Ǹjẹ́ Jésù Ní Bíbélì Nígbà Tó Wà Láyé?
RÁRÁ o, Jésù kò ní Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà ayé Jésù, kò sí odindi Bíbélì bí irú èyí tá a ní lónìí. Àmọ́, àwọn àkájọ ìwé máa ń wà láwọn sínágọ́gù, àwọn ohun tí wọ́n kọ sínú wọn ló sì di apá kan Bíbélì tá a mọ̀ lónìí. Jésù ka àkájọ ìwé Aísáyà ní sínágọ́gù ti Násárétì. (Lúùkù 4:16, 17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ “kíka Òfin àti ìwé àwọn Wòlíì ní gbangba” ní Áńtíókù ti Písídíà. (Ìṣe 13:14, 15) Bákan náà ni Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé wọ́n máa ‘ń ka àwọn àkọsílẹ̀ Mósè sókè nínú àwọn sínágọ́gù ní gbogbo sábáàtì.’—Ìṣe 15:21.
Ǹjẹ́ àwọn èèyàn kan ní ọ̀rúndún kìíní tiẹ̀ ní àwọn àkájọ Ìwé Mímọ́? Ó hàn gbangba pé ìwẹ̀fà ará Etiópíà tó ń ṣiṣẹ́ láàfin Ọbabìnrin Káńdésì ní in, nítorí pé “ó jókòó sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì ń ka ìwé wòlíì Aísáyà sókè” nígbà tí Fílípì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ bá a lójú ọ̀nà tó lọ sí Gásà. (Ìṣe 8:26-30) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ fún Tímótì pé kó kó “àwọn àkájọ ìwé” wá fóun, “ní pàtàkì àwọn ìwé awọ.” (2 Tímótì 4:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù kò sọ irú àwọn àkájọ ìwé tí wọ́n jẹ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ apá kan Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Alan Millard tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú èdè Hébérù, èdè Árámáíkì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ṣe sọ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kìkì àwọn tó ní àkájọ Ìwé Mímọ́ láàárín àwọn Júù ni “àwọn èèyàn pàtàkì ilẹ̀ Palẹ́sìnì, àwọn tó pe ara wọn ní ọ̀mọ̀wé, àwọn kan lára àwọn Farisí, àtàwọn olùkọ́, irú bíi Nikodémù.” Ọ̀kan lára ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé ó gbówó lórí gan-an nígbà náà. Millard fojú bù ú pé, yóò tó “owó dínárì mẹ́fà sí mẹ́wàá tí wọ́n ń ta ẹ̀dà kan ìwé Aísáyà” ó sì sọ pé láti ṣe odindi Bíbélì èdè Hébérù kan, “yóò gbà tó àkájọ ìwé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún,” ìyẹn ni pé yóò náni tó ìdajì owó iṣẹ́ ọdún kan.
Bíbélì kò sọ bóyá Jésù tàbí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkájọ ìwé tó jẹ́ Bíbélì tiwọn fúnra wọn. Àmọ́ kò sí àní-àní pé Jésù mọ Ìwé Mímọ́ gan-an, ó lè tọ́ka sáwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, ó sì lè sọ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ látorí. (Mátíù 4:4, 7, 10; 19:4, 5) Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí fún wa níṣìírí láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì dáadáa, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iye tí wọ́n ń tà á kì í fi bẹ́ẹ̀ wọ́n, ó sì rọrùn láti rí?