Lúùkù—Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Tó Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n
LÚÙKÙ wà ní Róòmù lọ́dún 65 Sànmánì Kristẹni. Ó mọ bó ṣe léwu tó láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọ̀rẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ń jẹ́jọ́ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lòun. Ó jọ pé ẹjọ́ ikú ni wọ́n fẹ́ dá fún Pọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n lákòókò tí nǹkan le koko yẹn, Lúùkù nìkan ṣoṣo ló wà pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—2 Tímótì 4:6, 11.
Orúkọ náà, Lúùkù, kò ṣàjèjì sáwọn tó ń ka Bíbélì torí pé orúkọ yìí ní wọ́n fi pe ìwé Ìhìn Rere tí Lúùkù kọ. Lúùkù bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò lọ sáwọn ibi tó jìnnà gan-an, Pọ́ọ̀lù sì pè é ní “oníṣègùn olùfẹ́ ọ̀wọ́n” àti “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” òun. (Kólósè 4:14; Fílémónì 24) Ìwé Mímọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Lúùkù, kódà ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré ló mẹ́nu kan orúkọ rẹ̀. Àmọ́ tó o bá gbé ohun táwọn olùwádìí sọ nípa Lúùkù yẹ̀ wò, wàá gbà pé èèyàn iyì tí Pọ́ọ̀lù pè é náà ló jẹ́.
Òǹkọ̀wé Bíbélì àti Míṣọ́nnárì Ni
Nígbà tó ti jẹ́ pé Tìófílọ́sì tí Lúùkù kọ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù sí náà ni wọ́n kọ ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì sí, ó ní láti jẹ́ pé Lúùkù ló kọ ìwé méjèèjì tí Ọlọ́run mí sí wọ̀nyẹn. (Lúùkù 1:3; Ìṣe 1:1) Lúùkù ò sọ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi ṣojú òun. Ńṣe ló sọ pé ọ̀dọ̀ àwọn tó rí bó ṣe ṣẹlẹ̀ lòun ti gbọ́ nǹkan tóun kọ, òun sì tún “tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye.” (Lúùkù 1:1-3) Torí náà, ó jọ pé ẹ̀yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Lúùkù di ọmọlẹ́yìn Kristi.
Àwọn kan sọ pé ọmọ ìlú Áńtíókù ní Síríà ni Lúùkù máa jẹ́. Wọ́n ní ìdí ni pé tí Ìwé Ìṣe bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Áńtíókù yìí, ńṣe ló máa ń sọ ọ́ lásọtán. Àti pé nígbà tó ń dárúkọ “ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè,” ó ní ọ̀kan jẹ́ ‘aláwọ̀ṣe ará Áńtíókù’ bẹ́ẹ̀ kò mẹ́nu kan ibi táwọn mẹ́fà tó kù ti wá. Àmọ́, àwa ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé torí pé Áńtíókù yìí jẹ́ ìlú Lúùkù ló ṣe pàfiyèsí síbẹ̀.—Ìṣe 6:3-6.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé Ìṣe ò dárúkọ Lúùkù, ó lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ bí “a,” “àwa” àti “wa” láwọn ibì kan, tó fi hàn pé Lúùkù kópa nínú àwọn kan lára ohun tí ìwé Ìṣe sọ pé ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Lúùkù ń sọ bí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò ṣe rìn ní Éṣíà Kékeré, ó ní: “Wọ́n ré Máísíà kọjá, wọ́n sì sọ̀ kalẹ̀ wá sí Tíróásì.” Tíróásì yìí ni Pọ́ọ̀lù ti rí ará Makedóníà kan lójú ìran tíyẹn sì bẹ̀ ẹ́ pé: “Rékọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” Lúùkù wá sọ pé: “Wàyí o, gbàrà tí ó ti rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Makedóníà.” (Ìṣe 16:8-10) Bí Lúùkù ṣe lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà “a” níhìn-ín dípò “wọ́n” tó lò ṣáájú fi hàn pé òun náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá Pọ́ọ̀lù rìn láti Tíróásì lọ. Lúùkù wá ròyìn bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe lọ ní ìlú Fílípì, ó sì sọ ọ́ lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ yẹn ni. Ó ní: “Ní ọjọ́ sábáàtì, a jáde lọ sẹ́yìn òde ibodè lẹ́bàá odò kan, níbi tí a ń ronú pé ibi àdúrà wà; a sì jókòó, a sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn obìnrin tí wọ́n ti péjọ sọ̀rọ̀.” Ìjíròrò yìí ló mú kí Lìdíà àti gbogbo agboolé rẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà tí wọ́n sì ṣèrìbọmi.—Ìṣe 16:11-15.
