tí wọ́n máa ń pín fún wọn. Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti gba irú ọrẹ bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀kan lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe láti wàásù ìhìn rere náà kárí ayé, ìyẹn iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè.

A Ń Tẹ Àwọn Ìwé Wa Jáde ní Èdè Irínwó Ó Lé Mẹ́tàdínlógójì [437]

Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lára àwọn ìwé tí wọ́n ń túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ láyé. A ti túmọ̀ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìròyìn, àtàwọn ìwé ńlá sí èdè irínwó ó lé mẹ́tàdínlógójì [437]. Àmọ́ ṣá o, iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè gba ọ̀pọ̀ ìnáwó àti ìnára bíi tàwọn iṣẹ́ mìíràn tá a máa ń ṣe kí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà lè ṣeé ṣe. Báwo la tiẹ̀ ṣe máa ń ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè yìí?

Nígbà táwọn tó máa ń kọ ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá kọ wọ́n tán lédè òyìnbó, wọ́n á wá fi ohun tí wọ́n kọ yìí ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà sáwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì wá níbi gbogbo káàkiri ayé. Àwùjọ atúmọ̀ èdè kọ̀ọ̀kan ló máa ń túmọ̀ àwọn ìwé tá à ń tẹ̀ jáde ní èdè ìbílẹ̀ wọn. Àwùjọ kọ̀ọ̀kan lè tó ẹni márùn-ún sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ó sinmi lórí bí àwọn ohun tí wọ́n máa ń túmọ̀ ṣe pọ̀ tó àti bí èdè wọn ṣe díjú tó.

Lẹ́yìn tí wọ́n bá túmọ̀ iṣẹ́ kan tán, wọ́n á fi èdè òyìnbó yẹ̀ ẹ́ wò, wọ́n á sì kà á láti ṣàtúnṣe tó bá yẹ sí i. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe èyí ni láti rí i pé ohun tí wọ́n túmọ̀ sí èdè ìbílẹ̀ bá ohun tó wà nínú èdè òyìnbó mú, ó sì yéni yékéyéké. Èyí kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ lórí àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n lo àkànlò èdè nínú rẹ̀, àwọn tó máa túmọ̀ àpilẹ̀kọ náà àtàwọn tó máa kà á láti ṣàtúnṣe tó bá yẹ sí i ní láti ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n á ṣe ìwádìí yìí nínú èdè tí wọ́n fi kọ àpilẹ̀kọ náà (ó lè jẹ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì tàbí èdè mìíràn bí èdè Faransé, Rọ́ṣíà, tàbí Sípáníìṣì), wọ́n á sì tún ṣèwádìí ohun tó yẹ kí ọ̀rọ̀ náà jẹ́ nínú èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n fẹ́ túmọ̀ rẹ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Jí! bá dá lórí àkòrí kan tó díjú tàbí tó jẹ mọ́ ìtàn, àwọn atúmọ̀ èdè ní láti ṣèwádìí tó pọ̀ gan-an kí wọ́n lè túmọ̀ rẹ̀ dáadáa.

Ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè ti ń ṣiṣẹ́. Àwọn kan ò níṣẹ́ mìíràn ju iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè yìí, àwọn kan sì ń fi ṣe iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́. Àwọn mìíràn ń ṣiṣẹ́ lágbègbè táwọn èèyàn ti ń sọ èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń túmọ̀ rẹ̀. Àwọn atúmọ̀ èdè kì í gbówó iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Ohun tí wọ́n ń pèsè fáwọn tí kò níṣẹ́ mìíràn lára wọn kò ju ilé, oúnjẹ àti owó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n lè fi ra àwọn nǹkan tí wọ́n bá nílò. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [2,800] làwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe iṣẹ́ atúmọ̀ èdè yìí jákèjádò ayé. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] lára ẹ̀ka àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ní àwọn atúmọ̀ èdè tàbí ló ń bójú tó àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n wà láwọn ibòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń bójú tó àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] lọ, ìyẹn àwọn tó ń fi iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè ṣiṣẹ́ ṣe àtàwọn tó ń ṣe é ní àbọ̀ṣẹ́. Èdè tí wọ́n ń túmọ̀ lé ní ọgbọ̀n, títí kan àwọn èdè kan táwọn tí kò sí lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ wọ́n ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀, ìyẹn àwọn èdè bíi Chuvash, Ossetian, àti Uighur.

