Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ojú wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi wo iṣẹ́ ọdẹ àti iṣẹ́ ẹja pípa?
Bíbélì kò sọ pé iṣẹ́ ọdẹ tàbí iṣẹ́ ẹja pípa burú. (Diutarónómì 14:4, 5, 9, 20; Mátíù 17:27; Jòhánù 21:6) Síbẹ̀, ó yẹ káwọn Kristẹni tó ń ṣiṣẹ́ ọdẹ tàbí iṣẹ́ ẹja pípa ronú lórí àwọn ìlànà bíi mélòó kan nínú Ìwé Mímọ́.
Ọlọ́run fàyè gba Nóà àtàwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ láti pa ẹran kí wọ́n sì jẹ̀ ẹ́, bí wọ́n bá sáà ti ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù kí wọ́n tó jẹ ẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Àṣẹ yìí jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé ó yẹ ká ka ìwàláàyè ẹran sí ohun pàtàkì tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni kò fi ń pa ẹran ṣeré tàbí kí wọ́n máa pa wọ́n nípakúpa.—Òwe 12:10.
Ohun kan tún wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò lórí kókó yìí, ìyẹn ni èrò tiwa fúnra wa. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú àwọn àpọ́sítélì tí wọ́n jẹ́ apẹja máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá rí ẹja tó pọ̀ pa. Síbẹ̀, kò sí ohunkóhun tó fi hàn pé wọ́n fọ́nnu pé àwọn mọ ẹja pa dáadáa tàbí pé àwọn mọ iṣẹ́ ọdẹ ṣe gan-an. Kò sì sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n ṣe é láti bá àwọn ẹlòmíràn díje, láti fi hàn pé akọni làwọn, tàbí láti fi hàn pé lílépa ẹran, kíkápá rẹ̀, àti pípa á máa ń múnú àwọn dùn.—Sáàmù 11:5; Gálátíà 5:26.
Nípa báyìí, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé èmi náà ní irú èrò tí Jèhófà ní nípa ìwàláàyè? Ṣé iṣẹ́ ẹran pípa tàbí ẹja pípa ló gbà mí lọ́kàn tàbí òun ni mo máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣáá? Ǹjẹ́ bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé pípẹja tàbí pípẹran lohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí jù, àbí ó fi hàn pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni mí? Ǹjẹ́ iṣẹ́ ẹran pípa tàbí iṣẹ́ ẹja pípa máa ń mú kí n máa bá àwọn aláìgbàgbọ́ kẹ́gbẹ́ tàbí kì í jẹ́ kí n ráyè gbọ́ ti ìdílé mi?’—Lúùkù 6:45.
Àwọn kan tó máa ń pẹja tàbí pa ẹran fún jíjẹ lè máa rò pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn pa ìpàdé tàbí òde ẹ̀rí tì lákòókò tí wọ́n máa ń rí ẹran tàbí ẹja pa gan-an. Àmọ́, nígbà tá ò bá fi ohunkóhun ṣáájú ìfẹ́ Ọlọ́run, ńṣe là ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run a sì gbẹ́kẹ̀ lé e. (Mátíù 6:33) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Kristẹni máa ń pa gbogbo òfin “Késárì” mọ́ lórí ọ̀ràn pípa ẹran tàbí pípa ẹja, yálà àwọn aláṣẹ á mú ẹni tó bá rú òfin náà tàbí wọn ò ní mú un.—Mátíù 22:21; Róòmù 13:1.
Láti lè máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu lórí ọ̀ràn ẹran pípa tàbí ẹja pípa, ó lè gba pé káwọn kan yí èrò wọn padà kó lè bá ìlànà Ọlọ́run mu. (Éfésù 4:22-24) Síbẹ̀, kò yẹ ká ṣàríwísí ìpinnu táwọn ẹlòmíràn bá ṣe nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni ní ìmọ̀ràn tó dára gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Kí a má ṣe máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́ lẹ́nì kìíní-kejì, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ fi èyí ṣe ìpinnu yín, láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí okùnfà fún ìgbéniṣubú sí iwájú arákùnrin.” (Róòmù 14:13) Fífi irú ìfẹ́ tó jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ hàn àti ọ̀wọ̀ máa ń jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ìjọ, ó sì máa ń múnú Ẹlẹ́dàá wa dùn, Ẹni tó dá ohun gbogbo.—1 Kọ́ríńtì 8:13.a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tún wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti May 15, 1990.