Àwọn alátakò dìde sí wọn nílùú Fílípì níbi tí Pọ́ọ̀lù ti lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ìránṣẹ́bìnrin kan tó ń fi “ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́” sàsọtẹ́lẹ̀. Bí àwọn ọ̀gá rẹ̀ ṣe rí i pé ọ̀nà òwò àwọn dí, ṣe ni wọ́n rá Pọ́ọ̀lù àti Sílà mú tí wọ́n lù wọ́n lálùbami tí wọ́n sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Ó jọ pé wọn ò mú Lúùkù ní tiẹ̀, torí pé ńṣe ló kàn sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ tí wọ́n mú. Nígbà tí wọ́n tú Pọ́ọ̀lù àti Sílà sílẹ̀, “wọ́n fún [àwọn ará] ní ìṣírí, wọ́n sì lọ.” Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù wá padà wá sílùú Fílípì ni Lúùkù tún kọ ìwé rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó ti wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àtàwọn yòókù. (Ìṣe 16:16-40; 20:5, 6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Lúùkù dúró sí Fílípì láti bójú tó iṣẹ́ ìwàásù tó ń lọ níbẹ̀.
Ibi Tí Lúùkù Ti Gbọ́ Àwọn Ohun Tó Kọ
Báwo ni Lúùkù ṣe rí àwọn ohun tó kọ sínú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù àti Ìṣe? Nínú ìwé Ìṣe, àwọn ibi tó ti ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé òun gan-an wà níbẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ó tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù láti Fílípì wá sí Jerúsálẹ́mù níbi tí wọ́n tún ti fàṣẹ ọba mú Pọ́ọ̀lù. Nígbà tí wọ́n ń lọ sí Jerúsálẹ́mù yìí, wọ́n dúró fúngbà díẹ̀ lọ́dọ̀ Fílípì ajíhìnrere ní Kesaréà. (Ìṣe 20:6; 21:1-17) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà yẹn ni Lúùkù gbọ́ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Samáríà látẹnu Fílípì, ẹni tó múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀. (Ìṣe 8:4-25) Ọ̀dọ̀ àwọn wo tún ni Lúùkù ti rí ìsọfúnni gbà?
Ó jọ pé ìgbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n ní Kesaréà fún ọdún méjì ni Lúùkù ráyè ṣèwádìí nípa ohun tó kọ sínú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù. Ìtòsí ibẹ̀ sì ni Jerúsálẹ́mù wà, níbi tó ti lè rí àkọsílẹ̀ ìtàn ìlà ìdílé Jésù kà. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí ìwé Lúùkù sọ nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ la ò lé rí nínú ìwé Bíbélì míì yàtọ̀ sí ìwé Lúùkù. Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa Bíbélì tọ́ka sí ibi méjìlélọ́gọ́rin tírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ wà nínú ìwé Lúùkù.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹnu Èlísábẹ́tì ìyá Jòhánù Olùbatisí ni Lúùkù ti gbọ́ ìtàn bó ṣe bí ọmọ rẹ̀ Jòhánù. Ẹnu Màríà ìyá Jésù ló ṣeé ṣe kí Lúùkù ti gbọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtàn nípa bó ṣe bí Jésù àtàwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé. (Lúùkù 1:5–2:52) Ó lè jẹ́ Pétérù, Jákọ́bù tàbí Jòhánù ló sọ ìtàn bí wọ́n ṣe rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja pa lọ́nà ìyanu fún Lúùkù. (Lúùkù 5:4-10) Inú ìwé Lúùkù nìkan la ti lè rí àwọn kan lára àwọn àpèjúwe Jésù, irú bíi ti aláàánú ará Samáríà, gbígba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé, ẹyọ owó dírákímà tó sọ nù, ọmọ onínàákúnàá àti ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ àti Lásárù.—Lúùkù 10:29-37; 13:23, 24; 15:8-32; 16:19-31.