A Ń Mú Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Èdè Dára Sí I

Gbogbo ẹni tó ti gbìyànjú láti kọ́ èdè tuntun ló mọ̀ pé kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá láti túmọ̀ ohun tí ẹlòmíràn ní lọ́kàn gẹ́gẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ohun tíṣẹ́ náà gbà ni pé kéèyàn túmọ̀ àwọn kókó àtohun tí wọ́n fẹ́ kéèyàn mọ̀ látinú èdè tí wọ́n fi kọ àpilẹ̀kọ náà, kéèyàn sì tún jẹ́ kí ohun tóun túmọ̀ bá ọ̀nà tí wọ́n ń gba sọ èdè ìbílẹ̀ òun mu, kó dà bíi pé èdè yẹn gan-an ni wọ́n fi kọ ọ́ níbẹ̀rẹ̀. Ẹni tó máa ṣe èyí sì gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ dáadáa. Ó máa ń gba àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di atúmọ̀ èdè ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó lè di atúmọ̀ èdè tó dáńgájíá, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì máa ń ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún wọn látìgbàdégbà. Àwọn arákùnrin tó mọṣẹ́ náà dunjú sábà máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè láti ṣèrànwọ́ kí iṣẹ́ ìtumọ̀ tí wọ́n ń ṣe lè dára sí i, kí wọ́n sì lè túbọ̀ mọ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà lò dáadáa.

Ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ń so èso rere. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Nicaragua sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ẹnì kan wá láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti Mẹ́síkò, tó wá dá àwọn tó ń bá wa túmọ̀ èdè sí èdè Miskito lẹ́kọ̀ọ́ lórí ìlànà tó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé àti ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà ṣe iṣẹ́ náà. Èyí sì ti jẹ́ kí ọ̀nà táwọn atúmọ̀ èdè wa gbà ń ṣiṣẹ́ wọn dára sí i gan-an. Àwọn ohun tí wọ́n ń túmọ̀ ti wá dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Wọni Lọ́kàn

Nítorí pé a fẹ́ kí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì àtèyí tó wà nínú àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ àwọn èèyàn lọ́kàn la ṣe ń túmọ̀ wọn sáwọn èdè ìbílẹ̀, ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. Lọ́dún 2006, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Bulgaria dùn gan-an nígbà tá a mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde ní èdè Bulgarian. Nítorí èyí, ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Bulgaria rí ọ̀pọ̀ lẹ́tà ìmọrírì gbà. Àwọn ará nínú ìjọ sọ pé: “Ìsinsìnyí ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ wá lọ́kàn, kì í ṣe pé a kàn ń kà á lásán.” Bàbá àgbàlagbà kan láti ìlú Sofia sọ pé: “Mo ti ń ka Bíbélì fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ mi ò tíì rí ọ̀kankan tó rọrùn láti lóye tó sì wọni lọ́kàn tààrà bí èyí.” Bákan náà lọ̀rọ̀ rí nílẹ̀ Albania, lẹ́yìn tí arábìnrin kan níbẹ̀ gba ẹ̀dà tiẹ̀ lára Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Titun, ó ní: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mà dùn ún kà ní èdè Albanian o! Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè ìbílẹ̀ wa!”

Ó lè gba àwùjọ atúmọ̀ èdè kan ní ọdún tó pọ̀ díẹ̀ kí wọ́n tó túmọ̀ odindi Bíbélì tán. Àmọ́ nígbà tí èyí bá mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tí wọn ò lóye rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ǹjẹ́ a ó ní sọ pé gbogbo ìsapá yẹn tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ?

“Àwa Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run”

Iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó ń mú ká lè máa wàásù ìhìn rere náà lọ́nà tó gbéṣẹ́. A máa ń ṣe ọ̀pọ̀ akitiyan a sì ń ná ọ̀pọ̀ owó bá a ti ń kọ àwọn ìwé tá a fi ń ṣàlàyé Bíbélì, tá a ń tẹ̀ wọ́n, tá a tún ń kó wọn ránṣẹ́ sáwọn ìjọ, tá a sì tún ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ mìíràn láwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, ní àyíká kọ̀ọ̀kan, àti láwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Síbẹ̀, àwọn èèyàn Ọlọ́run ń “fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn” láti ṣe iṣẹ́ yìí. (Sáàmù 110:3) Wọ́n gbà pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé àwọn lè ṣe ipa tiwọn, wọ́n sì tún kà á sí nǹkan iyì pé ṣíṣe táwọn ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń mú kí Jèhófà ka àwọn sí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú” òun.—1 Kọ́ríńtì 3:5-9.

Òótọ́ ni pé Jèhófà tó sọ pé “tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà” kò gbára lé owó tá a máa fi ṣèrànwọ́ kó tó lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́, ó pọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lé, ní ti pé ó fún wọn láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti kópa nínú sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, wọ́n sì ń ṣe èyí nípa fífi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wíwàásù ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ń gbẹ̀mí là, èyí tá à ń wàásù rẹ̀ “fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ǹjẹ́ kò wu ìwọ náà láti ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá ò ní padà ṣe mọ́ yìí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ àwọn èdè náà, wo ojú ìwé kejì ìwé ìròyìn yìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]

“WỌ́N Ń JẸ́ KÁ RONÚ JINLẸ̀ GAN-AN”

Ọmọdébìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù pé: “Lẹ́yìn tí mo ra gbogbo ohun tí mo máa nílò nílé ìwé lọ́dún yìí, mo wá ta méjì lára àwọn ìwé tí mo lò lọ́dún tó kọjá ní ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ owó Francs [ìyẹn ẹgbẹ̀ta ó lé márùndínlógójì [635] Náírà]. Mo fẹ́ fi owó yìí ṣètọrẹ, pa pọ̀ pẹ̀lú nǹkan bí igba ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta [254] Náírà tí mo tọ́jú pa mọ́. Mo gbà yín níyànjú pé kẹ́ ẹ máa bá iṣẹ́ àtàtà tẹ́ ẹ̀ ń ṣe nìṣó. Ẹ ṣé gan-an fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tẹ́ ẹ máa ń tẹ̀ jáde. Wọ́n ń jẹ́ ká ronú jinlẹ̀ gan-an.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

ỌRẸ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀

Ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Mẹ́síkò gba lẹ́tà tó wà nísàlẹ̀ yìí látọ̀dọ̀ Manuel, ọmọ ọdún mẹ́fà, tó ń gbé ní Ìpínlẹ̀ Chiapas. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ló bá a kọ lẹ́tà yìí nítorí pé kò tíì mọ̀wé kọ. Manuel sọ pé: “Ìyá mi àgbà fún mi ní abo ẹlẹ́dẹ̀ kan. Nígbà tó bímọ, mo mú èyí tó dára jù lára àwọn ọmọ náà, èmi àtàwọn ará ìjọ wa sì jọ tọ́jú rẹ̀ dàgbà. Inú mi dùn gan-an láti fi owó tí mo rí nígbà tí mo ta ẹlẹ́dẹ̀ náà ránṣẹ́ sí i yín. Ó wọn ọgọ́rùn-ún kìlógíráàmù, mo sì tà á ní ẹgbẹ̀rún kan àti àádọ́ta lé nígba owó pesos [nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá Náírà]. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ lo owó yìí fún Jèhófà.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

‘KẸ́ Ẹ FI OWÓ YÌÍ TÚMỌ̀ BÍBÉLÌ’

A mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde ní èdè Ukrainian láwọn àpéjọ àgbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wáyé lórílẹ̀-èdè Ukraine lọ́dún 2005. Lọ́jọ́ kejì tí wọ́n mú Bíbélì náà jáde, wọ́n rí lẹ́tà kan nínú àpótí ọrẹ. Lẹ́tà náà kà pé: “Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí. Ẹ ṣé gan-an fún Ìwé Mímọ́ lédè Griki. Màmá wa fún èmi àti àbúrò mi ní owó yìí pé ká máa fi wọ bọ́ọ̀sì lọ sílé ìwé. Àmọ́ nígbà tí òjò ò bá rọ̀, ẹsẹ̀ la fi máa ń rìn lọ sílé ìwé, a sì tọ́jú àádọ́ta owó hryvnia yìí [ẹgbẹ̀rún kan àti igba ó lé àádọ́rin [1,270] Náírà]. Èmi àti àbúrò mi á fẹ́ kẹ́ ẹ fi owó yìí túmọ̀ odindi Bíbélì sí èdè Ukrainian.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁWỌN KAN Ń GBÀ ṢÈTỌRẸ

ỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ

Ọ̀pọ̀ máa ń ya iye kan sọ́tọ̀ tí wọ́n á máa fi sínú àpótí ọrẹ tá a kọ “Contributions for the Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé]—Mátíù 24:14” sí lára.

Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi àwọn owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè wọn. O tún lè fi ọrẹ owó tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ fi sọ̀wédowó ránṣẹ́ sí wa, kọ “Watch Tower” sórí rẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún wa láti rí owó náà gbà. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn ṣètọrẹ. Kí lẹ́tà ṣókí tó máa fi hàn pé ẹ̀bùn ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ wà lára rẹ̀.

ỌRẸ TÍ A WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fowó ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Lára àwọn ọ̀nà náà rèé:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan (fixed deposit), tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì wa lẹ́nu iṣẹ́ síkàáwọ́ Watch Tower láti máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí owó náà ṣeé san fún Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni, níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.

Ìpín Ìdókòwò (Shares), Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò (Debenture Stocks) àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó (Bonds): A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta Watch Tower lọ́rẹ.

Ilẹ̀: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà ta Watch Tower lọ́rẹ, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbénú rẹ̀ ni, a lè fi ilé náà sílẹ̀ kí olùtọrẹ náà ṣì máa gbénú rẹ̀ nígbà tó bá ṣì wà láàyè. Kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ ilẹ̀ èyíkéyìí di èyí tó o fi tọrẹ.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Tí A Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jàǹfààní ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Àwọn ọrẹ tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “ọrẹ tí a wéwèé” gba pé kí ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ náà fara balẹ̀ wéwèé wọn.

Tó o bá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, o lè kàn sí Ẹ̀ka Iléeṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o pè wá lórí tẹlifóònù, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

Treasurer’s Office

Jehovah’s Witnesses

P.M.B. 1090,

Benin City 300001,

Edo State, Nigeria.

Telephone: (052) 202020

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn tó ń túmọ̀ ìwé sí èdè Miskito ní ẹ̀ka Nicaragua

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́