“Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Gan-an”
Ọ̀RỌ̀ tó wà lókè yìí ni ẹnì kan tó jẹ́ olórí ìjọba Belgium tẹ́lẹ̀ rí fi ṣàpèjúwe ìwé náà, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí.a Aládùúgbò rẹ̀ kan ló wá sílé rẹ̀ tó sì fún un ní ìwé yìí. Ó wá kọ lẹ́tà láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ ọkùnrin náà. Lẹ́tà náà kà pé: “Wíwá tẹ́ ẹ wá sílé mi lọ́jọ́sí wú mi lórí gan-an ni. Ohun tó sì mú kó túbọ̀ wú mi lórí ni ẹ̀bùn tó ṣeyebíye gan-an tẹ́ ẹ fún mi, ìyẹn ìwé tó dá lórí ‘Ọkùnrin Títóbilọ́lá Jù Lọ.’”
Olórí ìjọba tẹ́lẹ̀ rí yìí ti kàwé náà dáadáa, ìyẹn ló fi sọ pé: “Bí gbogbo èèyàn bá lè gbé ohun tó wà nínú ìwé Ìhìn Rere yẹ̀ wò dáadáa kí wọ́n sì máa fi àwọn ìlànà tí Jésù Kristi fi kọ́ni ṣèwà hù, ayé ì bá má rí bó ṣe rí yìí. A ò ní nílò Ìgbìmọ̀ Ààbò Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Dá Sílẹ̀, kì bá má sáwọn apániláyà, ìwà ipá gan-an ò tiẹ̀ ní sí láyé.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlá tí ò lè ṣẹ ló ka gbogbo ohun tó sọ yìí sí, ìbẹ̀wò tí aládùúgbò rẹ̀ ṣe wú u lórí gan-an ni.
Lẹ́tà ọ̀gbẹ́ni yìí ń bá a lọ pé: “Ó yẹ ká gbóríyìn fún yín, torí àwùjọ èèyàn tó fẹ́dàá fẹ́re ni yín. Ẹ kì í ṣàwọn tó gbà gbọ́ pé nǹkan máa dáa láìsapá rárá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì í ṣàwọn tó gbà gbọ́ pé nǹkan ò lè dáa rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ gbà gbọ́ pé èèyàn lè sapá láti mú kí ayé yìí dára.”
Ìgbàgbọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú kí ayé yìí dára, kì í ṣe ọmọ èèyàn. Àpẹẹrẹ Jésù Kristi, ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé. Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá ọ wá láìpẹ́ yìí? Tó o bá gbà wọ́n láyè, ẹ óò jọ ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó lárinrin nípa ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí. Inú wọn á dùn láti fún ẹ ní ìwé tí wọ́n fún olórí ìjọba tẹ́lẹ̀ rí náà tó sì wú u lórí gan-an.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.