Lúùkù fún ọ̀ràn tó kan àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Ó sọ nípa ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ tí Màríà rú, nípa bí Jésù ṣe jí ọmọ opó kan dìde àti bí obìnrin kan ṣe da òróró sí ẹsẹ̀ Jésù. Ó mẹ́nu kan àwọn obìnrin tó ń ṣèránṣẹ́ fún Kristi, ó sì sọ fún wa pé Màtá àti Màríà gba Kristi lálejò nílé wọn. Ìhìn Rere Lúùkù sọ nípa ìwòsàn obìnrin kan tí àìsàn ti mú kó tẹ̀ kòlòbà, ó sọ ti ọkùnrin kan tó ní àrùn ògùdùgbẹ̀ àti bí àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá ṣe rí ìwẹ̀nùmọ́ gbà. Lúùkù sọ ìtàn Sákéù, ọkùnrin kan tó kéré ní ìrísí tó lọ gorí igi kó bàa lè rí Jésù, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé aṣebi kan tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kristi ronú pìwà dà.—Lúùkù 2:24; 7:11-17, 36-50; 8:2, 3; 10:38-42; 13:10-17; 14:1-6; 17:11-19; 19:1-10; 23:39-43.
Ohun kan wà tó gbàfiyèsí, ìyẹn ni bí ìwé Lúùkù ṣe sọ̀rọ̀ nípa ọgbẹ́ kan tí aláàánú ará Samáríà tí Jésù sọ nínú àkàwé rẹ̀ tọ́jú. Ó dájú pé oníṣègùn tí Lúùkù jẹ́ hàn nínú bó ṣe kọ irú ìtọ́jú tí Jésù sọ pé ará Samáríà náà ṣe, títí kan bó ṣe da wáìnì sójú ọgbẹ́ ọkùnrin náà gẹ́gẹ́ bí oògùn apakòkòrò, tó da òróró sí i, tó sì wá dì í.—Lúùkù 10:30-37.
Lúùkù Tọ́jú Pọ́ọ̀lù Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n
Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ Lúùkù lógún gan-an ni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà látìmọ́lé ní Kesaréà, Fẹ́líìsì ará ilẹ̀ Róòmù tó jẹ́ ajẹ́lẹ̀ Jùdíà pàṣẹ fáwọn agbófinró pé kí wọ́n má ṣe ṣèdíwọ́ fún “ẹnì kankan lára àwọn ènìyàn [Pọ́ọ̀lù] láti ṣèránṣẹ́ fún un.” (Ìṣe 24:23) Ó ṣeé ṣe kí Lúùkù wà lára àwọn tó ń ṣèránṣẹ́ fún un. Pọ́ọ̀lù sábà máa ń ṣàìsàn, nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé títọ́jú tí “oníṣègùn olùfẹ́ ọ̀wọ́n” yìí ń tọ́jú rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan tó gbà ṣèránṣẹ́ fún un.—Kólósè 4:14; Gálátíà 4:13.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ké gbàjarè sí Késárì, Fẹ́sítọ́ọ̀sì ará ilẹ̀ Róòmù tó jẹ́ ajẹ́lẹ̀ Jùdíà wá ní kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ sí ìlú Róòmù. Lúùkù ò padà lẹ́yìn Pọ́ọ̀lù nígbà náà, ńṣe ló bá a rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn yẹn lọ sí Ítálì, ó sì kọ ìtàn bí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ ṣe rì. (Ìṣe 24:27; 25:9-12; 27:1, 9-44) Ìgbà tí wọn ò jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù jáde nílé fún ọdún méjì ní Róòmù ló kọ àwọn lẹ́tà kan tí Ọlọ́run mí sí, ó sì mẹ́nu kan Lúùkù nínú méjì lára wọn. (Ìṣe 28:30; Kólósè 4:14; Fílémónì 24) Ó sì jọ pé àárín ọdún méjì yẹn náà ni Lúùkù kọ ìwé Ìṣe.
Ńṣe ni ìgbòkègbodò tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn á máa lọ ní pẹrẹu nílé tí Pọ́ọ̀lù ń gbé ní Róòmù. Ibẹ̀ ni Lúùkù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pọ́ọ̀lù míì á ti bára pàdé, àwọn bíi Tíkíkù, Àrísítákọ́sì, Máàkù, Jọ́sítù, Epafírásì, Ónẹ́símù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.—Kólósè 4:7-14.
Nígbà tí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì, tó sì ń fura pé wọ́n ò ní pẹ́ pa òun, ńṣe ni Lúùkù onígboyà dúró tì í gbágbáágbá bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn yòókù fi í sílẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kí Lúùkù mọ̀ pé wọ́n lè torí wíwà tóun wà níbẹ̀ mú òun, síbẹ̀ kò kúrò. Bóyá òun gan-an ló tiẹ̀ bá Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà kan tí Pọ́ọ̀lù ti sọ pé: “Lúùkù nìkan ṣoṣo ni ó wà pẹ̀lú mi.” Ìtàn fi hàn pé kò pẹ́ sígbà náà ni wọ́n bẹ́ Pọ́ọ̀lù lórí.—2 Tímótì 4:6-8, 11, 16.
Lúùkù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ẹ̀dá tó ṣe tán láti lo ara ẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. Kò wá bó ṣe máa gbógo ara ẹ̀ yọ tàbí bó ṣe máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọ̀mọ̀wé gidi lòun. Ó lè jókòó ti iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn tó bá fẹ́, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ló gbájú mọ́. Ẹ jẹ́ ká ṣe bíi ti Lúùkù, ká máa sa gbogbo ipá wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere, ká sì máa fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn wa lọ́nà tí yóò gbé Jèhófà ga.—Lúùkù 12:31.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
TA NI TÌÓFÍLỌ́SÌ?
Tìófílọ́sì ni Lúùkù kọ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù àti ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì sí. Ìwé Lúùkù pe ọkùnrin náà ní “Tìófílọ́sì ẹni títayọlọ́lá jù lọ.” (Lúùkù 1:3) Irú èdè ọ̀wọ̀ bí “ẹni títayọlọ́lá jù lọ” ni wọ́n sábà máa ń lò fáwọn ọlọ́lá àtàwọn lọ́gàálọ́gàá nínú ìjọba Róòmù. Ohun tí Pọ́ọ̀lù pe Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó jẹ́ ajẹ́lẹ̀ ilẹ̀ Jùdíà nígbà ìjọba Róòmù náà nìyẹn.—Ìṣe 26:25.
Ó jọ pé Tìófílọ́sì ti gbọ́ nípa Jésù, ó sì fẹ́ mọ̀ sí i. Lúùkù gbà gbọ́ pé ìwé Ìhìn Rere tóun kọ á jẹ́ kí Tìófílọ́sì “lè mọ̀ ní kíkún, ìdánilójú àwọn ohun tí a ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ ọ.”—Lúùkù 1:4.
Ọ̀mọ̀wé Richard Lenski tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa ọ̀nà ìgbàkọ̀wé lédè Gíríìkì sọ pé kò dájú pé Tìófílọ́sì tíì di onígbàgbọ́ nígbà tí Lúùkù pè é ní “ẹni títayọlọ́lá jù lọ” nítorí pé “nínú gbogbo ìwé táwọn Kristẹni kọ, . . . kò sí Kristẹni kankan tó pe Kristẹni bíi tiẹ̀ láwọn orúkọ oyè bẹ́ẹ̀.” Nígbà tí Lúùkù máa wá kọ ìwé Ìṣe, kò lo orúkọ oyè náà, “ẹni títayọlọ́lá jù lọ” mọ́. Ohun tó kàn fi bẹ̀rẹ̀ ni: “Tìófílọ́sì.” (Ìṣe 1:1) Ìyẹn ni Lenski fi wá sọ pé: “Nígbà tí Lúùkù kọ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù sí Tìófílọ́sì, ọkùnrin ọlọ́lá yìí ò tíì di Kristẹni, àmọ́ ó fẹ́ láti mọ̀ nípa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni gan-an; ṣùgbọ́n nígbà tí Lúùkù fi máa kọ ìwé Ìṣe sí Tìófílọ́sì, ó ti di onígbàgbọ́.”